Àwọn Ìwé Mímọ́
Jákọ́bù 6


Orí 6

Olúwa yíò gba Ísráẹ́lì padà ní ọjọ́ ìkẹhìn—A ó fi iná jó ayé—Ènìyàn gbọdọ̀ tẹ̀lé Krístì kí o bã yẹra fún adágún iná àti imí ọjọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, ẹ̀yin arakunrin mi, gẹ́gẹ́bí mo ti sọ fún yin pé èmi yíò sọtẹ́lẹ̀, ẹ kíyèsĩ, èyí yĩ ni ìsọtẹ́lẹ̀ mi—wípé àwọn nkan tí wòlĩ Sénọ́sì dájúdájú yĩ sọ, nípa ará ilé Ísráẹ́lì, nínú èyítí ó fi nwọ́n we igi ólífì tí a ti tọ́jú, gbọdọ̀ ṣẹ.

2 Àti ọjọ́ nã tí òun yíò tún na ọwọ́ rẹ̀ nígbà kejì láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, ní ọjọ́ nã, bẹ̃ni, àní ìgbà ìkẹhìn, tí àwọn ìránṣẹ́ Olúwa yíò jáde lọ nínú agbára rẹ̀, láti ṣe ìtọ́jú àti pẹka ọgbà-àjàrà rẹ̀; àti lẹ́hìn èyí yĩ ni ìgbà òpin yíò dé tán.

3 Báwo ni nwọ́n ṣe jẹ́ alábùkún-fún to, àwọn ti nwọ́n ti ṣiṣẹ́ tọkàn-tara nínú ọgbà-àjàrà rẹ̀; báwo sì ni nwọ́n ṣe jẹ́ ẹni-ìdálẹ́bi to, àwọn tí a ó ta dànù sí àyè ara wọn! Tí a ó sì jó ayé pẹ̀lú iná.

4 Báwo sì ni Ọlọ́run wa ṣe ní ãnú fún wa tó, nítorítí ó rántí ará ílé Ísráẹ́lì, àti àwọn gbòngbò àti àwọn ẹ̀ka; ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí wọn ní gbogbo ọjọ́; nwọ́n sì jẹ́ ènìyàn ọlọ́rùn-líle àti asọ̀rọ̀-òdì; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ti nwọn kò bá sé ọkàn nwọn le ni a o gbàlà nínú ìjọba Ọlọ́run.

5 Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo bẹ̀ yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn wípé kí ẹ̀yin kí ó ronúpìwàdà, kí ẹ sì wá tọkàn-tọkàn, kí ẹ sì rọ̀ mọ́ Ọlọ́run, bí òun ṣe rọ̀ mọ́ ọ yín. Nígbàtí ó bá sì na apá ãnú rẹ̀ sí i yín nínú ìmọ́lẹ̀ ọjọ́, ẹ máṣe sé ọkàn yín le.

6 Bẹ̃ni, ní òní, tí ẹ̀yin yíò bá gbọ́ ìpè rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn yín le; kíni ìdí tí ẹ̀yin yíò ṣe fẹ́ láti kú?

7 Ẹ kíyèsĩ, lẹ́hìn tí a ti fún un yín ní ìtọ́jú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ọjọ́ gbogbo, njẹ́ ẹ̀yin yíò mú èso búburú jáde wá, kí a bã lè ké yín lulẹ̀, kí a sì sọ yín sínú iná?

8 Ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ẹ̀yin yíò kọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀ bí? Njẹ́ ẹ̀yin yíò kọ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ sílẹ̀ bí; njẹ́ ẹ̀yin yíò sì tún kọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí a ti sọ nípa Krístì, lẹ́hìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀; tí nwọn sì sẹ́ ọ̀rọ̀ rere Krístì, àti agbára Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, kí ẹ sì pana Ẹ̀mí Mímọ́, kí ẹ sì fi ìlànà ìràpadà nlá nã ṣẹ̀sín, èyítí a ti ṣe ìlànà rẹ̀ fún yín?

9 Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé bí ẹ̀yin bá ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, pé agbára ìràpadà àti àjĩnde, tí ó wà nínú Krístì, yíò mú yín dúró pẹ̀lú ìtìjú àti ìdálẹ́bi tí ó burú níwájú itẹ Ọlọ́run.

10 Àti pé, gẹ́gẹ́bí agbára àìṣègbè, nítorítí a kò lè sẹ́ àìṣègbè, ẹ̀yin níláti lọ sínú adágún iná àti imí ọjọ́ nã, èyítí a kò lè pa ọwọ́ iná rẹ̀, àti èyítí ẽfín rẹ gòkè lọ títí láéláé, adágún iná àti imí ọjọ́ èyítí íṣe oró àìnípẹ̀kun.

11 A! njẹ, ẹ̀yin ará mi àyànfẹ́, ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì wọ ẹnu ọ̀nà híhá nã, kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú ọ̀nà èyítí íṣe tõró, títí ẹ̀yin yíò rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà.

12 A! sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n; kíni èmi tún lè sọ síi?

13 Ní àkótán, mo kí yin pé ó dìgbàkan ná, títí èmi yíò pàdé yín níwájú itẹ Ọlọ́run èyítí ó láyọ̀, èyítí yíò kọlũ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìbẹ̀rù-bojo àti ìjayà. Àmín.