Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìbùkún Ti-Bábánlá Yín—Jẹ́ Ìdarí Ìmísí láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


9:28

Ìbùkún Ti-Bábánlá Yín—Jẹ́ Ìdarí Ìmísí láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run

Ìbùkún ti bàbá nlá mi ràn mí lọ́wọ́ láti ní òye ìdánimọ̀ ayérayé òtítọ́—ẹni tí mo jẹ́ àti ẹni tí mo lè dà.

A tọ́ mi láti ọwọ́ àwọn òbí oníyanu tí wọ́n ní ìfẹ́ tí wọ́n sí fi òtítọ́ kọ́ wa, àwọn ọmọ wọn, ní ìhìnrere. Pẹ̀lú ìbànújẹ́, àwọn àyànfẹ́ òbí mi làkàkà nínú ìgbeyàwó wọn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Mo jẹ́ ọmọ Alakọbẹrẹ nígbàtí mo mọ̀ pé ó ṣeéṣe kí àwọn òbí mi kọrasílẹ̀ níjọ́kan àti pé èmi yíò níláti yan òbí èyí tí mo fẹ́ bá gbé. Fún ìgbà pípẹ́, mo ní ìrírí àníyàn pàtàkì; bákannáà, ẹ̀bùn kan láti ọ̀dọ̀ Baba mi Ọ̀run tí ó yí ohun gbogbo padà fún mi nígbẹ̀hìn—ìbùkún ti-babanlá mi.

Ní ọjọ́ orí mọ́kànlá ní dídàmú púpọ̀ jọjọ nípa ìbáṣepọ̀ àwọn òbí mi, mo ní ìfẹ́ jinlẹ̀jinlẹ̀ láti gba ìbùkún ti babanlá mi. Mo mọ̀ pé Baba Ọ̀run mọ̀ mí dáadáa àti àwọn ipò mi ní pàtákì. Bákannáà mo mọ́ pé èmi ó gba ìdarí làti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ní kété lẹ́hìn ọjọ́ ìbí kejìlá mi, mo gba ìbùkún ti bàbá nlá mi. Ìyẹn ju bíi ìlàjí sẹ́ntúrì kan sẹ́hìn, ṣùgbọ́n mo rántí ìrírí mímọ́ náà kedere.

Pẹ̀lú ìmoore, a ní ìdarí ìmísí nípa àwọn ìbùkún ti babanlá nínú Ìwé Ìléwọ́ Gbogbogbò Ìjọ:

“Gbogbo àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n ti ṣe ìrìbọmi yíyẹ, ní ẹ̀tọ́ sí ìbùkún ti babanlá, èyí tí ó npèsè ìdarí ìmísí láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run.”

Ọmọ ìjọ kan níláti “dàgbà tó látí ní ìmọ̀ pàtàkì àti ìwà mímọ́ ti ìbùkún náà” àti “ní ìmọ̀ kókó ẹ̀kọ́ ìhìnrere.”

“Lódodo àwọn ọmọ ìjọ níláti jẹ́ ọ̀dọ́ tó kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpinnu ní ayé ṣì wà níwájú. … Àwọn olórí Oyè-àlùfáà kò gbọ́dọ̀ gbé ọjọ́ orí èyí tí ó kéré jùlọ lélẹ̀ fún ọmọ ìjọ láti gba ìbùkún ti babanlá kan. …

“Ìbùkún babanlá kọ̀ọ̀kan jẹ́ mímọ́, ìkọ̀kọ̀, àti ti araẹni. …

“Ẹnì kan tí ó gba ìbùkún babanlá kan níláti fi iyi fún àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, jíròrò wọn, kí a sì gbé yíyẹ láti gba àwọn ìlérí ìbùkún nínú ayé yí àti ní àìlópin.”1

Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni léraléra nípa pàtàkì ìbùkún ti babanlá,2 pé ó nfún ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó gbàá ní “ìkéde ìrandíran kan padà sí Abraham, Isaac, àti Jacob”3 àti pé ó jẹ́ “ìwé mímọ́ ti araẹni.”4

Ìbùkún ti bàbá nlá mi ṣe pàtàkì gan sí mi nígbàtí mo wà ní ọ̀dọ̀ nítorí àwọn èrèdí púpọ̀. Àkọ́kọ́, nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, ìbùkún ti bàbá nlá mi ràn mí lọ́wọ́ láti ní òye ìdánimọ̀ ayérayé òtítọ́—ẹni tí mo jẹ́ àti ẹni tí mo lè dà. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀, bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni, pé èmi “jẹ́ ọmọ Ọlọ́run kan,” “ọmọ [májẹ̀mú] kan,” àti “ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì kan.”5 Mo mọ̀ pé a mọ̀ mí a sì ní ìfẹ́ mi nípa Baba mi Ọ̀run àti Olùgbàlà mi àti pé Wọ́n wà nínú ayé mi níti-ara. Èyí ràn ìfẹ́ mí lọ́wọ́ láti fa súnmọ́ Wọn àti láti pọ̀si nínú ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé mi nínú Wọn.

Ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan ti ó darapọ̀ mọ́ Ìjọ bí ọ̀dọ́ àgbà ṣe àbápín pé: “Nígbàtí babanlá bá gbé ọwọ́ lé orí mi tí ó sì sọ orúkọ mi, ohungbogbo a yípadà … kìí ṣe nígbànáà nìkan ṣùgbọ́n fún ìyókù ayé mi. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mo ní òye pé—nípasẹ̀ agbára nípa èyí tí ó sọ̀rọ̀—a mọ̀ mí tímọ́tímọ́ àti ní jíjinlẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ wọnú gbogbo ẹran ara mi lọ. Mo mọ̀ pé Baba Ọ̀run mọ̀ mí, ní inú àti ní ìta.

Mímọ ẹni tí mo jẹ́ gan ràn mí lọ́wọ́ láti ní òye àti ìfẹ́ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run bá nretí nípa mi.6

Èyí darí mi láti ṣe àṣàrò àwọn májẹ̀mú tí mo ti dá àti ìlérí àwọn ìbùkún nínú májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Abraham.7 Ó fún mi ní ìwò ayérayé tí ó mísí mi láti pa àwọn májẹ̀mú mi mọ́ ní kíkún síi.

Mo ṣe àṣàrò ìbùkún ti babanlá mi lóòrèkóòrè àti, bí ọ̀dọ́, nígbàkugbà ní ojojúmọ́, èyí tí ó ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára títuni-nínú, títọ́nisọ́nà ti Ẹ̀mí Mímọ́, ẹnití ó ṣèrànwọ́ láti dín àníyàn mi kù bí mo ti ntẹ̀lé àwọn ìṣílétí Rẹ̀. Èyí mú ìfẹ́ mi láti fi aápọn pe ìmọ́lẹ̀, òtítọ́, àti Ẹ̀mí Mímọ́ nípa ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ mi àti gbígbàdúrà ní ojojúmọ́ pọ̀si àti gbígbìyànjú láti fi ìtara ṣe àṣàrò àti láti tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni wòlíì àti àwọn àpóstélì Ọlọ́run. Ìbùkún ti babanlá mi bákannáà ràn ìfẹ́ mí lọ́wọ́ láti gbọ́ran sí ìfẹ́ Baba mi Ọ̀run, àti pé ìdojúkọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìrírí ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ipò pípeniníja araẹni mi.8

Mo gba okun ti ẹ̀mí ní ìgbà kọ̀ọ̀kan tí mo bá ṣe àṣàrò ìbùkún babanlá mi. Nígbàtí àwọn òbí mi kọrasílẹ̀ tán, ìbùkún babanlá mi, bí Ààrẹ Thomas S. Monson ti kọ́ni, ti di “ìṣura iyebíye àti àìlóye ti araẹni,” àní “Atọ́nà araẹni kan.”9

Nísisìyí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe ṣì mí gbọ́. Èmi kò pé. Mo ṣe onírurú àwọn àṣìṣe. Ojúgbà ayérayé mi yíò fi èyí múlẹ̀ pé mo ṣì nṣeé. Ṣùgbọ́n ìbùkún ti babanlá mi ràn ìfẹ́ mí lọ́wọ́ láti ṣe dáradára si àti láti jẹ́ dáradára si.10 Lóòrèkóòrè ṣiṣe àṣàrò ìbùkún babanlá mi nmú ìfẹ̀ mi láti kojú àdánwò. Ó nràn mí lọ́wọ́ láti ní ìfẹ́ àti ìgboyà láti ronúpìwàdà, àti pé àníkún ìrònúpìwàdà ndi ètò aláyọ̀.

Ó jẹ́ kókó fún mi láti gba ìbùkún babanlá mi nígbàtí mo wà ní ọ̀dọ́ àti nígbàtí ẹ̀rí mi ṣì ndàgbà. Èmi ó fi ìmoore hàn títíláé pé àwọn òbí mi àti bíṣọ́ọ̀pù ní ìmọ̀ pé ìfẹ́ mi fihàn pé mo ti ṣetán.

Nígbàtí mo wà ní ọmọ ọdún méjìlá, ayé dínkù nínú mọ̀dàrú àti títàn ju ayé òní lọ. Ààrẹ Nelson ti júwe òní bí “ìgbà líle jùlọ nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn ayé,” ayé tí ó “kún fún ẹ̀ṣẹ̀” àti “ìmọtaraẹni.”11 Pẹ̀lú oríre àwọn ọ̀dọ́ wa ní òní ti dàgbà ju bí mo ti wà ní ọdún méjìlá, àti pé àwọn bákannáà ní àwọn ìpinnu pàtàkì líle láti ṣe nígbàtí wọn wà ní ọ̀dọ́! Bákannáà wọ́n nílò láti mọ ẹni tí wọ́n jẹ́ gan àti pé Ọlọ́run fẹ́ràn wọn àti pé ó ní ìfura nípa wọn ní pípé.

Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni yíò ní ìfẹ́ látiṣe ìbùkún ti babanlá wọn nígbà tí mo ṣe. Mo gbàdúrà pé àwọn ọmọ ìjọ tí wọn kò tíì gba ìbùkún ti babanlá wọn yíò fi àdúrà wá láti mọ ìgbàtí wọ́n máa ṣetán. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ̀yin bá múrasílẹ̀ níti ẹ̀mí, ìrírí yín, bíiti èmi, yíò jẹ́ mímọ́ síi yín. Bákannáà mo gbàdúrà pé kí àwọn ẹnití wọ́n ti gba ìbùkún ti babanlá wọn tẹ́lẹ̀ yíò ṣe àṣàrò rẹ̀ kí wọ́n sì fi iyì fún. Ṣiṣé ìkẹ́ ìbùkún ti babanlá mi nígbàtí mo wà ní ọ̀dọ̀ ti bùkún mi pẹ̀lú ìgboyà nígbàtí mo ní ìjákulẹ̀, ìtùnú nígbàtí mo ní ìbẹ̀rù, àláfíà nígbàtí mo ní ìmọ̀lára àníyàn, ìrètí nígbàtí mo ní ìmọ̀lára àìnírétí, àti ayọ̀ nígbàtí ẹ̀mí mi nílò rẹ̀ jùlọ. Ìbùkún ti bàbá nlá mi ràn mí lọ́wọ́ láti mú ìgbàgbọ́ mi àti ìgbẹ́kẹ̀lé mi nínú Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà mi pọ̀si. Bákannáà ó mú ìfẹ́ mi fún Wọn pọ̀si—àti pé o ṣì ríbẹ́ẹ̀ síbẹ̀.12

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ìbùkún ti babanlá npèsè ìdarí ìmísí láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run. Mo jẹ́ ẹ̀rí mi nípa òdodo ààyè ti Baba wa ní Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀—Olùgbàlà wa, Jésù Krístì—ẹnití ó mọ̀ wá, fẹ́ràn wa, tí ó sì fẹ́ láti bùkún wa. Bákannáà mo mọ̀ dájúdájú pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé ní òni. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Ìwé Iléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 18.17, 18.17.1, ChurchofJesusChrist.org.

  2. Wo Russell M. Nelson, “Opẹ́ fún Májẹ̀mú” (Ìfọkànsìn Unifásítì Brigham Young, Nov. 22, 1988), speeches.byu.edu; “Ìrètí Kan Títayọ Síi” (Brigham Young University devotional, Jan. 8, 1995), speeches.byu.edu; “Ìdánimọ̀, Ìṣíwájú, àti àwọn Ìbùkún” (Brigham Young University devotional, Sept. 10, 2000), speeches.byu.edu; “Àwọn Gbongbò àti Ẹ̀kọ́,” LiahonaMay 2004, 27–29; “Covenants,” Liahona; Nov. 2011, 86–89; “Àwọn Ọ̀dọ́ Ìbì Akọni: Kíni Ẹ̀yin Ó Yàn?” (Ìfọkànsìn Unifásítì Brigham Young–Hawaii, Sept. 6, 2013), broadcasts.ChurchofJesusChrist.org; “Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Ìkójọ Ísráẹ́lì, àti Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì,” Ensign, July 2014, 26–31; Làìhónà, July 2014, 24–29; “Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Borí,” Làìhónà, Nov. 2020, 92–95; “Májẹ̀mú Àìlópin,” Làìhónà, Oct. 2022, 1–6.

  3. Russell M. Nelson, “Àwọn Májẹ̀mú,” 88.

  4. Russell M. Nelson, “Ọpẹ́ fún Májẹ̀mú,” speeches.byu.edu.

  5. Russell M. Nelson, “Àwọn Yíyàn Fún Ayérayé” (worldwide devotional for young adults, May 12, 2022), ChurchofJesusChrist.org; àfikún àtẹnumọ́.

  6. Wo Russell M. Nelson, “Àwọn Májẹ̀mú,” 86–89.

  7. Wo Genesis 17:1–10; bákannáà wo Russell M. Nelson, “Àwọn Ọmọ Májẹ̀mú,” Ensign, May 1995, 32–34.

  8. See Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Yíyè Ti Ẹ̀mí,” Liahona, Nov. 2016, 81–84.

  9. Thomas S. Monson, “Ìbùkún Ti Bàbá Nlá Yín: Atọ́nà Ìmọ́lẹ̀,” Ensign, Nov. 1986, 65–66.

  10. See Russell M. Nelson, “A Lè Ṣe Dáradára Síi Kí A Sì Jẹ́ Dáradára Síi,” Liahona, May 2019, 67–69.

  11. Russell M. Nelson, “Bíborí Ayé àti Wíwá Ìsinmi,” Liahona, Nov. 2022, 95–96.

  12. Ìmísí nípasẹ̀ James E. Faust, “Àwọn Ìbùkún Oyè-àlùfáà,” Ensign, Nov. 1995, 62–64.