Àwọn Ìwé Mímọ́
Jákọ́bù 4


Orí 4

Gbogbo àwọn wòlĩ sin Bàbá ní orúkọ Krístì—Yíyọ̀da Ísãkì fún ìrúbọ, èyítí Ábráhámù ṣe, jẹ́ àwòkọ́ṣe ti Ọlọ́run àti ti Ọmọ Bíbí rẹ̀ Nìkanṣoṣo—Ènìyàn níláti bá Ọlọ́run làjà nípasẹ̀ Ètùtù nã—Àwọn Jũ yíò kọ okúta ìpìlẹ̀ nã sílẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí kíyèsĩ, ó sì ṣe tí èmi, Jákọ́bù, lẹ́hìn tí mo ti jíṣẹ́ púpọ̀ fún àwọn ènìyàn mi nínú ọ̀rọ̀ sísọ, (nkò sì lè kọ bí kò ṣe díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ mi, nítorí ìṣòro fifin àwọn ọ̀rọ̀ wa sí ara àwọn àwo) àwa sì mọ̀ wípé àwọn nkan tí a kọ sórí àwọn àwo níláti wà síbẹ̀;

2 Ṣùgbọ́n, ohunkóhun tí àwa bá kọ lé orí ohunkóhun, yàtọ̀ sí orí àwọn àwo níláti parun, kí wọn ó sì parẹ́; ṣùgbọ́n àwa lè kọ ọ̀rọ̀ díẹ̀ lé orí àwọn àwo, èyítí yíò fún àwọn ọmọ wa, àti àwọn arákùnrin wa àyànfẹ́, ní ìmọ̀ díẹ̀ nípa wa, tàbí nípa àwọn bàbá wọn—

3 Nísisìyí, nínú èyí ni àwa nyọ̀; àwa sì nṣiṣẹ́ tọkàn-tọkàn láti fín àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sórí ara àwọn àwo, ní ìrètí pé àwọn arákùnrin wa àyànfẹ́ àti àwọn ọmọ wa yíò gbà wọ́n pẹ̀lú ọkàn ìdúpẹ́, kí wọ́n sì wo wọn, kí wọn bá lè kọ́ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ayọ̀, kĩ ṣe pẹ̀lú ìrora-ọkàn bẹ̃ sì ni kĩ ṣe pẹ̀lú ìkẹgàn, nípa àwọn òbí wọn àkọ́kọ́.

4 Nítorí ìdí èyí ni àwa ṣe kọ àwọn nkan wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè mọ̀ pé àwa mọ̀ nípa Krístì, àti pé à ní ìrètí ògo rẹ̀ ní ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgọ̃rún ọdún ṣãjú bíbọ̀ rẹ̀; àti pé àwa nìkan kọ́ ní a ní ìrètí ògo rẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ tí wọ́n ti wà ṣãjú wa.

5 Kíyèsĩ, wọ́n gbàgbọ́ nínú Krístì, wọ́n sin Bàbá ní orúkọ rẹ̀, àwa nã sin Bàbá ní orúkọ rẹ̀. Àti nítorí ìdí èyí ni àwa ṣe pa òfin Mósè mọ́, nítorítí ó tọ́ka ọkàn wa sĩ; àti nítorí ìdí èyí ni ó ṣe wà ní ìyàsímímọ́ fún wa fún ìwà òdodo, pãpã gẹ́gẹ́bí a ṣe kãkún fún Ábráhámù nínú aginjù, pé kí ó ṣe ìgbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run nípa yíyọ̀da ọmọkùnrin rẹ̀ Ísãkì fún ìrúbọ, èyítí ó jẹ́ àwòkọ́ṣe ti Ọlọ́run àti ti Ọmọ Bíbí rẹ̀ Kanṣoṣo.

6 Nítorí-èyi, àwa ṣe àwárí àwọn wòlĩ, àwa sì nì ìfihàn tí ó pọ̀, àti ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀; nígbàtí àwa sì ti gba ẹ̀rí wọ̀nyí, a rí ìrètí gbà, ìgbàgbọ́ wa sì wa láìmì, tóbẹ̃ gẹ́ tí a fi lè pàṣẹ lõótọ́ ní orúkọ Jésù, fún àwọn igi, tàbí àwọn òkè gíga, tàbí àwọn ìrusókè omi òkun, tí nwọn sì gbọ́.

7 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa Ọlọ́run nfi àìlera wa hàn wá kí àwa kí ó lè mọ̀ pé nípa õre-ọ̀fẹ́ rẹ̀, àti ìrẹra-ẹni-sílẹ̀ títóbi nítorí àwọn ọmọ ènìyàn, ni àwa fi lè ní agbára láti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí.

8 Kíyèsĩ, títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ Olúwa. Awamaridi sì ni ìjìnlẹ̀ ìṣe rẹ̀; kòsí ṣeéṣe fún ènìyàn láti mọ gbogbo ọ̀nà rẹ. Kò sì sí ẹni nã tí ó mọ ọ̀nà rẹ, àfi bí a bá fi hàn an; nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ máṣe fi ẹnu àbùkù bá àwọn ìfihàn Ọlọ́run.

9 Nítorí kíyèsĩ, nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ènìyàn fi wá sí orí ilẹ̀ ayé, èyítí a dá nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí-èyi, bí Ọlọ́run bá lè sọ̀rọ̀, tí ayé sì wà, kí ó sì sọ̀rọ̀, tí a sì dá ènìyàn, A! njẹ́, báwo ni kò ṣe ní lè pàṣẹ fún ayé, tàbí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé nã, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti inúdídùn rẹ̀?

10 Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin, ẹ má ṣe lépa láti gba Olúwa ní ìmọ̀ràn, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó gba ìmọ̀ràn láti ọwọ́ rẹ̀. Nítori kíyèsĩ, ẹ̀yin tikara yín mọ̀ wípé ó nfún ni ní ìmọ̀ràn nínú ọgbọn, àti nínú àìṣègbè, àti nínú ọ̀pọ̀ ãnú, lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

11 Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin àyànfẹ́, ẹ bá làjà, nípasẹ̀ ètùtù Krístì, Ọmọ Bíbí rẹ̀ Kanṣoṣo, ẹ̀yin sì lè rí àjĩnde gbà gẹ́gẹ́bí agbára àjínde tí ó wà nínú Krístì, kí a sì fi yín sí iwájú Ọlọ́run, gẹ́gẹ́bí àkọ́bí Krístì, nípa ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ sì ti gba ìrètí ogo dáradára nínú rẹ̀, kí ó tó fi ara rẹ̀ hàn nínú ẹran ara.

12 Àti nísisìyí, ẹ̀nyin àyànfẹ́, ẹ máṣe jẹ́ kí ó yà yín lẹ́nu wípé èmi nsọ àwọn nkan wọ̀nyí fún yín; ẽṣe tí àwa kò sọ̀rọ̀ nípa ètùtù Krístì, kí àwa kí ó sì ní ìmọ̀ pípé nípa rẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwa yíò ṣe ní ìmọ̀ nípa àjinde àti ayé èyí tí ó nbọ̀?

13 Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹnití ó bá nsọ àsọtẹ́lẹ̀, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn; nítorítí Ẹ̀mí nsọ òtítọ́, kĩ sĩ purọ́. Nítorí-èyi, ó nsọ̀rọ̀ nípa ohun gbogbo bí wọ́n ṣe rí gan an, àti nípa ohun gbogbo bí wọ́n yíò ṣe rí gan an; nítorí-èyi, a fi àwọn nkan wọ̀nyí hàn wá ní kedere, fún ìgbàlà ọkàn wa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwa nìkan kọ́ ni à nṣe ẹlẹ́rĩ nínú àwọn nkan wọ̀nyí; nítorítí Ọlọ́run pãpã sọ wọ́n fún àwọn wòlĩ àtẹ̀hìnwá pẹ̀lú.

14 Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, àwọn Jũ jẹ́ ọlọrun líle ènìyàn; wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ ti o ṣe kedere, wọ́n sì pa àwọn wòlĩ, wọ́n sì ṣe àfẹ́rí àwọn nkan tí kò lè yé wọ́n. Nítorí-èyi, nítorí ìfọ́jú wọn, ìfọ́jú èyítí o bá nwọn nípa àwojúmọ́, wọ́n níláti ṣubú; nítorípé Ọlọ́run ti mú ìṣe-kedere rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan tí kò lè yé wọn, nítorí wọ́n fẹ́ẹ bẹ̃. Àti nítorítí wọ́n fẹ́ bẹ̃, Ọlọ́run ṣe é, kí wọ́n lè kọsẹ̀.

15 Àti nísisìyí, èmi, Jákọ́bù ni à darí nípa Ẹ̀mí láti sọtẹ́lẹ̀; nítorítí mo wòye nípa ìṣe Ẹ̀mí tí ó wà nínú mi, wípé nípa ìkọsẹ̀ àwọn Jũ wọn yíò kọ okuta nã sílẹ̀ orí èyítí wọ́n kì bá kọle sí, kí wọ́n sì ní ìpìlẹ̀ tí ó wà láìléwu.

16 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, gẹ́gẹ́bí àwọn ìwé-mímọ́, okuta yí yíò di nla, yíò sì jẹ́ èyí tí ó kẹ́hìn, àti ìpìlẹ̀ kanṣoṣo tí ó dájú, orí èyí tí àwọn Jũ yíò lè kọ́ ilé lé.

17 Àti nísisìyí, ẹ̀nyin àyànfẹ́ mi, báwo ni o ṣe lè ṣeéṣe pé àwọn wọ̀nyí, lẹ́hìn tí wọ́n ti kọ ìpìlẹ̀ nã tí ó dájú sílẹ̀, wọn yíò ha lè kọ́ ilé lée lórí, tí yíò sì jẹ́ òpómúléró fún nwọn bí?

18 Kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi yíò fi ìmọ̀ yí yé yín; bí èmi, ní ọ̀nàkọnà, kò bá yẹ̀ kúrò ní ìdúróṣinṣin mi nínú Ẹ̀mí, kí èmi sì kọsẹ̀ nítorí ìkó-ọkàn-sókè lórí nyín.