Àwọn Ìwé Mímọ́
Jákọ́bù 3


Orí 3

Àwọn ọlọ́kàn-mímọ́ gba ọ̀rọ̀ ìdùnnú Ọlọ́run-òdodo àwọn ará Lámánì tayọ ti àwọn ará Nífáì—Jákọ́bù kìlọ̀ nípa àgbèrè ìfẹ́kúfẹ́ ara, àti ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èmi, Jákọ́bù, yíò sọ̀rọ̀ sí ẹ̀yin ọlọ́kàn-mímọ́. Gbé ojú rẹ sókè sí Ọlọ́run pẹ̀lú àìyẹra ọkàn, sì gbàdúrà síi pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́, òun yíò sì tù ọ́ nínú ní inu àwọn ìṣòro rẹ, òun yíò sì ṣe alágbàwí fún ọ, yíò sì rán aiṣegbe sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn tí nwọ́n wá ìparun rẹ̀.

2 A!, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọlọ́kàn-mímọ́, ẹ gbé orí yín sókè, kí ẹ sì gba ọ̀rọ̀ ìdùnnú Ọlọ́run, kí ẹ sì ṣe àpèjẹ lórí ìfẹ́ rẹ̀; nítorítí ẹ̀yin le ṣe eleyĩ, tí ẹ bá ní ìdúró ṣinṣin ọkàn, títí láé.

3 Ṣùgbọ́n, ègbé, ègbé, ni fún ẹ̀nyin tí ẹ kò jẹ́ ọlọ́kàn-mímọ́, tí ẹ jẹ́ elẽrí loni níwájú Ọlọ́run; nítorípé, bíkòṣepé ẹ̀yin ronúpìwàdà, ìfibú ni ilẹ̀ nã nítorí yín; àti àwọn ará Lámánì, tí wọ́n kò jẹ́ elẽrí bĩ tiyín, bíótilẹ̀ríbẹ̃, tí a fi bú pẹ̀lú ègún kíkan, wọn yíò kọlũ yín sí ìparun.

4 Ìgbà nã sì dé kánkán, bíkòṣepé ẹ̀yin bá ronúpìwàdà, wọn yíò jogún ilẹ̀ ìní yín, Olúwa yíò sì sin àwọn olódodo jáde kúrò ní ãrín yín.

5 Kíyèsĩ, àwọn àrá Lámánì arákùnrin yín, tí ẹ̀yin korira nítorí ìwà ẽrí wọn àti ègún tí ó ti wá sí ara nwọn, jẹ́ olododo jù yín lọ; nítorítí wọn kò tĩ gbàgbé òfin Olúwa, èyítí a fún àwọn bàbá wa—pé wọn kò gbọ́dọ̀ ní ju ìyàwó kan lọ, àti pé nwọn kò gbọ́dọ̀ ní àlè, àti pẹ̀lú pé a kò gbọ́dọ̀ rí ìwà àgbèrè ní ãrín wọn.

6 Àti nísisìyí, òfin yĩ ni wọ́n gbiyanju láti pa mọ́; nítorí-èyi, nítorí àkíyèsí yĩ, nípa pípa òfin yĩ mọ́, Olúwa Ọlọ́run kò ní pa wọ́n rẹ́, ṣùgbọ́n yíò ṣe ãnú fún wọn; ní ọjọ́ kan, wọ́n yíò di ẹni ìbùkún.

7 Kíyèsĩ, àwọn ọkọ wọn fẹ́ràn àwọn ìyàwó wọn, àwọn ìyàwó nwọn sì fẹ́ràn àwọn ọkọ wọn; àti àwọn ọkọ wọn àti àwọn ìyàwó fẹ́ràn àwọn ọmọ wọn; àti pé àìgbàgbọ́ wọn àti ikorira wọ́n sí yín sì jẹ́ nítorí àìṣedẽdé àwọn bàbá wọn; nítorí-èyi, báwo ni ẹ̀yin ṣe dára jù wọ́n lọtó, lójú Ẹlẹ́dã yín tí ó tóbi?

8 A! ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀rù nbá mí pé, bí kò ṣe pé ẹ̀nyin bá ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ yín, awọ ara wọn yíò funfun ju tiyín lọ, nígbàtí a ó mù yin wá pẹ̀lú wọn síwájú ìtẹ́ Ọlọ́run.

9 Nítorí-èyi, àṣẹ kan ni mo fi fún un yín, èyítí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pé kí ẹ̀nyin máṣe kẹ́gàn wọn mọ́ nítorí dúdú awọ ara wọn; bẹ̃ni ẹ̀nyin kì yíò sì kẹ́gàn wọn nítorí ìwà ẽrí wọn; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yíò rántí ìwà ẽrí yín, kí ẹ sì rántí pé ìwà ẽrí nwọn wá nítorí àwọn bàbá wọn.

10 Nítorí-èyi, ẹ̀yin yíò rántí àwọn ọmọ yín, bí ẹ̀yin ṣe ti bà nwọn lọ́kàn jẹ nítorí àpẹrẹ tí ẹ fi lélẹ̀ níwájú wọn; àti pẹ̀lú, kí ẹ rántí pé ẹ̀yin lè ti ipasẹ̀ ìwà ẽrí yín mú ìparun bá àwọn ọmọ yín, a o sì di ẹ̀ṣẹ̀ wọn lée yín lórí ní ọjọ ìkẹhìn.

11 A! ẹ̀yin ará mi, ẹ fi etí sílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi; ẹ ta ọkàn yín jí; ẹ gbọn ara yín nù, kí ẹ̀yin kí ó lè tají kúrò nínú õgbé ikú; kí ẹ sì tú ara yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìrora ọ̀run àpãdì, kí ẹ̀yin kí ó má bà di àwọn ángẹ́lì ti èṣù, tí a ó jù sínú adágún iná àti imí ọjọ́ nã, èyítí í ṣe ikú èkejì.

12 Àti nísisìyí èmi, Jákọ́bù, sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan síwájú sĩ fún àwọn ará Nífáì, ní kíkìlọ̀ fún nwọn nípa ìwà àgbèrè àti ifẹkufẹ-ara, àti irúkírú ẹṣẹ, mo sì sọ fún wọn nípa èrè àwọn ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí.

13 Àti pé, idá kan nínú ọgọrun ìṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ sí di púpọ̀ bayĩ, ni a kò lè kọ sorí àwọn àwo wọ̀nyí; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣe wọn ni a kọ sórí àwọn àwo tí ó tóbi ju àwọn tí a sọ wọ̀nyí, àti àwọn ogun wọn, àti asọ̀ wọn, àti ìjọba àwọn ọba wọn.

14 Àwọn àwo wọ̀nyí ni a pè ní àwo Jákọ́bù, a sì ṣe wọ́n nípasẹ̀ ọwọ́ Nífáì. Èmi sì mú sísọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá sí òpin.