Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Dídúró de Olúwa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Dídúró de Olúwa

Àmì náà ni pé ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run ní àwọn ìgbà rere àti ibi, àní bí ìyẹn bá tilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjìyà títí tí a ó fi rí ọwọ́ Rẹ̀ hàn ní ìtilẹhìn wa.9

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin, gbogbo wa nyára—kò sí ẹnìkan ju èmi lọ—láti gbọ́ ìparí ọ̀rọ̀ látẹnu àyànfẹ́ wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson. Èyí ti jẹ́ ìpàdé àpapọ̀ tó yanilẹ́nu, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìgbà kejì ti àrùn COVID-19 ti ba àṣà ìtẹ̀síwájú wa jẹ́. Ìkóràn yí ti sú wa tí a fi ní ìmọ̀lára bí ẹnipé irun wa ntu jáde. Ó hàn gbangba, pé àwọn kan lára Arákùnrin mi ti gba ọ̀nà ìṣe náà. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé a ngbàdúra léraléra fún àwọn tí ó ti kàn ní ọ̀nàkọnà, nípàtàkì fún ẹnikẹ́ni tí ó ti pàdánù àwọn olólùfẹ́. Gbogbo ènìyàn faramọ pé èyí ti wa tipẹ́, tipẹ́tipẹ́ púpọ̀.

Báwo ni a ó ṣe dúró fún ìrànlọ́wọ́ tó látinu àwọn ìṣòrò tí ó nwá sórí wa? Báwo ni fífarada àwọn àdánwò araẹni wa nígbàtí a bá ndùrò tí à ndúró ṣe lè dàbí ìrànlọ́wọ́ lọ́ra ní wíwá? Kíni ìdí ìfàsẹ́hìn nígbàtí ó dàbí àwọn àjàgà pọ̀ ju bí a ti lè faramọ?

Nígbàtí a bá bèèrè irú ìbèèrè bẹ́ẹ̀, a lè, gbọ́ igbe aruwo ẹlòmíràn látinú òkùnkùn, òkùnkùn ọgbà ẹ̀wọ̀n ní àárín ìgbà òtútù tó tutù jùlọ nígbànáà lórí àkọsílẹ̀ ní ibi náà.

“Áà Ọlọ́run, níbo ni ìwọ wà?” ni a gbọ́ látinú jíjìn Ẹ̀wọ̀n Líberty. “Níbo ni ágọ́ tí ó bo ibi ìpamọ́ rẹ̀ wà? Yíò ti pẹ́ tó tí ìwọ yíò dá ọwọ́ rẹ dúró?”1 Yíò ti pẹ́ tó, Áà Olúwa, yíò ti pẹ́ tó?

Nítorínáà, a kìí ṣe àkọ́kọ́ tàbí kí a jẹ́ ìgbẹ̀hìn láti bèèrè irú ìbèèrè bẹ́ẹ̀ nígbàtí ìkorò bá wá sílẹ̀ sórí wa tàbí tí ìrora kan nínú ọkàn wa bá nlọ síwájú àti síwájú si. Èmi kò sọ̀rọ̀ àjàkàlẹ̀ àrùn tàbí ẹ̀wọ̀n nísisìyí ṣùgbọ́n nípa yín, ẹbí yín, àti àwọn aladugbo yín tí wọ́n ndojúkọ oyekóye àwọn ìpènijà. Mo sọ̀rọ̀ nípa ìyára àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n fẹ́ ṣe ìgbeyáwó tí wọn kò lè ṣe tàbí tí wọ́n ṣe ìgbeyàwó tí wọ́n rò pé ìbáṣepọ̀ wọn ìbá jẹ́ ti sẹ̀lẹ́stíà si. Mo nsọ̀rọ̀ nípa àwọn wọ̀nnì tí ó ní láti dojúkọ híhàn àìfẹ́ ti ipò ìlera nlá kan—bóyá ọ̀kan tí kò ṣeé wòsàn—tàbí tí ó dojúkọ ìjà ìgbà pípẹ́ pẹ̀lú àrùn-ìdílé tí kò ní ìtọ́jú rárá. Mo nsọ̀rọ̀ nípa ìlàkàkà tí ó ntẹ̀síwájú pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn àti àwọn ìpenija àìlera ọpọlọ tó wúwo lórí ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n njìyà pẹ̀lú wọn, àti lórí ọkàn àwọn tí wọ́n nifẹ tí wọ́n sì njìyà pẹ̀lú wọn. Mo nsọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀tọ̀ṣì, ẹnití Olùgbàlà wí fún wa pé kí a máṣe gbàgbé, mo sì nsọ̀rọ̀ nípa yín tí ẹ̀ ndúró dé ìpadàbọ̀ ọmọ kan, bí ó ti wù kí ọjọ́ orí wọn tó, ẹnití ó ti yan ipa ọ̀nà tí ó yàtọ̀ kúró ní èyí tí ẹ gbàdúrà kí ọkùnrin tàbí obìnrin náà gbà.

Síwájú síi, mo jẹ́wọ́ pé àní àwọn ìto lẹ́sẹẹsẹ gígùn yí fún èyí tí a lè dúró níti-ara tí kò gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ ìṣúná títóbi, òṣèlú, àti àníyàn àwùjọ tí ó ndojúkọ wá papọ̀. Baba wa ní Ọ̀run nretí kí a dásí àwọn ọ̀rọ̀ dìdunni gbangbà bákannáà bí ti àwọn araẹni, ṣùgbọ́n àwọn ìgbà kan yíò wà nínú ayé wa àní nígbàtí ìtiraka ti ẹ̀mí wa jùlọ àti ìtara, àwọn àdúrà ẹ̀bẹ̀ ko ní mú ìṣẹ́gun èyí tí à nfẹ́ jáde, bóyá ní ìkàsí àwọn ọ̀ràn títóbi àgbáyé tàbí àwọn kékeré ti araẹni. Nítorínáà nígbàtí a bá ṣiṣẹ́ tí a sì dúró papọ̀ fún ìdáhùn sí àwọn àdúra wa, mo fún yín ní ìlérí ti-àpóstélì mi pé wọ́n má gbọ́ wọn sì máa dáhùn si, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bóyá kìí ṣení ìgbà tàbí ọ̀nà tí ẹ fẹ́. Ṣùgbọ́n a máa gba ìdáhùn sí wọn nígbàgbogbo ní ìgbà àti nínú ọ̀nà àrà àti àánú ayérayé tí àwọn òbí gbọ́dọ̀ dá wọn lóhùn. Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ní ìmọ̀ pé Ẹni tí kìí sùn tí kìí tòògbé2 nṣe ìtọ́jú fún ìdùnnú àti ìgbéga òpin àwọn ọmọ Rẹ̀ kọjá gbogbo ohun míràn lọ tí ẹlẹ́ran-ara ọ̀run ní láti ṣe. Òun ni ìfẹ́ mímọ́, ẹni ológo, àti pé Baba Aláàánú ni orúkọ Rẹ̀.

“Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀,” ẹ lè wípé, “njẹ́ kò yẹ kí ìfẹ́ àti àánú Rẹ̀ pín okùn pupa araẹni wa níyà kí ó sì gbà wá láàyè láti rìn nínú àwọn wàhàlà wa lórí ìyàngbẹ ilẹ̀? Njẹ́ kó yẹ kí Òun rán àwọn ẹyẹ àkẹ sẹ́ntúrì-mọ́kànlélógún gbígbọn-ìyẹ́ wá látibikan láti sọ gbogbo akàn pẹ́skì sẹ́ntúrì-mọ́kànlélógún wa jẹ?”

Ìdáhùn sí irú ìbèèrè bẹ́ẹ̀ ni “Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run lè pèsè iṣẹ́ ìyanu lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n láìpẹ́ tàbí lẹ́hìnwá a kọ́ pé àwọn ìgbà àti àkokò ìrìnàjò ayé ikú jẹ́ Tirẹ̀ àti Tirẹ̀ nìkan láti darí.” Ó nṣe àkóso tí ó fi ọjọ́ sí gbogbo olúkúlùkù ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Nítorí gbogbo aláìsàn ènìyàn ni ó nwòsàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ bí ó ti ndúró láti wọnú odò Bẹ́tsáídà,3 ẹlòmíràn dúró lógójì ọdún nínú aṣálẹ̀ láti wọnú ilẹ̀ ìlérí.4 Nítorí gbogbo ara Néfì àti Léhì ni a dáààbò bò látinú àyíká iná fún ìgbàgbọ́ wọn,5 a jó Ábínádì kan nínú iná ìléru fún tirẹ̀6 Àti pé a rántí pé Èlíjàh kannáà ẹnití ó pè iná kalẹ̀ láti ọ̀run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti jẹri lòdìsí àwọn àlùfáà Báàlì7 ni Èlíjàh kannáà tí ó farada àkokò kan nígbàtí kò sí òjò fùn ọ̀pọ̀ ọdún àti ẹnití, ó jẹun látinú ohun ìmúnidúró kékeré tí èékán ẹyẹ lè gbé wá, fún ìgbà kan.8 Nípa ìwọ̀n mi, ìyẹn kìí ṣe ohun tí a lè pè ní “oúnjẹ dídùn.”

Àmì náà? Àmì náà ni pé ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run ní àwọn ìgbà rere àti ibi, àní bí ìyẹn bá tilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjìyà títí tí a ó fi rí ọwọ́ Rẹ̀ hàn ní ìtilẹhìn wa.9 Ìyẹn lè ṣòrò ní ayé òde òní nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti gbàgbọ́ pé rere tí ó ga jùlọ láyé ni láti yẹra fún gbogbo ìjìyà, tí ẹnìkankan kò joró lorí ohunkóhun.10 Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ yẹn kò lè darí sí “ìwọ̀n gígùn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Krístì.”

Pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ sí Alàgbà Neal A, Maxwell fún títiraka láti tún ohunkan tí ó sọ rí ṣe, èmi náà daba pé “ìgbé ayé ẹnìkan … kò lè kún fún ìgbàgbọ́ àti àìní wàhálà bákannáà.” Kò lè ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ “láti lọ nínú ayé pẹ̀lú àìmọ̀,” kí a wípé bí a ṣe nmú ago lẹ́mọ́nédì míràn: “Olúwa, fún mi ní gbogbo ìwàrere dídára jùlọ, ṣùgbọ́n mọ̀ dájúdájú kí ó máṣe fún mi ní ìbànújẹ́, tàbí ìkorò, tàbí ìrora, tàbí àtakò. Jọ̀wọ́ máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kóríra mi tàbí dalẹ̀ mi, àti níparí gbogbo rẹ̀, máṣe jẹ́ kí nní ìmọlára ìpatì látọwọ́ Rẹ tàbí àwọn tí mo fẹ́ràn. Nítòótọ́, Olúwa, ẹ ṣe jẹ́jẹ́ láti pa mí mọ́ kúrò nínú gbogbo àwọn ìrìrì tí ó mú Yín jẹ́ tọ̀run. Ṣùgbọ́n nígbàtí ìkọlù gbokogbòko látọwọ́ àwọn míràn bá parí, jọ̀wọ́ jẹ́ kí nwá gbé pẹ̀lú Rẹ, níbi tí mo ti lè lẹ́nu nípa bí àwọn okun wa àti ìwa wa ti rí bákannáà àti bí a ṣe nlọ lẹgbẹ ìkukù ìtunilára ti Krìstẹ́nì.”12

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, Krìstẹ́nì ntunilára, ṣùgbọ́n ko tu ni lárá nígbàkugbà. Ipá sí ìwàmímọ́ àti ìdùnnú nihin àti lẹ́hìnwá jẹ́ pípẹ́ àti gbókogbòko nígbàmíràn. O gba àkokò àti láti rìn tààrà nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n, bẹ́ẹ̀náà, èrè fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ní ìrántí. Òtítọ́ yí ni a kọ́nì kedere àti pẹ̀lú ìrọni nínú orí kejìlélọ́gbọ̀n ti Álmà nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì Níbẹ̀ àlùfáà gíga nlá yí kọ́ni pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni a gbìn nínú ọkàn wa bí èso lásán, tí a bá tọ̀jù wọn láti bomirin, tunṣe, ṣìkẹ́, kí a sì gbàá ní ìyànjú, yíò mú èso “èyí tí ó jẹ́ iyebíye jùlọ, … tí ó dùn tayọ gbogbo ohun tí ó dùn,” jíjẹ èyí tí ó darí sí ipò tí kò fi sí òrùngbẹ mọ́.

Ọ̀pọplọpọ̀ ẹ̀kọ́ ni a kọ̀ní nínú orí tí ó lápẹrẹ yí, ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ àringbùngbun sí gbogbo wọn ni ásíọ̀mù tí a níláti tọ́ èso rẹ̀ a sì gbọ́dọ̀ dúró fun láti dàgbà; “[ìfojú] sọ́nà pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́ sí èso rẹ̀.”14 Álmà wípé, ìkórè wa, nwá díẹ̀ díẹ̀.”15 O parí aṣẹ alápẹrẹ rẹ̀ pẹ̀lú ìyanilẹ́nu kékeré pé nípa títún ìpè pè ní ìgbà mẹ́ta fún aápọn àti sùúrù ní títọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ọkàn wa, “ní dídúró” bí ó ti wí, pẹ̀lú “ìpamọ́ra … fún igi náà láti so èso jáde fún yín.”16

COVID àti àrùn jẹjẹrẹ, ìṣiyèméjì àti ìjayà, wàhálà ìṣúná àti àwọn àdánwò ẹbí. Nígbà wo ni a ó gbé àwọn àjàgà wọ̀nyí kúrò? Ìdáhùn náà ni “díẹ̀ díẹ̀.”17 Àti bóyá ìyẹn jẹ́ ìgbà kúkurú tàbí ọ̀kan gígùn tí kìí ṣe tiwa láti sọ, ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àwọn ìbùkún yíò wá sọ́dọ̀ àwọn ẹnití ó di ìhìnrere Jésù Krístì mú daindain. Ọ̀ràn náà ni a pẹ̀tù ní ìkọ̀kọ̀ ọgbà gan an àti ní òkè gbangban gan an ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn ní Jerusalem.

Nísisìyí bí a ṣe ngbọ́ látẹnu àyànfẹ́ wòlíì tí yíò parí ìpàdé àpapọ̀, a lè rántí, bí Russell Nelson ṣe fihàn ní gbogbo ìgbé ayé rẹ̀, pé àwọn ẹnití ó “dúró de Olúwa yíò tún agbára wọn ṣe [yíò] si fi ìyẹ́ gun òkè bí ìdì; wọn ó sáré, kì yíò sì rẹ̀ wọ́n; … wọn ó rìn, àárẹ̀ kì yíò sì mú wọn.”18 Mo gbàdúrà ní “ṣísẹ̀ ntẹ̀lé”—láìpẹ́ tàbí lẹ́hìnwá—àwọn ìbùkún yíò wá sọ́dọ̀ gbogbo àwọn ẹnití ó nwá ìrànlọ́wọ́ látinú àwọn ìkorò yín àti òmìnira kúrò nínú ìbànújẹ́ yín. Mo jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ Baba Ọ̀run àti Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ológo Rẹ̀, èyí ni ọ̀nà tàbí òmíràn tí ó fi ndáhùn sí gbogbo ọ̀ràn tí a ndojúkọ nínú ayé. Ní orúkọ ìràpadà ti Jésù Krístì, àmín