Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣá Maa Tẹ̀síwájú—pẹ̀lú Ìgbàgbọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Ṣá Maa Tẹ̀síwájú—pẹ̀lú Ìgbàgbọ́

Ṣùgbọ́n lílo ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, nràn wá lọ́wọ́ láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì ohunkóhun tí àwọn ìdènà tí a nkojú le jẹ́.

Alàgbà George A. Smith, Àpóstélì kan, gba ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Wòlíì Joseph Smith ní àkókò ìṣoro nlá kan: “Ó sọ fún mi kí nmáṣe rẹ̀wẹ̀sì láé, èyíkéyí àwọn ìṣoro tí ó le yí mi ká. Bí mo bá rì sínú ọ̀gbun rírẹlẹ̀ jùlọ ti Nova Scotia àti tí gbogbo àwọn Òkè Olókũta kójọ lé mi lórí, kò yẹ kí èmi ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ṣùgbọ́n kí èmi ó dìrọ̀mọ́ síbẹ̀, lo ìgbàgbọ́, kí nsì pa ìgboyà rere mọ́ àti kí èmi ó jáde wá sí orí òkè ebè náà ní ìkẹhìn.”1

Báwo ni Wòlíì Joseph náà ṣe le sọ èyí—sí ẹnìkan tí ó njìyà? Nítorípé ó mọ̀ pé òtítọ́ ni. Ó gbé ìgbé ayé rẹ̀. Jósẹ́fù ní ìrírí àwọn ìṣòro líle léraléra nínú ìgbé ayé rẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí ó ti lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, tí ó sì ntẹ̀síwájú, ó borí àwọn ìdènà tí ó dàbí àìlèborí.2

Loni yío wù mí láti sọ ẹ̀bẹ̀ Jósẹ́fù di ọ̀tun làti máṣe jẹ́kí ìrẹ̀wẹ̀sì borí wa nígbàtí a bá dojúkọ ìjákulẹ̀, àwọn ìrírí tí ó kún fún ìrora, àwọn àìpé ti ara wa tàbí àwọn ìpèníjà mĩràn.

Nígbàtí mo wí pé ìrẹ̀wẹ̀sì, èmi kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpèníjà asọni-di-aláìlágbára ti àárẹ̀ ọkàn ti ilé ìtọ́jú, àwọn aláìlétò àníyàn, tàbí àwọn àìlera mĩràn tí wọ́n nílò ìtọ́jú pàtàkì.3 Emi kan nsọrọ̀ nípa ìrẹ̀wẹ̀sì àtijọ́ tí ó máa nwá pẹ̀lú àwọn gegele àti àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti ìgbé ayé.

Mo ní ìmísí nípasẹ̀ àwọn akọni mi tí wọ́n kàn ntẹ̀síwájú—pẹ̀lú Ìgbàgbọ́—ohunkóhun tí ó lè jẹ́.4 Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a kà nípa Sórámù, ìránṣẹ́ Lábánì. Nígbàtí Néfì gba àwọn àwo idẹ náà, Sórámù ní ìdojúkọ pẹ̀lú yíyàn láti tẹ̀lé Néfì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ sí inú ijù tàbí bí ó ti ṣeéṣe kí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

Irú yíyàn kan! Ohun tí Sórámù kọ́kọ́ fẹ́ ṣe ni láti sá, ṣùgbọ́n Néfì dì í mú ó sì ṣe ìbúra kan pé bí ó bá lọ pẹ̀lú wọn, òun yío di òmìnira yío sì ní ibikan pẹ̀lú ẹbí wọn. Sórámù ṣe ìgboyà ó sì lọ pẹ̀lú wọn.5

Sórámù jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpọ́njú nínú ìgbé ayé rẹ̀ titun, síbẹ̀ ó tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́. A kò ní atọ́ka kankan pé Sórámù so mọ́ ìgbà àtijọ́ rẹ̀ tàbí fi ààyè gba ìbínú sí Ọlọ́run tàbí àwọn ẹlòmíràn.6 Ó jẹ́ ọ̀rẹ́ òtítọ́ sí Néfì, wòlíì kan, òun àti irú ọmọ rẹ̀ sì gbé ní òmìnira àti ìṣe rere nínú ilẹ̀ ìlérí náà. Ohun tí ó ti jẹ́ ìdènà nlá kan ní ipa ọ̀nà Sórámù darí ní ìgbẹ̀hìn sí àwọn ìbùkún ọlọ́rọ̀, nítorí ìgbàgbọ́ àti síṣetán rẹ̀ láti ṣá maa tẹ̀síwájú—pẹ̀lú ìgbàgbọ́.7

Láìpẹ́ yí mo tẹ́tísí arábìnrin onígboyà kan tí ó ṣe àbápín bí ó ti fi ara dà la àwọn ìṣoro kọjá.8 Ó ní àwọn ìpèníjà kan, àti pé ní Ọjọ́ Isinmi kan ó jókòó nínú Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ní fífetí sí olùkọ́ni kan ẹnití ó rò pé ó ngbé ìgbé ayé pípé-bíi-àwòrán—tí ó yàtọ̀ pátápátá sí tirẹ̀. O rẹ̀ ẹ́ ó sì ní ìrẹ̀wẹ̀sì. Ó ní ìmọ̀lára bí ẹnipé òun kò kún ojú òsùnwọ̀n—tàbí jẹ́ ti ẹgbẹ́ pàápàá—nítorínáà ó díde ó sì lọ, ní rírò láti máṣe padà sínú ijọ mọ́ láé. Bí ó ti nlọ sí ibi ọkọ̀ rẹ̀, ó ní ìmọ̀lára títẹ̀mọ́ tí ó yàtọ̀ kan pé: “Lọ sínú ilé ìjọsìn kí o sì fetísí olùsọ̀rọ̀ ibi ìpàdé oúnjẹ Olúwa.” Ó ja ìṣìlétí náà níyàn ṣùgbọ́n ó ní ìmọ̀lára rẹ̀ líle lẹ́ẹ̀kansíi, nítorínáà ó lọ sí inú ìpàdé náà.

Ọrọ̀ náà jẹ́ ohun tí ó nílò gan an. Ó ní ìmọ̀lára Ẹmí Ó mọ̀ pé Olúwa fẹ́ pé kí ó dúró ti Òun, láti jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀, àti láti máa wá sí ilé ìjọsìn, nítorínáà ó ṣe bẹ́ẹ̀.

Njẹ́ ẹ mọ ohun tí ó dúpẹ́ fún? Pé òun kò juwọ́lẹ̀. Ó ṣá tẹ̀síwájú—pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, àní nígbàtí ó nií lára, òun àti ẹbí rẹ̀ sì di alábùkún fún lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ó ti ntẹ̀síwájú.

Ọlọ́run ọ̀run àti ayé yío ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì àti èyíkéyi àwọn ìdènà ti a le dojukọ bí a bá wò Ó, tí a tẹ̀lé àwọn ìṣílétí ti Ẹmí Mímọ́,9 àti tí a ṣá ntẹ̀síwájú—pẹ̀lú ìgbàgbọ́.

Pẹ̀lú ọpẹ́, nígbàtí a bá ní àìlera tàbí àlébù, Olúwa lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Ó lè mú agbára wa pọ̀si kọjá ti arawa. Mo ti ni ìrírí èyí. Ó jú ogún ọdún sẹ́hìn, tí a pè mí láìròtẹ́lẹ̀ bíi Àádọrin Agbègbè kan, mo sì ní ìmọ̀lára àìkún-ojú-òsùnwọ̀n gan. Ní títẹ̀lé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn iṣẹ́ yíyàn mi, èmi níláti ṣe àkóso àkọ́kọ́ mi ní ibi ìpàdé àpapọ̀ èèkàn.10 Ǎàrẹ èèkàn náà àti èmi fi ara balẹ̀ ṣe ètò gbogbo nkan. Ní àkókò díẹ̀ ṣaájú ìpàdé àpapọ̀ náà, Ààrẹ Boyd K. Packer, Àdele Ààrẹ ti Ìyejú àwọn Àpóstelì Méjìlá nígbànáà, pè láti ríi bóyá òun le bá mi lọ. Ó yà mí lẹ́nu àti pé, bẹ́ẹni, mo gbà. Mo bééré bí ó ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ìgbàtí ó jẹ́ pé òun ni yío ṣe àkóso. Ó dá àbá pé kí a pa àwọn ètò náà tì kí a sì múra láti tẹ̀lé Ẹ̀mí. Pẹ̀lú ọpẹ́, mo ṣì ní ọjọ́ mẹ́wàá láti ṣe àṣàrò, gbàdúrà, àti láti múra.

Pẹ̀lú ìlànà tó ṣí sílẹ̀ kan, a ti dé orí ìjókòó ní ogún ìṣẹ́jú kí ìpàdé àwọn olùdarí tó bẹ̀rẹ̀. Mo fi tẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ààrẹ èèkàn náà mo sì sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, “Èèkàn ìyanu kan ni èyí.”

Ààrẹ Packer rọra fi ìgbùnwọ́ kan mí ó sì wípé, “Kò sí ọ̀rọ̀ sísọ.”

Mo dáwọ́ ọ̀rọ̀ sísọ dúró, ọ̀rọ̀ ìpàdé-àpapọ gbogbogbò rẹ̀ “Ìdákẹ́jẹ́ Npe Ìfihàn”11 sì wá sí ọkàn. Mo ṣe àkíyèsí pé Ààrẹ Packer nkọ àwọn atọ́ka ìwé mímọ́ sílẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ sí mi pé ó ngba àwọn ìtẹ̀mọ́ra fún ìpàdé náà. Ìrírí ẹ̀kọ́ kíkọ́ mi ti ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀

Ààrẹ Packer sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún àkọ́kọ́ ó sì tẹnumọ́ pàtàkì dídárí àwọn ìpàdé bí Ẹmí Mímọ́ bá ṣe tọ́ni.12 Nígbànáà ó sọ pé, “A ó gbọ́ nisisìyí láti ẹnu Alàgbà Cook.”

Bí mo ti nlọ sí orí àga ìwáàsù, mo béèrè iye àkókò tí ó fẹ́ kí ngbà àti bí ó bá ní àkòrí kan pàtó tí ó fẹ́ kí nsọ̀rọ̀ lé lórí. Ó wípé, “Lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún sì tẹ̀síwájú bí ó bá ṣe ní ìmọ̀lára ìmísí.” Mo lo ìṣẹ́jú mẹ́rìnlá mo sì ṣe àbápín gbogbo ohun tí mo ní lọ́kàn.

Ààrẹ Packer tún dìde ó sì sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún mĩràn. Ó ṣe àbápín ìwé mímọ́ yí:

“Ẹ sọ àwọn èrò tí èmi yíò fi sínú ọkàn yín, a kì yíò sì dààmú yín níwájú àwọn ènìyàn;

“Nítorí a ó fi fún yín … ní ìṣẹjú náà gan an, ohun tí ẹ̀yin yíò wí.”13

Nígbànáà ó sọ pé, “A ó gbọ́ nisisìyí láti ẹnu Alàgbà Cook.”

Ó yàmí lẹ́nu. Èmi kò rò ó rí láé pé ó ṣeéṣe kí a pèmí láti sọ̀rọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mejì nínú ìpàdé kan. Èmi ko ní ohun kan lọ́kàn láti sọ. Ní gbígbàdúrà pẹ̀lú ìtara àti gbígbẹ́kẹ̀lé Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, bákannáà, a bùkún mi pẹ̀lú èrò kan, ìwé mímọ́ kan, ó sì ṣeéṣe fún mi láti sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún mĩràn. Mo jókòó pẹ̀lú rírẹ̀ tán pátápátá.

Ààrẹ Packer tún sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún nípa títẹ̀lé Ẹmí ó sì ṣe àbápín àwọn ìkọ́ni Paulù pé a kò sọ “àwọn ọ̀rọ̀ èyítí ọgbọ́n ènìyàn nkọ́ni, ṣùgbọ́n èyítí Ẹmí Mímọ́ fi nkọ́ni.”14 Bí ẹ ti le fi ojú inú wòó, ó yàmí lẹ́nu nígbàtí ó ní ìtẹ̀mọ́ra láti sọ fún ìgbà kẹta pé, “A ó gbọ́ nisisìyí láti ẹnu Alàgbà Cook.”

Mo jẹ́ òfìfo. Èmi kò ní ohunkóhun. Mo mọ̀ pé ó jẹ́ àkókò láti lo ìgbàgbọ́ síi. Pẹ̀lú ìlọ́ra, mo wá ọ̀nà mi lọ sí ibi àga ìwàásù, ní bíbẹ Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́. Bí mo ti dé ibi gbohùn-gbohùn, pẹ̀lú ìyàlẹ́nu Olúwa bùkún mi láti fúnni ní ọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún mĩràn.15

Ìpàdé náà parí ní ìgbẹ̀hìn, ṣùgbọ́n mo tètè rántí pé abala ti àwọn àgbà yío bẹ̀rẹ̀ ní wákàtí kan. “Ah, rárá! Bíi Sórámù, ní tòótọ́ mo fẹ́ sá, ṣùgbọ́n bí Néfì ṣe mú un, mo mọ̀ pé Ààrẹ Packer yío mú mi. Ìpàdé àwọn àgbà tẹ̀lé irú àpẹrẹ kannáà gan an. Mo sọ̀rọ̀ ní ìgbà mẹ́ta síi. Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lé ní abala gbogbogbò, mo sọ̀rọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan.

Lẹ́hìn ìpàdé àpapọ̀ náà, Ààrẹ Packer sọ pẹ̀lú ìfẹ́ni pé, “Jẹ́ ká tún ṣe é lẹ́ẹ̀kansíi nígbà míràn.” Mo fẹ́ràn mo sì mọ rírì Ààrẹ Boyd K. Packer àti gbogbo ohun tí mo kọ́.

Njẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ní ìmoore fún? Pé èmi kò juwọ́lẹ̀—tàbí ṣe àtakò. Bí mo bá ti fàyè gba ìfẹ́ inú mi kíkan láti sálọ kúrò nínú àwọn ìpàdé wọnnì, èmi kì bá ti pàdánù ànfàní láti mú kí ìgbàgbọ́ mi pọ̀ síi kí nsì gba ọ̀pọ̀ ìtújáde ìfẹ́ àti àtìlẹ́hìn ọrọ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi Ọrun. Mo kọ́ nípa àánú Rẹ̀, agbára ìmúṣeéṣe yíyanilẹ́nu ti Jésù Kristì àti Ètùtù Rẹ̀, àti ipá tó lágbára ti Ẹmí Mímọ́. Pẹ̀lú àìlágbára mi,16 mo kọ́ pé mo le sìn, mo le dásí nígbàti Olúwa bá wà ní ẹ̀gbẹ́ mi bí mo bá ṣá tẹ̀síwájú—pẹ̀lú Ìgbàgbọ́.

Láìka ìwọ̀n, bí ó ti tó, àti ṣíṣe pàtàkì àwọn ìpèníjà tí a ndojúkọ nínú ayé sí, gbogbo wa ní àwọn àkókò nígbàtí a ní ìmọ̀lára bíi dídúró, kíkúrò, sísálọ, tàbí bí ó ti ṣeéṣe láti juwọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n lílo ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, nràn wá lọ́wọ́ láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì ohunkóhun tí àwọn ìdènà tí a nkojú le jẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà ti parí iṣẹ́ ti a fifún Un lati ṣe, Ó ní agbára láti rànwá lọ́wọ́ láti parí iṣẹ́ ti a ti fi fúnwa,17 A le bùkún wa láti sún síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú, bí ó ti wù kí ó di olókuta tó, àti ní ìgbẹ̀hìn kí a gba ìyè ayérayé.18

Bí Wòlíì Joseph Smith ti sọ, “Ẹ dúro ṣinṣin, ẹ̀yin Ènìyàn Mímọ́ ti Ọlọ́run, ẹ dúró pẹ́ díẹ̀ síi, àti pé ìjì ayé yío kọjá, a ó sì fún yín ní èrè láti ọwọ́ Ọlọ́run náà ìránṣẹ́ ẹni tí ẹ̀yin í ṣe.”19 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. George A. Smith, nínú Àwọn Ìkọ́ni Àwọn Ààrẹ Ijọ: Joseph Smith (2007), 235.

  2. Wo Àwọn Ìkọ́ni: Joseph Smith, 227–36.

  3. Nígbàtí mo sọ̀rọ̀ nípa ìrẹ̀wẹ̀sì, èmi kò dá àbá pé “láti ṣá maa tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì” nìkan ni aápọn tí a nílò fún àwọn ènìyàn tí wọ́n nní ìrírí àárẹ̀ ọkàn ti ilé ìtọ́jú, àwọn aláìlétò àníyàn, tàbí àwọn àìlera mĩràn. Fún àwọn ọ̀rẹ́, àwọn ọmọlẹ́bí, àti àwọn míràn tí wọ́n ngbọ́, mo ṣe àtúnsọ ìmọ̀ràn àwọn olùdarí Ìjọ wa láti jọ̀wọ́ wá ìtọ́jú ti ìṣègùn òyìnbó, ti ọpọlọ, àti ti ẹ̀mí bí wọ́n ti nní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa. Ọkàn mi lọ sí ọ̀dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín tí ó ti jìyà àwọn àdánù wọ̀nyí tàbí òmíràn. À ngbàdúrà fún yín nítòótọ́.

  4. Díẹ̀ lára àwọn akọni mi nínú àwọn ìwé mímọ́ ní Caleb (wo Númérì 14:6–9, 24), Jobù (wo Jobù 19:25–26), ati Néfì nínú (wo 1 Nephi 3:7), ní àfikún sí àwọn akọni mi ti òde-oní.

  5. Wo 1 Néfì 4:20, 30–35, 38.

  6. Wo Dale G. Renlund, “Infuriating Unfairness,” Liahona, May 2021, 41–45.

  7. Wo 2 Nefi 1:30–32. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé [Sórámù] níláti fi ara da ọwọ́ líle, pàkúté tí a fi mú un jẹ́ ipò gan an nípasẹ̀ èyí tí Ọlọ́run ti pinnu láti bùkún rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó nílati fi ilẹ̀ ìbí rẹ̀ sílẹ̀, Ọlọ́run npèsè ìkan tí ó dárajù” (David B. Paxman, “Zoram àti èmi: Gbígba àwọn Ìtàn Wà Tààrà” [Brigham Young University devotional, July 27, 2010], 8 speeches.byu.edu).

  8. Mo gbọ́ ẹ̀rí arábìnrin yí ní wọ́ọ̀dù kan ní Èèkàn Riverdale Utah ni Ọjọ́ Kọkànlá Oṣù Kejìlá, 2022. Ìrírí tí ó ṣe àbápín rẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní wọ́ọ̀dù kan tí ó nlọ tẹ́lẹ̀.

  9. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 11:12–13

  10. Iṣẹ́ yíyàn mi jẹ́ ní Èèkàn Benson Utah ní 3–4 Oṣù Kọkànlá, 2001. Ààrẹ Jerry Toombs ni ààrẹ èèkàn.

  11. Wo Boyd K. Packer, “Reverence Invites Revelation,” Ensign, Nov. 1991, 21–23.

  12. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 46:2.

  13. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 100:5–6; bákannáà wo àwọn ẹsẹ 7–8.

  14. 1 Kọ́ríntì 2:13.

  15. Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ pé, “Nígbàtí o bá nà tàntàn ní ti ẹ̀mí tayọ ohunkóhun tí o ti ṣe tẹ́lẹ̀rí, nígbànáà agbára [ti Olùgbàlà] yío ṣàn sí ọ̀dọ̀ rẹ” (“Fífa Agbára Jésù Krístì Sínú Ayé Wa,” Liahona, May 2017, 42).

  16. Wo Étérì 12:27.

  17. Wo Jòhánù 17:4.

  18. Wo 2 Néfì 31:20; Mòsíà 2:41; Álmà 36:3.

  19. Àwọn Ìkọ́ni: Joseph Smith, 235.