Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìkórè Àìpé
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


11:2

Ìkórè Àìpé

Olùgbàlà dúró ní ṣíṣetán láti gba àwọn ẹbọ ọrẹ ìrẹ̀lẹ̀ wa kí a sì ṣe wọ́n ní pípé nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀. Pẹ̀lú Krístì, kò sí ìkórè àìpé.

Bí ọmọdékùnrin kan, mo kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ìyípadà àgbàyanu ní àwọn àkókò ọdún ní Gúúsù-ìwọ̀ òòrùn Montana, níbi tí mo ti dàgbà. Àkókò tí mo fẹ́ràn jù lọ ni ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn—àkókò ìkórè. Ẹbí wa nírètí wọ́n sì ti gbàdúrà pé kí àwọn oṣù iṣẹ́ àṣekára wa kó ní èrè pẹ̀lú ìkórè lọ́pọ̀lọpọ̀. Àwọn òbí mi nṣàníyàn nípa ojú ọjọ́, ìlera àwọn ẹranko àti àwọn ohun ọ̀gbìn, àti ọ̀pọ̀ ohun míràn tí wọn ní àkóso kékeré lé lórí.

Bí mo ṣe ndàgbà, mo túbọ̀ nmọ̀ nípa ìkánjú tó wà nínú rẹ̀. Ìgbé-ayé wa dá lórí ìkórè. Baba mi kọ́ mi nípa àwọn ohun èlò tí a fi nkórè ọkà. Mo ti wo bí ó ṣe ngbe ẹ̀rọ náà lọ sórí pápá, gé kékeré lára ọkà, ati lẹ́hìnnáà ṣàyẹ̀wò lẹ́hìn àpapọ̀ náà láti rii dájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà bí ó ti ṣeé ṣe bọ́ sínú ìkòkò àti pé wọn kò dà sọnù pẹ̀lú ìyàngbò. Ó tún ìdárayá yí ṣe ní ìgbà púpọ̀, ní títún ẹ̀rọ náà sún ní àkókò kọ̀ọ̀kan. Mo sáré lẹ́gbẹ̀ẹ́ mo sì fi pápá gba ìyàngbò náà kọjá pẹ̀lú rẹ̀ mo sì ṣẹ̀tàn bí ẹni pé mo mọ ohun tí mò nṣe.

Lẹ́hìn tí ó ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn àtúnṣe sí ẹ̀rọ náà, mo rí àwọn ọkà èkùrọ́ díẹ̀ nínú ìyàngbò tí ó wà lórí ilẹ̀ mo sì fi wọ́n hàn fún un pẹ̀lú wíwò pàtàkì. Èmi kò ní gbàgbé ohun tí baba mi sọ: “Ó dára tóó sì dára jùlọ pé ẹ̀rọ yí lè ṣeé.” Láì ní ìtẹ́lọ́rùn gan pẹ̀lú àlàyé rẹ̀, mo jírórò àwọn àìpé ti ìkórè yí.

Ní àkókò díẹ̀ lẹ́hìnnáà, nígbàtí ojú ọjọ́ di tútù ní ìrọ̀lẹ́, mo rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn súwánì, egan, àti pẹ́pẹ́yẹ tí wọ́n nṣí lọ sí ibi pápá náà láti bọ́ ara wọn nínú ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn wọn síhà gúúsù. Wọ́n jẹ ọkà tó ṣẹ́kù lára ​​ìkórè àìpé wa. Ọlọ́run ti sọ ọ́ di pípé. Àti pe kò sí èkùrọ́ kan tí ó sọnù.

Ó jẹ́ ìdánwò nígbàgbogbo ní ayé wa àti pàápàá láàrín àṣà ti Ìjọ láti ṣe àkíyèsí nípa jíjẹ́ pípé. Ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn, àwọn ìfojúsọ́nà tí kò bọ́gbọ́n mu, àti àríwísí tiwa sí ara wa sábà máa nfa ìmọ̀lára àìkún ojú òsùnwọ̀n—pé a kò dára tó àti pé a kò lé dára láé. Àwọn kan tilẹ̀ ní àṣìgbọ́ ìpè Olùgbàlà “kí ẹ̀yin jẹ́ pípé nígbànáà.”1

Rántí pé ìwà pípé kìí ṣe bákannáà pẹ̀lú jíjẹ́ pípé nínú Krístì.2 Ìwà pípé nbéèrè fún ohun tí kò ṣeé ṣe, òsùnwọ̀n àfiṣe-araẹni tí ó fi wá wé àwọn ẹlòmíràn. Èyí fa ẹ̀bi àti àníyàn ó sì le mú wa fà sẹ́hìn kí à sì ya ara wa sọ́tọ̀.

Dída pípé nínú Krístì jẹ́ ọ̀rọ̀ míràn. Ó jẹ́ ìlànà náà—tí a tọ́ pẹ̀lú ìfẹ́ni nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́—ti dída bíi Olùgbàlà díẹ̀ síi. Àwọn ìlànà náà ni a gbé kalẹ̀ nípasẹ̀ Baba Ọ̀run kan onínúure tí ó sì mọ ohun gbogbo, tí a sì ṣe ìtumọ̀ rẹ̀ ní kedere nínú àwọn májẹ̀mú tí a pè wá láti gbà mọ́ra. Ó máa ntú wa sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹrù ẹ̀bi àti àìkún ojú òsùnwọ̀n, ní títẹnumọ́ ẹni tí a jẹ́ lójú Ọlọ́run nígbà gbogbo. Nígbàtí ìlànà yí ngbé wa ga tí ó sì ntìwá láti dára si, a njẹ́ dídíwọ̀n nípa ìfọkànsìn araẹni wa sí Ọlọ́run pé a fi hàn nínú àwọn ìtiraka wa láti tẹ̀lé E nínú ìgbàgbọ́. Bí a ṣe ngba ìpè Olùgbàlà láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, láìpẹ́ a mọ̀ pé dídára jùlọ wa dára tó àti pé oore-ọ̀fẹ́ olùfẹ́ni Olùgbàlà yíò ṣe àfikún ìyàtọ̀ ní àwọn ọ̀nà tí a kò lè ronú.

À lè rí ìlànà yí ní mímúlò nígbàtí Olùgbàlà bọ́ àwọn ẹgbẹ̀run márun.

“Nígbàtí Jésù gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ẹgbẹ́ nla kan tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Fílíppì pé, Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ? …

“Fílíppì dá a lóhùn pé, Igba owó idẹ kò tó fún wọn, tí olúkúlùkù wọn lè mú díẹ̀.

“Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀, Ándérù, arákùnrin Símónì Pétérù, wí fún un pé,

“Ọmọdékùnrin kan wà níhìn-ín, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùn-ún, àti ẹja kékeré méjì: ṣùgbọ́n kí ni wọ́n nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ bẹ́ẹ̀?”3

Njẹ́ ó tiẹ̀ máa nyàyín lẹ́nu nípa ìmọ̀lára Olùgbàlà nípa ọmọdékùnrin yìí, ẹni tó fi ìgbàgbọ́ ọmọdé ṣèrú ohun tí ó gbọ́dọ̀ mọ̀ pé kò tóótun ní ojú iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀?

“Jésù sì mú ìṣù àkàrà náà; nígbàtí ó sì ti dúpẹ́, ó pin fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ sì fún àwọn tí ó jòkó; àti bákannáà nínú àwọn ẹja bí wọ́n ti fẹ́.

“Nígbàtí wọ́n yó, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àwọn àjẹkù tí ó ṣẹ́ kù, kí ohunkóhun má bàa sọnù.”4

Olùgbàlà mú ọrẹ ìrẹ̀lẹ̀ di pípé.

Láìpẹ́ lẹ́hìn ìrírí yí, Jésù rán àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ ṣíwájú nínú ọkọ̀ ojú-omi. Kò pẹ́ tí wọ́n fi bá ara wọn lórí ìjì òkun ní àárín òru. Ẹ̀rù bà wọ́n nígbà tí wọ́n rí ẹni bíi iwin kan tó nrìn lọ sọ́dọ̀ wọn lórí omi.

“Ṣùgbọ́n lójúkannáà ni Jésù wí fún wọn pé Ẹ tújúká; èmi ni, ẹ má bẹ̀rù.

“Pétérù sì dá a lóhùn wí pé, Olúwa, bí ìwọ bá ni, pàṣẹ kí èmi tọ̀ ọ́ wá lórí omi.

“Ó sì wí pé, Wá. Nígbàtí Pétérù sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀, ó rìn lórí omi, láti lọ sọ́dọ̀ Jésù.

“Ṣùgbọ́n nígbàtí ó rí tí afẹ́fẹ́ le, ẹ̀rù bá á; àti nítorítí ó bẹ̀rẹ̀sí rì, ó kígbe, wípé, Olúwa, gbà mi.

“Lójúkanáà Jésù sì na ọwọ́ rẹ, ó si dìí mú, ó sì wí fun pé, Ìwọ onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì?”5

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, èyí lè má jẹ́ òpin ọ̀rọ̀ sísọ náà. Mo gbàgbọ́ pé bí Pétérù àti Olùgbàlà ti nrìn padà sí ibi ọkọ̀ ojú-omi ní apá nínú apá, Pétérù ní rírẹ tutù àti bóyá ní níní mọ̀lára bí jíjẹ́ aláìgbọ́n, Olùgbàlà lè ti sọ nkan bí èyí: “Ah, Pétérù, má bẹ̀rù má sì ṣe àníyàn. Bí o bá lè rí ara rẹ bí mo ti rí ọ, iyèméjì rẹ yíò parẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ yíò sì pọ̀ si. Mo nífẹ rẹ, Pétérù ọ̀wọ́n; o jáde kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi. Ẹbọ-ọrẹ rẹ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, àti bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣìnà, Èmi yíò wà níbẹ̀ nígbà-gbogbo láti gbé ọ láti inú ibú wá, àti pé a ó sọ ẹbọ-ọrẹ rẹ di pípé.”

Alàgbà Dieter F. Uchtdorf kọ́ni:

“Mo gbagbọ́ pé Olùgbàlà Jésù Krístì yío fẹ́ kí ẹyin ó rí, kí ẹ ní imọlára, kí ẹ si mọ pé Oun ni okun yín. Pé pẹlú iranlọ́wọ́ Rẹ̀, ko sí opin sí ohun tí ẹ le ṣe ní aṣeyọrí. Pé agbára ṣíṣe yín ko ní opin. Òun yío fẹ́ kí ẹ rí ara yín ní ọ̀nà bí Òun ti rí yín. Èyí sì yàtọ̀ gan sí ọ̀nà tí ayé ti rí yín. …

“Ó nfi agbára fún awọn tó ti rẹ̀; àti fún àwọn tó ní imọlára ailágbára, Ó nmú okun pọ síi.”7

A gbọ́dọ̀ rántí pé ohunkóhun tó le jẹ́ ẹbọ-ọrẹ wa tó dára jùlọ ṣùgbọ́n tí kò pé, Olùgbàlà lè sọ ọ́ di pípé. Bí ó ti wù kí ìsapá wa ṣe lè dà bí ẹni pé kò ṣe pàtàkì tó, a kò gbọ́dọ̀ fojú kéré agbára Olùgbàlà láéláé. Ọ̀rọ̀ inú rere rírọrùn kan, àbẹ̀wò rànpẹ́ ṣùgbọ́n àtinúwá, tàbí ẹ̀kọ́ Alákọ́bẹ̀rẹ̀ kan tí a kọ́ni pẹ̀lú ìfẹ́ni lè, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà, pèsè ìtùnú, mú àwọn ọkàn rọ̀, kí ó sì yí ìyè ayérayé padà. Ìgbìyànjú wa tí ó díjú lè darí si àwọn iṣẹ́ ìyànu, àti nínú ìlànà, a lè kópa nínú ìkórè pípé kan.

Nígbà-gbogbo a gbé wa sí àwọn ipò tí yíò jẹ́ kí á nà tàntàn. A lè má ní ìmọ̀lára kíkúnjú òṣùwọ̀n sí áwọn iṣẹ-ṣiṣe náà. A lè máa wo àwọn tí a jọ nsìn kí á sì ní ìmọ̀lára pé a ò lè kún ojú ìwọ̀n láé. Ẹ̀yin Arákùnrin àti arábìrin, bí ẹ bá ní ìmọ̀lára lọ́nà yí, ẹ wo àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n joko lẹ́hìn mi.

Mo ní ìmọ̀lára ìrora yín.

Ṣùgbọ́n, mo ti kọ́, pé gẹ́gẹ́bí ìjẹ́pípé kì tií ṣe ọ̀kan náà pẹ̀lú pípé nínú Kristi, fífi ara-ẹni wé ẹlòmíràn kì í ṣe ọ̀kannáà pẹ̀lú àfarawé. Nígbà tí a bá ṣe àfiwé ara wa sí àwọn ẹlòmíràn, àbájáde méjì nìkan ni ó lè jẹ́. Bóyá a ó rí ara wa bí ẹni tí ó dára ju àwọn elòmíràn lọ kí á di olùdájọ́ kí á sì ṣe aláríwísí wọn, tàbí a ó rí ara wa bí ẹni tí ó kéré jù àwọn míràn lọ kí á di àìfarabalẹ̀, aláríwísí araẹni, àti rírẹ̀wẹ̀sì. Fífi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn kì í sábà méso jáde, kì í gbéni ró, ó sì máa nkó ìrẹ̀wẹ̀sì báni nígbà míràn. Ní pàtó, àwọn ìfiwéra wọ̀nyí lè ṣè ìparun nípa ti ẹ̀mí, ní dídè wá lọ́nà kúrò ní gbígba ìrànlọ́wọ́ ti ẹ̀mí tí a nílò. Ní ọ̀nà míràn ẹ̀wẹ̀, ṣíṣe àfarawé àwọn tí a bọ̀wọ̀ fún tí wọ́n nfi àwọn ìwà bíi ti Kristi hàn lè jẹ́ pípaláṣẹ àti gbígbéniga ó sì lè rànwá lọ́wọ́ láti di ọmọ-ẹ́hìn Jésù Krístì dídára síi.

Olùgbàlà fún wa ní àwòkọ́ṣe láti tẹ̀lé bí Ó ṣe fi ara wé Baba. Ó pàṣẹ fún ọmọẹ̀hìn Rẹ Philip: “Ṣé mo ti wà pẹ̀lú rẹ fún ìgbà pípẹ́ tó báyìí, tí o kò sì mọ̀ mí, Fílíppì? Ẹnití ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba; àti báwo ní ìwọ ṣe wípé, Fi Baba hàn wa?”8

Ó sì kọ́ni pé, “Lõtọ́, lõtọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, àwọn iṣẹ́ tí èmi nṣe ni òun yíò ṣe pẹ̀lú.”9

Láìbìkítà báwo ni àwọn ìgbìyànjú wa ṣe le kéré tó, tí a ba jẹ́ olódodo, Olùgbàlà yíò lò wá láti ṣe àṣeparí iṣẹ́ Rẹ. Bí a bá ṣe bí a ti le ṣe dára jùlọ tó tí a sì gbẹ́kẹ̀le E láti ṣe èyí tó fi yàtọ̀, a lè di apákan àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó yí wa ká.

Alàgbà Dale G. Renlund wípé, “Ẹ kò ní láti jẹ́ pípé, ṣùgbọ́n a nílò yín, nítorí gbogbo ẹnití ó ṣetán lè ṣe ohun kan.”10

Àarẹ Nelson kọ́wa pé, “Oluwa fẹ́ràn ìtiraka.”11

Olùgbàlà dúró ní síṣetán láti gba àwọn ẹbọ ọrẹ ìrẹ̀lẹ̀ wa kí a sì ṣe wọ́n ní pípé nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀. Pẹ̀lú Krístì, kò sí ìkórè àìpé. A gbọ́dọ̀ ní ìgboyà láti gbàgbọ́ pé oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ wà fún wa—pé Òun yíò rànwá lọ́wọ́, yíò gbà wá lọ́wọ́ àwọn ibú nígbàtí a bá ṣe àṣìṣe, yíò sì sọ àwọn ìtiraka wa tí o kéré-ju-pípé-lọ di pípé.

Nínú òwe afúnrúgbìn, Olùgbàlà ṣe àpèjúwe àwọn irúgbìn tí a gbìn ní ilẹ̀ tí ó dára. Díẹ̀ nínú wọn mú ọgọ́rũn-ọgọ́rùn-ún, àwọn kan ọgọ́ta, àti àwọn míràn ọgbọ̀n. Gbogbo wọn jẹ́ ara ìkórè pípé Rẹ̀.12

Wòlíì Mórónì pe gbogbo ènìyàn, “Bẹ́ẹ̀ni, ẹ wá sọ́dọ̀ Krístì, kí ẹ sì jẹ́ pípé nínú rẹ̀, … bí ẹ̀yin bá sì sẹ́ ara yín ní gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run, tí ẹ sì fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo agbára, inú àti okun yín, nígbà náà ni oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fún yín, pé nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ẹ lè di pípé nínú Kristi.”13

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì, ẹni tí ó ní agbára láti ṣe àní ọrẹ wa tí ó jẹ́ ìrẹ̀lẹ̀ jùlọ ní pípé. Ẹ jẹ́ kí á sa ipá wa, mú ohun tí a lè mú wá, àti, pẹ̀lú ìgbàgbọ́, tẹ́ ọrẹ àìpé wa sí ibi ẹsẹ̀ Rẹ̀. Ní orúkọ Rẹ̀ ẹni tí ó jẹ́ Olùkọ́ ìkórè pípé, àní Jésù Krístì, àmín.