Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ojú láti Rí
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Àwọn Ojú láti Rí

Nípa agbára ti Ẹ̀mí Mímọ́, Krístì yio ró wa ní agbára láti rí ara wa àti láti rí àwọn ẹlòmíràn bí Òun ti ṣe.

Rírí Ọwọ́ Ọlọ́run

Mo fẹ́ràn ìtàn ọ̀dọ́mọkùnrin kan nínú Májẹ̀mu Láéláé ẹnití ó sin wòlíì Èlíshà. Ní kùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kan ọ̀dọ́mọkùnrin náà ta jí, ó bọ́ sóde, ó sì ríi pé a ti yí ìlú náà ká pẹ̀lú ọ̀wọ́ ogun nlá kan ní èrò láti pa wọ́n run. Ó sáré tọ Èlíṣà lọ: “Áà, ọ̀gá mi! Báwo ni àwa ó ṣe?”

Èlíṣà dáhùn pé, “Má bẹ̀rù, nítorí àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú wọn.”

Èliṣà mọ̀ pé ọ̀dọ́mọkùnrin náà nílò ju ìdánilójú tí nfini lára balẹ̀ lọ; ó nílò ìran. Àti nítorínáà “Eliṣa gbàdúrà, … Olúwa, … la ojú rẹ̀ kí ó le ríran. Olúwa sí la ojú ọ̀dọ́mọkùnrin náà; òun sì rí: àti pé, kíyèsíi, orí òkè náà kún fún àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ti iná yíká kiri Èlíṣà.”1

Àwọn àkókò kan le wà nígbàtí ìwọ, bíi ìránṣé náà, nrí ara rẹ ní títiraka láti ríi bí Ọlọ́run ti nṣiṣẹ́ nínú ayé rẹ—àwọn àkókò nígbàtí ìwọ ní ìmọ̀lára wíwà ní abẹ́ ìdènà—nígbàtí àwọn àdánwò ayé kíkú bá mú ọ wá sí orí eékún rẹ. Dúró kí o sì ní ìgbẹ̀kẹ̀lé nínú Ọlọ́run àti àkókò síṣe Rẹ̀, nítorípé o le gbẹ́kẹ̀lé ọkàn Rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo tìrẹ. Ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ kejì kan wà níhin yi. Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ̀yin náà le gbàdúrà fún Olúwa láti la ojú yín láti rí àwọn ohun tí ẹ kò leè rí lásán.

Rírí Ara Wa bí Ọlọ́run Ti Rí Wa

Bóyá àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ fún wa láti rí kedere ni ẹnití Ọlọ́run í ṣe àti ẹnití àwa jẹ́ gan an—àwa ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ti àwọn òbí ọ̀run pẹ̀lú “àdánidá àtọ̀runwá àti àyànmọ́ ayérayé kan.”2 Ẹ sọ fún Ọlọ́run kí ó fi àwọn òtítọ́ wọ̀nyí hàn sí yín, papọ̀ pẹ̀lú irú ìmọ̀lára tí Ó ní nípa yín. Bí ẹ bá ti nní òye ìdánimọ̀ yín tòótọ́ síi àti èrò, jinlẹ̀ dé ọkàn, bẹ́ẹ̀ ni yío máa ní ipá lórí ohun gbogbo nínú ìgbé ayé yín.

Rírí Àwọn Ẹ̀lòmíràn

Níní òye bí Ọlọ́run ti rí wa npèsè ọ̀nà láti ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ẹlòmíràn bí Òun ti ṣe. Olùkọ̀wé David Brooks sọ pé: “Púpọ̀ nínú àwọn ìṣòro nla ti àwùjọ wa nwá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọn kò ní ìmọ̀lára rírí àti mímọ̀ wọ́n. … [Kókó àbùdá kan] wà … tí gbogbo wa nílati ṣe … dáadáa síi nínú rẹ̀[, àti pé èyí] ni àbùdá rírí àwọn ẹlòmíràn jinlẹ̀ àti kí a jẹ́ rírí jinlẹ̀.”3

Jésù Krístì rí àwọn ènìyàn jìnlẹ. Ó rí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan, àwọn àìní wọn, àti ẹni tí wọ́n le dà. Níbí tí àwọn ẹlòmíràn ti rí àwọn apẹja, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn agbowó òde, Jésù rí àwọn ọmọ ẹ̀hìn; níbi tí àwọn ẹlòmíràn ti rí okùnrin kan tí ó ní ẹmí èṣù, Jésù wò kọjá ìrora àfojúrí, ó gbà á, ó sì wò ó sàn.4

Àní nínú ìgbé ayé wa tí ọwọ́ dí, a lè tẹ̀lé àpẹrẹ ti Jésù kí a sì rí àwọn ẹnikọ̀ọ̀kan—àwọn àìní wọn, ìgbàgbọ́ wọn, ìtiraka wọn, àti ẹni tí wọ́n le dà.5

Bí mo ti gbàdúrà kí Olúwa la ojú mi láti rí àwọn ohun tí mo lè má tilẹ̀ rí déédé, mo bì ara mi léérè àwọn ìbèèrè méjì mo sì kọjúsí àwọn ìsàmìsọ́kàn tí o wá: “Kíni mo nṣe tí o´ yẹ kí nfisílẹ̀ ní ṣíṣe?” àti pé “Kíni àwọn ohun tí èmi kò ṣe tí o´ yẹ́ kí nbẹ̀rẹ̀ síi ṣe?”6

Ní àwọn oṣù sẹ́hìn, nínú ìsìn oúnjẹ, mo bi ara mi ní àwọn ìbéèrè wọ̀nyí mo ní ìyanu nípasẹ̀ ìmọ̀lára tí ó wá. “Dáwọ́ wíwo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ dúró nígbàtí o bá ndúró lórí ìlà.” Wíwo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi lórí ìlà ti fẹ́rẹ̀ di bárakú; mo rí i bí àsìkò rere kan láti ṣe ohun miràn, láti lé àwọn iwé ifiránṣẹ́ mi bá, láti wo àwọn àkòrí, tàbí wo ohun tí ó wà lóri àwùjọ ayélujára.

Ní òwúrọ̀ tí ó tẹ̀lé, mó rí ara mi ní dídúró lórí ìlà gígùn kan ní ilé ìtajà. Mo fa fóònù mi síta àti nígbànáà mo rántí ìmọ̀lára tí mo ti gbà. Mo fi fóònù mi sí ibikan mo sì wò àyíká. Mo rí àgbàlagbà ọkùnrin kan ní ori ilà níwájú mi. Kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ṣófo bíkòṣe fún àwọn agolo díẹ̀ ti ounjẹ ológbò. Mo ní ìmọ̀lára tí kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n mo wí ohun kan nítòótọ́ tí ó dàbí ọgbọ́n, “Mo ríi pé o ní ológbò.” Ó sọ pé ìjì kan nbọ̀wá, àti pé kò fẹ́ kí ó ká òun mọ́ láìní ounjẹ ológbò. A sọ̀rọ̀ ní kúkúrú, àti lẹ́hìnnáà ó yí sími ó sì wí pé, “O mọ̀, èmi kò tíi sọ èyí fún ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n òní ni ọjọ́ ìbí mi.” Ọkàn mi yọ́. Mo kí i kú ewu ọjọ́ ìbí mo sì gba àdúra jẹ́jẹ́ ti ìdúpẹ́ pé èmi kò ti wà ní orí fóònù mi kí nsì pàdánù ànfààní kan láti rí nítòótọ́ kí nsì ní àsopọ̀ pẹ̀lú ènìyàn míràn kan tí ó nílò rẹ̀.

Pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi èmi kò fẹ́ dà bíi àlùfáà tàbí ara Léfì ní ojú ọ̀nà sí Jẹ́ríkò—ẹni tí ó wò tí ó sì kọjá lọ.7 Ṣùgbọ́n ní ìgbà púpọ̀ mo rò pé mo rí bẹ́ẹ̀.

Rírí Iṣẹ́-Rírán ti Ọlọ́run fún Mi

Láìpẹ́ yi mo kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó níyelórí kan nípa rírí jinlẹ̀ láti ara ọ̀dọ́mọbìnrin kan ti orúkọ rẹ̀ njẹ́ Rozlyn.

Ìtàn yí ni a pín pẹ̀lú mi láti ọwọ́ ọ̀rẹ́ mi ẹnití ó dabarú nígbàtí ọkọ rẹ̀ fún ogún ọdún kó jáde níle. Pẹ̀lú bí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe npín àkókò láàrin àwọn òbí, ìrètí àti dá lọ sí ilé ìjọsìn dàbíi bíbanilẹ́rù. Ó ṣèrántí:

“Nínú ìjọ níbití ẹbí ti jẹ́ kókó pàtàkì, dídá jókòó le roni lára. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àkọ́kọ́ mo rìn wọlé ní gbígbàdúrà pé kí ẹnikẹ́ni má sọ̀rọ̀ sí mi. Mo nfi agídi mú un papọ̀, súgbọ́n omijé ti dé bèbè ojú. Mo jókòó ní ibi ààyè mi, pẹ̀lú ìrètí pé ẹnikẹ́ni kò ní fura sí bí ìjókòó náà ṣe dàbí pé ó ṣófo.

“Ọ̀dọ́mọbìnrin kan ní wọ́ọ̀dù wa yí ó sì wò mí. Mo díbọ́n pé mo rẹ́rĩn músẹ́. Ó rẹrín músẹ́ padà. Mo lè rí àníyàn ní ojú rẹ̀. Mo bẹ̀bẹ̀ ní ìdákẹ́jẹ́ pé kò ní wá láti bá mi sọ̀rọ̀—èmi kò ní ohunkóhun gidi kan láti sọ mo sì mọ̀ pé èmi ó sunkún. Mo wo ilẹ̀ padà sí orí ẹsẹ̀ mi mo sì yẹra fún kí ojú pàdé.

“Ní ààrin wákàtí tí ó kàn, mo fura pé ó nwò mí padà ní ẹ̀ẹ̀kọ̀kan. Ní kété bí ìpàdé náà ti parí, ó wá tààrà sí ọ̀dọ̀ mi. ‘Pẹ̀lẹ́ Rozlyn,’ mo sọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́. Ó ró àwọn apá rẹ̀ mọ́ mi lára ó sì sọ pé, ‘Arábìnrin Smith, mo le sọ pé òní jẹ́ ọjọ́ búrúkú fún ọ. Mo kàánú púpọ̀ Mo nifẹ rẹ.’ Bí mo ṣe ròó síwájú, àwọn omijé wá bí ó ṣe gbàmí mọ́ra lẹ́ẹ̀kansíi. Ṣùgbọ́n bí mo ti rìn kúrò, mo ròó sí ara mi pé, “Bóyá mo le ṣe èyí ṣá.”

Àwòrán
Rozlyn àti Arábìnrin Smith

“Ọ̀dọ́mọbìnrin dídùn náà ẹni-ọdún-mẹ́rìndínlógún, tí kò tó ìlàjì ọjọ́ orí mi, wá mi rí ní gbogbo Ọjọ́ Ìsinmi fún ìyókù ọdún náà láti gbà mí mọ́ra àti láti bèèrè pé, ‘Báwo ni o?’ Ó mú ìyàtọ̀ wá tó bẹ́ẹ̀ nínú irú ìmọ̀lára tí mo nní nípa wíwá sí ilé ìjọsìn. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé mo bẹ̀rẹ̀ sí gbáralé àwọn ìgbàmọ́ra wọnnì. Ẹnìkan fura sí mi. Ẹnìkan mọ̀ pé mo wà níbẹ̀. Ẹnìkan ṣàníyàn,”

Bíi ti gbogbo àwọn ẹ̀bùn tí Baba fi lélẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ inú tó bẹ́ẹ̀, rírí jinlẹ̀ nílò wa láti béèrè lọ́wọ Rẹ̀—àti nígbànáà gbé ìgbésẹ̀. Béèrè láti rí àwọn ẹlòmíràn bí Òun ti ṣe—àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Rẹ̀ tòótọ́ pẹ̀lú agbára àìlópin àti àtọ̀runwá. Lẹ́hìnnáà gbé ìgbésẹ̀ nípa fífẹ́ni, sísìn, àti fífi ẹsẹ̀ yíyẹ àti líleṣe wọn múlẹ̀ bí a ti mí síi yín. Bí èyí ti ndi àwórán ìgbé ayé wa, a ó rí ara wa pé a ndi “àtẹ̀lé tòótọ́ ti … Jésù Krístì.”8 Àwọn ẹlòmíràn yío le gbẹ́kẹ̀lé ọkàn wa pẹ̀lú tiwọn. Àti pé nípa àwòrán yi awa bákannáà yío le ṣe àwárí ìdánimọ̀ àti èrò òtítọ́ tiwa.

Àwòrán
Ìwonisàn Olùgbàlà

Ọ̀rẹ́ mi rántí ìrírí miràn nígbàtí ó jókòó nínú píù síṣófo yi kannáà, ní òun nìkan, tí nrò bóyá akitiyan ogún ọdún láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere nínú ilé rẹ̀ bá jẹ́ gbogbo rẹ̀ fún asán. Ó nílò ju ìdánilójú fífi ara ẹni balẹ̀ lọ; ó nílò ìran. Ó ní ìmọ̀lára pé ìbéèrè kan gún ọkàn rẹ̀: “Kínni ìdí tí o fi ṣe àwọn nkan wọnnì? Njẹ́ o ṣe wọ́n fún èrè, fún ìyìn àwọn ẹlòmíràn, tàbí fún ìyọrísí ìfẹ́ inú?” Ó lọ́ra fún ìgbà díẹ̀, ó wá inú ọkàn rẹ̀, àti lẹ́hìnáà ó le dáhùn pẹ̀lú ìdánilójú pé, “mo ṣe wọ́n nítorípé mo fẹ́ràn Olùgbàlà. Mo sì fẹ́ràn ìhìnrere Rẹ̀.” Olúwa la ojú rẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́ láti ríran. Ìyípadà ìran tó rọrùn ṣùgbọ́n tó lágbára yi ràn án lọ́wọ́ ní títẹ̀síwájú láti máa tìí lọ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì, láìka àwọn ipò rẹ̀ sí.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì fẹ́ràn wa Ó sì le fún wa ní ojú láti rí—àní nígbàtí ó le, àní nígbàtí ó rẹ̀ wá, àní nígbàtí a nìkan wà, àti àní nígbàtí àwọn àyọrísí kò jẹ́ ohun tí a ti ní ìrètí. Nípa oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀, Òun yíò bùkún wa yíò sì mú agbára wa lékún síi. Nípa agbára ti Ẹ̀mí Mímọ́, Krístì yio ró wa ní agbára láti ara wa àti láti àwọn ẹlòmíràn bí Òun ti ṣe. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, a lè mọ ohun tí o wúlò jùlọ. A lè bẹ̀rẹ̀ sí rí ọwọ́ Olúwa tí ó nṣiṣẹ́ nínú àti nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ lásán ti ìgbé ayé wa—a ó rí jinlẹ̀.

Àti nígbànáà, ní ọjọ́ nlá náà “nigbàtí òun yío fi ara hàn àwa ó dàbí rẹ̀, nítorí àwa yío rí i bí ó tí rí; pé kí a lè ní ìrètí yi”9 ni àdúrà mi ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. 2 Àwọn Ọba 6:15–17.

  2. Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrinChurchofJesusChrist.org.

  3. David Brooks, “Rírí Ọ̀nà Sí Ìwà” (Brigham Young University forum address, Oct. 22, 2019), speeches.byu.edu.

  4. Wo Mark 5:1-15.

  5. “Ó jẹ́ ohun tí ó ṣe kókó láti gbé nínú àwùjọ àwọn tí ó ṣeéṣé láti jẹ́ ọlọ́run àti ọlọ́runbìnrin, láti rántí pé ẹnìkan tí tí kò jáfáfá jùlọ … tí ko sì wuni jùlọ láti bá sọ̀rọ̀ le fi ọjọ́ kan jẹ́ ẹ̀dá kan tí, bí o bá rí i nísisìyí, ìwọ ó ní àdánwò lílágbára láti. … Kò sí àwọn ènìyàn lásán” (C. S. Lewis, Ìwọ̀n ti Ogo [2001], 45–46).

  6. Kim B. Clark, “A Yí Wọn Ká Nípa Iná” ( Seminaries and Institutes of Religion Satellite Broadcast, Aug. 4, 2015), ChurchofJesusChrist.org.

  7. Wo Lúkù 10:30–37.

  8. Mórónì 7:48.

  9. Mórónì 7:48; àfikún àtẹnumọ́.