Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ìkọ́ni ti Jésù Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Àwọn Ìkọ́ni ti Jésù Krístì

A fún wa ní àwọn ìwé mímọ́ láti darí ìgbé ayé wa. Ọ̀rọ̀ mi ní òní wà pẹ̀lú àṣàyàn àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà wa kan—ohun tí Ó wí.

A Gbàgbọ́ nínú Krístì Àwa gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn, a jọ́sìn Rẹ̀ a sì ntẹ̀lé àwọn Ìkọ́ni Rẹ̀ nínú àwọn ìwé mímọ́.

Ṣíwájú Ìṣubú, Baba wa Ọ̀run sọ̀rọ̀ tààrà sí Ádámù àti Éfà. Lẹ́hìnnáà, Baba fi Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Nìkanṣoṣo, Jésù Krístì hàn, bí Olùgbàlà àti Olùràpadà wa ó sì fún wa ní àṣẹ láti “gbọ́ Tirẹ̀.”1 Látinú ìdarí yí a parí pé àwọn àkọsílẹ̀ ti ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ tí a sọ nípasẹ̀ “Ọlọ́run” tàbí “Olúwa” nígbàgbogbo fẹ́rẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ ti Jèhófàh, Olúwa àjínde wa, Jésù Krístì.2

A fún wa ní àwọn ìwé mímọ́ láti darí ìgbé ayé wa. Bí wòlíì Néfì ti kọ́ wa, a níláti “ṣe àpéjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì; nítorí kíyèsíi, àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ ohun gbogbo fún yín èyí tí ẹ̀yin ó ṣe.”7 Púpọ̀ jùlọ lára àwọn ìwé mímọ́ tí ó nròhìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Jésù jẹ́ ìjúwe ti ohun tí Òun ṣe. Ọ̀rọ̀ mi ní òní wà pẹ̀lú àṣàyàn àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà wa kan—ohun tí Ó . Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọsílẹ̀ nínú Májẹ̀mú Titun (pẹ̀lú àwọn àfikún ìmísí Joseph Smith) àti nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Púpọ̀ jùlọ àwọn àṣàyàn jẹ́ ṣísẹ̀ntẹ̀lé nínú èyí tí Olùgbàlà ti sọ̀rọ̀ sí wọn.

“Lootọ, lootọ, ni mo wí fún yín, Bíkòṣepé a fi omi àti Ẹ̀mí bí ènìyàn. Òun kò lè wọ íjọba Ọlọ́run.”3

“Alábùkún-fún sì ni … àwọn tí ebi npa àti àwọn tí òungbẹ ngbẹ sí ipa òdodo, nítorí a ó yó wọn pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́.”5

“Alábùkúnfún ni àwọn onílàjà: nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.”1

“Ẹ ti gbọ́ ní ẹnu àwọn ìgbàanì pé, Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣàgà:

“Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan, láti ṣe ìfẹ́-kúfẹ síi, ó ti bã ṣe panṣágà tán ní ọkàn rẹ̀.”6

“Ẹ gbọ́ bí a ti wipé, Ẹ̀yin gbọ́dọ̀ fẹ́ ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì kóríra ọ̀tá yín.

“Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ẹ súre fún àwọn ẹnití nfi yín ré, ẹ máa ṣe õre fún àwọn tí ó kórìra yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tí nfi àránkan bá yín lò, tí wọn nṣe inúnibíni sí yín;

“Kí ẹ̀yin ó lè máa jẹ́ ọmọ Baba yín tí nbẹ ní Ọ̀run: nítorí ó nmú òòrun rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti sára rere, ó sì nrọ̀jò fún àwọn olootọ àti fún àwọn aláìṣòótọ́.”7

“Nítorí, bí ẹ̀yin bá dárí ìrékọjá àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ní ọ̀run nã yíò dáríjì yín:

“Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dárí ìrékọjá àwọn ènìyàn jì wọ́n, bákannã ni Baba yín kò ní dári ìrékọjá yín jì yín.”8

“Ìbáṣepé ẹ̀yin íṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ àwọn tirẹ̀: ṣùgbọ́n nítorítí ẹ̀yin kìí ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé kóríra yín.”9

“Nítorínáà, ẹ máṣe wá ohun ayé yí ṣùgbọ́n kí ẹ kọ́kọ́ wá láti gbé ìjọba Ọlọ́run ga, kí ẹ sì gbé òdodo rẹ̀ kalẹ̀, gbogbo ohun wọ̀nyí ni a ó si fikun fún yín.”10

“Nítorínã, gbogbo ohunkóhun tí ẹ̀yin bá nfẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ̃ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́, nítorí-èyí ni òfin àti àwọn wòlĩ.”11v-p17

“Ẹ máa kíyèsára nítorí àwọn wòlĩ èkè, tí wọn ntọ̀ yín wá nínú awọ àgùtàn, ṣùgbọ́n apanijẹ ìkòkò ni wọ́n nínú.

“Ẹ̀yin yíò mọ̀ wọ́n nípa èso wọn. Njẹ́ ènìyàn a máa ká èso àjàrà lórí ẹ̀gún ọ̀gàn, tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀wọ̀n bí?

“Gẹ́gẹ́ bẹ̃ gbogbo igi rere ni íso èso rere; ṣùgbọ́n igi búburú ni íso èso búburú.”12

“Kì íṣe gbogbo ẹnití npè mi ní Olúwa, Olúwa, ni yíò wọ ìjọba ọ̀run; bíkòṣe ẹnití nṣe ìfẹ́ ti Baba mi tí nbẹ ní ọ̀run.”13

“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó nṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.

“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí: ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.

“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”14

“Bí ẹnìkẹ́ni bá nfẹ́ láti tọ̀ mí lẹ́hìn, kí ó sẹ́ ararẹ̀, kí o sì gbé agbélèbú rẹ, kí o sì máa tọ̀ mí lẹ́hìn.

“Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti gbé àgbélèbú rẹ̀, kí ó sẹ́ ararẹ̀ kúrò nínú gbogbo àìmọ́, àti gbogbo àdánù ayé, kí ó sì pa òfin mi mọ́.”15

“Nítorínáà, ẹ fi ayé sílẹ̀, kí ẹ sì gba ẹ̀mí yín là; nítorí èrè kí kíni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kíni ènìyàn yíò fúnni ní ìrọ́pò fún ẹ̀mí rẹ̀?”16

“Bí ẹnikẹ́ni yíò bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀ òun yíò mọ ẹ̀kọ́ náà, bóyá ó jẹ́ ti Ọlọ́run ni, tàbí bóyá mo sọọ́ nípa arami.”17

“Ẹ bẽrè, a ó sì fi fún yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣíi sílẹ̀ fún yín.

“Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá bẽrè, nrí gbà; ẹnití ó bá sì wá kiri nrí; ẹnití ó bá sì kànkùn ni a ò ṣíi sílẹ̀ fún.”18

“Èmi ní àwọn àgùtàn míràn, tí wọn kì íṣe ti agbo yĩ: àwọn pẹ̀lú ni èmi níláti mú wá, wọn yíò sì gbọ́ ohùn mi; agbo kanṣoṣo ni yíò sì wà, àti olùṣọ́-àgùtàn kanṣoṣo.”19

“Jésù wí fún un pe, “Èmi ni àjíǹde, àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yíò yè:

“Ẹnikẹ́ni tí ó nbẹ láàye tí ó sì gbà mí gbọ́ kì yíò kú.”20

“[Àṣẹ nlá nínú òfin ni èyí:] Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ̀, àti gbogbo ọkàn rẹ̀, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.

“Èyí ni èkínní àti òfin ńlá.

“Èkejì sì dàbíi rẹ̀, Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.

“Nínú àwọn òfin méjèjì yí ni gbogbo òfin àti wòlíì rọ̀ mọ́.”21

“Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì npa wọ́n mọ́, òun ni ẹnití ó fẹ́ràn mi: ẹnití ó bá sì fẹ́ràn mi a ó fẹ́ràn rẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.”22

“Àláfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín, àláfíà mi ni mo fi fún yín: kìí ṣe bí ayé ti í funni, ni èmi fi fún yín. Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó wárìrì.”24

“Èyí ni òfin mi, Pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín, bí èmi ti fẹ́ràn yín.”24

“Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkarami ni: ẹ dì mi mú, kí ẹ wòó; nítorí iwin kò ní ẹran òun egungun lára, bí ẹ̀yin ti ri tí mo ní”26

“Nítorínáà ẹ lọ, ẹ máa kọ́ orílè-èdè gbogbo, kí ẹ sì báptísì wọ́n ní orúkọ Baba, àti níti Ọmọ, àti níti Ẹ̀mí Mómọ́:

“Kí ẹ máa kọ́ wọn láti má kíyèsí ohun gbogbo ohunkóhun tí mo pa ní áṣẹ fún yín: ẹ sì kíyèsíi, èmi wà pẹ̀lú yín nígbàgbogbo, títí ó fi dé òpin ayé.”27

Lẹ́hìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Mímọ́, Ó farahan àwọn olódodo ní orí ilẹ̀ American. Ìwọ̀nyí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Ó sọ níbẹ̀:

“Ẹ kíyèsĩ, èmi ni Jésù Krístì Ọmọ Ọlọ́run. Èmi ni ó dá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn. Èmi wà pẹ̀lú Baba láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Mo wà nínú Baba, Baba nã sì wà nínú mi; nínú mi sì ni Baba ti ṣe orúkọ rẹ̀ lógò.”28

“Èmi ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé. Èmi ni Álfà àti Òmégà, ìpilẹ̀sẹ̀ àti òpin.

“Ẹ̀yin kò sì ní rú ẹbọ ìtàjẹ̀sílẹ̀ sí mi mọ; bẹ̃ni, àwọn ọrẹ ẹbọ yín àti àwọn ọrẹ ẹbọ sísun yín yíò dópin, nítorí èmi kò ní tẹwọ́gba ọ̀kan nínú àwọn ọrẹ ẹbọ nyín tàbí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun yín.

“Ẹ̀yin yíò sì rú ẹbọ ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ sí mi fún ọrẹ ẹbọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tọ̀ mí wá pẹ̀lú ọkàn ìrora àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, òun ni èmi ó rìbọmi pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́. ….

“Ẹ kíyèsĩ, èmi wá sínú ayé láti mú ìràpadà wá sínú ayé, láti gba ayé là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.”29

“Àti pẹ̀lú mo wí fún yín, ẹ níláti ronúpìwàdà, kí a sì rì yín bọmi ni órúkọ mi, kí ẹ sì dàbí ọmọdé, bí kò bá rí bẹ̃ ẹ̀yin kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run.”30

“Nítorínáà mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó wà ní pípé àní gẹ́gẹ́bí èmi, tàbí Baba yín tí nbẹ ní ọ̀run ti wà ní pípé.”31

Lóotọ́, lóotọ́, mo wí fún yín, ẹ níláti máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà-gbogbo, kí èṣù ó má bã dán yín wò, kí ó sì mú yín ní ìgbèkùn.”32

“Nítorínã ẹ níláti máa gbàdúrà nígbà-gbogbo sí Baba ní orúkọ mi.”33

“Nítorínáà, ohunkóhun tí ẹ bá ṣe, ẹ ó ṣe ní orúkọ mi; nítorínáà ni ẹ̀yin ó pe ìjọ náà ní orúkọ mi.”34

“Ẹ kíyèsĩ èmi ti fi ìhìnrere mi fún yín, èyí sì ni ìhìnrere èyítí èmi ti fi fún yín—pé mo wá sínú ayé láti ṣe ìfẹ́ Baba mi, nítorípé Baba mi ni ó rán mi.

“Baba mi sì rán mi kí a lè gbé mi sókè sí orí àgbélèbú; lẹ́hìn tí a sì ti gbé mi sókè sí orí àgbélèbú, kí èmi ó lè fa gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ mi … láti gba ìdájọ́ iṣẹ́ wọn, boyá rere ni wọ́n, tàbí bóyá búburú.”35

“Nísisìyí èyí ni àṣẹ nã: Ẹ ronúpìwàdà, gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mi, kí ẹ̀yin ó di mímọ́ nípa gbígba Ẹ̀mí Mímọ́, kí ẹ̀yin ó lè dúró ní àìlábàwọ́n níwájú mi, ní ọjọ́ ìkẹhìn.”36

A Gbàgbọ́ nínú Krístì Mo parí pẹ̀lú ohun tí Ó sọ nípa bí a níláti mọ̀ kí a sì tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Rẹ̀:

“Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹnití Baba yíò rán ní orúkọ mi, òun yíò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yíò sì ràn yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín.”37

Mo tẹnumọ́ òtítọ́ àwọn ìkọ́ni wọ̀nyí ní orúkọ̀ Jésù Krístì, Àmín.