Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìkójọ̀pọ̀ Sílé Lálàfíà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Ìkójọ̀pọ̀ Sílé Lálàfíà

A wà ní ipò àiláfiwé láti kó Ísráẹ́lì jọ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú bí kò tiṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ètò Baba.

Ààrẹ Russell M. Nelson, olùfẹ́ wòlíì wa, ti ṣe àtẹnumọ́ jinlẹ̀jinlẹ̀ pé ojúṣe àìláfiwé wa ni làti ṣerànwọ́ láti kó àwọn olùfọ́nká Ísráẹ́lì jọ àti kí a múra ayé sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Jésù Krístì.1 Baba àwọn ẹ̀mí wa nfẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ jẹ́ kíkójọ ní aláfíà sílé.

Ètò Baba wa Ọ̀run láti kó àwọn ọmọ Rẹ̀ jọ ní àláfíà sí ilé tọ̀run kò dálé orí àṣeyege ti ayé, ipò ìṣúná, ẹ̀kọ́, ẹ̀yà, tàbí lákọlábo. Ètò Baba dálé orí òdodo, pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, àti gbigba àwọn ìlànà mímọ́ àti bíbu ọlá fún àwọn májẹ̀mú tí a dá.2

Ẹ̀kọ́ onimisi ti ọ̀run pé gbogbo wa jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin àti pé “gbogbo wa jẹ́ bákannáà sí Ọlọ́run” ni kúlẹ̀kúlẹ̀ iṣẹ́ nlá kíkójọ́ yí. Ẹ̀kọ́ yí ní ìbárẹ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n nifẹ tó jìnlẹ̀ fún àwọn ènìyàn onìrurú ipò ìsúná àti ẹ̀yà láti ní ìrírí àwọn ìgbè ayé dídara si. A yẹ́sí a sì darapọ̀ mọ́ irú ìtiraka bẹ́ẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ní ìfẹ́ fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti láti gba àwọn ìbùkún ayérayé tí Òun nfúnni nípasẹ̀ ìhínrere Rẹ̀.3 Nínú ọ̀rọ́ ìṣaájú Olúwa sí Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú Ó kéde, “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ènìyàn láti ọ̀nà jíjìn; àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní erékùṣù òkun, ẹ fetísílẹ̀ papọ̀.”4

Mo ní ìfẹ́ pé ẹsẹ àkọ́kọ́ gan nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní “erékùṣù òkun.” Mo ti ní àwọn kókó ìpè mẹ́ta láti sìn àti láti gbé ní àwọn erékùṣù òkun. Mo kọ́kọ́ sìn bí ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere sí Erékùṣù British, ẹ̀ẹ̀kejì bí Aláṣẹ Gbogbogbò ní Erékùṣù Philippine, àti lẹ́hìnnáà bí Ààre Agbègbè ní Erékùṣù Pacific èyí tí ó pẹ̀lú Erékùṣù Polynesian.

Gbogbo mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àwọn agbègbè wọ̀nyí ti fi àṣeyege kó àwọn onígbàgbọ́ jọ sí ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere dé sí Erékùṣù British ní 1837. Èyí jẹ́ ọdún kan lẹ́hìn tí Joseph Smith ya Tẹ́mpìlì Kirtland sí mímọ́, níbití Mósè ti fúnni “àwọn kọ́kọ́rọ́ kíkójọ Ísráẹ́lì láti igun mẹ́rin ilẹ̀ ayé, àti ní dídarí àwọn ẹ̀yà mẹwa láti ilẹ̀ àríwá.”5 Àṣeyege ìsíwájú ní Erékùṣù Brítish jẹ́ ìtàn àtẹnudẹ́nu. Ní 1851 ó ju ìlàjì àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n jẹ́ olùyípadà-ọkan tí a rìbọmi tí wọ̀n ngbé ní Erékùṣù British.6

Ní 1961 Alàgbà Gordon B. Hinckley ṣèbẹ̀wò tí ó sì fi ìtiraka iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìgbà kíkún lọ́lẹ̀ ní Erékùṣù Philippine. Ní àkokò náà ẹyọ Filipino Oyè-àlùfáà Mẹlkisẹ́dékì kanṣoṣo ni ó wà. Pẹ̀lú ìyanu, àwọn ọmọ Ìjọ ju 850,000 tí ó wà ní Erékùṣù Philippine ní òní. Mo nifẹsi àwọn èníyàn Philippine; wọ́n ní ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ àti ìbágbé fún Olùgbàlà.

Bóyá àìmọ̀ dáadáa ni ìtiraka iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó nlọ lọwọ́ lọ sí Erékùṣù Polynesian. Ó bẹ̀rẹ̀ ní 1843 nígbàtí Addison Pratt dé sí ibi tí a mọ̀ nísisìyí bí French Polynesia.7 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Polynesia ti gbàgbọ́ nínú ẹbí ayérayé wọ́n sì tẹ́wọ́gba Jésù Krísì bí Olùgbàlà wọn. Ní òní ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ìpín mẹẹdọgbọn àwọn ará Erékùṣù Polynesia, ni ọmọ Ìjọ.8

Nígbàkan mo fetísílẹ̀ sí ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan ní ọ̀nàjíjìn erékùṣù Tahitian tí ó jẹ́ iran ọmọ ìjọ keje. Ó gbé oríyìn fún àwọn babanla rẹ̀ tí wọ́n di olùyípadà-ọkàn ní 1845 ní Tubuai, ọdún méjì ṣíwájú kí àwọn ọmọ Ìjọ̀ ìṣaájú tó dé Àfonífojì Salt Lake Valley.9

Ẹ̀kọ́ wa hàn kedere pé àkokò kan yíò wà àti ìgbà kan fún gbogbo ènìyàn láti gbà àti láti fèsì sí ọ̀rọ̀ ìhìnrere. Àwọn àpẹrẹ wọ̀nyí kàn jẹ́ ara ìwò títóbi púpọ̀ kan ni. Ààrẹ Nelson ti tẹnumọ léraléra pé kíkójọ Ísráẹ́lì ni “ìpènijà , … èrò, àti …iṣẹ́ gígajùlọ lórí ilẹ̀ ayé ní òní.”10

Títí di Ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Jésù Krístì, pẹ̀lú jíjádé Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti ìfihàn àti àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà tí a fún Wòlíì Joseph Smith, níní òye kíkójọ Ísráẹ́lì jẹ́ àkékù ó sì ní òpin.11

Orúkọ pàtàkì “Ísráẹ́lì” ni àkọlé tí a fi sórí Jákọ̀bù.12 Ó wá láti ṣojú ìran Ábráhámù nípasẹ̀ Ísákì àti Jákọ́bù. Ìlérí àtètèkọ́ṣe àti májẹ̀mú sí Baba Ábráhámù ni a gbé kalẹ̀ nínú Abraham 2:9–10, èyí tí ó kà ní apákan pé:

“Èmi ó sì sọ ọ́ di orílè èdè nlá, …

“Èmi yíò sì bùkún fún [gbogbo orílẹ̀ èdè] nípasẹ̀ orúkọ rẹ; nítorí iye àwọn tí wọ́n bá gba Ìhìnrere yí ni a ó pè tẹ̀lé orúkọ rẹ̀, a ó sì kà wọ́n sí irú ọmọ rẹ̀, wọn yíò sì dìde sókè láti bùkún fún ọ, bíi baba wọn.”

Ní ìgbà Ìgbìmọ ní Ọ̀run nínú wíwà ìṣíwájú ayé, a sọ̀rọ̀ ètò ìgbàlà a si ṣe ìmúdúró. Ó pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà oyè-àlùfáà kan tí a fi lọ́lẹ̀ ṣaájú ìpìlẹ̀ ayé tí a sì sọ tẹ́lẹ̀ lórí ìkójọpọ̀.13 Bákannáà ó pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ tí ó borí agbára láti yàn.

Lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn sẹ́ntúrì bí àwọn ènìyàn alágbára, pẹ̀lú àkóso ti Saul, David, àti Solomon, Ísráẹ́lì pínyà. Ẹ̀yà Judah àti ara ẹ̀yà Benjamin di ìjọba Judah. Ìyókù, tí a mọ̀ bí àwọn ẹ̀yà mẹwa, di ìjọba Ísráẹ́lì.14 Lẹ́hìn igba ọdún ti wíwà ní ìyapa, fífọ́nká àkọ́kọ́ ti Ísráẹ́lì ṣẹlẹ̀ ní ọdún 721 kí á tó bí Olúwa wa nígbàtí a gbé àwọn ẹ̀yà mẹwa ní ìgbèkùn láti ọwọ́ ọba Assyrian.15 Lẹ́hìnnáà wọ́n lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè àríwá.16

Ní ọdún 600 kí a tó bí Olúwa wa ní ìbẹ̀rẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Baba Léhì darí ìletò àwọn ará Ísráẹ́lì lọ sí àwọn Amẹ́ríkà. Léhì ní òye fífọ́nká Ísráẹ́lì ti èyí tí òun jẹ́ ara kan. Néfì ṣe àyọsọ nípa rẹ̀ bí ó ti wípé ilé Ísráẹ́lì “ni a lè fi wé igi ólífì , èyí tí a já ẹ̀ka rẹ̀ kúrò tí a sì fọ́nká kiri gbogbo ojú ilẹ̀ ayé.”17

Nínú èyítí a pè ní Ayé Titun bẹ́ẹ̀, àkọọ́lẹ̀-ìtàn àwọn ará Néfì àti Lámánì bí a ti gbekalẹ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì parí ní déédé bí irínwó AD. Àwọn àtẹ̀lé Baba Léhì tàn káàkiri àwọn Amẹ́ríkà.18

Èyí ni a júwe kedere nípa Mọ́mọ́nì nínú 3 Néfì 5:20, tí ó kà pé: “Mọ́mọ́nì ni èmi íṣe, mo sì jẹ́ àtẹ̀lé Léhì lódodo. Mo ní ìdí láti bùkún Ọlọ́run mi àti Olùgbàlà mi Jésù Krístì, pé ó mú àwọn baba wa jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jerusalem.”19

Ní kedere àmì gíga ninú ṣísẹ̀ntẹ̀lé àkọọ́lẹ̀-ìtàn ni ìbí, ọ̀rọ̀, iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti iṣẹ́ ìhìnrere Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.21

Lẹ́hìn ìtúnṣe-àìlópin ikú àti Àjínde Olùgbàlà, ìkejì fífọ́nka tí a mọ dáadáa nípa Judah ṣẹlẹ̀ ní àádọ́rin AD àti àrúndínlógóje AD nígbàtí, nítorí ìnilára àti inúnibíni Roman, àwọn Júù tàn káàkiri ayé tí a mọ̀ nígbànáà.

Ààrẹ Nelson ti kọ́ni pé, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti wá gẹ́gẹ́bí àmì kan pé Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ láti kó àwọn ọmọ májẹ̀mú [náà] jọ.”22 Bayi, Ìwé ti Mọ́mọ́nì, tí a yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ padà láti ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith nípasẹ̀ ẹ̀bùn agbára Ọlọ́run, ni a darí sí àwọn àtẹ̀lé Léhì, olùfọ́nká Ísráẹ́lì, àti àwọn Gentile tí a gbàtọ́ sínú àwọn ẹ̀yà Ísráẹ́lì. Àkọlé sí 1 Néfì 22 kà ní apákan pé, “A ó fọ́n Ísráẹ́lì ká lórí gbogbo ilẹ̀ ayé—Àwọn Gentile yíò tọ́jú wọn yíò sì ṣìkẹ́ Ísráẹ́lì pẹ̀lú ìhìnrere ní àwọn ọjọ́ ikẹ̀hìn.” Ojú ewé àkọlé Ìwé ti Mọ́mọ́nì kà pé ọ̀kan lára àwọn èrèdí ìwé náà ni fún “pípàrọwa sí Júù àti Gentile pé Jésù ni Krístì.” Pẹ̀lú Ìmúpadàbọ̀sípò àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì, èrò ti kíkójọ Ísráẹ́lì ti gbòòrò gidigidi.23

Àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́gba ìhìnrere Jésù Krístì, láìka ìran sí, di ara ìkọ́jọ Ísráẹ́lì.24 Pẹ̀lú kíkójọ náà àti oríṣiríṣi àwọn tẹ́mpìlì tí a kọ́ tí a sì kéde, a wà ní ipò àiláfiwé láti kó Ísráẹ́lì jọ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú bí kò tiṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ètò Baba.

Ààrẹ Spencer W. Kimball, ní sísọ̀rọ gan nípa kíkójọ Ísráẹ́lì, wípé: “Nísisìyí, kíkójọ Ísráẹ́lì wà pẹ̀lú dídarapọ̀ mọ́ ìjọ òtítọ́ àti … wíwá sí ìmọ̀ Ọlọ́run òtítọ́. … Nítorínáà, ẹnikẹ́ni, tí ó bá tẹ́wọ́gba ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere, tí ó sì nwá láti jọ́sìn Olúwa nínù èdè tí ara rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní àwọn orílẹ̀ èdè níbití ó ngbé nísisìyí, ti wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin kíkójọ Ísráẹ́lì ó sì jẹ́ ajogún sí gbogbo àwọn ìbùkún tí a ṣe fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí.”25

“Nísisìyí Kíkójọ Ísráẹ́lì wà pẹ̀lú ìyípadà ọkàn.”26

Bí a ti wòó nínú àwo gbígbòòrò kedere, àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní ànfàní nlá ìfẹ́ni ti pípín, pípè, àti ṣíṣe ìrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ láti gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìbùkún májẹ̀mú ti Olúwa. Èyí pẹ̀lú àwọn Africans àti Europeans, Gúsù àti Àríwá Americans, Asians, Australians, àti àwọn tí wọ́n wà lórí erékùṣù ti òkun. “Nítorí lootọ ni ohùn Olúwa sí gbogbo ènìyàn.”27 “Kíkójọ yí yíò tẹ̀síwájú títí àwọn olódodo yíò fi kórajọ nínú ìjọ àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní àwọn orílẹ̀ èdè ayé.”28

Kò sí ẹnìkan tí ó ti sọ̀rọ̀ lórí kíkójọ Ààrẹ Nelson ti sọ: “Ìgbàkugbà tí ẹ bá ṣe ohunkóhun tí ó ran ẹnìkan lọ́wọ́—ní èyíkéyí ẹ̀gbẹ́ ti ìbòjú—ẹ gbé ìgbésẹ̀ kan sí ìhà dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run àti gbígba àwọn ìlànà ìrìbọmi àti ti tẹ́mpìlì tó ṣe kókó sí wọn, o nṣe ìrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ. Ó jẹ́ rírọrùn bí èyí.”29

Níbo ni ìjọ náà wà ní òní? Ní ọdún méjìlélọ́gọ́ta tí mo ti bẹ̀rẹ sísìn ní ibi iṣẹ́ ìhìnrere ní 1960, oye àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere tí wọ́n nsìn lábẹ́ ìpè kan láti ọ̀dọ̀ wòlíì ti pọ̀si láti 7,683 sí 62,544. Oye àwọn ibi iṣẹ́ ìhìnrere ti pọ̀si láti méjìdínlọ́gọ́ta sí irínwólémọ́kànlá. Oye àwọn ọmọ ìjọ ti pọ̀si láti mu súnmọ́ míllíọ̀nù 1,700,000 sí sísúnmọ́ míllíọ̀nù mmẹ́tàdínlógún.

Àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19 pa díẹ̀ lára ránpẹ́ ní àwọn ànfàní láti pín ìhìnrere. Bákannáà ó pèsè ìrírí lílo ẹ̀rọ̀ ìgbàlódé titun, èyí tí yíò mú kíkọ́jọ gbòòrò si gidigidi, A fi ìmoore hàn sí àwọn ọmọ ìjọ̀ àti ìránṣẹ́ ìhìnrere tí wọ̀n nmú ìtiraka ìkójọ ti olùfọ́nká Ísráẹ́lì nísisìyí. Ìdàgbàsókè ntẹ̀síswájú níbigbogbo, nípàtàkì Gúsù America àti Africa. Bákannáà a mọ rírì pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ káàkiri ayé ti fèsì sí ìpè alágbára Ààrẹ Nelson kí iṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere púpọ̀ si Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ìfaramọ́ wa láti ní ìfẹ́, pín, àti láti pè lè gbòòrò si gidigidi.

Apàkan pàtàkì nípa ìtiraka iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ọmọ̀ ìjọ láti di àwọn àpẹrẹ ìmọ́lẹ̀ dídán31 níbikíbí tí à ngbé.32 A kò lè ṣẹ̀tàn, Àpẹrẹ inúrere, òdodo, ìdùnnú, àti ifẹ́ àtinúwá fún gbogbo ènìyàn lè dá kìí ṣe ìtọ́nisọ́nà ìmọ́lẹ̀ dídán nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ìmọ̀ kan pé ibi ààbò wà nínù àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga ti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ní ìmọ̀ pé àwọn ìbùkún alámì wà ní pípín ìhìnrere Jésù Krístì. Àwọn ìwé mímọ́ sọ̀rọ̀ ayọ̀ àti àláfíà, ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀, ààbò kúrò nínú ìdánwò, àti agbára ìmúdúró láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.33 Ní wíwò kọjá ayé ikú yí, a ó múrasílẹ̀ láti pín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn wọnnì “nínú òkùnkùn àti lábẹ́ ìgbèkùn ti ẹ̀ṣẹ̀ nínú ayé ẹ̀mí ti ikú.”34

Kókó àdúrà mi ní òní ni fún gbogbo ọmọ, ọ̀dọ́mọkùnrin, ọ̀dọ́mọbìnrin, ẹbí, àti iyejú, Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, àti kílásì láti yẹ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ yíò ti tẹ́wọ́gba ìmọ̀ràn ìyára láti ṣèrànwọ́ láti kó Ísraẹ́lì jọ tí Olúwa àti olùfẹ́ wòlíì wa ti gbé jáde.

A bọ̀wọ̀ fún agbára láti yàn. Nínú ayé ọ̀làjú yí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò ní fèsì wọ́n kò sì ní kópa nínú kíkójọ Ísráẹ́lì. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò ṣé, Olúwa sì nretí àwọn ẹnití wọ́n ti gba ìhìnrere Rẹ̀ láti fi kánkán làkàkà láti jẹ́ àpẹrẹ ìmọ́lẹ̀ dídán tí yíò ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Èyí nfi ààyè gba àwọn arákùnrin àti arábìnrin káàkiri ilẹ̀ ayé láti gbádùn àwọn ìbùkùn tó tayọ àti àwọn ìlànà ti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì tí a kójọ sílé ní àláfíà.

Mo jẹ́ ẹ̀rí mi tó dájú àti ẹ̀rí àpóstélì kan nípa àtọ̀runwá Jésù Krístì àti ètò Baba wa ní Ọ̀run fún wa ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Russell M. Nelson, “Ọ̀rọ̀ Ìkínni-káàbọ̀,” Liahona, May 2021, 7.

  2. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:37.

  3. Wo 2 Néfì 26:33.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:1. Nínú Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:4, Olúwa tẹ̀síwájú, “Ohùn ìkìlọ̀ sì wá fún gbogbo ènìyàn, láti ẹnu àwọn ọmọẹ̀hìn mi, tí mo ti yàn ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn.”

  5. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110:11.

  6. Ní 1851 àwọn ọmọ Ìjọ 52,165 ló wà lápapọ̀. Gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ Ìjọ àti “Ìkànìyàn ẹ̀sìn ti 1851” ní England àti Wales, ó ju àwọn ọmọ ìjọ ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ̀gbọ̀n ló wà ní àwọn ibi wọnnì (wo Robert L. Lively Jr., “Àwọn Ìrònú Ti-ìmọ-ara ní Sẹ́ntúrì-mọ́kàndínlógún Míṣọ̀n British,” nínú Àwọn Mọ́mọ́nì ní Kùtùkùtù Victorian Britain, ed. Richard L. Jensen àti Malcolm R. Thorp [1989], 19–20).

  7. Wo Àwọn Ènìyàn Mímọ́: Ìtàn Ìjọ Jésù Krístì ní àwọn Ọjọ́ Ìkẹhìn, vol. 1, Oṣùwọ̀n Òtítọ́h, 1815–1846 (2018), 494–95, 514–15, 573.

  8. Tonga—ìpín 45; Samoa—ìpín 31; American Samoa—ìpín 22.5; àti French Polynesia—ìpín 7.

  9. Wo Àwọn Ènìyàn Mímọ́, 573–74.

  10. Russell M. Nelson, “Ìrètí of Israelì” (worldwide youth devotional, June 3, 2018), HopeofIsrael.ChurchofJesusChrist.org.

  11. Ẹ̀kọ́ àìláfiwé àti alágbára ni ó wà nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti àbáṣepọ̀ nínú nkan ìgbàgbọ́ kẹwa, éyí tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú, “Àwa gbàgbọ́ nínú ìkójọpọ̀ tòótọ́ ti Ísráẹ́lì àti nínú ìmúpadàbọ̀ sípò ti àwọn Ẹ̀yà Mẹwa” (woJames E. Talmage, Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́, 12th ed. [1924], 314–44).

  12. Bí a ti kọ́sílẹ̀ nínú Genesis 32:28, apkọsílẹ̀ ti ìwé mímọ́ kà pé, “Orúkọ rẹ kò ní jẹ́ Jákọ́bù mọ́, ṣùgbọ́n Israel: nítorí bí ọmọba ìwọ ní agbára pẹ̀lú Ọlọ́run àti ènìyàn.”

  13. Wo Joseph Smith, in “Àkọọ́lẹ̀-ìtàn, 1838–1856, volume D-1,” 1572, josephsmithpapers.org; bákannáà wo Joseph Smith, “Discourse, 11 June 1843–A, as Reported by Wilford Woodruff,” [42–43], josephsmithpapers.org; Joseph Smith, “Discourse, 11 June 1843–A, as Reported by Willard Richards,” [241], josephsmithpapers.org.

  14. Wo Ìtumọ̀ Bíbélì, “Israel, Ìjọba ti”; James E. Talmage, Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́, 315. Nígbàtí Rehoboam àti àwọn olùsọ̀mgbé rẹ̀ tí a mọ̀ sí Ìjọba Judah tí ó wà ní apákan gúsù ti Israel òní.

  15. Wo 2 Àwọn Ọba 17:23.

  16. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 133:26; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110:11.

  17. 1 Néfì 10:12. Lẹ́hìnnáà Ammon wípé, “Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run mi, ẹnití ó ti í ṣe ìrántí àwọn ènìyàn yĩ, tí í ṣe ẹ̀ka kan ti ìdílé Ísráẹ́lì, tí ó sì ti yapa kúrò lára rẹ̀ ní ilẹ̀ àjèjì” (Álmà 26:36).

  18. Ààrẹ Spencer W. Kimball, speaking of Lamanite Israel, taught that Zion is all the Americas. Ó wípé, “Àwa wà ní Israel à sì nkó wa jọ” (Àwọn Ìkọ́ni Spencer W. Kimball, ed. Edward L. Kimball (1982), 439.

  19. Nígbàtí a páṣẹ fún Baba Léhì láti kó ẹbí rẹ̀ kí ó sì lọ sínú aginjù, ara ìdí náà kàn jẹ́ pé a ó pa Jerusalem run (see 1 Nefi 2). Ìparun Tẹ́mpìlì ti Solomon, ìjákulẹ̀ Jerusalem, àti kíkó lẹ́rú ẹ̀yà Judah ṣẹlẹ̀ ní bíi 586 kí a tó Bí Olúwa wa.

    “Israel ni a ṣẹ́gun ní 720 B.C.E., a sì le àwọn ẹ̀yà mẹ́wá lọ sí àtìpó. … [Ní] Jerusalem …Tẹ́mpìlì ti Solomon gba onírurú àtakò nípasẹ̀ àwọn agbára àjèjì ṣíwájú òpin, ní 586 B.C.E., tí a pa wán run tán nípasẹ̀ ọmọ ogun Nebuchadnezzar, ọba Babylony” (David B. Green, “The History of the Jewish Temple in Jerusalem,” HaaretzAug. 11, 2014, haaretz.com/jewish/.premium-history-of-the-temple-in-jerusalem-1.5256337). Bákannáà wo 2 Àwọn Ọba 25:8–9.

  20. Wo Tad R. Callister, Ètùtù Àìlópin (2000).

  21. Russell M. Nelson, “Àwọn Ọmọ Májẹ̀mú,” Ensign, May 1995, 33; bákannáà wo “Àwọn Májẹ̀mú,” Liahona, Nov. 2011, 88.

  22. Wo Russell M. Nelson, in R. Scott Lloyd, “Seminar for New Mission Presidents: ‘Swift Messengers’ to Scattered Israel,” Church News, July 13, 2013, thechurchnews.com. Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ pé kíkíjọ “kìí ṣe ọ̀ràn ibí àfojúrí; ó jẹ́ ọ̀ràn ìfarasìn ẹnìkọ̀ọ̀kan. Àwọn ènìyàn ni a lè mú ‘wá sí òyè Olúwa’ [3 Nefi 20:13] láìsí fífi ilẹ̀-ìbí wọn sílẹ̀” (“Kíkójọ Olùfọ́nká Ísráẹ́lì,” Liahona, Nov. 2006, 81). Bákannáà wo 3 Néfì 21:1–7.

  23. Ẹ̀kọ́ wa hàn kedere; Olúwa fọ́n àwọn ẹ̀yà Israel ká nítorí oríkunkun wọn àti àìṣòdodo. Bákannáà,Olúwa lo fífọ̀nká àwọn ènìyàn Rẹ̀ tí a yàn ní àárín àwọn orílẹ̀ èdè ayé láti bùkún àwọn orílẹ̀ èdè wọnnì. Wo Ìtọ́sọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́, “Israel—Ìfọ́nká Ísráẹ́lì,” scriptures.ChurchofJesusChrist.org.

  24. Spencer W. Kimball, Àwọn Ìkọ́ni Spencer W. Kimball, 439.

  25. Spencer W. Kimball, Àwọn Ìkọ́ni Spencer W. Kimball, 438. Bákannáà wo “Gbogbo Wa Jẹ́ Bákannáà Sí Ọlọ́run,” ed. E. Dale LeBaron (1990), àkópọ̀ àwọn ìtàn ìyípadà mẹ́tàlélógún nípa Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn Afríkà Dúdú. Arábìnrin Julia N. Mavimbla sọ pé kí òun tó darapọ̀ mọ́ Ìjọ tí òun sì wá sí ọ̀rọ̀ náà d Israel, pé òun yíò “ju ìwé sẹgbẹ yíò sì wípé, ‘Àwọn funfun ni ó wà fún. Kìí ṣe fún wa. A kò yàn wà.’ Ní òní mo mọ̀ pé mo wà pẹ̀lú ẹbí ọlọ́ba kan, bí mo bá gbé ìgbé ayé òdodo. Èmi jẹ́ ará Israel kan, àti pé nígbàtí mo nṣe àwọn ìlànà mi nínú tẹ́mpìlì, mo ní ìmọ̀lára pé gbogbo wa wà ní ilẹ̀ ayé bí ẹbí kan” (in “Gbogbo Wa Jẹ́ Bákannáà Sí Ọlọ́run,” 151).

  26. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 1:2.

  27. Spencer W. Kimball, Àwọn Ìkọ́ni ti Spencer W. Kimball, 438.

  28. Russell M. Nelson, ”Ìrètí ti Ísráẹ́lì,”

  29. Àpóstélì Páùlù wí fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ kékeré Timothy láti “jẹ́ … àpẹrẹ ti àwọn onígbàgbọ́” (1 Timothy 4:12).

  30. Wo 3 Néfì 18:24.

  31. Wo Mosiah 18:8–13; 3 Nefi 18:25; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 18:25; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀múi 18:10–16; 31:5; 62:3.

  32. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 138:57.