Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 1


Ìwé ti Mòsíà

Orí 1

Ọba Bẹ́njámínì kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní èdè àti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ ti bàbá nwọn—Àwọn ẹ̀sìn nwọn àti ọ̀làjú nwọn ti wà ní ìpamọ́ nítorí àwọn ìwé ìrántí tí a kọ sórí onírũrú àwọn àwo—A yan Mòsíà bí ọba a sì fún un ní ìṣọ́ lórí àwọn ìwé ìrántí nã àti àwọn nkan míràn. Ní ìwọ̀n ọdún 130 sí 124 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí kò sí ìjà mọ́ nínú gbogbo ilẹ̀ Sarahẹ́múla, ní ãrin gbogbo àwọn ènìyàn tí nwọ́n jẹ́ ti ọba Bẹ́njámínì, tó bẹ̃ tí ọba Bẹ́njámínì ní àlãfíà títí ní gbogbo ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀.

2 Ó sì ṣe tí ó ní ọmọ mẹ́ta; ó sì pe orúkọ nwọn ní Mòsíà, Hẹ́lórómù àti Hẹ́lámánì. Ó sì mú kí a kọ́ wọn ní gbogbo èdè àwọn bàbá rẹ̀, wípé nípasẹ̀ èyí nwọn yíò di onímọ̀ ènìyàn; àti pé kí nwọn lè mọ̀ nípa àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ tí a ti sọ láti ẹnu àwọn bàbá nwọn, tí a fi lé nwọn lọ́wọ́ nípa ọwọ́ Olúwa.

3 Òun sì tún kọ́ wọn nípa àwọn ìwé ìrántí èyítí a fín sí ara àwọn àwo idẹ, ó sì wí báyĩ: Ẹ̀yin ọmọ mi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin rántí pé bíkòbáṣe ti àwọn àwo wọ̀nyí, tí wọn ní àwọn ìwé ìrántí àti àwọn òfin wọ̀nyí nínú nwọn, àwa ìbá ti jìyà nínú àìmọ̀, bẹ̃ni títí di lọ́wọ́lọ́wọ́ yĩ, láìní ìmọ̀ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti Ọlọ́run.

4 Nítorítí kò bá ṣeéṣe fún bàbã wa, Léhì, kí ó rántí gbogbo ohun wọ̀nyí, láti fi nwọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, bíkòṣe nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ti àwọn àwo wọ̀nyí; nítorí tí a ti kọ́ ọ ní èdè àwọn ará Égíptì, nítorí-èyi òun lè ka àwọn òfin wọ̀nyí, kí ó sì fi nwọn kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, pé nípa báyĩ, nwọn yíò lè kọ́ àwọn ọmọ nwọn, nwọn yíò sì mú awọn òfin Ọlọ́run ṣẹ, tí ó fi di ìgbà lọ́wọ́lọ́wọ́ yĩ.

5 Mo wí fún nyín, ẹ̀yin ọmọ mi, bíkòbáṣe nítorí àwọn nkan wọ̀nyí, tí a ti fi pamọ́ tí a sì tọ́jú nípa ọwọ́ Ọlọ́run, kí àwa lè kà kí ó sì yé wa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ rẹ̀, kí a sì ní àwọn òfin rẹ̀ ní iwájú wa nígbà-gbogbo, pé àwọn bàbá wa pãpã ìbá ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, àwa ìbá sì ti ri bí àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì, tí wọn kò mọ́ ohunkóhun nípa àwọn nkan wọ̀nyí, tí wọn kò sì tún gbà wọ́n gbọ́ nígbàtí a fi nwọ́n kọ́ nwọn, nítorí àṣà ti àwọn bàbá nwọn, tí kò pé.

6 A! ẹ̀yin ọmọ mi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin rántí pé àwọn ọ̀rọ̀ nwọ̀nyí jẹ́ òtítọ́, àti pé àwọn ìwé ìrántí wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́. Ẹ kíyèsĩ, àwọn àwo ti Nífáì pẹ̀lú, tí ó ní àwọn ìwé ìrántí àti àwọn ọ̀rọ̀ àwọn bàbá wa láti ìgbà tí wọ́n ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù títí di ìsisìyí, nwọ́n sì jẹ́ òtítọ́; àwa sì lè mọ̀ nípa ìdánilójú nwọn nítorítí a ní nwọ́n níwájú wa.

7 Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọ mi, èmi fẹ́ kí ẹ rántí láti ṣe àyẹ̀wò nwọn lẹ́sọ̀lẹsọ̀, kí ẹ̀yin lè ṣe ànfãní nípa èyí; èmi sì fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè ṣe rere ní orí ilẹ̀ nã, gẹ́gẹ́bí àwọn ìlérí tí Olúwa ti ṣe fún àwọn bàbá wa.

8 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun míràn ni ọba Bẹ́njámínì sì kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, èyítí a kò kọ sínú ìwé yĩ.

9 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí ọba Bẹ́njámínì ti dẹ́kun kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì darúgbó, ó sì ríi pé òun fẹ́rẹ̀ lọ sí ibi tí gbogbo ará nlọ; nítorí-èyi, ó gbèrò pé ó tọ́ láti fi ìjọba fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀.

10 Nítorí-èyi, ó ní kí a mú Mòsíà wá sí iwájú òun; àwọn wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún un, wípé: Ọmọ mi, èmi fẹ́ kí o ṣe ìkéde jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ yĩ ní ãrin àwọn ènìyàn yĩ, tàbí àwọn ará Sarahẹ́múlà, àti àwọn ará Mòsíà ti nwọn ngbé inú ilẹ̀ nã, nípa èyítí nwọn ó péjọpọ̀; nítorípé ní ọ̀la, èmi yíò kéde fún àwọn ènìyàn mi wọ̀nyí láti ẹnu èmi tìkara mi pé ìwọ ni ọba àti olórí àwọn ènìyàn yí, ẹnítí Olúwa Ọlọ́run wa ti fún wa.

11 Àti pẹ̀lú, èmi yíò fún àwọn ènìyàn yí ní orúkọ kan, pé tí a ó fi yà nwọ́n sọ́tọ̀ lórí gbogbo ènìyàn tí Olúwa Ọlọ́run ti mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù; èmi sì ṣe èyí nítorípé wọ́n ti jẹ́ onítara ènìyàn nípa pípa awọn òfin Olúwa mọ́.

12 Èmi sì fún nwọn ní orúkọ kan tí a kò lè parẹ́ láéláé, bíkòṣe nípa ìrékọjá.

13 Bẹ̃ni, àti pãpã mo wí fún nyín, wípé tí àwọn ènìyàn Olúwa tí a ṣe ojúrere sí wọ̀nyí bá ṣubú sínú ìrékọjá, tí nwọ́n sì di ìkà àti alágbèrè ènìyàn, pé Olúwa yíò jọ̀wọ́ nwọn, nípa èyí tí wọn ó di aláìlágbára gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin wọn; òun kò sì ní pa nwọn mọ́, nípa agbára rẹ̀ nlá aláìlẹ́gbẹ́, bí ó ti ṣe pa àwọn bàbá wa mọ́ di ìsisìyí.

14 Nítorítí èmi wí fún ọ, pé tí kò bá ṣe pé ó na apá rẹ̀ fún ìpamọ́ àwọn bàbá wa, nwọ́n ìbá ti ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Lámánì, nwọ́n ìbá sì ti di ẹni ìpalára sí ìkórira wọn.

15 Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí ọba Bẹ́njámínì parí ọ̀rọ̀ rẹ ní sísọ fún ọmọ rẹ̀, ni ó sì fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ìjọba nã.

16 Àti pẹ̀lú, ó fún un ní àṣẹ lórí ìwé ìrántí èyítí a fín sórí àwọn àwo idẹ; àti sórí àwọn àwo ti Nífáì; àti bákannã idà Lábánì, àti lórí ìṣù tàbí afọ̀nàhàn, èyítí ó mú àwọn bàbà wa la aginjù já, èyítí a pèsè láti ọwọ́ Olúwa wípé nípa rẹ̀, a ó ṣe amọ̀nà nwọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí ó ṣe ṣe àkíyèsí àti ìtara èyítí a fún un.

17 Nítorí-èyi, bí nwọ́n ṣe ṣe àìṣõtọ́ nwọ́n kùnà láti ṣe rere àti láti lọ síwájú nínú ìrìnàjò nwọn, ṣùgbọ́n a lé nwọn padà, nwọ́n sì fa ìbínú Ọlọ́run sórí nwọn; nítorí-èyi a fi ìyàn àti ìpọ́njú gidigidi bá nwọn jà, kí ó lè rú nwọn sókè ní ìrántí iṣẹ́ nwọn.

18 Àti nísisìyí, ó sì ṣe tí Mòsíà kọjá lọ, tí ó sì ṣe gẹ́gẹ́bí bàbá rẹ̀ ti pàṣẹ fún un, tí ó sì kéde sí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, pé nípa bẹ̃ nwọn o kó ara nwọn jọ pọ̀, láti gòkè lọ sí tẹ́mpìlì láti gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ tí bàbá rẹ̀ níláti bá nwọn sọ.