Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 7


Orí 7

Ámọ́nì ṣe àwárí ilẹ̀ àwọn Léhì-Nífáì, níbití Límháì ti jẹ́ ọba—Àwọn ará Límháì wà nínú oko-ẹrú àwọn ará Lámánì—Límháì sọ ìtàn ìgbésí ayé nwọn—Wòlĩ kan (Ábínádì) ti jẹ́ ẹ̀rí pé Krístì ni Ọlọ́run àti Bàbá ohun gbogbo—Àwọn tí nwọ́n nfúrúgbìn ẹ̀gbin yíò kórè ãjà, àwọn tí nwọ́n bá sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa ni a ó kó yọ. Ní ìwọ̀n ọdún 121 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ọba Mòsíà ti ní àlãfíà títí fún ìwọ̀n ọdún mẹ́ta, ó wũ kí ó mọ̀ nípa àwọn ènìyàn nã tí nwọ́n kọjá lọ láti gbé ilẹ̀ àwọn Léhì-Nífáì, tàbí ní ìlú nlá ti Léhì-Nífáì; nítorítí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò gburo nwọn láti ìgbàtí nwọ́n ti kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; nítorínã, nwọ́n dã lágara pẹ̀lú ìyọlẹ́nu nwọn.

2 Ó sì ṣe tí ọba Mòsíà gbà pé kí mẹ́rìndínlógún nínú àwọn ọkùnrin alágbára nwọn kọjá lọ sí ilẹ̀ Léhì-Nífáì, láti lọ ṣe ìwádĩ nípa àwọn arákùnrin nwọn.

3 Ó sì ṣe pé, ní ọjọ́ kejì, tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí gòkè lọ, nwọ́n sì mú ẹnìkan tí à npè ní Ámọ́nì lọ́wọ́, nítorítí ó jẹ́ alágbára àti ènìyàn títóbi, àti ọmọ Sarahẹ́múlà; ó sì tún jẹ́ aṣãjú nwọn.

4 Àti nísisìyí, nwọn kò mọ ọ̀nà tí nwọn ìbá gbà nínú aginjù kí nwọ́n lè lọ sí ilẹ̀ àwọn Léhì-Nífáì; nítorínã nwọn rìn kiri fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ nínú aginjù, àní fún ogójì ọjọ́ ni nwọ́n fi rìn kiri.

5 Nígbàtí nwọ́n sì ti rìn kiri fún ogójì ọjọ́, nwọ́n dé ibi òkè kan, tí ó wà ní apá àríwá sí ilẹ̀ ti Ṣílómù, níbẹ̀ ni nwọ́n sì pàgọ́ nwọn sí.

6 Ámọ́nì sì mú mẹ́ta nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, orúkọ nwọn sì ni Ámálẹ́kì, Hẹ́lẹ́mù, àti Hẹ́mù, nwọ́n sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ilẹ̀ ti Nífáì.

7 Sì kíyèsĩ, nwọ́n bá ọba àwọn ènìyàn nã tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Nífáì àti ní ilẹ̀ ti Ṣílómù pàdé; àwọn ìṣọ́ ọba sì yí nwọn ká, nwọ́n sì mú nwọn, nwọ́n sì dì nwọ́n, nwọ́n sì gbé nwọn sọ sínú túbú.

8 Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n ti wà nínú túbú fún ọjọ́ méjì, a sì tún mú nwọn wá síwájú ọba, a sì tú ìdè nwọn; nwọ́n sì dúró níwájú ọba, a sì gbà nwọ́n lãyè, tàbí kí a wípé pã láṣẹ, pé kí nwọ́n dáhùn àwọn ìbẽrè tí òun yíò bí nwọ́n.

9 Ó sì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, èmi ni Límháì, ọmọ Nóà, tí ó jẹ́ ọmọ Sẹ́nífù, tí ó jáde kúrò nínú ilẹ̀ ti Sarahẹ́múlà láti jogún ilẹ̀ yĩ, tí ó jẹ́ ilẹ̀ bàbá nwọn, tí a fi ṣe ọba gẹ́gẹ́bí ohùn àwọn ènìyàn nã.

10 Àti nísisìyí, èmi fẹ́ láti mọ́ ìdí èyítí ẹ̀yin ṣe ní ìgboyà tó bẹ̃gẹ̃ tí ẹ fi wá sí itòsí odi ìlú yĩ, nígbàtí èmi, tìkarã, mi wà pẹ̀lú àwọn ìṣọ́ mi ní ẹnu ọ̀nà òde?

11 Àti nísisìyí, fún ìdí èyí ni èmi ṣe jẹ́ kí a dá a yín sí, kí èmi kí o lè ṣe ìwádĩ lẹ́nu yín, bí bẹ̃ kọ́, èmi ìbá ti ní kí àwọn ìṣọ́ mi pa yín. A gbà yín lãyè pé kí ẹ sọ̀rọ̀.

12 Àti nísisìyí, nígbàtí Ámọ́nì ríi pé a gba òun lãyè láti sọ̀rọ̀, ó jáde síwájú, ó sì tẹríba níwájú ọba; ó sì tún dìde, ó wípé: Á! ọba, èmi dúpẹ́ níwájú Ọlọ́run ní ọjọ́ òní yíi pé mo ṣì wà lãyè, tí a sì gbà mí lãyè láti sọ̀rọ̀; èmi yíò sì gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà;

13 Nítorítí ó dá mi lójú pé tí ìwọ bá ti mọ̀ mí ìwọ kò ní gbà kí èmi kí ó wọ àwọn ìdè wọ̀nyí. Nítorípé èmi ni Ámọ́nì, èmi sì jẹ́ ọmọ Sarahẹ́múlà, èmi sì ti jáde wá láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà láti ṣe ìwádĩ nípa àwọn arákùnrin wa, ti Sẹ́nífù mú jáde wá kúrò nínú ilẹ̀ nã.

14 Àti nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí Límháì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ámọ́nì, inú rẹ̀ dùn lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì wípé: Nísisìyí, mo mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé, àwọn arákùnrin mi ti nwọn wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà sì wà lãyè. Àti nísisìyí èmi yíò ṣe àjọyọ̀; àti ní ọ̀la, èmi yíò mú kí àwọn ènìyàn mi nã ṣẹ àjọyọ̀ pẹ̀lú.

15 Nítorí kíyèsĩ, àwa wà ní oko-ẹrú àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì nmú wa sìn ní ọ̀nà tí ó burú jùlọ láti faradà. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, àwọn arákùnrin wa yíò gbà wá kúrò nínú oko ẹrú nã, tàbí kí a wípé, kúrò l’ọ́wọ́ àwọn ará Lámánì, àwa yíò sì di ẹrú nwọn; nítorítí ó sàn fún wa kí àwa kí ó jẹ́ ẹrú àwọn ará Nífáì ju pé kí àwa kí ó san owó-òde fún ọba àwọn ará Lámánì.

16 Àti nísisìyí, ọba Límháì pàṣẹ fún àwọn ìṣọ́ rẹ pé kí nwọ́n máṣe de Ámọ́nì tàbí àwọn arákùnrin rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n kí nwọ́n lọ sí òkè nã, tí ó wà ní ìhà àríwá Ṣílómù, kí nwọ́n sì mú àwọn arákùnrin nwọ́n wá sínú ìlú nã, pé nípa bẹ̃ nwọn yíò lè jẹun, kí nwọn sì mumi, kí nwọ́n sì simi ara nwọn kúrò nínú wàhálà ìrìnàjò nwọn; nítorítí nwọ́n jìyà ohun púpọ̀; nwọ́n ti jìyà fún ebi, òùngbẹ, àti ãrẹ̀.

17 Àti nísisìyí, ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, tí ọba Límháì ṣe ìkéde lãrín gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀, pé nípa èyí nwọn yíò péjọ pọ̀ sí inú tẹ́mpìlì, láti gbọ́ ọ̀rọ̀ èyítí yíò bá nwọn sọ.

18 Ó sì ṣe, nígbàtí nwọ́n ti péjọ, ó sì bá nwọn sọ̀rọ̀ báyĩ, wípé: Á! ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé órí nyín sókè, kí a sì tù nyín nínú; nítorí kíyèsĩ, àkokò nã ti dé tán, tàbí kí a wípé kò jìnà, tí àwa kò ní foríbalẹ̀ fún àwọn ọ̀tá wa mọ́, l’áìṣírò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyàjú wa ni ó ti já sí asán; síbẹ̀síbẹ̀, èmi gbàgbọ́ wípé ìyànjú tí ó kù fún wa láti ṣe yíò jẹ́ aláìtàsé.

19 Nítorínã, ẹ gbé orí nyín sókè, kí ẹ sì yọ̀, kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, nínú Ọlọ́run nnì tí íṣe Ọlọ́run Ábráhámù, àti Ísãkì, àti Jákọ́bù; àti pẹ̀lú, Ọlọ́run nnì tí ó mú àwọn ọmọ Ísráẹ́lì jáde kúrò nínú ilẹ̀ Égíptì, tí ó sì mú nwọn la Òkun Pupa kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí ó sì bọ́ nwọn pẹ̀lú mánà kí nwọ́n má bã parun nínú aginjù; òun sì tún ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun fún nwọn síi.

20 Àti pẹ̀lú, Ọlọ́run kan nã ni ó ti mú àwọn bàbá wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, tí ó sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ títí di àkokò yíi; ẹ sì kíyèsĩ; ó mú wa wá sínú oko-ẹrú yíi nítorí ìwà àìṣedẽdé àti ìwà ìríra wa.

21 Gbogbo nyín sì ni ẹlẹ́rĩ ní ọjọ́ òní, tí Sẹ́nífù, ẹnití a fi ṣe ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹnití ó ní ìtara tí ó tayọ láti jogún ilẹ̀ àwọn bàbá rẹ, nípasẹ̀ èyítí, a sì tàn an jẹ nípa ọgbọ́n àrékérekè ọba Lámánì, ẹni tí ó ṣe àdéhùn pẹ̀lú ọba Sẹ́nífù, tí ó sì ti yọ̃da apákan ilẹ̀ nã, tàbí kí a wípé ìlú nlá tí Léhì-Nífáì, àti ìlú nlá ti Ṣílómù; àti gbogbo ìlú tí ó wà ní agbègbè wọn—

22 Gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí ni ó sì ṣe, fún ìdí kanṣoṣo láti mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ìrẹ̀sílẹ̀ tàbí sínú oko-ẹrú. Ẹ sì kíyèsĩ, àwa, ní àkokò yí, nsan owó-òde fún ọba àwọn ará Lámánì, èyí tí ó tó ìwọ̀n ìdásíméjì ọkà wa, àti bàbà wa, àti gbogbo wóró irúgbìn wa ní onírurú, àti ìdásíméjì gbogbo ọ̀wọ́ ẹran àti agbo-ẹran wa; àti pẹ̀lú ìdásíméjì gbogbo ohun tí a ní tàbí kí a wípé ohun ìní wa, ni ọba àwọn Lámánì lọ́gbà lọ́wọ́ wa, bí kò jẹ́ bẹ̃ òun ó gba ẹ̀mí wa.

23 Àti nísisìyí, njẹ́ èyí kò ha ṣòro láti faradà? Njẹ́ ìpọ́njú wa yĩ kò ha pọ̀ bí? Ẹ kíyèsĩ nísisìyí, èrèdí tí àwa fi nkẹ́dùn ọkàn ni èyí.

24 Bẹ̃ni, mo wí fún nyín, èrèdí tí àwa fi nkẹ́dùn ọkàn pọ̀ púpọ̀; nítorí melo nínú àwọn arákùnrin wa tí a ti pa, tí a ti ta ẹ̀jẹ̀ nwọn sílẹ̀ lórí asán, gbogbo ohun wọ̀nyí rí bẹ̃ nítorí ìwà àìṣedẽdé.

25 Nítorípé bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò bá tĩ ṣubú sínú ìwàìrékọjá, Olúwa kìbá ti yọ̃da kí ibi yĩ wá sórí nwọn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nwọn kò ní fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n ìjà bẹ́ sílẹ̀ lãrín nwọn, tóbẹ̃gẹ̃ tí nwọn ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ lãrín ara nwọn.

26 Nwọ́n sì ti pa wòlĩ Olúwa, bẹ̃ni, ẹni yíyàn Ọlọ́run, tí ó sọ fún wọn nípa ìwà búburú àti ẹ̀gbin nwọn, tí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí nbọ̀wá, bẹ̃ni, àní bíbọ̀ Krístì.

27 Àti nítorípé ó sọ fún nwọn pé Krístì ni Ọlọ́run nã, Bàbá ohun gbogbo, tí ó sì sọ wípé yíò farahàn ní àwòrán ènìyàn, yíò sì jẹ́ àwòrán ìrú èyítí a fi dá ènìyàn ní àtètèkọ́ṣe; tàbí kí a sọ́ ní ọ̀nà míràn, ó wípé a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run, àti pé Ọlọ́run yíò sọ̀kalẹ̀ sí ãrin àwọn ọmọ ènìyàn, yíò sì gbé ẹ̀ran ara àti ẹ̀jẹ̀ wọ̀, yíò sí lọ kiri ní ojú àgbáyé—

28 Àti nísisìyí, nítorítí ó sọ eleyĩ, nwọ́n pa á; ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun míràn ni nwọ́n sì ṣe, èyítí ó mú ìbínú Ọlọ́run wá sórí nwọn. Nítorínã, tani ó nyàlẹ́nu pé nwọ́n wà ní oko-ẹrú, àti pé a nfi ìpọ́njú púpọ̀ bẹ̀ wọ́n wò?

29 Nítorí ẹ kíyèsĩ, Olúwa ti wípé: Èmi kò ní ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn mi ní ọjọ́ ìwàìrékọjá nwọn; ṣùgbọ́n èmi yíò ṣe ìdènà nwọn kí nwọn kí ó má ṣe ṣe rere; kí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ nwọn yíò sì jẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ níwájú nwọn.

30 Àti pẹ̀lú, ò wípé: Bí àwọn ènìyàn mi bá fúrúgbìn ẹ̀gbin nwọn yíò kórè ìyàngbò rẹ̀ nínú ãjà; èrè rẹ̀ sì ni májèlé.

31 Àti pẹ̀lú, ò wípé: Bí àwọn ènìyàn mi bá fúrúgbìn ẹ̀gbin, nwọn yíò kórè ìjì láti apá ìlà oòrùn, tí ó mú ìparun wá lọ́gán.

32 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, ìlérí Olúwa ti di ìmúṣẹ, a sì kọlũ nyín, a sì pọ́n nyín lójú.

33 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá lè yí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú èrò ọkàn yín ní kíkún kí ẹ̀yin sì gbẹ́kẹ̀ nyín lé e, kí ẹ sì sìn ín pẹ̀lú ìtara ọkàn nyín, bí ẹ̀yin bá ṣe èyí, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú rẹ, yíò gbà yín kúrò nínú oko-ẹrú.