Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Gbígbẹ́kẹ̀lẹ́ Ẹ̀kọ́ Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


10:30

Gbígbẹ́kẹ̀lẹ́ Ẹ̀kọ́ Krístì

Nígbàtí a bá ti kọ́ àwọn ilé wa sórí ìpìlẹ̀ ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú pẹ̀lú Krístì, a ngbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì.

Ní ojú inú mi, mo rí wòlíì Néfì tí ó ti darúgbó ní orí tábìlì rẹ̀, àwọn àwo wúrà tí wọ́n tàn kálẹ̀ níwájú rẹ̀, stylus rẹ̀ wà lọ́wọ́.

Néfì wà nínú ètò píparí fífín tó gbẹ̀hìn lórí àkọsílẹ̀ náà. Ó kọ̀wé pé, “Àti nísisìyí, ẹ̀yin ará àyànfẹ́ mi, mo parí àwọn ọ̀rọ̀ mi.”1 Ṣùgbọ́n láìpẹ́ lẹ́hìnnáà, Ẹ̀mí rọ Néfì láti padà sí àkọsílẹ̀ rẹ̀ kí ó sì kọ ọ̀rọ̀ ìparí kan. Lábẹ́ ipa alágbára ti Ẹ̀mí Mímọ́, wòlíì nlá yẹn tún mú stylus ni ọwọ́ rẹ̀ ó sì kọ̀wé pé, “Nítorínáà, àwọn ohun … tí mo kọ ti tó mi, bí kò ṣe àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ … mo gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Krístì.”2

Báwo ni a ṣe nfi ìmoore ayérayé hàn fún “àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ wọ̀nnì”3 àti fún Néfì tí Ẹ̀mí fi agbára mú láti kọ wọ́n. Ìwé àtọwọ́dọ́wọ́ Néfì lórí ẹ̀kọ́ ti Krístì jẹ́ ìṣúra iyebíye kan fún àwọn tí wọ́n ṣe àpèjẹ lórí rẹ̀. Ó pẹ̀lú ìran ìrìbọmi ti Olùgbàlà4 àti ohùn ti Ọmọ, tí npe gbogbo ènìyàn láti tẹ̀ lé E5 kí a sì “ṣe àwọn ohun tí [a] ti rí tí [Ó] nṣe.”6 Ó ní ẹ̀rí Néfì nínú pé àwọn ẹnití, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì, bá ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tọkàntọkàn tí wọ́n sì tẹ̀lé Olùgbàlà sínú omi ìrìbọmi yíò “gba Ẹ̀mí Mímọ́; bẹ́ẹ̀ni, nígbànáà ni ìrìbọmi ti iná àti ti Ẹmí Mímọ́ nwá.”6 A gbọ́ ohùn Baba tí njẹ́ ẹ̀rí pé: “Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ọ̀rọ̀ Àyànfẹ́ mi jẹ́ òtítọ́ àti òdodo. Ẹni tí ó bá forítìí títí dé òpin, òun nã ni a ó gbàlà.”8

Ààrẹ Russell M. Nelson nígbà kan tẹnumọ́ jíjẹ́ pàtàkì kanṣoṣo ti ẹ̀kọ́ Krístì nígbàtí ó nsọ̀rọ̀ sí àwọn olùdarí iṣẹ́ ìránṣẹ ìhìnrere tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pè: “Ju ohunkóhun míràn lọ, a fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ ìhìnrere wa … ní ẹ̀kọ́ Krístì ní fífín sí ọkàn wọn—ní títa gbòngbò … nínú mùdùn-múdùn inú egungun wọn.”9

Wàásù ìhìnrere Mi nṣe àfihàn àwọn èròjà marun ti ẹ̀kọ́ Krístì. Ó wípé “[A] npe àwọn ẹlòmíràn wá sí ọ̀dọ̀ Krístì nípa rírànwọ́nlọ́wọ́ láti gba ìhìnrere tí a mú padàbọ̀sípò nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, gbígba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti fífi ara dà dé òpin.”10

Ṣùgbọ́n jíjẹ́ pàtàkí ẹ̀kọ́ Krístì kìí ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nikan! Àti pé ó jinlẹ̀ púpọ̀ síi ju àtúnwí àkópọ̀ lásán ti àwọn kókó èròjà rẹ̀ marun. Ó pẹ̀lú òfin ti ìhìnrere. Ó jẹ́ ètó nlá fún ayérayé náà.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí a bá fẹ́ gba ìpè Ààrẹ Nelson láti jẹ́ kí ẹ̀kọ́ Krístì fìdímúlẹ̀ nínú mùdùn-múdùn inú egungun wa a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyípadà wa jinlẹ̀ sí Olúwa nípa àṣàrò, nípa àdúrà, gbígbé ayé òtítọ́, àti títẹ̀síwájú nínú ìrònúpìwàdà. A gbọ́dọ̀ pe Ẹ̀mí Mímọ́ láti fín ẹ̀kọ́ Krístì sínú “àwọn tábìlì ẹran ọkàn [wa]”11 ní jíjìnlẹ̀ àti ní pípẹ́ títí bí a ti fín in láti ọwọ́ Néfì sórí àwọn àwo wúrà.

Oṣù Kẹwa tó kọjá, Ààrẹ Nelson béèrè, “Kí ni ó túmọ̀ sí láti ṣẹ́gun ayé?” Ní àárín àwọn ohun míràn, ó wípé, “Ó túmọ̀ sí gbígbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì ju àwọn ọgbọ́n ènìyàn lọ.”12

Ọ̀rọ̀ náà ìgbẹ́kẹ̀lé ni ó túmọ̀ sí “gbígbáralé ìdánilójú lórí ìwà, agbára, okun, tàbí òtítọ́ ẹnìkan tàbí ohunkan.”13 Pé ẹnìkan ni Jésù Krístì, àti pé ohun kan náà ni ẹ̀kọ́ Rẹ̀.

Báwo ni mímọ̀ọ́mọ̀ láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹ̀kọ́ Krístì yíò ṣe yí ọ̀nà tí a fi ngbé ìgbésí ayé wa padà?

Bí a bá ti gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì, a ó gbẹ́kẹ̀lé Krístì tó láti gbé nípa gbogbo ọ̀rọ̀ Rẹ̀.14 A ó fi gbogbo ọjọ́ ayé ṣe àṣàrò Jésù Krístì,15 Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, àti Ètùtù àìlópin Rẹ̀, pẹ̀lú Àjínde ológo Rẹ̀. A ó ṣe àṣàrò nípa àwọn ìlérí Rẹ̀ àti àwọn ipò lórí èyítí a ti nfùnni ní àwọn ìlérí Rẹ̀.16 Bí a ṣe nṣàṣàrò, a ó kún fún ìfẹ́ nlá fún Olúwa.

Bí a bá gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì, a ó tọ Baba Ọ̀run wá lójoójúmọ́ nínú ìrẹ̀lẹ̀, àdúrà ìkọ̀kọ̀, níbití a ti lè fi ọpẹ́ hán fún ẹ̀bùn Ọmọ Rẹ̀ àti fún gbogbo àwọn ìbùkún wa.17 A lè gbàdúrà fún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ìfihàn ti Ẹ̀mí Mímọ́,18 gbàdúrà láti mú ìfẹ́ wa dọ́gba pẹ̀lú rẹ̀,19 gbàdúrà láti ronú lórí àwọn májẹ̀mú wa kí a sì tún ìpinnu wa láti pa wọ́n mọ́ ṣe.20 A lè gbàdúrà láti ṣemùdúró àti láti fi ìfẹ́ hàn fún àwọn wòlíì wa, àwọn aríran, àti àwọn olùfihàn;21 láti gbàdúrà fún agbára ìwẹ̀nùmọ́ ìdáríjì;22 àti láti gbàdúrà fún agbára láti tako ìdánwò.23 Mo pè yín kí ẹ fi àdúrà ṣe ààyò nínú ayé yín, ní wíwá lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan láti mú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ yín pọ̀ si pẹ̀lú Ọlọ́run.

Bí a bá gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì, a ó ya àwọn ohun dídán ti ayé sọ́tọ̀, kí a baà lè dojúkọ Olùràpadà ayé.24 A ó ṣe àdinkù tàbí ìmúkúrò àkokò lílò lórí ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn; àwọn eré orí ayélujára; ìdáni-lárayá ṣíṣòfò, púpọ̀jù, tàbí tí kò yẹ; ìfanimọ́ra ti àwọn ìṣúra àti àwọn ohun asán ayé yí; àti àwọn ìṣẹ ṣíṣe míràn tí ó nfi àyè fún àwọn àṣà èké àti àwọn ìtọ́ni-òdì ti àwọn ìmọ̀ ènìyàn. Nínú Krístì nìkan ni a ti rí òtítọ́ àti ìmúṣe.

Ìrònúpìwàdà tòótọ́25 yíò di apákan ayọ̀26 ti ìgbésí ayé wa—méjèèjì láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì àti láti di yíyípadà ní àwòrán Krístì.27 Ìrònúpìwàdà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì fún wa ní ààyè sí Ètùtù Krístì. Ààrẹ Dallin H. ​​Oaks ti kọ́ni pé nígbàtí Olùgbàlà bá dáríjì, Ó “ṣe ju wíwẹ̀ [wa] mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Ó tún fún wa ní agbára titun.”28 Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nílò okun yí láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ àti láti mú èrò ìgbésí ayérayé wa ṣẹ.

Nínú Jésù àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀, a rí okun. Ó wípé, “Lõtọ́, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé èyí ni ẹ̀kọ́ mi, àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́lé lé èyí kọ́lé sórí àpáta mi, àwọn ẹnu-ọ̀nà ọ̀run àpáàdì kì yíò lè borí wọn.”29

A rí tí ìlérí yí di mímúṣẹ nínú ayé àwọn olõtọ́ ènìyàn. Ní bí ọdún ó lé sẹ́hìn tí mo ní ànfàní láti pàdé Travis àti Kacie. Wọ́n ṣe ìgbéyàwó ìlú ní ọdún 2007. Nígbà náà, Travis kì í ṣe ọmọ ìjọ. Kacie, bíótilẹ̀jẹ́pé a ti tọ́ dàgbà nínú ilé aláápọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn, ó ti ṣáko kúrò nínú ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú àwọn àkókò ọ̀dọ́ rẹ̀ ó sì ti ṣáko lọ kúrò ní ìpìlẹ̀ rẹ̀.

Ní 2018, Travis pàdé àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ó sì ṣe ìrìbọmi ní 2019. Travis di ìránṣẹ́ ìhìnrere sí Kacie, ẹnití ó ní ìrírí ìyípadà-ọkàn tó nyí ìgbé ayé ẹni padà. Wọ́n fi èdìdí dì wọ́n ní tẹ́mpìlì ní Oṣù Kẹsan, 2020. Ní nkan bí ọdún méjì lẹ́hìn ìrìbọmi rẹ̀, wọ́n pè Travis láti sìn nínú ajọ bíṣọ́pù.

Travis ní àrùn kan tí ó ṣọ̀wọ́n tí ó máa nṣe àwọn ìṣùpọ̀ àwọn èèmọ́ nígbà gbogbo nínú àwọn ẹ̀yà ara inú rẹ̀. Ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ abẹ láti yọ àwọn èèmọ́ tó npadà wá náà kúrò, ṣùgbọ́n àìsàn náà kò ṣèe wòsàn. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, wọ́n fún Travis ní ó kéré ju ọdún mẹwa lọ láti gbé.

Kacie ní retinitis pigmentosa, àrùn jíìnì tí ó ṣọ̀wọ́n kan tí ó nfa dídínkù tí kò ṣeé yípadà ti ààyè ríríran títí tó fi fọ́jú pátápátá.

Kacie sọ nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀ fún mi. Ó nretí àkókò náà, tí kò jìnnà, nígbà tí òun yíò di opó, afọ́jú, láìsí ìtìlẹ́hìn owó, tí yíò sì fi òun nìkan sílẹ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ mẹ́rin tí ndàgbà. Mo bèèrè lọ́wọ́ Kacie báwo ní yíò ṣe lè kojú irú ọjọ́ iwájú tí ó ṣófo bẹ́ẹ̀. Ó rẹ́rin músẹ́ ní àláfíà ó sì wípé, “Èmi kò tíì ní ìdùnnú tàbí ìrètí díẹ̀ síi ní ayé mi. A ndi àwọn ìlérí tí a gbà ní tẹ́mpìlì mú.”

Travis ti di Bíṣọ́pù bayi. Oṣù méjì sẹ́hìn ó ṣe iṣẹ́ abẹ nlá míràn. Ṣùgbọ́n ó nírètí àti àláfíà. Ìríran Kacie ti burú si. Ó ní ajá kan bí atọ́nà báyìí kò sì lè wakọ̀. Ṣùgbọ́n ó ní ìtẹ́lọ́rùn, ó sì ntọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà ó sì nsìn bí olùdámọ̀ràn nínú àjọ aàrẹ Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin.

Travis àti Kacie nkọ́ ilé wọn sí orí àpáta. Travis àti Kacie gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì àti ìlérí pé Ọlọ́run “yíò ya àwọn ìpọ́njú [wọn] sọ́tọ̀ fún èrè [wọn].”30 Nínú ètò pípé ti Ọlọ́run, ìjìyà jẹ́ ìsopọ̀ sí jíjẹ́ pípé nínú Krístì.31 Gẹ́gẹ́bí ọlọgbọ́n ọkùnrin náà nínú òwe tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta,32 nígbàtí òjò rọ̀, ti ìṣàn omi sì dé, tí afẹ́fẹ́ sì fẹ́, tí ó sí fẹ́ ilé tí Travis ati Kacie nkọ́, kò lè ṣubú, nítorí a ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí àpáta kan.33

Jésù kò sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣeéṣe ti òjò àti ìkún omi àti afẹ́fẹ́ nínú ayé wa; Ó sọ nípa ìdánilójú pé àwọn ìjì yíò dìde. Àyípadà nínú òwe kìí ṣe bóyá ìjì yíò dé bíkòṣe bí a ṣe ndáhùn sí ìpè ìfẹ́ni Rẹ̀ láti gbọ́ àti láti ṣe ohun tí Ó ti kọ́.34 Kò sí ọ̀nà míràn láti yè.

Nígbàtí a bá ti kọ́ àwọn ilé wa sórí ìpìlẹ̀ ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú pẹ̀lú Krístì, a ngbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì, bí a sì ti nwá sọ́dọ̀ Rẹ̀, a ó sì gba ìlérí ayéraye Rẹ̀. Àwọn ènìyàn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì ntẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì wọ́n sì nní ìfaradà dé òpin. Kò sí ọ̀nà míràn níbití a ti lè ní ìgbàlà nínú ìjọba ọ̀run.35

Mo jẹ́rìí araẹni ìwàláàyè, àjínde òtítọ́ ti Jésù Krístì. Mo jẹ́rìí pé Ọlọ́run Baba wa fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí Ó rán Ọmọ Rẹ̀ láti ràwá padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀35 ó sì wò wá sàn kúrò nínú ìbànújẹ́.36 Mo jẹ́rìí pé Ó ti pe wòlíì Ọlọ́run ní àkókò wa, àní Ààrẹ Russell M. Nelson, nípasẹ̀ ẹni tí Ó nsọ̀rọ̀ tí ó sì ntọ́ wa sọ́nà.

Pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, mo pé yín láti gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì, kí ẹ sì kọ́ ayé yín lé àpáta ti Olùràpadà. Kò ní já wa kulẹ̀ láéláé. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.