Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àkókò láti Gba Ìbùkún Baba Nlá Rẹ
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Àkókò láti Gba Ìbùkún Baba Nlá Rẹ

Nígbàtí ẹ bá gba ìbùkún yín, ẹ ó mọ̀ ẹ ó sì ní ìmọ̀lára bí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ṣe fẹ́ràn yín àti bí Wọ́n ṣe fi ojú sùn sí yín bí ẹnìkọ̀ọ̀kan.

Ní àná ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n Alàgbà Randall K. Bennett sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún bàbá nlá. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ nlá ó sì mí sí gbogbo wa. Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, njẹ́ mo le sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbùkún bàbá nlá bákannáà? Ẹyin Bàbá nlá, bí ìbéèrè fún àwọn ìbùkún bàbá nlá ti le pẹ̀ síi, mo gbàdúrà pé Olúwa yío bùkún yín bí ẹ ti tẹ̀síwájú láti mú ìpè yín tóbi.

Bí mo ti máa nlọ sí àwọn ìpàdé àpapọ̀ ti èèkàn, nígbà gbogbo mo máa nṣe àbẹ̀wò pẹ̀lú bàbá nlá èèkàn àti ẹnìkejì rẹ̀. Àwọn bàbá nlá jẹ́ oníwà tútù, onígbọràn, àti olùdarí àrà ọ̀tọ̀ tí a pè láti ọwọ́ Ọlọ́run. Wọ́n máa nsọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrírí ìyanu ti ẹ̀mí. Mo máa nbi wọ́n léèrè ọjọ́ orí ènìyàn tí ó kéré jùlọ àti tí ó dágbà jùlọ tí wọ́n ti fún ní ìbùkún. Títí di ìsisìyí, èyítí ó kéré jùlọ jẹ́ mọ́kànlá, èyítí ó sì dàgbà jùlọ jẹ́ mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn.

Mo gba ìbùkún bàbá nlá mi bíi ènìyàn tuntun nínú Ìjọ, ní ọjọ́ orí 19, ọdún méjì lẹ́hìn tí a rì mí bọmi. Bàbá nlá mi ti dàgbà gidigidi. Ó darapọ̀ mọ́ Ijọ ni 1916 ó sì jẹ́ olùlànà kan ti Ìjọ ní Japan. Ó jẹ́ iyì nlá fúnmi láti gba ìbùkún bàbá nlá mi láti ọwọ́ àrà ọ̀tọ̀ ọmọ-ẹ̀hìn Olúwa náà. Èdè Japaníìsì rẹ̀ fẹ́ ṣòro fúnmi díẹ̀ láti ní òye, ṣùgbọ́n ó lágbára.

Àwọn bàbá nlá tí mo ti pàdé sọ fúnmi pé púpọ̀ àwọn ènìyàn ngba àwọn ìbùkún ti bàbá nlá wọn ní gẹ́rẹ́ ṣáajú kí wọn ó tó lọ sìn ní míṣọ̀n. Ẹyin ọ̀dọ́mọkùnrin, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin, ẹyin òbí, àti ẹ̀yin bíṣọ́pù mi ọ̀wọ́n, àwọn ìbùkún ti bàbá nlá kìí ṣe fún láti ìgbaradì láti sìn ní míṣọ̀n nìkan. Àwọn ọmọ ìjọ yíyẹ tí a ti rìbọmi le gba ìbùkún bàbá nlá wọn nígbàtí àkókò bá tọ́ fún wọn.1

Ẹyin olùfẹ́ àgbà ọmọ ìjọ, àwọn kan lára yín kò tíì gba ìbùkún bàbá nlá yín síbẹ̀. Ẹ rántí, kò sí ọjọ́ orí tó pọ̀jù.

Ìyá ìyáwó mi jẹ́ ọmọ Ìjọ tó ní aápọn gidi, ní sísìn bíi olùkọ́ nínú Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ títí ó fi kọjá lọ ní ọjọ́ orí mọ́kànlé ní àádọ́rún. Ó bà mí nínú jẹ́ láti gbọ́ pé kò gba ìbùkún bàbá nlá. Ó ní ìrírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣoro nínú ayé rẹ̀, àti nítorípé òun kò ní ẹnití ó di oyè àlùfáà mú nínú ilé, kò gba púpọ̀ àwọn ìbùkún oyè àlùfáà. Ìbùkún bàbá nlá kan le ti fún un ní ìtùnú nígbàtí ó nílò rẹ̀ jùlọ.

Ẹyin àgbà, bí ẹ kò bá tíì gba ìbùkún bàbá nlá síbẹ̀, ẹ jọ̀wọ́ ẹ má ṣèyọnu! Àkókò ti gbogbo oníkalukú ní ti ẹ̀mí jẹ́ ọ̀tọ̀tọ̀ Bí o bá jẹ́ ẹni 35 tàbí 85 tí o sì ní ìfẹ́ inú, bá bíṣọ́pù rẹ sọ̀rọ̀ nípa gbígba ìbùkún rẹ.

Ẹyin ọmọ Ìjọ tuntun, njẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa àwọn ìbùkún bàbá nlá? Èmi ò mọ̀ nípa ànfààní láti gba ọ̀kan nígbàtí mo darapọ̀ mọ́ Ìjọ, ṣùgbọ́n àyànfẹ́ bíṣọ́pù mi sọ fúnmi nípa àwọn ìbùkún bàbá nlá ó sì gbàmí níyànjú láti múra láti gba tèmi lẹ́hìn tí a rì mí bọmi. Ẹyin olùfẹ́ ọmọ ìjọ tuntun, ẹ lè gba ìbùkún bàbá nlá bákannáà. Olúwa yíò ràn yín lọ́wọ́ láti múra fún ànfààní mímọ́ yí.

Ẹ jẹ́kí a wo àwọn ìdí mẹ́jì fún ìbùkún bàbá nlá:

  1. Ìbùkún bàbá nlá ní ìmọ̀ràn ti ara-ẹni láti ọ̀dọ̀ Olúwa sí yín nínú.2

  2. Ìbùkún bàbá nlá nsọ ẹ̀yà ẹbí yín nínú ilé Ísráẹ́lì.

Ìbùkún bàbá nlá yín bákannáà jẹ́ iṣẹ́ rírán láti ọ̀dọ̀ Baba yín Ọrun ó sì ṣeéṣe kí ó ní àwọn ìlérí àti ìmọ̀ràn ìmísí nínú láti tọ́ yín sọ́nà ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ìbùkún bàbá nlá kan kò ní ya àwòrán ìgbé ayé yín tàbí kí ó dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè yín. Bí kò bá mẹnuba ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan ní ìgbé ayé, ẹ máṣe rí èyí láti túmọ̀ sí pé ẹ kò ní ní ànfààní náà. Bákannáà, kò sí ìdánilójú pé gbogbo ohun tó wà nínú ìbùkún yín ni yíó wá sí ìmúṣẹ nínú ayé yí. Ìbùkún bàbá nlá jẹ́ ti ayérayé, àti pé bí ẹ bá gbé ní yíyẹ, àwọn ìlérí ti kò bá wá sí ìmúṣẹ nínú ayé yí yío jẹ́ fífúnni ní èyi tí nbọ̀.3

Bí ẹ ti gba ìkéde ti ẹ̀yà ẹbí, ẹ ó mọ̀ pé ẹ jẹ́ ti ilé Ísráẹ́lì àti irú ọmọ Abrahamu.4 Láti ní òye jíjẹ́ pàtàkì èyí, ẹ fi ojú sùn sí àwọn ìlérí ti Olúwa ṣe fún ilé Ísráẹ́lì nípasẹ̀ Abrahamu.

Nínú àwọn ìlérí wọnnì ni:

  • “Àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ yío jẹ́ àkàìníye (ẹ wo Genesisi 17:5–6; Abrahamu 2:9; 3:14).

  • “Àwọn irú ọmọ rẹ̀, tàbí àwọn àtẹ̀lé rẹ̀, yíó gba ìhìnrere wọn ó sì ní oyè àlùfáà (ẹ wo Abrahamu 2:9).

  • “Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti irú-ọmọ rẹ̀, ‘gbogbo àwọn ẹbí ti ilẹ̀ ayé [yío] di alábùkún fún, àní pẹ̀lú àwọn ìbùkún Ìhìnrere, èyí tí ó jẹ́ àwọn ìbùkún ìgbàlà, àní ti ìyè ayérayé’ (Abrahamu 2:11).”5

Àwa bí ọmọ Ìjọ, a jẹ́ ọmọ májẹ̀mú náà.6 A ngba àwọn ìbùkún bíi ti májẹ̀mú Abrahamu bí a ti ngbọràn sí àwọn òfin àti àwọn ìlànà ìhìnrere.

Ìmúrasílẹ̀ fún ìbùkún bàbá nlá yín yío ràn yín lọ́wọ́ láti mú ìgbàgbọ́ yín nínú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì pọ̀ síi. Àti nígbàtí ẹ bá gba ìbùkún yín tí ẹ sì kà á àti tí ẹ ronú rẹ̀ jìnlẹ́, ẹ ó le fojúsùn sí Wọn léraléra síi.

Ààrẹ Thomas S. Monson ṣe àlàyé pé, “Olúwa kannáà ẹnití ó pèsè Làìhónà fún Léhì npèsè ẹ̀bùn kan tó ṣọ̀wọ́n àti iyebíye fún ẹ̀yin àti fún èmi lóni láti fúnni ní ìdarí sí ayé wa, láti fi àmì sí àwọn ewu sí ààbò wa, àti láti la ipa ọ̀nà, àní àwọn ọ̀nà àìléwu—kìí ṣe sí ìlẹ̀ ìléri kan, ṣùgbọ́n sí ilé wa ọ̀run.”7

Ẹyin bíṣọ́pù, ẹ̀yin òbí, ẹ̀yin ààrẹ iyejú àwọn alàgbà àti ti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, ẹ̀yin olùdarí míṣọn ní wọ́ọ̀dù, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin oníṣẹ ìránṣẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ jọ̀wọ́ ẹ gba àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọdọ́mọbìnrin, àwọn àgbà ọmọ ìjọ, àti àwọn ọmọ ìjọ tuntun tí wọn kò tíì gba ìbùkún bàbá nlá wọn níyànjú láti wá ìtọ́ni àti ìrànlọ́wọ́ Olúwa ní gbígba ara wọn dì láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Mo máa nka ìbùkún bàbá nlá mi léraléra àti tàdúrà-tàdúrà; ó máa nfi ìgbà gbogbo fúnmi ní ìgbani-níyànjú. Mo mọ ohun tí Olúwa nreti nípa mi, ó sì ti rànmí lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà kí nsì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Nígbàtí mo bá kà á tí mo sì ronú jinlẹ̀, mo máa nfẹ́ láti gbé ìgbé ayé yíyẹ fún gbígba àwọn ìbùkún tó ṣèlérí.

Gẹ́gẹ́bí àwọn ìwé mímọ́ tí a ti kà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ṣe máa nní ìtumọ̀ tuntun sí wa lẹ́hìnwá, ìbùkún bàbá nlá wa yío ní ìtumọ̀ tó yàtọ̀ sí wa ní àwọn àkókò ọ̀tọ̀tọ̀. Tèmi ni ìtumọ̀ tó yàtọ̀ nísisìyí ju bí ó ti ní nígbàtí mo jẹ́ 30 àti nígbàtí mo jẹ́ 50. Kìí ṣe pé àwọn ọ̀rọ̀ yípadà, ṣùgbọ́n a nrí wọn ní ọ̀nà tó yàtọ̀.

Ààrẹ Dallin H. Oaks sọ pé ìbùkún bàbá nlá “njẹ́ fífúnni lábẹ́ ìmísí ti Ẹmí Mímọ́ ó sì gbọdọ̀ jẹ́ kíkà àti títúmọ̀ lábẹ́ ipá Ẹmí yí kannáà. Ìtumọ̀ àti síṣe pàtàkì ìbùkún bàbá nlá yío jẹ́ kíkọ́ni ìlà lórí ìlà bí àkókò ti nkọjá nípa agbára ti Ẹmí kannáà tí ó mú ìmísí [rẹ̀] wá.”8

Ẹyin arákùnrin àti ẹ̀yin arábìnrin, mo jẹ́ ẹ̀rí mi pé Bàbá Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Bíbi Rẹ̀ Kanṣoṣo, Olúwa Jésù Krístì, wà láàyè. Wọ́n fẹ́ràn wa. Ǎwọn ìbùkún bàbá nlá jẹ́ àwọn ẹ̀bùn mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Wọn. Nígbàtí ẹ bá gba ìbùkún yín, ẹ ó mọ̀ ẹ ó sì ní ìmọ̀lára bí Wọ́n ṣe fẹ́ràn yín àti bí Wọ́n ṣe fi ojú sùn sí yín bí ẹnìkọ̀ọ̀kan.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ẹ̀rí mĩràn nípa Jésù Krístì. Mo fi ìmoore hàn láti jẹ́ dídarí nípasẹ̀ wòlíì alààyè kan, Ààrẹ Russell M. Nelson.

Mo fi ìmoore hàn gidigidi fún Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Ní Ọjọ́ Ìsinmi Ajínde yí èmi ó fojúsùn sí Òun àti Ajínde Rẹ̀, èmi ó sì jọ́sìn Rẹ̀ èmi ó sì dúpẹ́ fún ìrúbọ Rẹ̀. Mo mọ̀ pé Ó jìyà jinlẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ nítorípé Ó ní ìfẹ́ wa jinlẹ̀ tóbẹ́ẹ̀. Mo mọ̀ pé a jí I dìde nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa. Ó wà nítòótọ́ Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbo: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 4.1, ChurchofJesusChrist.org.

  2. Wo “Àwọn Ìbùkún Ti Babanla,” nínú Òtítọ́ sí Ìgbàgbọ́ Náà (2004), 112.

  3. Wo “Àwọn Ìbùkún Ti Babanla,” nínú Òtítọ́ sí Ìgbàgbọ́ Náà, 113.

  4. Wo Abrahamu 2:10.

  5. Májẹ̀mú Ti Ábráhámù,” nínú Òtítọ́ sí Ìgbàgbọ́ Náà, 5.

  6. Wo 3 Néfì 20:25–26.

  7. Thomas S. Monson, “Ìbùkún Ti Bàbá Nlá Yín: Atọ́nà Ìmọ́lẹ̀,” Ensign, Nov. 1986, 65.

  8. Dallin H. Oaks, “Àwọn Ìbùkún Bàbá Nlá,” Worldwide Leadership Training Meeting: The Patriarch, Jan. 8, 2005, 10.