Àwọn Ìwé Mímọ́
Jákọ́bù 5


Orí 5

Jákọ́bù sọ ọ̀rọ̀ ti Sénọ́sì sọ nípa ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ti igi ólífì tí a tọ́jú àti ti asọdigbó. Nwọ́n jẹ́ àfiwé fún Isráẹ́lì àti àwọn Kèfèrí—Fífọ́nka àti Kíkójọpọ̀ Ísráẹ́lì jẹyọ nínú ọ̀rọ̀—A ṣe ìtọ́ka sí àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì àti gbogbo ìdílé Ísráẹ́lì—Àwọn Kèfèrí yíò di àkékún sí ará Ísráẹ́lì—Lẹhinorẹhin, ọgbà-àjàrà nã yíò di jíjó. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, ṣé ẹ̀yin kò rántí pé ẹ ti ka àwọn ọ̀rọ̀ ti wòlĩ Sénọ́sì, èyítí o sọ fún ará ilé Ísráẹ́lì, wípé:

2 Fi etí sílẹ̀, A! ẹ̀yin ará ilé Ísráẹ́lì, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, èmi wòlĩ Olúwa.

3 Nítorí ẹ kíyèsĩ, báyĩ ni Olúwa wí, Èmi yíò ṣe àfiwé rẹ, A! ará ilé Isráẹ́lì, pẹ̀lú igi olifi kan tí a tọ́jú ti ọkùnrin kan mu, tí ó sì tọ́jú nínú ọgbà-àjàrà rẹ; tí ó sì dàgbà, tí ó sì gbo, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí díbàjẹ́.

4 Ó sì ṣe, tí olùtọ́jú ọgbà-àjàrà nã jáde lọ, tí ó sì ríi pé igi olifi nã ti bẹ̀rẹ̀ si díbàjẹ́; ó sì wípé: Èmi yíò pa ẹ̀ka rẹ̀, èmi yíò si gbẹ́ ilẹ̀ yĩ ka, èmi yíò sì tọ́jú rẹ̀, pé bóyá yíò rúwé, kò sì ní parun.

5 O sì ṣe, o pa ẹka rẹ, ó sì wa ilẹ̀ yi i ka, ó sì tọ́jú rẹ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

6 Ó sì ṣe, lẹ́hìn ọjọ́ púpọ̀, ó bẹ̀rẹ̀sí yọ jáde ní díẹ̀díẹ̀, àwọn ẹ̀ka tí ó jẹ́ ọ̀dọ́; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, òkè orí igi nã bẹ̀rẹ̀ sí parun.

7 Ó sì ṣe, nígbàtí olùtọ́jú ọgbà-àjàrà nã rií, ó sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ wípé: Ó jẹ́ ohun ẹ̀dùn ọkàn fún mi wípé èmi yíò pàdánù igi yĩ; nítorí-èyi, lọ, kí ó ké àwọn ẹ̀yà ẹ̀ka igi ólífì asọdigbó, kí ó sì mú wọn tọ̀ mí wá; àwa yíò sì ké àwọn ẹ̀ka ti wọ́n ti bẹ̀rẹ̀sí rẹ̀ dànù nì kúrò, àwa yíò sì jù wọ́n sínú iná kí wọn kí ó lè jóná.

8 Sì kíyèsĩ, ni Olúwa ọgbà-àjàrà nã wí, èmi yíò mu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iruwe ọ̀dọ́ ẹ̀ka wọ̀nyí kúrò, èmi yíò sì pa ẹ̀ka wọn sí ara igi èyítí o bá wu mi; ko si bá ohunkóhun wí, pé tí ó bá jẹ́ wípé gbòngbò igi yĩ yíò parun, èmi yíò tọ́jú èso rẹ̀ fún ara mi; nítorí-èyi, èmi yíò mú àwọn ọ̀dọ́ ẹ̀ka rírọ wọ̀nyí, èmi yíò si fi wọ́n bọ igi èyítí ó bá wù mi.

9 Mú ẹ̀ka igi ólífì asọdigbó nni, sì fi nwọ́n bọ ara igi míràn dípò èyí tí ó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀; àwọn wọ̀nyí, tí èmi ti ké kúrò ni èmi yíò jù sínú iná tí èmi yíò sì jó wọn, kí wọn kí ó má bã fún gbãyè ọgbà-àjàrà mi.

10 Ó sì ṣe pé ìránṣẹ́ Olúwa ọgbà-àjàrà nã ṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Olúwa ọgbà-àjàrà nã ti pã láṣẹ ó sì fi ẹ̀ka igi ólífì asọdigbó bọ ãrín rẹ̀.

11 Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì jẹ́ kí a gbẹ́ ilẹ̀ yíi ká, kí a sì pẹ̀ka rẹ̀, kí a sì ṣe ìtọ́jú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: Ó jẹ́ ìbànújẹ́ fún mi pé èmi yíò pàdánù igi yíi; nítorí-èyi, pé bóyá èmi lè tọ́jú gbòngbò rẹ, kí wọ́n má bã parun, kí èmi kí ó ṣe ìtọ́jú wọn fún ara mi, ni èmi ṣe ṣe nkan yĩ.

12 Nítorí-èyi, máa bá tìrẹ lọ; máa ṣọ igi nã, kí o sì tọ́jú rẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ mi.

13 Àwọn nkan wọ̀nyí ni èmi yíò gbe ka ibi ìkángun ìhà ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà mi, ibikíbi èyí tí ó wù mi, kò já mọ́ nkankan sí ọ; èmi sì ṣeé kí èmi lè tọ́jú fún ara mi ẹ̀ka abinibi igi nã; àti pẹ̀lú, kí èmi lè kó èso rẹ̀ pamọ́ di ìgbà míràn sí ara mi; nítorítí ó jẹ́ ohun ẹ̀dùn fún mi láti pàdánù igi yĩ àti èso rẹ̀.

14 Ó sí ṣe wípé Olúwa ọgbà-àjàrà nã bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ, ó sì fi àwọn ẹ̀ka àbinibí igi ólífì tí a tọ́jú pamọ́ sí ibi ìkángun ìhà ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà nã, àwọn kan nínú ọ̀kan, àwọn kan nínú òmíràn, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti ìdunnú rẹ.

15 Ó sì ṣe, tí ọjọ́ pípẹ́ kọjá lọ, tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀: Wá, jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ọgbà-àjàrà nã, kí àwa kí ó lè ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà nã.

16 Ó sì ṣe, tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã, àti ìránṣẹ́ nã pẹ̀lú, sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà-àjàrà nã láti ṣiṣẹ́. Ó sì ṣe, tí ìránṣẹ́ nã sì sọ fún Olúwa rẹ̀, wípé: Kíyèsĩ, wo ibi yĩ; wo igi nã.

17 Ó sì ṣe, tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì wò, ó sì kíyèsí igi nã inú èyítí o ti fi ẹ̀ka igi ólífì asọdigbó bọ̀; ó sì ti hù, ó sì bẹ̀rẹ̀sí nso èso. Ó sì kíyèsĩ pé ó dára; èso rẹ̀ sì dàbĩ ti èso àdánidá.

18 Ó sì wí fún ìránṣẹ́ nã pé: Kíyèsĩ, ẹ̀ka igi asọdigbó nã fa omi mu láti inú egbò rẹ̀ ti inú èyí nã, tóbẹ̃gẹ́ tí egbò nã ti ní agbára púpọ̀; àti nítorí agbára púpọ̀ ti egbò yĩ, ẹ̀ka igi asọdigbó nã ti mú èso igi tí a tọ́jú jáde. Nísisìyí, tí kò bá jẹ́ pé àwa lọ́ si ínú àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí, igi nã kò bá ti parun. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, èmi yíò sì kó èso púpọ̀ pamọ́, èyítí igi nã ti so jáde; èso rẹ̀ ni èmi yíò sì kó pamọ́ di ìgbà míràn, fún ara mi.

19 Ó sì ṣe, tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún ìránṣẹ́ nã wípé: Wá, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sí ìkángun ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà nã, kí a sì kíyèsĩ, tí àwọn ẹ̀ka àdánidá ti igi nã kò bá tĩ mú èso púpọ̀ jáde bákannã, kí èmi kí ó lè kó àwọn èso nã jọ pamọ́ di ìgbà míràn, fún ara mi.

20 Ó sì ṣe, tí nwọ́n sì lọ sí ibití Olúwa nã ti fi àwọn ẹ̀ka àdánidá igi nã pamọ́ si, ó sì sọ fún ìránṣẹ́ nã wípé: Kíyèsí àwọn wọ̀nyí; ó sì ríi wípé àwọn ti àkọ́kọ́ ti mú èso púpọ̀ jáde wá; ó sì ríi pẹ̀lú pé ó dára. Ó sì sọ fún ìránṣẹ́ nã wípé: Mú nínú àwọn èso ti inú èyí, kí o sì kó wọn jọ pamọ́ di ìgbà míràn, kí èmi kí ó lè tọ́jú nwọn pamọ́ fún ara mi; nítorí kíyèsĩ, ni ó wí, ìgbà pípẹ́ yĩ ni mo ti tọ́jú rẹ, òun si ti so èso púpọ̀ jáde wá.

21 Ó sì ṣe tí ìránṣẹ́ nã sọ fún Olúwa rẹ̀, wípé: Kíni ìdí rẹ̀ tí ìwọ wá sí ibí yĩ láti gbin igi yĩ, tàbí ẹ̀ka igi yĩ? Nítorí kíyèsĩ, ọ̀gangan tí ó ṣá jùlọ nínú gbogbo ilẹ̀ ọgbà-àjàrà rẹ ni.

22 Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún un, pé: Ma gbà mí nímọ̀ràn; èmi mọ̀ pé ilẹ̀ nã ti ṣá; nítorí-èyi ni mo ṣe sọ fún ọ wípé, èmi ti tọ́jú rẹ̀ ní àkókò pípẹ́ yĩ, ìwọ si kíyèsĩ pé ó ti mú èso púpọ̀ jáde wá.

23 Ó sì ṣe tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: Wo ibi yĩ; kíyèsĩ èmi ti gbin ẹ̀ka míràn nínú igi nã; ìwọ sì mọ̀ wípé ilẹ̀ apá ibí yĩ ṣá ju ti àkọ́kọ́ lọ. Ṣùgbọ́n, wo igi nã. Èmi ti tọ́jú rẹ̀ títí di àkokò pípẹ́ yĩ, ó sì ti mú èso púpọ̀ jáde wá; nítorí-èyi, kóo jọ, kí o sì kóo jọ pamọ́ di ìgbà nã, kí èmi kí ó lè tọ́jú nwọn pamọ́ fún ara mi.

24 Ó sì ṣe tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã tún wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: Wo ibí yí, sì kíyèsí ẹ̀ka míràn pẹ̀lú, èyítí mo ti gbìn; kíyèsĩ pé mo ti tọ́jú òun pẹ̀lú, ó sì ti mú èso jáde wá.

25 Ó sì wí fún ìránṣẹ́ nã pé: Wo ibí yĩ, kí o sì kíyèsí ti ìkẹhìn. Kíyèsĩ, èyí ni mo ti gbìn sí orí ilẹ̀ tí ó dára; mo sì ti tọ́jú rẹ̀ títí di àkokò pípẹ́ yíi, díẹ̀ nínú igi nã ni ó sì mú èso tí a tọ́ju jáde, apá kejì igi nã sì mú èso asọdigbó jáde; kíyèsĩ, mo ti tọ́jú igi yĩ bĩ gbogbo àwọn tí ó kù.

26 Ó sì ṣe ti Olúwa-ọgbà àjàrà nã sì sọ fún ìránṣẹ́ nã, wípé: Ke àwọn ẹ̀ka wọnnì kúrò tí kò mu èso rere jáde, kí o sì jù nwọ́n sínú iná.

27 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìránṣẹ́ nã sọ fún un, wípé: Ẹ jẹ́ kí a pa ẹ̀ka rẹ̀, kí a sì wa ilẹ̀ yíi ká, kí a sì tọ́jú rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ síi, pé ó ṣeéṣe kí ó mú èso dáradára jáde wá fún nyín, kí ẹ̀nyin kí ó sì lè kó jọ pọ̀ di ìgbà nã.

28 Ó sì ṣe ti Olúwa ọgbà-àjàrà nã àti ìránṣẹ́ Olúwa ọgbà-àjàrà nã tọ́jú gbogbo èso inú ọgbà-àjàrà nã.

29 Ó sì ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ti rékọjá, Olúwa ọgbà-àjàrà nã si sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ wípé: Wá, jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà-àjàrà nã, kí àwa kí ó tún ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà nã. Nítorí kíyèsĩ, àkokò nã súnmọ́lé, òpin sì dé tán, nítorí-èyi, èmi níláti kó èso jọ papọ̀ di ìgbà nã, fún ara mi.

30 Ó sì ṣe tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã àti ìránṣẹ́ nã lọ sínú ọgbà-àjàrà nã; nwọ́n sì dé ẹ̀bá igi èyítí a ti ké ẹ̀ka àdánidá rẹ̀ kúrò, tí a sì ti mú àwọn ẹ̀ka asọdigbó bọ̀ nínú; sì kíyèsĩ, oríṣiríṣi èso bò igi nã mọ́lẹ̀.

31 Ó sì ṣe tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì tọ́ ní ara èso nã wò, nínú gbogbo onírurú èso ọgbà-àjàrà nã. Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì wípé: Kíyèsĩ, títí di àkokò pípẹ́ yí ni àwa ṣe ìtọ́ju igi yĩ, èmi sì ti kó èso púpọ̀ jọ papọ̀ fún ara mi, di ìgbà nã.

32 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ní ìgbà yí, ó ti mú èso púpọ̀ jáde wá, kò sì sí èyí tí ó dára nínú rẹ. Sì kíyèsĩ, àwọn èso búburú onírurú ni ó wà; kò sì ṣe ànfàní kankan fún mi, l’áìṣírò fún gbogbo lãlã wa; àti nísisìyí jẹ́ ohun ẹ̀dùn fún mi láti pàdánù igi yĩ.

33 Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún ìránṣẹ́ nã wípé: Kíni kí àwa kí ó ṣe sí igi yĩ, kí èmi kí ó leè tun ṣe ìtọ́jú àwọn èso dáradára láti inú rẹ̀ fún ara mi?

34 Ìránṣẹ́ nã sì wí fún Olúwa rẹ̀ pé: Kíyèsĩ, nítorípé ìwọ ti fi ẹ̀ka igi ólífì asọdigbó bọ ãrín igi wọ̀nyí, nwọn sì ti bọ́ àwọn gbòngbò igi nã, wọ́n sì yè, nwọn kò sì parun; nítorí-èyi ni ìwọ ṣe ríi pé nwọ́n ṣì wà ní dídára.

35 Ó sì ṣe tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: Igi nã kò wúlò fún mi, àwọn gbòngbò rẹ ko sì wúlò fún mi pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ wípé èso ibi ni ó nso jáde.

36 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi mọ̀ wípé àwọn gbòngbò rẹ dára, èmi sì ti ṣe ìtọ́jú wọn fún ìwulò ara mi; àti nítorí agbára nwọn ni nwọ́n ṣe mú èso dáradára jáde láti inú àwọn ẹ̀ka tí ó jẹ́ asọdigbó.

37 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ẹ̀ka asọdigbó nã ti gbilẹ̀ nwọ́n ti borí gbòngbò; àti nítorítí ẹ̀ka asọdigbó nã ti gbilẹ̀ borí àwọn gbòngbò rẹ, ó sì ti mú èso búburú púpọ̀ jáde wá; àti nítorítí ó ti mú èso búburú púpọ̀ jùlọ jáde wa, iwọ̀ kíyèsí pé ó bẹ̀rẹ̀ sí parun; yíò sì pọ́n l’áìpẹ́ ọjọ́, kí a lè ju sínú iná, àfi tí àwa bá gbé ìgbésẹ̀ láti lè tọ́jú rẹ̀, kí ó sì yè.

38 Ó sì ṣe ti Olúwa ọgbà-àjàrà nã sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, wípé: Jẹ́ kí a lọ sí àwọn ibi ìhà ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà nã, kí a sì ṣe àkíyèsí bóyá àwọn ẹ̀ka àdánidá nã ti mú èso búburú jáde pẹ̀lú.

39 Ó sì ṣe, tí nwọ́n sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn ibi ìhà ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà nã. Ó sì ṣe, tí nwọ́n ṣe àkíyèsí pé èso ẹ̀ka àdánidá nã pẹ̀lú ti díbàjẹ́; bẹ̃ ni, èkínní àti ìkejì àti ti ìkẹhìn pẹ̀lú; gbogbo nwọn sì ti díbàjẹ́.

40 Èso asọdigbó ti ìkẹhìn si ti borí apá igi nã tí ó mú èso dáradára jáde, tóbẹ̃gẹ́ tí ẹ̀ka igi nã ti rẹ̀ dànù, ó sì ku.

41 Ó sì ṣe, ti Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọkún, ó sì wí fún ìránṣẹ́ nã wípé: Kíni èmi ìbá ti tún ṣe fún ọgbà-àjàrà mi?

42 Kíyèsĩ, mo mọ̀ pé gbogbo èso ọgbà-àjàrà nã, yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí, ni nwọ́n ti díbàjẹ́. Àwọn wọ̀nyí ẹ̀wẹ̀ ti nwọ́n sì ti mú èso dáradára jáde wá ní ìgbà kan rí, sì tún díbàjẹ́ pẹ̀lú; àti nísisìyí gbogbo àwọn igi ọgbà-àjàrà mi kò dára fún ohunkóhun, àfi kí a ké wọn lulẹ̀ kí a sì jù nwọ́n sínú iná.

43 Sì kíyèsí èyí tí ó kẹ́hìn yĩ, èyítí ẹ̀ká rẹ̀ ti rẹ̀ dànù, èmi gbìn ín sí ibi ilẹ̀ tí ó dára; bẹ̃ni, àní èyí tí mo yàn fún ara mi ju gbogbo apá ilẹ̀ yókù nínú ọgbà-àjàrà mi.

44 Ìwọ sì ṣe àkíyèsí pé èmi kée lùlẹ̀ pẹ̀lú, èyítí ó bò apá ibi ilẹ̀ yí mọ́lẹ̀, kí èmi kí ó lè gbin igi yĩ dípò rẹ̀.

45 Ìwọ sì ṣe àkíyèsí pé díẹ̀ nínú igi yĩ mú èso dáradára jáde wa, díẹ̀ nínú rẹ̀ sì mú èso tí asọdigbó jáde; àti nítorítí èmi kò ké àwọn ẹ̀ka rẹ̀, kí a sì jù wọ́n sínú iná, kíyèsĩ, nwọ́n ti bò àwọn ẹ̀ka dáradára mọ́lẹ̀, tó bẹ̃ tí ó ti rẹ̀ dànù.

46 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, l’áìṣírò fún gbogbo ìtọ́jú tí àwa ti ṣe lórí ọgbà-àjàrà mi, àwọn igi rẹ̀ ti díbàjẹ́, ti nwọn kò sì so èso dáradára jáde wá; àwọn wọ̀nyí ni èmi sì ti ní ìrètí nínú láti kó èso nwọn jọ pamọ́ di ìgbà nã, fún ara mi. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, nwọn ti dàbí igi ólífì asọdigbó, nwọn kò sì wúlò fún ohunkóhun, bíkòṣe pé kí a ké nwọn lulẹ̀, kí a sì jù nwọ́n sínú iná; ó sì bà mí nínú jẹ́ pé èmi yíò pàdánù nwọn.

47 Ṣùgbọ́n kíni èmi ìbá tún ṣe nínú ọgbà-àjàrà mi? Njẹ́ èmi ṣe ìjáfara bí, ti èmi kò si tọ́jú rẹ? Rárá, èmi ti ṣe ìtọ́jú rẹ̀, mo sì ti wa ilẹ̀ yĩ ka, mo si ti pa ẹ̀ka rẹ kuro, mo ti fi ajílẹ̀ bọ́ọ; èmi sì ti sa gbogbo agbára mi lée lórí, ní ọjọ́ pípẹ́, ìgbẹ̀hìn sì ti dé tán. Ó sì bà mí nínú jẹ́ pé mo níláti gé gbogbo igi inú ọgbà-àjàrà mi lulẹ̀, kí èmi kí ó sì jù nwọ́n sínú iná kí nwọn kí ó lè jóná. Tani ẹni nã tí ó mú kí ọgbà-àjàrà mi díbàjẹ́?

48 Ó sì ṣe, ti ìránṣẹ́ nã sì sọ fún Olúwa rẹ̀, pé: Njẹ́ kĩ ha íṣe gbígbõrò ọgbà-àjàrà rẹ—njẹ́ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kò ha ti borí àwọn gbòngbò tí ó dára bí? Nítorípé àwọn ẹ̀ka ti borí àwọn gbòngbò kíyèsĩ nwọ́n dàgbà sókè ju agbára àwọn gbòngbò lọ, nwọ́n sì ngba agbára sí ara wọn. Kíyèsĩ, èmi wípé, njẹ́ kĩ ṣe eleyĩ ni ó fã tí àwọn igi inú ọgbà-àjàrà rẹ ṣe ti díbàjẹ́?

49 Ó sì ṣe, ti Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún ìránṣẹ́ nã pé: Jẹ́ kí àwa kí ó lọ, kí a sì gé àwọn igi inú ọgbà-àjàrà nã lulẹ̀, kí a sì jù nwọ́n sínú iná, kí nwọn kí ó ma ṣe gbilẹ̀ nínú ọgbà-àjàrà mi, nítorítí èmi ti sa gbogbo ipá mi lórí ọgbà-àjàrà yí. Kíni èmi ìbá tún ṣe fún ọgbà-àjàrà mi?

50 Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, ìránṣẹ́ nã sọ fún Olúwa ọgbà-àjàrà nã pé: Ẹ dáa sí fún ìgbà díẹ̀ síi.

51 Olúwa nã sì wípé: Bẹ̃ni, èmi yíò dáa sí fún ìgbà díẹ̀ síi, nítorítí ó jẹ́ ohun ẹ̀dùn ọkàn fún mi wípé èmi yíò pàdánù àwọn igi inú ọgbà-àjàrà mi.

52 Nítorí-èyi, jẹ́ kí a mú nínú àwọn ẹ̀ka àwọn èyí tí èmi ti gbìn sí ibi ìhà ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà mi, kí o sì jẹ́ kí a lọ́ àwọn ẹ̀ka nã bọ inú àwọn igi ara èyítí a ti mú wọn jáde wa; kí a sì fa àwọn ẹ̀ka tí wọ́n ti so èso kíkorò yọ kúrò lára igi nã, kí a sì fi àwọn àdánidá ẹ̀ka bọ inú igi nã dípò àwọn wọ̀nyí.

53 Èyí ni èmi yíò sì ṣe kí igi nã má ṣe parun, wípé, bóyá, èmi lè ṣe ìtọ́jú gbòngbò rẹ fún ìwúlò ara mi.

54 Àti kíyèsĩ, àwọn gbòngbò ẹ̀ka àdánidá igi èyí tí mo gbìn sí ibi èyí tí ó wù mí wà lãyè; nítorí-èyi, kí èmi kí ó lè ṣe ìtọ́jú àwọn nã fun ìwúlò ara mi, èmi yíò mú nínú ẹ̀ka igi eleyĩ, èmi yíò sì fi nwọ́n bọ inú wọn. Bẹ̃ni, èmi yíò fi àwọn ẹ̀ka ìdí igi nwọn bọ ãrín wọn, kí èmi kí ó lè dá gbòngbò nwọn pẹ̀lú sí fún èmi tìkalára mi, pé nígbàtí nwọ́n bá ti gbó bóyá nwọn yíò mú èso dáradára jáde wá fún mi, èmi sì le gba ògo nínú èso ọgbà-àjàrà mi síbẹ̀.

55 Ó sì ṣe, ti nwọn sì mú igi àdánidá nã èyítí ó ti di asọdigbó, tí wọ́n sì fi bọ inú àwọn igi àdánidá, èyítí ó ti di asọdigbó bákannã.

56 Nwọ́n sì mú nínú àwọn igi àdánidá tí ó ti di asọdigbó, nwọ́n sì fi nwọ́n bọ inú ìdí igi nwọn.

57 Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì wí fún ìránṣẹ́ nã pé: máṣe gé àwọn ẹ̀ka asọdigbó kúrò lára àwọn igi nã, afi àwọn tí ó korò púpọ̀ jùlọ; ínú nwọn ni ìwọ yíò sì fi bọ gẹ́gẹ́bí èmi ti sọ.

58 Àwa yíò sì tún ṣe ìtọ́jú àwọn igi ọgbà-àjàrà nã, a o sì pa àwọn ẹ̀ka tí ó wà lára rẹ̀; àwa o si ge kúrò lára àwọn igi nã àwọn ẹ̀ka ti nwọn ti díbàjẹ́, tí nwọ́n níláti parun, kí a sì dà wọ́n sínú iná.

59 Èyí ni èmi sì ṣe wípé, bóyá, àwọn gbòngbò rẹ̀ yíò ní agbára nítorí dídára nwọn; àti nítorítí a ti pãrọ̀ àwọn ẹ̀ka nwọn, kí rere lè borí búburú.

60 Àti nítorípé èmi ti tọ́jú àwọn ẹ̀ka àdánidá àti àwọn gbòngbò nwọn, àti wípé èmi ti tún ṣe ìfibọ àwọn ẹ̀ka àdánidá sínú ìdí igi nwọn, tí èmi sì ti tọ́jú àwọn gbòngbò ìdí-igi nwọn, pé, bóyá, àwọn igi inú ọgbà-àjàrà mi yíò tún so èso rere jáde wa; kí èmi sì tún ni ayọ̀ nínú èso inú ọgbà-àjàrà mi, àti wípé, bóyá èmi lè yọ lọ́pọ̀lọpọ̀ wípé èmi ṣe ìtọ́jú gbòngbò àti ẹ̀ka eso àkọ́kọ́ nã—

61 Nítorí-èyi, lọ, kí o sì pe àwọn ìránṣẹ́, kí àwa lè ṣiṣẹ́ taratara pẹ̀lú agbára wa nínú ọgbà-àjàrà nã, kí àwa kí ó lè tún ọ̀nà nã ṣe, kí èmi tún lè mú èso àdánidá jáde wá, eso adanida èyítí ó dára tí ó sì níye lórí ju gbogbo eso yókù lọ.

62 Nítorí-èyi, jẹ́ kí àwa kí ó lọ, kí a sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo agbára wa ní ìgbà ìkẹhìn yĩ, nítorí kíyèsĩ, òpin súnmọ́ tòsí, ìgbà ìkẹhìn sì nìyí tí èmi yíò pa ẹ̀ka ọgbà-àjàrà mi.

63 Fi àwọn ẹ̀ka nã bọ ãrín igi; bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kẹ́hìn kí nwọ́n lè jẹ́ èkíní, àti kí èkíní lè jẹ́ ìkẹhìn, kí o sì wa ilẹ̀ yí àwọn igi nã ká, gbígbó àti ọ̀dọ́, èkíní àti ìkẹhìn; àti ìkẹhìn àti èkíní, kí gbogbo nwọn lè di títọ́jú lẹ́ẹkan síi fún ìgbà ìkẹhìn.

64 Nítorí-èyi, wa ilẹ̀ yí wọn ká, kí o sì pa ẹ̀ka nwọn, kí o sì fi ajílẹ̀ sí wọn lẹ̃kan síi, fún ìgbà ìkẹhìn, nítorítí ìgbà òpin ti dé tán. Tí ó bá sì jẹ́ bẹ̃ wípé àwọn ẹ̀ka ifibọ wọ̀nyí yíò hù, kí nwọn sì so èso àdánidá jáde, nígbànã ni àwa yíò tún ọ̀nà ṣe fún nwọn, kí nwọn kí o lè dàgbà.

65 Bí nwọn bá sì ti ndàgbà, ẹ̀nyin yíò gbá àwọn ẹ̀ká tí ó nso èso kíkorò kúrò gẹ́gẹ́bí agbára èyí tí ó dára, àti títóbi rẹ̀; ẹ̀nyin kò sì ní gbá àwọn tí kò dára níbẹ̀ kúrò lẹ̃kanṣoṣo, kí gbòngbò rẹ̀ má bã lágbára ju ẹ̀ka ifibọ, àti kí ẹ̀ka ifibọ má bã parun, kí èmi má bã sì pàdánù awọn igi ọgbà-àjàrà mi.

66 Ó sì bà mí nínú jẹ́ wípé èmi yíò pàdánù awọn igi ọgbà-àjàrà mi; nítorí-èyi ìwọ yíò gbá èyítí ó jẹ́ búburú kúrò gẹ́gẹ́bí èyítí ó jẹ́ rere yíò ṣe hù, kí gbòngbò àti orí lè wa ní ọgbọ̃gba nínú agbára, títí rere yíò borí búburú, tí a ó sì ké búburú lulẹ̀ kí a sì sọọ́ sínú iná, kí nwọn kí ó máṣe fún ilẹ̀ ọgbà-àjàrà mi pa; báyĩ ni èmi yíò sì ṣe gbá búburú kúrò nínú ọgbà-àjàrà mi.

67 Ẹ̀ka igi àdánidá ni èmi yíò tún ṣe fífibọ sí inú igi àdánidá;

68 Àwọn ẹ̀ka igi àdánidá ni èmi yíò sì fibọ̀ sínú àwọn ẹ̀ka àdánidá igi nã; báyĩ ni èmi yíò sì kó nwọn jọ lẹ̃kan síi, tí nwọn yíò sì so èso àdánidá jáde, nwọn yíò sì jẹ́ ọkan.

69 Èyítí kò dára ni a ó sì jù dànù, bẹ̃ni, àní kúrò nínú gbogbo ilẹ̀ ọgbà-àjàrà mi; nítorí kíyèsĩ, ẹ̃kan yĩ ni èmi yíò pa ẹ̀ka igi ọgbà-àjàrà mi.

70 Ó sì ṣe, tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì ran ìránṣẹ́ rẹ̀; ìránṣẹ́ nã sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́bí Olúwa nã ti pàṣẹ fún un, ó sì mú àwọn ìránṣẹ́ míràn wa; nwọn kò sì pọ̀.

71 Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún nwọn pé: Ẹ lọ, kí ẹ sì ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà nã, pẹ̀lú agbára yin. Nítorí kíyèsĩ, èyí ni ìgbà ìkẹhìn tí èmi yíò ṣe ìtọ́jú ọgbà-àjàrà mi; nítorítí òpin ti dé tán, àkókò nã sì nsúré tete bọ̀ wá; tí ẹ̀yin bá sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára yín pẹ̀lú mi, ẹ̀yin yíò ní ayọ̀ nínú èso nã tí èmi yíò ko pamọ́ fún ara mi di ìgbà nã tí kò ní pẹ́ dé.

72 Ó sì ṣe tí àwọn ìránṣẹ́ nã sì lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára wọn; Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn; nwọ́n sì ṣe ìgbọràn sí àwọn òfin Olúwa ọgbà-àjàrà nã nínú ohun gbogbo.

73 Èso àdánidá sì bẹ̀rẹ̀sí yọ jáde nínú ọgbà-àjàrà nã; ẹ̀ka àdánidá nã sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà nwọn sì yè dáradára; àwọn asọdigbó sì bẹ̀rẹ̀sí di kíké kúrò áti jíjù nù; nwọ́n sì jẹ́ kí gbòngbò àti orí igi wà ní ọgbọ̃gba, gẹ́gẹ́bí agbára rẹ̀.

74 Báyĩ ni nwọ́n ṣe lãlã pẹ̀lú àìsimi gbogbo, gẹ́gẹ́bí àṣẹ Olúwa ọgbà-àjàrà nã, àní títí a fi ju èyí búburú nù kúrò nínú ọgbà-àjàrà nã, tí Olúwa ti fi pamọ́ fún ara rẹ̀ pé kí àwọn igi nã tún padà di èso àdánidá; tí nwọ́n sì padà di ẹ̀yà ara kanṣoṣo; tí àwọn èso sì jẹ́ ọgbọ̃gba; tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã ti fi èso àdánidá, èyítí ó níye lórí jùlọ, fún ara rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀.

75 Ó sì ṣe, nígbàtí Olúwa ọgbà-àjàrà nã ríi pé èso nã dára, àti pé ọgbà-àjàrà rẹ̀ kò díbàjẹ́ mọ́, ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, fún ìgbà ìkẹhìn yí ni àwa ti tọ́jú ọgbà-àjàrà mi; ẹ̀yin sì ríi wípé èmi ti ṣe gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú mi; èmi sì ti tọ́jú èso àdánidá rẹ̀ tí ó dára, àní gẹ́gẹ́bí ó ṣe rí ní ìbẹ̀rẹ̀. Alábùkún-fún sì ni ẹ̀yin; nítorítí ẹ̀yin ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú mi láìsinmi nínú ọgbà-àjàrà mi, ẹ̀yin sì ti pa àwọn òfin mi mọ́, ẹ̀yin sì tún ti mú èso àdánidá padà fún mi, tí ọgbà-àjàrà mi kò díbàjẹ́ mọ́, a sì ti da èyí tí ó burú nù, kíyèsĩ, ẹ̀nyin yíò ní ayọ̀ pẹ̀lú mi nítorí èso inú ọgbà-àjàrà mi.

76 Nítorí kíyèsĩ, fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni èmi yíò ṣe àkójọ èso ọgbà-àjàrà mi fún ara mi di àkókò nã, èyítí ó dé kánkán; àti pé fún ìgbà ìkẹhìn ni èmi ti ṣe ìtọ́jú ọgbà-àjàrà mi, tí mo pa ẹ̀ka rẹ̀, tí mo wa ilẹ̀ yĩ ká, tí mo sì yĩ ní ọ̀rá; nítorí-èyi, ni èmi yíò kó èso rẹ̀ jọ fún ara mi fún ìgbà pípẹ́, gẹ́gẹ́bí èyí tí èmi ti sọ.

77 Nígbàtí àkokò nã bá sì dé tí èso ibi yíò tún padà wá sí inú ọgbà-àjàrà mi, ìgbà nã ni èmi yíò jẹ́ kí a kó èso rere àti búburú jọ; èyítí ó jẹ́ rere ni èmi yíò ṣe ìtọ́jú fún ara mi, èyítí ó jẹ́ búburú ni èmi yíò sọ dànù sí ãyè ara rẹ̀. Nígbànã ni àkókò àti òpin yíò sì dé; ọgbà-àjàrà mi ni èmi yíò sì ní kí á jó pẹ̀lú iná.