Fojúsun Jésù Krístì
Olúwa Jésù Krístì ni ojútùú sí àwọn ìṣòro wa, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ gbé ojú wa sókè kí a sì gbé àwọn ìríran wa sókè láti rí I.
Baba mi máa nsọ fún mi pé, “Má ṣe ní ìfojúsùn líle tóbẹ́ẹ̀ sórí àwọn ìṣòro rẹ débi pé o kò lè rí ojútùú rẹ̀.”
Mo jẹ́ ẹ̀rí pe Jésù Krístì Olúwa jẹ́ ojútùú sí àní àwọn ìṣòro tí ó nira júlọ. Ní pàtó, Ó ti borí àwọn ìṣòro mẹ́rin tí olukúlùkù wa dojúkọ àti tí kò sí ọ̀kan nínú wa tí ó lè yanjú rẹ̀ fúnra wa:
-
Ìṣoro àkọ́kọ́ jẹ́ ikú ti ara. A lè gbìyànjú láti dá a dúró tàbí fojú fò ó, ṣùgbọ́n a kò lè borí rẹ̀ fúnra wa. Síbẹ̀síbẹ̀ Jésù Krístì ṣẹ́gun ikú fún wa, àti bíi àyọrísí, gbogbo wa ni a ó jí dìde lọ́jọ́ kan.1
-
Ìṣòro kejì ní àwọn ìpọ́njú, àwọn ìrírí líle, ìbànújẹ́, ìrora, àti àìṣòdodo ti ayé yíì nínú. Jésù Krístì ṣẹ́gun gbogbo èyí. Fún àwọn wọ́nnì tí wọ́n ntiraka láti tẹ̀lé E, Òun yìó “nu gbogbo omijé nù” ní ọjọ́ kan yìó sì mú àwọn nkan ṣe déédé lẹ́ẹ̀kansi.2 Ní ìgbà yìí, Ó lè fún wa lókun láti la àwọn ìdánwò wa kọjá pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀, ìtúraká rere, àti àláfíà.3
-
ìṣòro kẹ́ta jẹ́ ikú ti ẹ̀mí tí ó nwá láti inú ẹ̀ṣẹ̀. Jésù Krístì borí ìṣòro yìí nípa gbígbé “ìnà àlàáfíà wa” lé ara Rẹ̀.4 Nítorí ẹbọ ètùtù Rẹ̀, a lè so wá di òmìnira kúrò lọ́wọ́ àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tí a bá ní ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà, tí a ronúpìwàdà tọkàntọkàn, gba májẹ̀mú tí Baba fifún wa nípasẹ̀ àwọn ìlànà pàtàkì bíi ìrìbọmi, tí a sì faradà dé òpin.5
-
Ìṣòro kẹ́rin ni àwọn àdánidá wató ní ìwọ̀n, tó sì jẹ́ àìpé. Jésù Krístì ní ojútùú sí ìṣòro yìí pẹ̀lú. Òun kò kàn pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́ kúrò kí ó sì sọ wá di aláìlẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi. Ó lè ṣe iṣẹ́ “ìyípadà nlá nínú … ọkàn wa, tí a kò ní ní ìtẹ̀sí láti ṣe ibi mọ́, ṣùgbọ́n láti máa ṣe rere títílọ.”6 A lè di pípé nípa oore-ọ̀fẹ́ Krístì àti ní ọjọ́ kan kí a dàbí Rẹ̀.7
Ó ṣeni láànú pé lọ́pọ̀ ìgbà a máa nronú púpọ̀ lórí àwọn ìṣòro tiwa tóbẹ́ẹ̀ tí a npàdánù ìfojúsùn sí orí ojútùú náà, Jésù Kristi, Olùgbàlà wa. Báwo ni a ṣe lè yẹra fún àṣìṣe yí? Mo gbàgbọ́ pé ìdáhùn dá lórí àwọn májẹ̀mú tí a pè wá láti dá pẹ̀lú Rẹ̀ àti Baba wa ní Ọ̀run.
Fífojúsùn sí Jésù Krístì nípasẹ̀ àwọn Májẹ̀mú
Àwọn májẹ̀mú wa máa nrànwá lọ́wọ́ láti fojúsùn àkíyèsí wa, àwọn ìrònú wa, àti àwọn ìṣe wa sí Krístì. Bí a ṣe “nfi ara mọ́ àwọn májẹ̀mú [tí a ti] dá,” a lè túbọ̀ máa fi ìrọ̀rùn dá “àwọn ohun ti ayé yìí” mọ̀ tí a gbọ́dọ̀ “fi sílẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan” àti “àwọn ohun ti [ayé] tí ó dára jù” tí a ní láti fi taratara wá.8
Èyí ni ohun tí àwọn ènìyàn Ámónì ṣe nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Bí wọ́n ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù Krístì tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú ìgbésí ayé wọn sùn Ún, wọ́n dáa mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n ó sin àwọn ohun ìjà ogun wọn, wọ́n sì di olóòtọ́ ní pípé, wọ́n sì “dá yàtọ̀ fún ìtara wọn sí Ọlọ́run.”9
Pípa májẹ̀mú mọ́ ndarí wa láti lépa ohunkóhun tí ó bá npe ipá ti Ẹ̀mí kí a sì kọ ohunkóhun tí ó bá lé e lọ sílẹ̀—“nítorí a mọ̀ pé bí a bá lè jẹ́ kíkàyẹ ní wíwà níwájú Ẹmí Mímọ́, a tún lè jẹ́ kíkàyẹ láti gbé ní iwájú Baba Ọ̀run àti Ọmo Rẹ̀, Jésù Krístì.”10 Èyí lè túmọ̀ sí pé a ní láti yí àwọn ìsọ̀rọ̀ wa padà, ní lílo àwọn ọ̀rọ̀ rere. Ó lè túmọ̀ sí rírọ́pò àwọn àṣà tí kò dára tó ní ti ẹ̀mí pẹ̀lú àwọn àṣà titun tó nfún àjọṣe wa pẹ̀lú Olúwa lókun, irú bí àdúrà ojoojúmọ́ àti ṣíṣe àṣàrò ìwé mímọ́, bí ẹnì kọ̀ọ̀kan àti pẹ̀lú ẹbí wa.
Ààrẹ Russell M. Nelson wípé “ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ndá àwọn májẹ̀mú nínú àwo ìrìbọmi àti nínú àwọn tẹ́mpìlì—tí wọ́n sì npa wọn mọ́—ní ààyè púpọ̀ sí agbára Jésù Krístì. …
“Èrè fún pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni agbára àtọ̀runwá—agbára tí ó nfún wa lokun láti kojú àwọn ìpèníjà, ìdánwò, àti ìrora-ọkàn wa dáadáa.”11
Títún àwọn májẹ̀mú wa ṣe lákokò oúnjẹ Olúwa ní ọjọ́ Ìsimi kọ̀ọ̀kan jẹ́ ànfààní nlá láti ṣe àyẹ̀wò ara wa12 kí a sì tún dojú ayé wa kọ Jésù Krístì. Nípa jíjẹ oúnjẹ Olúwa, a nkéde pé a “rántí rẹ̀ nígbà gbogbo.”13 Ọ̀rọ̀ náà nígbà gbogbo jẹ́ pàtàkì púpọ̀. Ó na ipá Olúgbàlà sí gbogbo abala ìgbésí ayé wa. A kò rántí Rẹ̀ ní ilé ìjọsìn nìkan tàbí nígbà àwọn ádúrà òwúrọ̀ wa nìkan tàbí nígbàtí a bá wà nínú ìṣòro nìkan tí a sì nílò nkan.
Bẹ́ẹ̀ni, a máa nní ìdàmú nígbà míràn. A ngbàgbé. A npàdánù ìfojúsùn wa. Ṣùgbọ́n sísọ àwọn májẹ̀mú wa di ọ̀tun túmọ̀ sí pé a fẹ́ láti rántí Olùgbàlà nígbà gbogbo, pé a ó gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ náà, àti pé a ó tún ìfọkànsìn àti ìfojúsùn wa ṣe sí Òun lẹ́ẹ̀kan síi ní ibi tábìlì oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sẹ̀ tó nbọ̀.
Fífi ojúsùn sí Jésù Krístì Nínú Ilé wa
Ní kedere, fífojúsun sí Jésù Krístì gbọ́dọ̀ ju iṣẹ́ síṣe ọjọ́ Ìsinmi, ni-ilé ìjọsìn lọ. Nígbàtí Ààrẹ Nelson ṣe àfihàn Wa, Tẹ̀lé Mi ní 2018, ó wípé, “Àkókò tó fún Ìjọ tí ó fi illé sí ààrin gbùngbùn.”14 Ó wípé a gbọ́dọ̀ “yí ilé [wa] padà sí ibi mímọ́ ti ìgbàgbọ́” àti “ibi ìkẹ́kọ́ ìhìnrere.” Ó sì ṣ̣e àwọn ìlérí àgbàyanu mẹ́rin fún wa tí a bá ṣe.15
Ìlérí àkọ́kọ́: “Àwọn ọjọ́ Sábáàtì yín yíò jẹ́ aládùn ní tòótọ́.” Yíò di ọjọ́ tí a sún mọ́ Olùgbàlà wa síi. Bí ọ̀dọ́mọbìnrin kan láti Peru ṣe sọ, “Ọjọ́ Olúwa ni ọjọ́ tí mo máa nrí ìdáhùn tó pọ̀ jùlọ gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa.”
Ìlérí Kejì: “Inú àwọn ọmọ yín yíò dùn láti kọ́ ẹkọ àti láti gbé ìgbé ayé àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà.” Ìdí nìyí tí, “a nsọ̀rọ̀ nípa Krístì, a nyọ̀ nínú Krístì, a si nwãsù nípa Krístì, … pé kí àwọn ọmọ wa lè mọ́ orísun èwo ni àwọn lè wò fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”16
A ṣe èyí kí ó lè jẹ́ pé lọ́jọ́ kan, nígbà tí ọmọ wa bá jáde lọ ṣiṣẹ́ tàbí láti rìn lórí àwọn òkè tàbí láti dọdẹ ẹranko nínú igbó, bí Énọ́sì ti ṣe, kí òun ó lè rántí ohun tí a kọ́ ọ nípa Kristi àti nípa ayọ̀ gbígbé ìgbé ayé ìhìnrere náà. Tani ó mọ̀? Bóyá èyí yíò jẹ́ ọjọ́ náà nígbà tí òun yíò ní ìmọ̀lára ebi ti ẹ̀mí nígbẹ̀hìn tí yíó yí i padà sọ́dọ̀ Jésù Kristi kí ó lè gbọ́ ohùn Olúwa tí ó nsọ fún un pé, “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, a ó sì bùkún ọ́.”17
Ìlérí kẹ́ta: “Ipá ò̩tá ní ìgbésí-ayé yín àti nínú ilé yín yíò dínkù.” Kínìdí? Nítorípé bí a bá ti nfojúsùn sí Jésù Krístì, bẹ́ẹ̀ni ẹ̀ṣẹ̀ npàdánù ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.18 Bí àwọn ilé wa ṣe kún fún ìmọ́lẹ̀ Olùgbàlà, ààyè ndínkù si fún òkùnkùn ọ̀tá.
Ìlérí kẹrin: “Àwọn ìyípadà nínú ẹbí yín yíò jẹ́ àgbàyanu àti mímúnidúró.” Kínìdí? Nítorí pé ìyípadà tí Jésù Krístì mú wá jẹ́ “ìyípadà nlà.”19 Ó yí àwọn àdánidá wa gan-an padà; a di “ẹ̀dá titun,”20 A nfi díẹ̀díẹ̀ dàbí Olùgbàlà, tí ó kún fún ìfẹ́ àìlábàwọ́n Rẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.
Tani kò ní fẹ́ kí àwọn ìlérí wọ̀nyí ṣẹ nínú ìgbésí ayé wọn àti nínú ẹbí wọn? Kí la ní láti ṣe kí á lè rí wọn gbà? Ìdáhùn ni láti yí àwọn ilé wa padà sí ibi mímọ́ ti ìgbàgbọ́ àti gbùngbùn ti kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere. Àti pé báwo ni a ó ti ṣe èyí? Nípa fífojúsùn sí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì, ní sísọ Wọ́n di àárín gbùngbùn ìgbésí ayé ẹbí wa, ipá tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ilé wa.
Njẹ́ mo lè dábàá pé kí ẹ bẹ̀rẹ̀ nípa fífi àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, tí a rí nínú àwọn ìwé mímọ́, ṣe apákan ìgbésí ayé yín lójoójúmọ́? Kò sí ìlànà àgbékalẹ̀ fún ṣíṣe àṣàrò ìwé-mímọ́ pípé. Ó lè jẹ́ ìṣẹ́jú márùn-ún tàbí mẹ́wàá ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan—tàbí díẹ̀ síi tí ẹ bá lè ṣeé. Ó lè jẹ́ orí kan tàbí àwọn ẹsẹ díẹ̀ ní ọjọ́ kan. Àwọn ẹbí míràn fẹ́ láti ṣe àṣàrò ní òwúrọ̀ kí wọ́n tó lọ sí ilé-ìwé tàbí ibi iṣẹ́. Àwọn míràn fẹ́ láti kà ní alẹ̀ kí wọ́n tó sùn. Àwọn tọkọtaya ọ̀dọ́ kan ti sọ fún mi pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa nṣe àṣàrò lọ́nà ibi iṣẹ́ àti lẹ́hìnnáà wọ́n máa nsọ ìjìnlẹ̀ òye pẹ̀lú ara wọn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ni a kọsílẹ̀ sílẹ̀.
Wá, Tẹ̀lé Mi npèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìmọ̀ràn ti àwọn ìṣe àti àwọn orísun tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún olúkúlùkù àti àwọn ẹbí láti kọ́ àwọn ìlànà ìhìnrere láti inú àwọn ìwé-mímọ́. Àwọn fídíò Bíbélì àti àwọn fídíò Ìwé ti Mọ́mọ́nì tún lè jẹ́ irinṣẹ́ tó ṣe iyebíye láti mú kí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ túbọ̀ rọrùn fún ẹbí yín. Àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ọmọdé fi ìgbàgbogbo ní ìmísí nípa àwọn ìtàn mánigbàgbé nínú àwọn ìwé-mímọ́. Àwọn ìtàn wọ̀nyí àti àwọn ẹ̀kọ́ ìhìnrere tí wọ́n nkọ́ni yíò dúró pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, bíi àwọn ọ̀rẹ́ tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé, nígbàtí wọ́n bá nílò àwọn àpẹrẹ rere ti iṣẹ́-ìsìn, ìwà rere, ìgboràn, sùúrù, ìfaradà, ìfihàn araẹni, ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ìrẹ̀lẹ̀, àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Bí àkókò ti nlọ, ìdúróṣinṣin yín nínú jíjẹ àpùjẹ lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yíò ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Olùgbàlà. Wọn yíò wá láti mọ̀ Ọn ju ti ìgbà ìṣaájú rí lọ.
Jésù Krístì Olúwa wà láàyè lónìí. Ó lè jẹ́ ohun tí nṣe ìṣe lọ́wọ́, wíwà ní ojoójúmọ́ nínú ayé wa. Òun ni ojútùú sí àwọn ìṣòro wa, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ gbé ojú wa sókè kí a sì gbé àwọn ìríran wa sókè láti rí I. Ó ti wípé, “Wò mi nínú gbogbo èrò, máṣe ṣiyèméjì, máṣe bẹ̀rù.”21 Bí a ṣe nfojúsùn sí Òun àti Baba wa ní Ọ̀run, tí a ndá májẹ̀mú tí a sì npa wọ́n mọ́ pẹ̀lú Wọn, tí a sì fi Wọ́n ṣe ipá pàtàkì jùlọ nínú ilé àti ẹbí wa, a ó di irú àwọn ènìyàn tí Ààrẹ Nelson fi ojú ìran wò: “Àwọn ènìyàn tí wọ́n lágbára, tí wọ́n ṣetán, tí wọ́n sì yẹ láti gba Olúwa nígbàtí ó bá tún dé, àwọn ènìyàn tí wọ́n ti yan Jésù Krístì tẹ́lẹ̀ lórí ayé ìṣubú yìí, àwọn ènìyàn tí wọ́n láyọ̀ nínú agbára òmìnira wọn láti gbé ìgbé ayé àwọn òfin gíga jù, mímọ́ jù ti Jésù Krístì.”22 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.