Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023 Abala Òwúrọ̀ Sátidé Abala Òwúrọ̀ Sátidé Gary E. StevensonÌtàn Ọdún Àjínde Títóbijùlọ Tí A Ti Sọ RíAlàgbà Stevenson jẹ́ ẹ̀rí nípa ìjẹ́rí alágbára ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì nípa Jésù Krístì ó sì ṣe ìfọwọ́sí kí a fi ṣe apákan àwọn ayẹyẹ Ọdún Àjínde wa. Bonnie H. CordonMáṣe fi Ànfàní láti jẹ́rìí Krístì sílẹ̀Ààrẹ Cordon kọ́ wa láti sún mọ́ Krístì, gba ẹ̀rí Rẹ̀, mú àwọn àṣà mímọ́ dàgbà, kí a sì jẹ́rìí nípa Rẹ̀. Nígbànáà ni a ó dàbíi Rẹ̀ síi. Carl B. CookṢá Maa Tẹ̀síwájú—pẹ̀lú Ìgbàgbọ́Alàgbà Carl B, Cook kọ́ wa pé a lè borí ìjákulẹ̀ kí a sì gba àwọn ìbùkún nlá bí a ó bá tẹramọ́ lílọsíwájú—pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Gerrit W. GongṢíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́Alàgbà Gong kọ́ni pé ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ọ̀nà Olùgbàlà yíò fi ràn wá lọ́wọ́ láti súnmọ́ si àti láti dàbíi ti Jésù Krístì síi. Quentin L. CookÌkójọ̀pọ̀ Sílé LálàfíàAlàgbà Cook kọ́ni pé Olúwa nretí àwọn ẹnití wọ́n ti gba ìhìnrere Rẹ̀ láti fi kánkán tiraka láti jẹ́ àpẹrẹ tí yíò ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Allen D. HaynieWòlíì Alààyè Kan fún Àwọn Ọjọ́ ÌkẹhìnAlàgbà Haynie kọ́ni ní pàtàkì títẹ̀lé ìmọ̀ràn wòlíì alààyè kíákíá. Henry B. EyringWíwá Àláfíà AraẹniÀàrẹ Eyring kọ́ni pé bí a ti nní ìrírí ẹ̀bùn Olùgbàlà ti àláfíà araẹni, a lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rí i, kí àwọn náà, lè tìí síwájú, ní ìgbẹ̀hìn. Abala Ọ̀sán Ọjọ́ Sátidé Abala Ọ̀sán Ọjọ́ Sátidé Dallin H. OaksÌmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè GbogbogbòÀàrẹ Oaks ṣè àgbékalẹ̀ àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò kalẹ̀ fún ìbò ìmúdúró. Jared B. LarsonÌròhìn Ẹ̀ka Jíjẹ́rí Ìṣírò owó Ìjọ, Ọdún 2022Jared B. Larson gbé ìròhìn Ẹ̀ká ìjẹ́ri Ìṣirò Ohun-ìní Ìjọ fún 2022 kalẹ̀. Dale G. RenlundNíní-ààyè sí Agbára Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn Májẹ̀múAlàgbà Relund kọ́ni pé bí a ti nwá sọ́dọ̀ Krístì tí a sìn nsopọ̀ mọ́ Ọ àti Baba wa Ọ̀run nípa májẹ̀mú, a lè yípòpadà kí a sì di pípé nínú Jésù Krístì. Peter F. MeursÓ Lè Wò Mí Sàn!Alàgbà Meurs kọ́ni bí Jésù Krístì ṣe ràwápadà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa tí ó sì wò wá sàn kúrò nínú àwọn ìjìyà wa. Randall K. BennettÌbùkún Ti-Bábánlá Yín—Jẹ́ Ìdarí Ìmísí láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀runAlàgbà Bennett kọ́ni pé àwọn ìbùkún ti babanlá npèsè ìdarí ìmísí láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run. Craig C. Christensen“Kò Sí Ohunkankan Tí ó Tayọ Adùn àti Ayọ̀ Tí Mo Ní”Alàgbà Christensen kọ́ni pé a lè gba ayọ̀ òtítọ́ nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Evan A. SchmutzGbígbẹ́kẹ̀lẹ́ Ẹ̀kọ́ KrístìAlàgbà Schmutz kọ́ni nípa àwọn ìbùkún tó nwá nígbàtí a bá gbẹ́kẹ̀lẹ́ ẹ̀kọ́ Krístì. Benjamín De HoyosIṣẹ́ ti Tẹ́mpìlì àti Ìtàn Ẹbí Náà—Ọkan àti Iṣẹ́ KannáàAlàgbà De Hoyos kọ́ni pé àkọọ́lẹ̀-ìtàn ẹbí àti iṣẹ́ tẹ́mpìlì jẹ́ gbùgbun sí èto Baba Ọ̀run fún àwọn ọmọ Rẹ. Dieter F. UchtdorfJésù Krístì Ni Okun Àwọn ÒbíAlàgbà Uchtdorf kọ́ni bí Jésù Krístì ṣe nran àwọn òbí lọ́wọ́ mú àwọn ojúṣe àtọ̀runwá wọn ṣe láti kọ́ àti àti ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn. Abala Ìrọ̀lẹ́ Sátidé Abala Ìrọ̀lẹ́ Sátidé Mark A. BraggDídúró Bíiti KrístìAlàgbà Bragg gbà wá lámọ̀ràn láti mú dídúró bíiti Krístì gbèrú si láti ràn wá lọ́wọ́ ní àwọn ìgbà ìpènija àti láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ dáradára si nínú àwọn ìpènijà wọn bákannáà. Milton CamargoFojúsun lórí Jésù KrístìArákùnrin Camargo rán wa léti nípa àwọn ìbùkún ti dídá gbùngbun-ìhìnrere nílé sílẹ̀ àti ìkọ́ni pé Jésù Krístì nràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro bíi ti ikú, ẹ̀ṣẹ̀, àti àìlera. K. Brett NattressṢé A Ti Dáríjì Mí Nítòótọ́?Alàgbà Nattress kọ́ni pé ìdáríjì wà fún gbogbo ènìyàn nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin Jésù Krístì. Juan A. UcedaOlúwa Jésù Krístì Kọ́ Wa láti Ṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́Alàgbà Uceda kọ́ni pé Jésù Krístì ni Olùṣọ́-àgùtàn rere àti pé a lè tẹ̀lé E àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ bí a ti nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ara wa nínú ìfẹ́. Abala Òwúrọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi Abala Òwúrọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi D. Todd ChristoffersonỌ̀kan nínú KrístìAlàgbà Christofferson ṣe àpèjúwe bí a ti lè ṣe àṣeyege ìrẹ́pọ̀ bíótilẹ̀jẹ́pé a ní àwọn ìyàtọ̀—nípa wíwá ẹnìkọ̀ọ̀kan sọ́dọ̀ Jésù Krístì. Camille N. JohnsonJésù Krístì Ni Ìrànlọ́wọ́Ààrẹ Johnson kọ́ni pé a lè bá Olùgbàlà ṣepọ̀ láti fi ìrànlọ́wọ́ ti ara àti ti ẹ̀mí fún àwọn wọnnì nínú àìní. Ulisses SoaresÀwọn Atẹ̀lé Ọmọ-Aládé Àláfíà.Alàgbà Soares kọ́ni nípa àwọn ìhùwàsí Ìwàbíi-Krístì tí ó nrànwá lọ́wọ́ láti gbé àlàáfíà ga kí a sì di atẹ̀lé Jésù Krístì tòótọ́. Kazuhiko YamashitaÀkókò láti Gba Ìbùkún Baba Nlá RẹAlàgbà Yamashita gba àwọn ọmọ ìjọ níyànjú láti gbà àti láti tún àwọn ìbùkún ti bàbánlá wọn wò, èyí tí ó ní àmọ̀ràn araẹni láti ọ̀dọ̀ Olúwa nínú. Neil L. AndersenỌkàn Álmà ṣe ìdìmú lórí ero ti Jésù yí.Alàgbà Andersen kọ́ni bí a ti lè gba ìtọ́sọ́nà tọ̀runn àti agbára tọ̀run bí a ti nṣe ìdìmú lórí èrò Jésù Krístì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀. Kevin R. DuncanOhùn ìdùnnú kan!Alàgbà Duncan kọ́ni pé pípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́ yíò fún àwọn ẹ̀rí wa lókun yíò sì rànwá lọ́wọ́ láti wọlé sí agbára ìwòsàn ti Olùgbàlà. Russell M. NelsonA Nílò àwọn OnílàjàÀàrẹ Nelson pè wá láti yẹ ọkàn wa wò kí a sì gbé ohunkóhun tí ó lè dènà wá kúrò ní jíjẹ́ onílàjà kúrò, ojúṣe kan fún àwọn ọmọẹ̀hìn tòótọ́ ti Jésù Krístì—nípàtàkì nígbàtí wọ́ bá wà lábẹ́ ìgbóná. Abala Ọ̀sán Ọjọ́ Ìsinmi Abala Ọ̀sán Ọjọ́ Ìsinmi Dallin H. OaksÀwọn Ìkọ́ni ti Jésù KrístìÀàrẹ Oaks pín àwọn ìwé mímọ́ tí ó ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Krístì. M. Russell BallardẸ Rántí Ohun Tó Ṣe Kókó JùlọÀàrẹ Ballard kọ́ni nípa àwọn ohun tí ó ṣe kókó jùlọ, pẹ̀lú àwọn ìbáṣepọ̀ wa, àwọn ìṣíléti ti-ẹ̀mí wa, àti àwọn ẹ̀rí wa. Ronald A. RasbandHòsánnà sí Ọlọ́run Gíga JùlọAlàgbà Rasband kọ́ni pé Jésù Krístì fi ìṣẹ́gun wọ Jerusalem àti pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ọ̀sẹ̀ náà tí ó tẹ̀lé jẹ́ àpẹrẹ ẹ̀kọ́ tí a lè lò nínú ayé wa ní òní. Vern P. StanfillÌkórè ÀìpéAlàgbà Stánfill kọ́ni ní ìyàtọ̀ ní àárín lílé àṣepé ti ayé àti dídi pípé nínú Krístì. W. Mark BassettLẹ́hìn Ọjọ́ Kẹ́rin NáàAlàgbà Bassett kọ́ni pé bí a ṣe npa àwọn òfin mọ́ tí a sì nṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe, Jésù Krístì yíò ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nínú ìgbésí ayé wa. Ahmad S. CorbittNjẹ́ O Mọ Ìdi Tí Èmi Bíi Krístíẹ́nì Ṣe Gbàgbọ́ Nínú Krístì?Alàgbà Corbitt kọ́ni nípa ètò ìgbàlà, ẹ̀kọ́ krístì, àti pátákì pípín àwọn òtítọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. David A. Bednar“Gbé nínú mi, àti Emi nínú Rẹ, Nítorínáà, Rìn pẹ̀lú Mi”Alàgbà Bednar kọ́ni pé nígbàtí a bá ngbé nínú Olùgbàlà, Òun yíò gbé nínú wa a ó sì di alábùkún fún. Russell M. NelsonNígbàgbogbo Ni Ìdáhùn Jẹ́ Jésù Krístì.Ààrẹ Nelson jẹri nípa Jésù Krístì ó sì kéde àwọn ibi ìtẹ̀dó fún àwọn tẹ́mpìlì titun.