Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Wòlíì Alààyè Kan fún Àwọn Ọjọ́ Ìkẹhìn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Wòlíì Alààyè Kan fún Àwọn Ọjọ́ Ìkẹhìn

Baba Ọ̀run ti yan àwòṣe ìfihàn òtítọ́ sí àwọn ọmọ Rẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì.

Nígbàtí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin, mo fẹ́ràn Sátidé nítorí gbogbo ohun tí mo bá ṣe ní ọjọ́ náà máa ndàbí pé ó jẹ́ ìdáwọ́lé. Ṣùgbọ́n ohun yòówù kí nṣe, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo rẹ̀ ló máa nṣáájú—wíwo àwọn àwòrán eré lórí tẹlifíṣọ̀n. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sátidé bẹ́ẹ̀ kan, bí mo ṣe dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ tẹlifíṣọ̀n tí mo sì nlọ káàkiri lórí àwọn ìkànnì, mo ṣàwárí pé eré aláwòrán tí mo retí láti rí ni a rọ́pò pẹ̀lú ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. Bí mo ṣe nwo tẹlifíṣọ̀n, tí mo sì ndárò pé kò sí eré aláwòrán, mo rí ọkùnrin onírun funfun kan ó wọ kóòtù àti táì ó sì jókòó sórí àga dáradára kan.

Ohun tó yàtọ̀ kan wà nípa rẹ̀, torínáà mo bèèrè lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n mi àgbà jùlọ pé, “Taa ni?”

Ó wípé, “Ààrẹ David O. McKay nìyẹn; wòlíì ni.”

Mo rántí níní ìmọ̀lára ohun kan àti ní mímọ̀ pé ó jẹ́ wòlíì. Lẹ́hìnnáà, nítorí pé mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin tó fẹ́ràn eré aláwòràn, mo yí ìkànnì náà padà. Ṣùgbọ́n èmi ò tíì gbàgbé ohun ti mo mọ̀lára lákokò ìfihàn kúkurú, àìrotẹ́lẹ̀ náà. Pẹ̀lú wòlíì, nígbà míràn ó má ngba àkokò kékere kan láti mọ̀.1

Mímọ̀ nípasẹ̀ ìfihàn pé wòlíì alààyè kan wà lórí ilẹ̀ ayé nyí ohun gbogbo padà.2 Ó máa njẹ́ kí ẹnì kan má nífẹ̀ẹ́ sí àríyànjiyàn nípa ìgbà wo ni wòlíì kan nsọ̀rọ̀ bíi wòlíì tàbí bóyá a dá ẹnìkan láre rí nígbàtí ó bá yan ìkọ̀sílẹ̀ ìmọ̀ràn ti wòlíì.3 Irú ìmọ̀ tí a ṣípayá bẹ́ẹ̀ npe ènìyàn láti gbẹ́kẹ̀lé ìmọ̀ràn wòlíì alààyè,4bí a kò tilẹ̀ lóye rẹ̀ ní kíkún.4 Lẹ́hìn ohun gbogbo, Baba pípé àti olùfẹ́ni ní Ọ̀run ti yan àpẹrẹ ti ṣíṣe àfihàn òtítọ́ sí áwọn ọmọ Rẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì kan, ẹnìkan tí kò lépa irú ipè mímọ́ bẹ́ẹ̀ láé àti ẹni ti kò nílò ìrànlọ́wọ́ wa láti mọ àwọn àìpé tìrẹ.5 Wòlíì jẹ́ ẹnìkan tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti pèsè sílẹ̀, tó tí pè, tó tí túnṣe, tó ti mísí, tó tí bá wí, yà sí mímọ́, tí ó sì ti mú dùró.6 Ìdí nìyí tí a kò fi sí nínú ewu ti ẹ̀mí láé ní títẹ̀lé ìmọ̀ràn àsọtẹ́lẹ̀.

Bí a fẹ́ bí a kọ̀, gbogbo wa ni a yàn ní àṣà díẹ̀ nínú ìgbésí ayé ìṣaájú-ayé láti bí ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí. Àwọn òtítọ́ méjì wà tí ó ní nkan ṣe pẹ̀lú àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Òtítọ́ àkọ́kọ́ ni pé a ó tún àgbékalẹ̀ ìjọ Krístì ṣe padà lórí ilẹ̀ ayé. Òtítọ́ kejì ni pé àwọn nkan yíò di yíyípadà gan an. Ìwé Mímọ́ fihàn pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn “ìjì líle nlá kan yíò wà tí a rán jáde láti pa àwọn irè oko ilẹ̀ run,”7 àwọn ìyọnu,8 “ogun àti ìró àwọn ogun, gbogbo ayé yíò sì wà nínú ìdàrúdàpọ̀, … àti pé àìṣedéédé yíò pọ̀.”9

Nígbàtí mo wà lọ́mọdé, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nnì dẹ́rù bà mí, wọ́n sì mú kí nmáa gbàdúrà pé kí Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì má ṣe wá ní ìgbà ayé mi, pẹ̀lú àṣeyọrí díẹ̀ mo lè fi kún un títí di báyìí. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí mo gbàdúrà fún òdìkejì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpèníjà tí a sọtẹ́lẹ̀ náà jẹ́ dídánilójú,10 nítorí pé nígbà tí Krístì bá padà wá jọba, gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá Rẹ̀ yíò “dùbúlẹ̀ láìséwu.”11

Àwọn ipo lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ayé ti mú kí àwọn kan bẹ̀rù. Àwa bí ọmọ májẹ̀mú Ọlọ́run, a kò nílò láti lépa èyí tàbí ìyíinì láti mọ bí a ṣe lè gbà la àwọn àkokò ìdàmú wọ̀nyí kọjá. A kò níláti bẹ̀rù.12 Ẹkọ́ àti àwọn ìlànà tí a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé láti là á já nípa ti ẹ̀mí ká sì lè fara dà á nípa ti ara wà nínú ọ̀rọ̀ wòlíì alààyè.13 Ìdí nìyí tí Ààrẹ M. Russell Ballard fi kéde pé “Kì í ṣe ohun kékeré… láti ní wòlíì Ọlọ́run ní àárín wa.”14

Ààrẹ Russell M. Nelson ti jẹ́rìí sí i pé “Ọ̀nà tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ tipẹ́tipẹ́ nípa kíkọ́ àwọn ọmọ Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì fi dá wa lójú pé Òun yíò bùkún wòlíì kọ̀ọ̀kan àti pé Òun yíò bùkún àwọn tí wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn àsọtẹ́lẹ̀.”15 Nítorínáà kókó ni láti tẹ̀lé wòlíì alààyè.16 Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, ní yíyàtọ̀ sí àwọn ìwé apanilẹ́rìn àtijọ́ àti àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ti ó wọ́pọ̀, àwọn ìkọ́ni alásọtẹ́lẹ̀ kìí ní iye lórí díẹ̀ síi pẹ̀lú ọjọ́-orí. Ìdí nìyí tí a kò fi gbọ́dọ̀ wá láti lo ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tó ti kọjá láti pa ìkọ́ni àwọn wòlíì alààyè tì.17

Mo fẹ́ràn àwọn òwe tí Jésù Krístì lò láti kọ́ àwọn ìlànà ihinrere jíjinlẹ̀. Èmi yíò fẹ́ láti pín òwe ayé-gidi kan tí ó jẹ́ irú rẹ̀ pẹ̀lú yín ní òwúrọ̀ yí.

Lọ́jọ́ kan, mo wọ ilé oúnjẹ tó wà ní olú ílé-iṣẹ́ Ìjọ láti jẹ oúnjẹ ọ̀sán. Lẹ́hìn tí mo gba àtẹ oúnjẹ kan, mo wọ ibi tí wọ́n ti njẹun, mo sì ṣàkíyèsí tábìlì kan níbi tí gbogbo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti Àjọ Ààrẹ Ìkínní jókòó sí, pẹ̀lú àga òfìfo kan. Àìláàbò mi mú kí nyára yí padà kúrò ní tábìlì náà, àti nígbànáà ni mo gbọ́ ohùn wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, wípé, “Allen, àga òfo kan wà níbí. Wá jókòó pẹ̀lú wa.” Mo sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Sísúnmọ́ ìparí oúnjẹ ọ̀sán, ẹnu yà mí láti gbọ́ ariwo nlá kan, nígbàtí mo wo òkè, mo ríi pé Ààrẹ Nelson ti mú ìgò ike omi rẹ̀ dúró tààrà ó sì ṣé pẹrẹsẹ lẹ́hìnnáà ó sì dá ìdérí padà.

Ààrẹ Dallin H. ​​Oaks béèrè ìbéèrè tí mo fẹ́ béèrè pé, “Ààrẹ Nelson, kí ló dé tí o fi tẹ ìgò ike omi rẹ pẹrẹsẹ?”

Ó dáhùn pé, “ó mú kí ó rọrùn fún àwọn tí wọ́n nṣe ìtọ́jú àwọn ohun èlò tí a lè túnlò nítorí kò níi gba ààyè púpọ̀ nínú àpótí àtúnlò.”

Bí mo ṣe nronú lórí ìdáhùn náà, mo tún gbọ́ irú ìró rírún kannáà lẹ́ẹ̀kansíi. Mo wo apá ọ̀tún mi, Ààrẹ Oaks ti ṣe ìgò ike omi rẹ̀ pẹrẹsẹ gẹ́gẹ́bí ti Ààrẹ Nelson. Mo gbọ́ ariwo díẹ̀ sí apá òsì mi, Ààrẹ Henry B. Eyring nṣe ìgò ike omi ṣiṣu rẹ̀ pẹrẹsẹ, bótilẹ̀jẹ́pé o ngba ìlànà ọ̀tọ̀ nípa síṣe é nígbàtí ìgò náà wà ní ìdùbúlẹ̀, èyítí ó gba ìgbìyànjú díẹ̀ síi ju kí ìgò náà wà ní ìnàró tààrà lọ. Ní ṣíṣàkíyèsí èyí, Ààrẹ Nelson pẹ̀lú inú rere fi ìlànà kí ìgò wà ní ìnàró hàn án láti mú kí ó rọrùn síi ní títẹ ìgò náàpẹrẹsẹ.

Ní ọ̀gangan yí, mo tẹ̀ díẹ̀ sí Ààrẹ Oaks mo sì bèèrè ní kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, “Ṣé ṣíṣe ìgò omi rẹ ní pẹrẹsẹ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àtúnlò titun ti ilé oúnjẹ?”

Ààrẹ Oaks fèsì, pẹ̀lú ẹ̀rín lójú rẹ̀, “Ó dára, Allen, o nílò láti tẹ̀lé wòlíì.”

Mo ní ìgboyà pé kìí ṣe pé Ààrẹ Nelson nkéde ẹ̀kọ́ tuntu tí ó dá lórí àtúnlò ní ilé oúnjẹ ní ọjọ́ náà. Ṣùgbọ́n a lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìdáhùn ní kíá18 ti Ààrẹ Oaks àti Ààrẹ Eyring sí àpẹrẹ Ààrẹ Nelson àti ìfọkànsí Ààrẹ Nelson láti ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn tí wọ́n kópa ní ọ̀nà tí ó dára jù.19

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Alàgbà Neal A. Maxwell ṣàjọpín àwọn àkíyèsí àti ìmọ̀ràn tí ó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ lórí kókó nípa ọjọ́ wa:

“Ní àwọn oṣù àti àwọn ọdún tó nbọ̀, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣeé ṣe kí ó nílò ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan láti pinnu bóyá òun lọ́kùnrin [tàbí lóbìnrin] yíò tẹ̀lé Àjọ Ààrẹ ìkínní tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Àwọn ọmọ ìjọ yíò ní ìṣòro díẹ̀ síi láti dúró díẹ̀ síi láarín àwọn àṣàyàn èrò ọkàn méjì. …

“… Ẹ jẹ́kí a fi àkọsílẹ̀ kan sílẹ̀ kí àwọn yíyàn náà lè ṣe kedere, ní jíjẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn ṣe bí wọ́n ṣe fẹ́ ní ojú ìmọ̀ràn alásọtẹ́lẹ̀. …

“Jésù wí pé nígbà tí àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ bá yọ ewé wọn, ‘ìgbà ẹ̀rùn ti sún mọ́lé.’ … Ní kíkìlọ̀ báyìí pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn dé bá wa, ẹ má ṣe jẹ́ kí a ráhùn nípa ooru!”20

Ìran tí ndìde ndàgbà ní àkókò tí àwọn ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀ sí i tí ooru sì nbẹ síi. Òtítọ́ náà gbé ẹrù ojúṣe wíwúwojù kan karí ìran tí ó ti dìde tẹ́lẹ̀rí, ní pàtàkì nígbà tí ó bá kan títẹ̀lé ìmọ̀ràn alásọtẹ́lẹ̀. Nígbà tí àwọn òbí bá pa ìmọ̀ràn wòlíì alààyè náà tì, kì í ṣe pé wọ́n máa npàdánù àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí fún ara wọn nìkan ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìbànújí, wọ́n tún nkọ́ àwọn ọmọ wọn pé ohun tí wòlíì kan sọ kò ṣe pàtàkì tàbí pé ìmọ̀ràn alásọtẹ́lẹ̀ ni a lè ṣà nínú rẹ̀ lọ́nà ìpàtẹ ounjẹ kan láìbìkítà fún àbájáde àìrí-ìtọ́jú ti ẹ̀mí.

Alàgbà Richard L. Evans ṣàkíyèsí nígbà kan pé: “Àwọn òbí kan máa nfi àṣìṣe mọ̀lára pé àwọn lè sinmi díẹ̀ ní ti ìhùwàsí àti wíwà ní ìbámu … pé wọ́n lè ní ìrọ̀rùn díẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀ láì ní ipa lórí ẹbí wọn tàbí ọjọ́ iwájú ẹbí wọn. Ṣùgbọ́n, bí òbí kan bá yà lọ díẹ̀ kúrò ní ipa ọ̀nà, ó ṣeéṣe kí àwọn ọmọ kọjá àpẹrẹ ti àwọn òbí.”21

Bíi ìran kan tí ó ní àṣẹ mímọ́ láti múra ìran tí ndìde sílẹ̀ fún ipa rẹ̀ tí a ti sọtẹ́lẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn,22 ojúṣe èyítí a gbọ́dọ̀ múṣẹ ní àkókò ìgbà tí ọ̀tá wà ní góńgó agbára rẹ̀,23 a kò lè jẹ́ orísun ìdàrúdàpọ̀ nípa pàtàkì títẹ̀lé ìmọ̀ràn àsọtẹ́lẹ̀. Ìmọ̀ràn náà gan-an ni yíó fún ìran tí ó ndìde láàyè láti rí “ọ̀tá nígbàtí ó ṣì wà [ní] òkèèrè; nígbànáà [wọn lè múra]” láti kojú ìkọlù àwọn ọ̀tá.24 Àwọn ìyapa wa tí ó dàbí ẹnipé ó kéré, àìbìkítà ìdákẹ́jẹ́, tàbí àwọn àtakò kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ní ìdáhùn sí ìmọ̀ràn àsọtẹ́lẹ̀ lè já sí rírìn wá nítòsí etí bèbè ipa ọ̀nà májẹ̀mú níkan; ṣùgbọ́n nígbàtí ọ̀tá bá mú un tóbi nínú ìgbésí ayé àwọn ìran tí ndìde, irú àwọn ìṣe bẹ́ẹ̀ lè nípa lórí wọn láti fi ipa ọ̀nà náà sílẹ̀ pátápátá. Irú àyọrísí bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìdíyelé ìrandíran kan tí ó ga jù.25

Díẹ̀ nínú yin lè lérò pé ẹ ti kùnà nínú àwọn ìgbìyànjú yin láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn Ààrẹ Russell M. Nelson. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbànáà ronúpìwàdà, bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi láti máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn wòlíì tí Ọlọ́run yàn. Ẹ gbé ìdààmú àwọn eré aláwòrán ọmọdé sí apákan kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹni-àmì-òróró Olúwa. Ẹ yọ̀ nítorípé lẹ́ẹ̀kan sí “Wòlíì kan wà ní Isráẹ́lì”26

Àní bí ẹ kò tilẹ̀ ní ìdánilójú, mo jẹ́ ẹ̀rí pé a lè kojú ooru ti àwọn ọjọ́ ìkẹhìn àti kí a tilẹ̀ ṣe rere nínú wọn. Àwa ni àwọn ènìyàn mímọ́ ọjọ́ ìkẹhìn, ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọjọ́ nlá. A ṣe àníyàn láti wá sí ilẹ̀ ayé ní àkókò yìí, a ní ìgbọ́kànlé pé a kì yíò fi wá sílẹ̀ láti kọsẹ̀ nígbàtí a bá ní ìdojúkọ àwọn ìkùukù síṣókùnkùn àti ti ìdàrúdàpọ̀ ti ọ̀tá27 ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ láti gba ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ ẹni náà tí a nìkan fún ní ẹ̀tọ́ láti sọ fún wa àti fún gbogbo ayé pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí.”28 Ní orúkọ mímọ́ ti wòlíì náà ẹ̀nití Ọlọ́run gbé dìde, Ẹni Mímọ́ Ísráẹ́lì,29 àní Jésù Kírísítì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Láìpẹ́ Ààrẹ Russell M. Nelson ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Yunifásítì Brigham Young láti ní ìrírí ìṣípayá ti ara ẹni kan náà: “Béèrè lọ́wọ́ Bàbá Ọ̀run bí a bá jẹ́ àpóstélì àti wòlíì Olúwa ní tòótọ́. Bèèrè bóyá a ti gba ìfihàn lórí èyí àti àwọn ọ̀ràn míràn” (“Ìfẹ́ àti àwọn Òfin Ọlọ́run” [Brigham Young University devotional, Sept. 17, 2019], speeches.byu.edu). Bákanáà wo Neil L. Andersen, “Wòlíì Ọlọ́run,” Liahona, May 2018, 26–27: “A ni ànfàní gẹ́gẹ́bí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn láti gba ẹ̀rí ti araẹni pé ìpè Ààrẹ Nelson wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Ìtàn ti iyípadà Álmà láti gbígbọ́ sí wòlíì Ábínádáì npèsè ẹ̀rí síwájú síi pé ìfihàn nípa wòlíì kan wà fún gbogbo wa (wo Mòsíàh 13:5; 17:2).

  2. “Àwa ní wòlíì tàbí a kò ní nkan kan; àti níní wòlíì, a ní ohun gbogbo” (Gordon B. Hinckley, “A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Yín, Ah Ọlọ́run, fún Wòlíì kan,” Ẹ́nsáìn, Oṣù kínní 1974, 122).

  3. “Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìgbàgbọ́ nínú ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti nínú ẹ̀mí ìfihàn; Àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run sì tẹ́ wọ́n lójú” (Hélámánì 4:23; bákanáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 11:25). “À nkorin a sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbàgbogbo, ‘A Dúpẹ́ lọ́wọ́ Yín, Óò Ọlọ́run, fún Wòlíì kan láti darí wa ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló wà tí wọ́n [yẹ́ kí wọ́n] fi ìwé ìfiwéránṣẹ́ sí bẹ́ẹ̀ kí wọ́n sì wípé: ‘Bí ó bá tọ́ wa sọ́nà láti bá àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tiwa àti ìfẹ́ inú ara wa mu’” (Teachings of Presidents of the Church: Heber J. Grant [2002], 80).

  4. “Nígbà míràn, a máa gba ìmọ̀ràn tí a ò lè lóye tàbí tó dà bíi pé kò kan wa, àní lẹ́hìn tí a bá ti fara balẹ̀ gbàdúrà tí a sì ti ronú jinlẹ̀. Máṣe da ìmọ̀ràn náà nù, ṣùgbọ́n mú u mọ́ra. Bí ẹnìkan tí o fọkàn tán bá fún ọ ní ohun tí dà bíi pé kì í ṣe iyanrìn pẹ̀lú ìlérí pé wúrà wà nínú rẹ̀, o lè fi ọgbọ́n dì í mú lọ́wọ́ rẹ fúngbà díẹ̀, kí o sì gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Ní gbogbo ìgbà tí mo bá ti ṣe ìyẹn pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ wòlíì kan, lẹ́yìn ìgbà kan, àwọn fìtílà wúrà náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í hàn, mo sì ń dúpẹ́” (Henry B. Eyring, “Rírí Àbò Nínú Ìmọ̀ràn,” Ẹ́nsáìnOṣù karun 1997, 26; bákanáà wo 3 Néfì 1:13; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:14).

  5. Wo 2 Néfì 4:17–18. “Ẹ máṣe dá mi lẹ́bi nítori àwọn àbùkù mi, tàbí baba mi, nítorí àwọn àbùkù rẹ̀, tàbí àwọn tí ó ti kọ̀wé ṣãjú rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run pé o ti fi àwọn àbùkù wa hàn sí yín, kí ẹyin ó lè kọ́ láti jẹ́ ọlọgbọ́n jù bí àwa tí jẹ́” (Mọ́mọ́nì 9:31).

  6. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 3:6–8; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 93;47.

  7. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 29:16.

  8. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:97; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 87:6.

  9. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 45:26, 28.

  10. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:38.

  11. Hóséà 2:18. “Nítorí èmi ò fi ara mi hàn láti ọ̀run wá pẹ̀lú agbára àti ògo nlá, pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, èmi ó sì bá àwọn ènìyàn gbé nínú òdodo ní ayé ní ẹgbẹ̀rún ọdún, àwọn ènì ibi kì yíò sì dúró” (Ẹkọ ati awọn majẹmu 29:11).

  12. Wo 3 Néfì 22:16–17; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 59:23.

  13. “Nítorí kíyèsĩ, wọn ti kọ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì. Nítorínáà, tí baba mi bá gbé ní ilẹ̀ náà lẹ́hìn tí a ti pa á láṣẹ pé kí ó sá kúrò ní ilẹ̀ náà, kíyèsĩ, òun yíò ṣègbé pẹ̀lú” (1 Nephi 3:18; bákanáà wo 2 Nephi 26:3; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 90:5).

  14. M. Russell Ballard, “Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ẹ̀yin Yíò Gbà,” Làìhónà, Oṣù Kéje 2001.

  15. Russell M. Nelson, “Béèrè, Wá kiri, Kànkù,” Làìhónà, Oṣu kọkanla. 2009, 82. “Kò sí ènìyàn tí ó lè láyọ̀ ju nípa ṣíṣègbọràn sí ìmọ̀ràn wòlíì alààyè.” (Àwọn Ẹ̀kọ́ ti Lorenzo Snow, ed. Clyde J. Williams [1996], 86).

  16. “Ẹ gbé ojú yín sí àwọn wọnni tí wọ́n nṣe olórí nínú ìjọ loni, tábì lọ́la, kí o sì ṣe àpẹẹrẹ ìgbésí-ayé yín ni àtẹ̀le wọn ju kí ẹ máa gbé lórí bí àwọn wòlíì àtijọ́ tí lè wò tàbí ronú tàbí sọ” (Àwọn Ẹ̀kọ́ ti Harold B. Lee [1996], 525).

  17. Ààrẹ Spencer W. Kimball ṣàkíyèsí nígbà kan pé “àwọn tí wọ́n ṣe ibojì àwọn wòlíì tí ó ti kú bẹ̀rẹ̀ nísinsìnyí nípa sísọ àwọn alààyè ní òkúta.” (Àwọn Ẹ̀kọ́ ti Spencer W. Kimball, ed. Edward L. Kimball [1982], 462). “Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí a lè gbọ́, ronú jinlẹ̀, tí a sì tẹ̀ lé ni àwọn tí a ṣípayá nípasẹ̀ wòlíì wa alààyè” (Ronald A. Rasband, “Àwọn Ohun ti Ọkàn Mi,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2021, 40).

  18. “Nígbàtí a bá gbọ́ ìmọ̀ràn Olúwa tí a sọ nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ti Ààrẹ Ìjọ, ìdáhùn wá yẹ kí ó jẹ́ ti rere àti kí ó yára” (M. Russell Ballard, Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ẹ̀yin Yíò Gbà,” Làìhónà, Oṣù Kéje 2001, 65).

  19. “Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ti fi ìgbàgbogbo jẹ́ dídarí nípasẹ̀ àwọn wòlíì alààyè àti àwọn àpọ́stélì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè kú, tí wọ́n sì wà lábẹ́ àìpé ẹ̀dá ènìyàn, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa ní ìmísí láti ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ohun ìdènà tí ó ń halẹ̀ mọ́ ìwàláàyè nípa tẹ̀mí àti láti ràn wá lọ́wọ́ láti là á já láìséwu nípasẹ̀ ikú dé ìgbẹ̀hìn, ibi ti ọ̀run” (M. Russell Ballard, “Ọlọrun Wà Níbẹ̀,” Làìhónà, Oṣu kọkanla. 2015, 24).

  20. Neal A. Maxwell, ”Ìpinnu Ọmọlẹ́hìn Díẹ̀ Síi, “ Ẹ́nsáìn, Oṣù Kejì 1979, 69, 70.

  21. Richard L. Evans, “Àwọn Ìpìlẹ̀ Ilé Ayọ̀,” ní Ìpàdé Àpapọ̀, Oṣu Kẹwa. 1964, 135–36.

  22. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 123:11; bákanáà wo Robert D. Hales, “Ojúṣe wa sí Ọlọ́run: Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Àwọn Òbí àti Àwọn Olórí sí Ìran Tí o Ndìde,” Làìhónà, Oṣù karun 2010, 95–98.

  23. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 52:14.

  24. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 101:54.

  25. Wo Mòsíàh 26:1–4.

  26. 2 Àwọn Ọba 5:8.

  27. “Ìwọ yíò fiyèsí sí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ àti òfin rẹ̀ tí òun yíò fi fún ọ bí ó ti ngbà wọ́n, …nítorí nípa ṣíṣe àwọn nkan wọ̀nyí… Olúwa Ọlọ́run yíò sì tú gbogbo agbára òkùnkùn ká kúrò ní iwájú yín, yío sì mú àwọn ọ̀run mi tìtì fún rere yín, àti nítorí ògo orúkọ rẹ̀” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 21:4, 6). “Kò sí ẹnìkan tí ó tẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ náà rí tàbí tí ó gba ìmọ̀ràn tàbí ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí aṣojú Olúwa rí tí ó ṣáko lọ” (Àwọn Ẹ̀kọ́ ti Ìgbàlà: Àwọn Ìwàásù àti Àwọn kíkọ ti Joseph Fielding Smith, ed. Bruce R. McConkie [1998], 243).

  28. Èsèkíẹ́lì 3:27. “Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ẹ̀yin yíò gba, bí ẹni pé láti ẹnu èmi fúnra mi ni, nínú gbogbo sùúrù àti ìgbàgbọ́” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 21:5).

  29. Wo 1 Néfì 22:20–21; bákannáà wo 3 Néfì 20:23.