Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Rírí Ayọ̀ nínú Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Rírí Ayọ̀ nínú Krístì

Ọ̀nà tí ó dájú jùlọ láti rí ayọ̀ nínú Krístì ni láti darapọ̀ mọ́ Krístì ní ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.

Olúwa kò ní kí àwọn Òyè-àlùfáà Ááróni wa ṣe ohun gbogbo, ṣùgbọ́n ohun tí Ó bèèrè jẹ́ ìmísí-ọ̀wọ̀.

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, ẹbí wa la ohun kan kọjá tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹbí ndojúkọ̀ nínú ayé ṣíṣubú yi. Ọmọkùnrin wa kékeré jùlọ, Tanner Christian Lund, ní àrùn jẹjẹrẹ. Ó jẹ́ ọkàn kan tí kò ṣeé gbàgbọ́, bí àwọn ẹni-ọdún-mẹ́san ṣe le rí. Ó máa nṣe àwọn àìdára tó npanilẹ́rin àti pẹ̀lú ìyanu ó mọ̀ ní ti ẹ̀mí. Impì àti ángẹ́lì, àìgbọràn àti dáadáa. Nígbàtí ó kéré tí ó sì maa nfi ojojúmọ́ dà wá láàmú pẹ̀lú àwọn wàhálà rẹ̀, a nrò bóyá yíó dàgbà sókè láti di wòlíì tàbí olè ilé ìfowópamọ́. Ní ọ̀nàkọ́nà, ó dàbíi pé ó máa fi àmì kan sí ayé.

Lẹ́hìnnáà ó bẹ̀rẹ̀ àìlera kíakía. Ní ààrin bíi ọdún mẹ́ta tó tẹ̀lé, egbòogi ìgbàlódé gbé àwọn ìgbésẹ̀ akọni, nínú èyí tí àwọn àtúngbìn mùdùnmúdùn inú egungun lẹ́ẹ̀mejì wà, níbití ó ti kó àrùn òtútù àyà, tí ó nílò rẹ̀ láti lo ọ̀sẹ̀ mẹwa lórí ẹ̀rọ afátẹ́gùn láìmọ ohunkóhun. Pẹ̀lú ìyanu, ó níwòsàn fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́hìnnáà àrùn jẹjẹrẹ padà.

Ní àkókò díẹ̀ kí ó tó kọjá lọ, àrùn Tanner ti bo àwọn egungun rẹ̀, àti pé àní pẹ̀lú àwọn ògùn líle fún ìrora, ṣì npaa lára. Ó fẹ́rẹ̀ má le jáde kúrò nínú ibùsùn. Ní òwúrọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi yi gan, ìyá rẹ̀, Kalleen, wá sí inú yàrá rẹ̀ láti bẹ̀ ẹ́ wò kí ẹbí náà to jáde lọ sí ilé ìjọ́sìn. Ó yà á lẹ́nu láti ríi pé ó ti múra fún ara rẹ̀ ó sì jókòó sí etí ibùsùn rẹ̀, nínú ìrora tí ó ntiraka pẹ̀lú bọ́tìnnì ṣẹ́ẹ̀tì kan. Kalleen jókòó sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ó wí pé, ‘”Tanner, njẹ́ ó dá ọ lójú pé ara rẹ lé tó láti lọ sí ilé ìjọ́sìn? “Bóyá kí ìwọ ó dúró nílé kí o sì sinmi lóni.”

Ó wo orí ilẹ̀. Ó jẹ́ díákóni kan. Ó ní iyejú kan. Ó sì ní iṣẹ́ yíyàn kan.

“Ó yẹ kí èmi ó pín àmì májẹ̀mú lóni.”

“Ó dára, ó dá mi lójú pé ẹnìkan le ṣe èyíinì fún ọ.”

“Bẹ́ẹ̀ni,” ṣùgbọ́n … mo ríi bí àwọn ènìyàn ṣe máa nwò mí nígbàtí mo bá npín àmì májẹ̀mú. Mo rò pé ó nràn wọ́n lọ́wọ́.”

Nítorínáà Kalleen ràn án lọ́wọ́ láti de bọ́tìnnì ṣẹ́ẹ̀tì rẹ̀ àti táì rẹ̀, wọ́n sì wakọ̀ lọ sí ilé ìjọ́sìn. Dájúdájú, ohun kan pàtàkì nṣẹlẹ̀.

Mo wọlé láti inú ìpàdé miràn nítorínáà ó yà mí lẹ́nu láti rí Tanner tó jóko ní ààyè àwọn díákónì. Kalleen sọ fúnmi jẹ́jẹ́ ìdí tí ó fi wà níbẹ̀ àti ohun tí ó ti sọ: “Mo rò pé ó nran àwọn ènìyàn lọ́wọ́.”

Àti nígbànáà mo ṣọ́ ọ bí àwọn díákónì ti jáde lọ sí ibi tábìlì àmì májẹ̀mú. Ó rọra tẹ̀ sí ara díákónì míràn bí àwọn àlùfáà ti gbé àwọn tíréè fún wọn. Tanner wọ́ dé ibi tí wọ́n yàn fún un ó sì di ìparí píù kan mú láti gbé ara rẹ̀ ró bí ó ti nfi oúnjẹ Olúwa náà fún ẹnití ó wà níwájú rẹ̀.

Ó dàbí pé gbogbo ojú nínú ibi ìsìn wà ní ara rẹ̀, ní wíwòye mímú ìrora rẹ̀ mọ́ra bí ó ti ṣe ipa rírọ̀rùn tirẹ̀. Bíótiwù-kíórí Tanner ṣe ìwáàsù ìdákẹjẹ́ bí ó ti nfi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, pẹ̀lú dídúró díẹ̀ sún láti ìjokòó kan sí ìkejì—tí orí rẹ̀ pípá ndán pẹ̀lú òógùn—ní síṣojú Olùgbàlà ní ọ̀nà tí àwọn díákónì nṣe. Ara líle ti díákónì rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí fúnra rẹ̀ ti jẹ́ pípalára, kíkán, àti fífàya díẹ̀, ó njìyà pẹ̀lú ìpinnu láti sìn nípa gbígbé àwọn àmì ti Ètùtù Olùgbàlà sí inú ayé wa.

Ríríi bí ó ti ronú nípa jíjẹ́ díakónì mú wa ronú yàtọ̀ bákannáà—nípa àmì májẹ̀mú, nípa Olùgbàlà, àti nípa àwọn díákónì àti àwọn olùkọ́ àti àwọn àlùfáà.

Mo ronú nípa iṣẹ́ ìyanu àìsọjáde tí ó ti gbà á níyànjú láti dáhùn pẹ̀lú ìgboyà bẹ́ẹ̀ sí ìpè jẹ́jẹ́, kékeré náà láti sìn, àti nípa okun àti àwọn agbára gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa tí ndàgbà bọ̀ bí wọn ti nti ara wọn láti dáhùn sí ìpè wòlíì kan láti fi orúkọ sílẹ̀ nínú àwọn ikọ̀ ológun ti Ọlọ́run kí wọn ó sì darapọ̀ nínú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga náà.

Ní gbogbo ìgbà tí díákónì kan bá gbé tíréè oúnjẹ Olúwa lọ́wọ́, a nrán wa létí ìtàn mímọ́ ti Ounjẹ Alẹ́ Olúwa, ti Getsemánì, ti Kálfárì, àti ti ibojì ọgbà. Nígbàti Olùgbàlà sọ fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀, “Ẹ ṣe èyí ní ìrántí mi,”1 Ó nsọ̀rọ̀ bákannáà la gbogbo ọdún já sí olukúlùkù wa. Ó nsọ̀rọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Òun ó pesè bí àwọn díákónì, àwọn olùkọ́ni, àti àwọn àlùfáà ọjọ́ iwájú tí yio gbé àwọn àmì Rẹ̀ tí wọn ó sì pe àwọn ọmọ Rẹ̀ láti tẹ́wọ́gba ẹ̀bùn Ètùtù Rẹ̀.

Gbogbo àwọn àmì ti ìlànà oúnjẹ́ Olúwa tọ́ka wa sí ẹ̀bùn náà. A nronú nípa àkàrà náà tí Òun bù ní ìgbà kan rí—àti àkàrà náà, ní ìdà kejì, tí àwọn àlùfáà nbù nísisìyí níwájú wa. A nrò nípa ìtumọ̀ nkan olómi yíyàsọ́tọ̀, nígbànáà àti nisisìyí, bí àwọn ọ̀rọ̀ inú àwọn àdúra oúnjẹ́ Olúwa wọnnì ti nfi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jáde láti ẹnu àwọn ọ̀dọ́ àlùfáà náà sínú ọkàn wa àti sí inú àwọn ọ̀run, ní àtúnṣe àwọn májẹ̀mú ìbáṣe wa sí àwọn agbára ìgbàlà ti Krístì gan. Ní ìgbà ìlànà oúnjẹ́ Olúwa, a le ronú nípa ohun tí ó túmọ̀sí nígbàtí díákónì kan bá gbé àwọn àmì mímọ́ náà wá sí ọ̀dọ̀ wa, tí ó dúró bí ó ti máa nṣe nibití Jésù ìbá dúró sí bí Òun bá wà níbẹ̀, tí ó nfẹ́ láti gbé àwọn ẹrù ara ẹni wa kí ó sì wo ìrora wa sàn.

Pẹ̀lú oríire, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti obìnrin kò nílò láti ṣàìsàn láti ṣe àwárí ayọ̀ àti èrèdí nínú sísin Olùgbàlà.

Alàgbà David A. Bednar ti kọ́ni pé láti dàgbà kí a sì dà bí àwọn oníṣẹ́ ìránṣẹ́ ti rí, a nílati ṣe bí àwọn oníṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ṣe, àti pé nígbànáà, “ìlà lórí ìlà àti ẹ̀kọ́ lórí ẹ̀kọ́, … díẹ̀díẹ̀ [a] le di oníṣẹ́ ìránṣẹ́ náà … tí Olùgbàlà nretí.”2

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí a bá ní èrò inú “láti dà bí Jésù, ”3 a nílati ṣe ohun tí Jésù nṣe, àti pé nínú gbólóhùn kan tí ó lápẹrẹ, Olúwa ṣe àlàyé ohun náà tí Òun nṣe: Ó wí pé, “Nítorí kíyèsíi, èyí ni iṣẹ́ mi àti ògo mi—láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ.”4

Iṣẹ́ Olùgbàlà ti fi gbogbo ìgbà jẹ́, àti pé títí láé ni ó jẹ́ láti sin Baba Rẹ̀ nípa gbígba àwọn ọmọ Rẹ̀ là.

Àti pé ọ̀nà tí ó dájú jùlọ láti rí ayọ̀ nínú ayé ni láti darapọ̀ mọ́ Krísti ní ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.

Èyí ni òtítọ́ ìrọ̀rùn náà tí ó ṣe ìmísí ètò Àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́.

Gbogbo àwọn iṣe ìdárayá àti ìkọ́ni ti Àwọn Ọmọdé àti Ọdọ́ jẹ́ nípa ríran àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn lọ́wọ́ láti dàbí Jésù síi bí wọ́n ti nṣiṣẹ́ pẹ̀lú Rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga.

Àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́ jẹ́ irinṣẹ́ kan láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún olukúlùkù àwọn ọmọ Alákọ́bẹ̀rẹ̀ láti dàgbà nínú jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn àti láti jèrè ìran kíkún fún ìgbàgbọ́ nípa bí ọ̀nà ìdùnnú ti rí. Wọn le mọ̀ láti fojú sọ́nà kí wọn ó sì pòngbẹ fún àwọn ibùdó àti àwọn òpó àmì ojú ọ̀nà ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú náà, níbi tí wọn ó ti jẹ́ ara àwọn iyejú àti àwọn kíláàsì Ọdọ́mọbìnrin, níbi tí wọn ó ti ní ìmọ̀lára ayọ̀ ti ríran ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípasẹ̀ tẹ̀létẹ̀lé àwọn ìṣe ti iṣẹ́ ìsìn bíi ti Krístì. Wọn ó ṣe àgbékalẹ̀ àwọn àfojúsùn, nlá àti kékeré, tí yío pèsè ìwọ̀ntún-wọ̀nsì sí ìgbé ayé wọn tí yío sì ràn wọ́n lọ́wọ́ dàbí Olùgbàlà síi. Àwọn ìpàdé apapọ̀ Fún Okun Àwọn Ọdọ́ àti àwọn magasínì, Ọrẹ́, àti áàpù Ìgbé Ayé Ìhìnrere yío ṣe ìrànwọ́ láti fi wọ́n sí ààrin rírí ayọ̀ nínú Krístì. Wọn ó fojú sọ́nà fún àwọn ìbùkún ti níní ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì tí ó ní òdiwọ̀n-ìlò, wọn ó sì ní ìmọ̀lára ẹ̀mí ti Elíjàh nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ bí wọ́n ti nlépa àwọn ìbùkún ti iṣẹ́ tẹmpìlì àti ìtàn ẹbí. Wọn yío jẹ́ títọ́sọ́nà nípa àwọn ìbùkún baba-nlá. Ní àkokò, wọn ó ri ara wọn ní lílọ sí inú àwọn tẹ́mpìlì láti di bíbùkúnfún pẹ̀lú agbára, láti rí ayọ̀ níbẹ̀ bí wọ́n ti nní ìsopọ̀ ayérayé pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn, bí ó ti wù kórí.

Dojúkọ àwọn afẹ́fẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn tó kárí ayé àti wàhálà, mímú àwọn ìlérí kíkún ti ètò túntun Àwọn Ọmọdé àti Ọdọ́ ṣe jẹ́ iṣẹ́ tó sì nlọ lọ́wọ́ síbẹ̀—ṣùgbọ́n pé ìkánjú wà. Àwọn ọ̀dọ́ wa kò le dúró fún ayé láti ṣe àtúnṣe ara rẹ̀ kí wọn ó to wa mọ Olùgbàlà. Àwọn kan nṣe àwọn ìpinnu àní nísisìyí tí wọn ìbá má ṣe bí wọ́n bá mọ ìdánimọ̀ wọn tòótọ́ àti—Tirẹ̀.

Àti pé nítorínáà ìpè ìkánjú náà láti ọ̀dọ̀ àwọn ikọ̀ ológun ti Ọlọ́run nínú ìdánilẹ́kọ́ pàtàkì ni kí “gbogbo ọwọ́ wà ní orí iṣẹ́!”

Ẹ̀yin ìyá àti ẹ̀yin bàbá, àwọn ọmọkùnrin yín nílò yín láti tì wọ́n lẹ́hìn nísisìyí pẹ̀lú ìtara bí ẹ ti ṣe kọjá nígbàtí wọ́n nṣe àwọn ohun kékeré. Ẹ̀yin ìyá àti ẹ̀yin bàbá, ẹ̀yin olórí àwọn olóyè àlùfáà àti Àwọn Ọdọ́mọbìnrin, bí àwọn ọ̀dọ́ yín bá ntiraka, Àwọn Ọmọdé àti Ọdọ́ yío ṣe ìrànwọ́ mú wọn padà wá sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, àti pé Olùgbàlà yío mú alàáfíà wá fún wọn.5

Ẹyin àjọ ààrẹ iyejú àti kíláàsì, ẹ gbéra sọ kí ẹ sì mú ipò ẹ̀tọ́ yín nínú iṣẹ́ Olúwa.

Ẹyin bíṣọ́pù, ẹ so kọ́kọ́rọ́ yín pọ̀ pẹ̀lú ti àwọn ààrẹ iyejú, àti pé àwọn iyejú yín—àti àwọn wọ́ọ̀dù yín—yío yípadà títí láe.

Síi ẹyin tí ẹ jẹ́ ti ogún ìbí ọlọ́lá, Mo jẹ́ ẹ̀rí, bí ẹni tí ó mọ̀, pé ẹ jẹ́ àyànfẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run àti pé Òun sì ní iṣẹ́ kan fún yín láti ṣe.

Bí ẹ ti ndìde sí ọlánlá àwọn ìpè yín, pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ipá, inú, àti agbára yín, ẹyin ó fẹ́ràn Ọlọ́run ẹ ó sì fi àwọn májẹ̀mú àti ìgbẹkẹ̀lé yín sínú Rẹ̀ bí ẹ ti nṣiṣẹ́ láti bùkún àwọn ẹlòmíràn, ní bíbẹ̀rẹ̀ láti ínú ile yín.

Mo gbàdúrà pé ẹ ó tiraka, pẹ̀lú àfikún okun, tí ó yẹ fún àkókò yí, láti sìn, lo ìgbàgbọ́, ronúpìwàdà, kí ẹ sì gbèrú síi ní ojojúmọ́, láti yege fún gbigba àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì àti ayọ̀ pẹ́títí tí ó nwá nípasẹ̀ ìhìnrere Jésù Krístì nìkan. Mo gbàdúrà pé ẹ ó gbaradì láti di alápọ̀n ìránṣẹ́ ìhìnrere náà, ọkọ tàbí aya tó ṣeé fọkàntán, olùfẹ́ni baba tàbí ìyá tí a ti ṣèlérí fún yín pé ẹ le dà níkẹhìn nípa jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn tòótọ́ ti jésù Krístì.

Ẹ le ṣèrànwọ́ láti múra ayé sílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ Olùgbàlà nípa pípe gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ Krístì kí wọn ó sì gba àwọn ìbùkún ti Ètùtù Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Lúkù 22:19

  2. David A. Bednar, “Dída Ìránṣẹ́ ìhìnrere kan,” Lìáhónà, Oṣù Kọkànlá 2005, 46

  3. “Mo ngbìyànjú láti dàbí Jésù; mo ntẹ̀lé ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. Mo ngbìyànjú láti fẹ́ràn bí oun ti ṣe, nínú gbogbo ohun ti mo nṣe àti sọ” (“Mo Ngbìyànjú láti Dà bí Jésù,” Ìwé Orin ti Àwọn Ọmọdé, (78-79).

  4. Mósè1:39.

  5. Èmi fúnra mi fi ìmoore hàn sí àwọn olùfọ̀kàsìn obí àti olórí káàkiri ìtàn wa tí wọ́n fìwà akọni ran àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn lọ́wọ́ láti ní ìrírí ìdàgbàsókè gidi. Mo jẹ́wọ́ pé àwọn ìtiraka titun Ọmọdé àti Ọ̀dọ́ ṣe pàtàkì sí ìṣe kọ̀ọ̀kan àti àṣeyege ètò tí ó ṣíwájú rẹ̀.