Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Rántí Ohun Tó Ṣe Kókó Jùlọ
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


13:30

Ẹ Rántí Ohun Tó Ṣe Kókó Jùlọ

Ohun tí ó ṣe kókó jùlọ ni ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, àwọn ẹbí wa, àti àwọn aladugbo wa, àti fífí ààyè gba Ẹ̀mí láti tọ́ wá sọ́nà.

Bí a ti nrántí ní òpin ọ̀sẹ̀ yí, wíwọlé bíi aṣẹ́gun ti Olùgbàlà sí Jerusalem ní kété ṣíwájú ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, mo rántí àwọn ọ̀rọ̀ ìrètí àti ìtùnú Rẹ̀: “Èmi ni àjínde, àti ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mi gbọ́, bíotilẹ̀ kú, síbẹ̀ yíò yè.”1

Mo nifẹ Rẹ̀. Mo gbà Á gbọ́ Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Òun ni Àjínde àti Ìyè.

Èrí yí ti tù mí nínú ó sì ti fún mi lókun ní ọdún mẹrin àti ààbọ̀ tí ó kọjá látigbà tí ìyàwó mi, Barbara, ti kọjá lọ. Mo ṣe dárò rẹ̀.

Nígbàkugbà, mo máa nronú lórí ìgbeyàwó ayérayé wa àti ìgbé ayé wa papọ̀.

Mo ti ṣe àbápín tẹ́lẹ̀ bí mo ti kọ́kọ́ bá Barbara pàdé àti bí ìrírí náà tí kọ́ mi láti lo iṣẹ́ ti “Títọ̀lẹ́hìn” tí mo kọ́ níbi iṣẹ́ ìhìnrere. Mo níláti ṣe títọ̀ọ́lẹ́hìn kíákíá pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́hìn tí a kọ́kọ́ pàdé nítorí ó rẹwà, ó lókìkì, ó sì ní kàlẹ́ndà ìbákẹ́gbẹ́ iṣẹ́ ṣíṣe gan. A nà mí ní kùtùkùtù nítorí òun ṣee bá sọ̀rọ̀ ó sì ṣeè bádọ́rẹ́. Mo fẹ́ràn inúrere rẹ̀. Mo ní ìmọ̀lára pé òun àti èmi wàpọ̀ papọ̀. Ó dàbí ẹnipé èyí rọrùn nínú mi.

Barbara àti èmi ndọrẹ, àti pé ìbáṣepọ̀ wa bẹ̀rẹ̀sí ndàgbà, ṣùgbọ́n kò dá a lójú pé ìgbéyàwó sí mi tọ́ fún òun.

Kò tó fún mi láti mọ pé; Barbara nílò láti mọ fún ararẹ̀. Mo mọ pé bí a bá lo àkokò ní gbígbàwẹ̀ àti gbígbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, Barbara lè gba ìfẹsẹ̀múlẹ̀ láti ọ̀run.

A lo òpin ọ̀sẹ̀ láì dọ́rẹ́ kí a lè gbàwẹ̀ àti àdúrà ní kọ̀ọ̀kan láti mọ̀ fúnra wa. Ní oríre fún mi, ó gba irú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ kannáà tí mo ní. Ìyókù, bí wọ́n ti sọ, ni àkọ́ọ́lẹ̀ ìtàn.

Nígbàtí Barbara kọjá lọ, àwọn ọmọ wa fi oríṣiríṣi ẹ́kọ́ tí Barbara nfẹ́ kí wọ́n rántí sí òkúta-orí rẹ̀. Ọ̀kàn lára àwọn ẹ̀kọ́ náà ni “ohun tí ó ṣe kókó jùlọ ni ohun tí ó npẹ́ jùlọ.”

Ní òní mo fẹ́ ṣe àbápín áwọn ìmọ̀lára díẹ̀ àti èrò lórí ohun tó ṣe kókó látinú ọkàn mi.

Àkọ́kọ́, ìbáṣepọ̀ kan pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Olúwa Jésù Krístì, ni ó ṣe pàtàkì jùlọ. Ìbáṣepọ̀ yí ṣe kókó jùlọ nísisìyí àti ní àìlópin.

Ìkejì, àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí wà ní àárín àwọn ohun wọnnì tí ó ṣe kókó jùlọ.

Nínú gbogbo iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, mo ti bẹ àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ẹbí tí a ti pa lára nípasẹ̀ àwọn àjálù àdánidá bíbani nínújẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò ríbi gbé, wọ́n pebi, àyá sì fo wọ́n. Wọ́n nílò àtìlẹhìn ìtọ́jú, oúnjẹ, àti ibùgbé.

Bákannáà wọ́n nílò àwọn ẹbí wọn.

Mo damọ̀ pé àwọn kan le má tilẹ̀ ní àwọn ìbùkún ẹbí tó sunmọ́ wọn, nítorínáà mo fi àwọn ẹbí gbígbòòrò, ọ̀rẹ́, àní àti àwọn ẹbí wọ́ọdù si bí “ẹbí.” Awọn ìbáṣepọ̀ wọ̀nyí ṣe pàtàkì fún ẹ̀dùn ọkàn àti ìlera ti ara.

Àwọn ìbáṣepọ̀ wọ̀nyí bákannáà lè fúnni ní ìfẹ́, ayọ̀, ìdùnnú, àti wíwà pẹ̀lú.

Ṣíṣìkẹ́ àwọn ìbáṣepọ̀ pàtàkì wọ̀nyí jẹ́ yíyàn. Yíyàn jẹ́ ara nínílò ìfarasìn ẹbí, ìfẹ́, sùúrù, ìbárasọ̀rọ̀, àti ìdáríjì.2 Àwọn ìgbà kan lè wà nígbàtí a bá njiyàn pẹ̀lú ẹni míràn, ṣùgbọ́n a lè ṣe bẹ́ẹ̀ láì bara jiyàn. Nínú fífẹ́ra àti ìgbeyàwó, a kìí bọ́ sínú ìfẹ́ tàbí jáde nínú ìfẹ́ bí ẹni pé a jẹ́ ohun èlò tí a ntì ká nínú pátákò-ìṣeré. A yàn láti ní ìfẹ́ àti láti mú ara wa dúró. À nṣe irúkannáà nínú àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí míràn àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n dàbíẹbí sí wa.

Ìkéde ẹbí wípé “ètò ìdùnnú tọ̀run fi ààyè gba àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí láti tẹ̀síwájú kọjá isa-òkú. Àwọn ìlànà àti májẹ̀mú mímọ́ wà nínú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ mu ṣeéṣe fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti fún ẹbí láti sopọ̀ ní ayérayé.”3

Ohun míràn tí ó ṣe kókó jùlọ ni títẹ̀lé àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí nínú àwọn ìbáṣepọ̀ wa pàtàkì àti nínú àwọn ìtiraka wa láti ní ìfẹ́ àwọn aladugbo wa bí ara wa. Pẹ̀lú àwọn ibi ìkọ̀kọ̀ àti gbangba iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa. Mo kọ́ ẹ̀kọ́ yí ní kùtùkùtu ìgbé ayé mi nígbàtí mo nsìn bí bíṣọ́ọ̀pù.

Pípẹ́ ní ìrọ̀lẹ́ tútù kan, ní ìgbà òtùtù oníyìnyín, mò nfi ibi iṣẹ́ bíṣọ́ọ̀pù mi sílẹ̀ nígbàtí mo ní ìtẹ̀mọ́ra líle kan láti bẹ òpó àgbàlagbà kan wò ní wọ́ọ̀dù. Mo wo aago mi—ó jẹ́ aago mẹwa alẹ́. Mo ronú pé ó ti pẹ́ jù láti ṣe ìbẹ̀wò irú bẹ́ẹ̀. Àti pé, yìnyín tún wà. Mo pinnú láti bẹ arábìnrin ọ̀wọ́n náà wò ní ohun àkọ̀kọ̀ ní òwúrọ̀ sànju yíyọ ọ́ lẹ́nu ní irú wákàtí pípẹ́ bẹ́ẹ̀. Mo wakọ̀ lọ sílé mo sì lọ sùn ṣùgbọ́n ní yíyí àti yíyípadà ní gbogbo alẹ́ nítorí Ẹ̀mí nrú mi sókè.

Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ tótẹ̀le, mo wakọ̀ tààrà lọ sí ilé opó náà. Ọmọbìnrin rẹ̀ dá mi lóhùn ní ẹnu ọ̀nà pẹ̀lú omijé ó wípé “Ah, Bíṣọ́ọ̀pù, o ṣé fún wíwá. Ìyá kọjá lọ ní wákàtí méjì sẹ́hìn”—mo sì banújẹ́. Èmi kò ní gbàgbé ìmọ̀lára ọkàn mi láéláé. Mo sọkún. Tani ó tọ́sí ju opó àwọ́n yí lọ láti ní bísọ́ọ̀pù rẹ tó di ọwọ́ rẹ̀ mú, tù ú nínú, àti bóyá fun ní ìbùkún ìkẹhìn? Mo sọ ànfàní náà nù nítorí mo ronú ìṣílétí líle yí kúrò nínú Ẹ̀mí náà.4

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin, àti àwọn ọmọ Alakọbẹrẹ, mo jẹ́ ẹ̀rí pé títẹ̀lé àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí ni ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó ṣe kókó nínú gbogbo àwọn ìbáṣepọ̀ wa.

Nígbẹ̀hìn, ní òpin ọ̀sẹ̀ Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ yí, mo jẹri pé jíjẹ́ yíyípada sí Olúwa, jíjẹ́ ẹ̀rí nìpa Rẹ̀, àti sísìn In bákannáà wà ní àárín àwọn ohun tí ó ṣe kókó jùlọ.

Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ni ìpìlẹ̀ àwọn ẹ̀rí wa. Ẹ̀rí kan ni ijẹri kan tàbí ìfẹsẹ̀múlẹ̀ òtítọ́ ayerayé tí a tẹ̀ mọ́ ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ẹ̀mí nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ. Ẹ̀rí kan nípa Jésù Krístì, tí a bí nípa tí a sì fún lókun nípasẹ̀ Èmí, nyí ìgbé ayé padà—ó nyí ọ̀nà tí a fi nronú àti bí a ti ngbé ìgbé ayé. Ẹ̀rí kan nyí wa síwájú Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ àtọ̀runwá Rẹ̀.

Álmà kọ́ni:

“Kíyèsi, mo jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé èmi mọ̀ pé àwọn ohun èyí tí mo sọ wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́. Àti pé báwo ni ẹ ṣe rò pé mo mọ̀ òdodo wọn?

“Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún un yín pé Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run ni ó fi wọ́n hàn mí. Kíyèsĩ, èmi ti gba ãwẹ̀ mo sì ti gbàdúrà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ohun wọ̀nyí fúnra mi. Àti nísisìyí èmi sì mọ̀ ọ́ fúnra mi pé òtítọ́ ni wọ́n; nítorítí Olúwa Ọlọ́run ti fi nwọ́n hàn mí nípa Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀.”5

Níní ẹ̀rí kan nìkan kò tó. Bí ìyípadà wa sí Jésù Krístì ṣe ndàgbà, a nfẹ láti jẹri nípa—inúrere Rẹ̀, ìfẹ́, àti ìwàrere Rẹ̀ fúnra wa.

Léraléra nínú àwọn ìpàdé ní àwọn Ọjọ́ Ìsinmi àwẹ̀, a ngbọ́ àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ “Èmi dúpẹ́” áti “Èmi nifẹ” ju bí a ti ngbọ́ àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ “Èmi mọ̀” àti “Èmi gbàgbọ́.”

Mo pe yín láti jẹ́ ẹ̀rí yín nípa Jésù Krístì léraléra si. Ẹ jẹ́ ẹ̀rí nipa ohun tí ẹ mọ̀ àti ohun tí ẹ gbàgbọ́ àti ohun tí ẹ ní ìmọ̀lára, kìí ṣe ohun tí ẹ ndúpẹ́ fún nìkan. Ẹ jẹri àwọn ìrírí ara yín nípa wíwá láti mọ̀ àti láti nifẹ Olùgbàlà, àti gbígbé àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, àti nípa agbára ìràpadà àti ìlèṣe Rẹ̀ nínú ayé yín. Bí ẹ ti njẹ́ ẹ̀rí nípa ohun tí ẹ mọ̀, gbàgbọ́, tí ẹ sì nímọ̀lára, pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò fi ẹsẹ̀ òtítọ́ múlẹ̀ sí àwọn wọnnì tí wọ́n nfi taratara fetísílẹ̀ sí ẹ̀rí yín. Wọn yíò ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí wọ́n ti nwò yín tí ẹ̀ ndi alalafia àtẹ̀lé Jésù Krístì. Wọn yíò rí ohun tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọmọẹ̀hìn Rẹ̀. Bákannáà wọn yíò ní ìmọ̀lára ohunkan tí wọ́n lè má tilẹ̀ ní ìmọ̀lára rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ẹ̀rí mímọ́ kan nwá látinú ìyípadà ọkàn àti pé a lè gbe nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ sínú ọkàn àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ṣísílẹ̀ láti gbà á.

Àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìmọ̀lára ohunkan bí àbájáde ẹ̀rí yín lè bèèrè lọ́wọ́ Olúwa nígbànáà nínú àdúrà láti fi ẹsẹ̀ òtítọ́ ẹ̀rí yín múlẹ̀. Nígbànáà wọ́n lè mọ̀ fún arawọn.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo jẹri mo sì jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé mo mọ̀ pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà aráyé. Ó wà láàyè. Òun ni olùjínde Ọmọ Ọlọ́run, èyí sì ni Ìjọ Rẹ̀, tí a darí nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀ àti àwọn àpóstélì. Mo gbàdúrà pé níjọ́kan nígbàtí mo bá kọjá lọ sí ayé tó nbọ̀, èmi a lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rí mi tí o njó ginringinrin.

Nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, mo kọ́ pé ohun tí ó ṣe kókó jùlọ ni àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, ẹbí wa, àti àwọn aladugbo wa, àti fífi àyè gba Ẹ̀mí Olúwa láti tọ́ wa sọ̀nà nínú àwọn ìbáṣepọ̀ wọnnì kí a lè jẹri àwọn ohun tí ó ṣe kókó jùlọ tí ó sì pẹ́ títí. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Jòhánnù 11:25.

  2. Wo àwọn nkan “Ẹbí,” “Ìrẹ́pọ̀,” àti “Ìfẹ́}” nínú Àwọn Àkọlé Ìkàwé Ìhìnrere (ní ChurchofJesusChrist.org tàbí ààpù ẹ̀rọ àgbéká) láti ka àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì, àpóstélì, àti àwọn olórí míràn lórí àkọlé yí.

  3. Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé,” ChurchofJesusChrist.org.

  4. Àkọsílẹ̀ ìrírí yí wà nínú Susan Easton Black àti Joseph Walker, Fi Ìtara Ṣiṣẹ́: Ìtàn ìgbé Ayé M. Russell Ballard (2021), 90–91.

  5. Álmà 5:45–46.