Njẹ́ O Mọ Ìdi Tí Èmi Bíi Krístíẹ́nì Ṣe Gbàgbọ́ Nínú Krístì?
Jésù Krístì ní láti jìyà, kú, ó sì dìde lẹ́ẹ̀kansi láti ra gbogbo ènìyàn padà kúrò nínú ikú ara àti láti fúnni ní ìyè ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lẹ́hìn iṣẹ́, ní àwọn ọdún sẹ́hìn, mo wọ ọkọ̀ èrò mi lọ sílé ní New Jersey láti Ìlú New York. Obìnrin tí ó ṣẹlẹ̀ pé mo jókòó tì kíyèsí ohun tí mo nkọ lórí kọ̀mpútà mi ó sì béèrè pé, “O gbàgbọ́ nínú … Krístì?” Mo sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ni, mo gbàgbọ́!” Bí a ti nsọ̀rọ̀, mo kọ́ pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá sí agbègbè náà láti orílẹ̀-èdè Asíà rírẹwà rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ní abala ìmọ̀ ẹ̀rọ ìwífúnni ìdíje púpọ̀ ní New York.
Ní àdánidá, mo bí í léèrè pe, “Njẹ́ o mọ ìdi tí èmi bíi Krístíẹ́nì ṣe gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì?” Òun náà fèsì bí ó ti yẹ, ó sì ní kí nsọ fún òun. Ṣùgbọ́n bí mo ti fẹ́ sọ̀rọ̀, mo ní ọ̀kan nínú àwọn àkókò wọnnì níbití àwọn èrò púpọ̀ ti nwa sí ọkàn yín. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí èmi ó ṣe àlàyé “ìdí” ẹ̀sìn Krístẹ́nì fún ẹnìkan tí kò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀ àti tí ó já fáfá gidi. Èmi ò kàn le sọ pé, “mo ntẹ̀lé Jésù Krístì nítorípé Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ jìyà tí ó sì kú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi.” Ó le ròó pé, “Ṣé Jésù níláti kú ni? Ṣé Ọlọ́run kò kàn le dáríjì kí ó sì wẹ̀ wá mọ́ ní ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa bí a bá béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀?”
Báwo ni ìwọ ò bá ti fèsì ní àwọn ìṣẹ́jú díẹ̀? Báwo ni ìwọ ó ti ṣe àlàyé èyí sí ọ̀rẹ́ kan? Ẹyin ọmọdé àti ọ̀dọ́: njẹ́ ẹ ó jọ̀wọ́ ẹ béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí tàbí olùdarí kan lẹ́hìnwá, “Kínni ìdí tí Jésù fi níláti kú?” Àti pé, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo ní ìjẹ́wọ́ kan láti ṣe: àní pẹ̀lú gbogbo ohun tí mo rò pé mo mọ̀ nípa ẹ̀kọ́, ìtàn, ìlànà Ìjọ, àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ bíi ààrẹ èèkàn ní àkókò náà, ìdáhùn sí ìbéèrè yí tó ṣe kókó sí ìgbàgbọ́ wa kò wá pẹ̀lú ìrọ̀run. Ní ọjọ́ náà, mo pinnu láti fojúsùn síi lórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ sí ìyè ayérayé.
Ó dára, mo sọ fún ọ̀rẹ́ mi titun1 pé a ní ẹ̀mí kan ní àfikún sí àgọ́ ara àti pé Ọlọ́run ni Bàbá ẹ̀mí wa.2 Mo sọ fún un pé a gbé pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run ṣaájú ìbí wa sí ayé kíkú yi.3 Nítorípé Ó fẹ́ràn rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀, Ó ṣe ètò kan fún wa láti gba ara ní àwòrán ara Rẹ̀ tí a ti ṣe lógo,4 láti jẹ́ ara ẹbí kan,5 àti lati padà sí ọ̀dọ̀ ìfẹ́ni Rẹ̀ láti gbádùn ìyè ayérayé pẹ̀lú àwọn ẹbí wa,6 bí Òun ti ṣe pẹ̀lú Tirẹ̀.7 Ṣùgbọ́n, mo wípé, a ó dojúkọ àwọn ìdènà pàtàkì méjì nínú ayé tí ìṣubú dandan yí:8 (1) ikú ti ara—yíya ara wa nípa kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀mí wa. Bẹ́ẹ̀ni, ó mọ̀ pé gbogbo wa ó kú. Àti (2) ikú ti ẹ̀mí—yíyapa wa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nítorípé àwọn ẹ̀ṣẹ̀, àwọn àṣìṣe, àti àwọn àlébù wa bíi ẹni kíkú mú wa jìnnà kúrò ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀ mímọ́.9 Ó mọ̀ nípa èyí bákannáà.
Mo sọ fún un pé èyí ni àyọrísí kan nípa òfin ìdáláre. Òfin ayérayé yí béèrè pé ìjìyà ayérayé kan níláti jẹ́ sísan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tàbí ríré àwọn òfin Ọlọ́run tàbí òtítọ́ kọjá, tàbí láé kí a má padà láti gbé ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀ mímọ́.10 Yíó jẹ́ àìṣòdodo, Ọlọ́run kò sì le sẹ́ òdodo.”11 O ní òye èyí ṣùgbọ́n ó fi ìrọ̀rùn gbà pé bákannáà Ọlọ́run jẹ́ alãnú, olùfẹ́ni, Ó sì ní ìtara láti mú ìyè ayérayé wa ṣẹ.12 Mo sọ fún ọ̀rẹ́ mi pé a ó ní alárẽkérekè, alágbára ọ̀tá kan—orísun ibi àti àwọn irọ́—ní títakò wá.13 Nítorínáà, ẹnìkan pẹ̀lú agbára àìlópin bíi ti Ọlọ́run láti borí gbogbo irú àtakò àti àwọn ìdènà bẹ́ẹ̀ yío nílò láti gbà wá là.14
Lẹ́hìnnáà mo pín ìròhìn rere náà pẹ̀lú rẹ̀—”ìhìn rere ti ayọ̀ nlá … sí gbogbo ènìyàn”15—pé “Ọlọ́run fẹ́ aráiyé tóbẹ́ẹ́ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàá gbọ́ má bàá ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”16 Mo jẹ́ri sí ọ̀rẹ́ mi, mo sì jẹ́ ẹ̀rí síi yín, pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà náà, pé Òun ní lati jìyà, kú, kí Ó sì dìde lẹ́ẹ̀kansíi—Ètùtù àìlópin Rẹ̀—láti rà gbogbo ẹ̀dá ènìyàn padà lọ́wọ́ ikú ti ara17 àti láti fi ìyè ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn ẹbí wa18 fún gbogbo ẹnití ó bá tẹ̀lé E. Ìwé ti Mọ́mọ́nì kéde pé, “Báyí ni Ọlọ́run … ní ìṣẹ́gun lóri ikú; ní fifún Ọmọ ní agbára láti bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn …; ní kíkún fún [àánú àti] ìyọ́nú …; nítorítí ó ti já ìdè ikú, ní gbígbé àìṣedẽdé wọn àti àwọn ìwàìrékọjá wọn rù, ní rírà wọ́n padà, tí ó sì ti tẹ àwọn ìbéèrè àìsègbè lọ́rùn.”19
Àwọn ìgbésẹ̀ tí Ọlọ́run fihàn pé a gbọdọ̀ gbé láti tẹ̀lé Jésù kí a sì gba ìyè ayérayé ni a pè ní ẹ̀kọ́ Krístì. Wọ́n wà pẹ̀lú “ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, ìrìbọmi [sínú Ijọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn], gbígba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti fíforítì dé òpin.”20 Mo pín àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi, ṣùgbọ́n níhĩn ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ nínú èyítí àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì ti kọ́ni bí ẹ̀kọ́ Krístì ṣe le bùkún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.
Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé: “Ẹkọ́ mímọ́ ti Krístì kún fún agbára. Ó nṣe àyípadà ìgbé ayé olukúlùkù ẹnití ó ní òye rẹ̀ tí ó sì nlépa láti mú un lò nínú ìgbé ayé rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin.”21
Alàgbà Dieter F. Uchtdorf taught, “[Atọ́nà] Fún Okun àwọn [ọ̀dọ́] hàn kedere ní kíkéde nípa … Krístì [àti] pípe [àwọn ọ̀dọ́] láti ṣe àṣàyàn tí ó dálé orí [rẹ̀].”22
Alàgbà Dale G. Renlund kọ́ni, “A pè àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere láti ṣe ohun tí wọ́n bèère lọ́wọ́ àwọn wọnnì tí wọ́n kọ́ láti ṣe: … lo ẹ̀kọ́ Krístì nínú ayé wọn [àti] títẹ̀síwájú kí wọ́n sì dúró lórí ipa-ọ̀nà májẹ̀mu.”23
Ẹkọ́ Krístì nró àwọn tí wọ́n ntiraka tàbí tí wọ́n ní ìmọ̀lára pé àwọn kò yẹ nínú Ìjọ lágbára nítorípé ó nràn wọ́n lọ́wọ́, bí Alàgbà D. Todd Christofferson ti sọ, “mo fi ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé: Jésù Krístì kú fún mi Ó [sì] fẹ́ràn mi.”24
Ẹ̀yin òbí, bí ọmọ yín bá ntiraka pẹ̀lú ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere kan tàbí ìkọ́ni bíi ti wòlíì, ẹ jọ̀wọ́ ẹ tako èyíkéyí irú sísọ̀rọ̀ ibi26 tàbí ìwà líle sí Ìjọ tàbí àwọn olórí rẹ̀. Àwọn ọ̀nà kékeré, ti ẹ̀kọ́ wọ̀nyí kò tóo yín ó sì léwu sí ìṣòdodo ọjọ́ iwájú ọmọ yín.26 Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ dáradára nípa yín pé ẹ ó dáàbò bò tàbí ṣe alágbàwí fún ọmọ iyebíye yín tàbí fi àwọn àmì ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ hàn lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin. Ṣùgbọ́n ìyàwó mi, Jayne, àti èmi mọ̀ láti inú ìrírí ara ẹni pé kíkọ́ àyànfẹ́ ọmọ yín ni ìdí tí gbogbo wa fi nílò Jésù Krístì dandan àti bí a ti le mú ẹ̀kọ́ aláyọ̀ Rẹ̀ lò ni ohun tí yío fún un lókun tí yío sì wò ó sàn lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin. Ẹ jẹ́kí a yí wọn sí ọ̀dọ̀ Jésù, ẹnití ó jẹ́ alágbàwí wọn tòótọ́ pẹ̀lú Baba. Àpóstélì Jòhánnù kọ́ni pé, “Ẹnikẹ́ni … ngbé nínú ẹ̀kọ́ Krístì … ní méjèèjì Baba àti Ọmọ.” Lẹ́hìnnáà ó kìlọ̀ fún wa láti ṣọ́ra “ bí ẹnikẹ́ni bá wá sí ọ̀dọ̀ yín, tí kò sí mú ẹ̀kọ́ yí wá.”27
Jayne àti èmi lọ láìpẹ́ yí sí aginjù níbití Mósè ti gbé ejò idẹ sókè níwájú alárìnkiri àwọn ọmọ Isráẹ́lì. Olúwa ti ṣe ìlérí láti wo gbogbo àwọn tí ejò olóró bá bù jẹ bí wọ́n bá kàn ti wò ó.26 Ní gbígbé ẹ̀kọ́ Krístì sókè níwájú wa, wòlíì Olúwa nṣe ohun kannáà, “pé kí òun le wo àwọn orílẹ̀ èdè sàn.”29 Eyíkéyí bíbùjẹ tàbí oró tàbí àwọn ìtiraka tí a nní ìrírí rẹ̀ nínú aginjù kíkú yí, ẹ máṣe jẹ́kí a dàbí àwọn, ti àtijọ́ àti lọ́wọ́lọ́wọ́ yí, ìbá ti jẹ́ wíwòsàn ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìbànújẹ́, “wọn kì yíó wòó … nítorípé wọn kò gbàgbọ́ pé yío wo wọ́n sàn.”30 Ìwé ti Mọ́mọ́nì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé: “Ẹ kíyèsĩ, … èyí ni ọ̀nà náà; kò sì sí ọ̀nà míràn tàbí orúkọ tí a fi fún ni lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba ènìyàn là ní ìjọba Ọlọ́run. Àti nísisìyí, kíyèsi, èyí ni ẹ̀kọ́ Krístì.“31
Ní ìrọ̀lẹ́ náà ní New Jersey, pípín ìdí tí a fi nílò Jésù Krístì àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀ fúnmi ní arábìnrin titun kan àti òun ní arákùnrin titun kan. A ní ìmọ̀lára ti àlàáfíà, tí ó nfi ẹsẹ̀ ẹ̀rí Ẹmí Mímọ́ múlẹ̀. Ní àdánidá, mo wí fún un kí ó sọ bí a ti le kàn síi kí ó sì tẹ̀síwájú nínú ìbánisọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa. Inú rẹ̀ dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀.
“Nítorínáà, bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ sí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé,” Ìwé ti Mọ́mọ́nì kéde—láti fẹ́ràn, pín, àti pè32 bí a ti nkó Isráẹ́lì ní gbogbo àwọn ìletò àti àwọn ẹbíwa—”pé kí wọn ó le mọ̀ pé kò sí ẹran ara tí yío gbé ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bíkòṣe pé ó jẹ́ nípasẹ̀ àwọn ìtọ́sí, àti àánú, àti oore ọ̀fẹ́ [àti ẹ̀kọ́] ti Messia Mímọ́ náà.”33 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.