Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 15


Orí 15

Bí Krístì ṣe jẹ́ Bàbá àti Ọmọ—Òun yíò ṣe alágbàwí, yíò sì gba ìrékọjá àwọn ènìyàn rẹ̀—Àwọn àti gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ jẹ́ irú-ọmọ rẹ̀—Ó mú Àjĩnde ṣẹ—Àwọn ọmọdé ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, Ábínádì wí fún nwọn pé: Èmi fẹ́ kí ó yé nyín pé Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yíò sọ̀kalẹ̀ wá sí ãrin àwọn ọmọ ènìyàn, yíò sì ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà.

2 Àti nítorípé ó wà nínú ẹran-ara, a o pè é ní Ọmọ Ọlọ́run, bí ó sì ti jọ̀wọ́ ẹran ara sí abẹ́ ìfẹ́ Bàbá, tí òun sì jẹ́ Bàbá àti Ọmọ—

3 Bàbá, nítorípé a lóyún rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run; àti Ọmọ, nípasẹ̀ ti ẹran-ara; báyĩ ni ó sì di Bàbá àti Ọmọ—

4 Nwọn sì jẹ́ Ọlọ́run kanṣoṣo, bẹ̃ni, àní Bàbá Ayérayé ti ọ̀run òhun ayé.

5 Báyĩ sì ni ẹran-ara di èyí tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sí abẹ́ Ẹ̀mí, tàbí Ọmọ sí abẹ́ Bàbá, tí nwọ́n jẹ́ Ọlọ́run kanṣoṣo, faradà ìdánwò, kò sì yọ̃da ara rẹ̀ fún ìdánwò nã, ṣùgbọ́n ó fi ara rẹ̀ sílẹ̀ pé kí a fi ṣe ẹlẹ́yà, kí a nã, kí a sọọ́ síta, kí àwọn ènìyàn rẹ̀ sì kọ̃.

6 Àti lẹ́hìn gbogbo èyí, lẹ́hìn tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu nlá-nlà lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, a o sì sìn jáde, bẹ̃ni, àní gẹ́gẹ́bí Isaiah ṣe sọ, bí àgùtàn tí ó yadi níwájú olùrẹ́rùn rẹ̀, bẹ̃ni kò ya ẹnu rẹ̀.

7 Bẹ̃ni, báyĩ nã ni a o sìn ín lọ, tí a ó kàn án mọ́ àgbélèbú, tí a ó sì pã, tí ẹran-ara yíò di jíjọ̀wọ́ àní títí dé ikú, ìfẹ́ Ọmọ yíò sì di gbígbémì nínú ìfẹ́ Bàbá.

8 Báyĩ sì ni Ọlọ́run já ìdè ikú, nítorítí ó ti gba ìṣẹ́gun lórí ikú; tí ó sì fún Ọmọ ní agbára láti ṣe alágbàwí fún àwọn ọmọ ènìyàn—

9 Tí ó sì gòkè re ọ̀run, tí ó sì ní ọ̀pọ̀ ãnú; ó sì kún fún ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ènìyàn; ó sì dúró lãrín nwọn àti àìṣègbè; tí ó sì ti já ìdè ikú, ó ti gbé àìṣedẽdé nwọn àti ìwàìrékọjá nwọn rù, ó sì ti rà nwọ́n padà, tí ó sì ti tẹ àwọn ìbẽrè àìsègbè lọ́rùn.

10 Àti nísisìyí mo wí fún nyín, tani yíò sọ nípa ìran rẹ̀? Kíyèsĩ mo wí fún nyín, pé nígbàtí a ti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ òun yíò rí irú-ọmọ rẹ̀. Àti nísisìyí kíni ẹ̀yin wí? Tani yíò sì jẹ́ irú-ọmọ rẹ̀?

11 Kíyèsĩ mo wí fún un yín, wípé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ, bẹ̃ni, gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ tí nwọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ nípa bíbọ̀ Olúwa–Mo wí fún nyín wípé gbogbo àwọn tí nwọ́n ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ nwọn, tí nwọ́n sì gbàgbọ́ pé Olúwa yíò ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, tí nwọ́n sì ti nretí ọjọ́ nã fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, mo wí fún nyín, pé àwọn wọ̀nyí ni irú-ọmọ rẹ̀, tàbí àwọn ni ajogún ìjọba Ọlọ́run.

12 Nítorípé àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó ti ru ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó kú fún, kí ó lè rà nwọ́n padà kúrò nínú ìwàìrékọjá nwọn. Àti nísisìyí, nwọn kò ha íṣe irú-ọmọ rẹ̀ bí?

13 Bẹ̃ni, njẹ́ àwọn wòlĩ kò ha kĩ ṣe irú-ọmọ rẹ̀ bí, gbogbo nwọn tí nwọ́n ti la ẹnu nwọn láti sọtẹ́lẹ̀, tí kò ṣubú sínú ìwàìrékọjá, àní gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ láti ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀? Mo wí fún nyín pé, irú-ọmọ rẹ̀ ni nwọ́n íṣe.

14 Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ti kéde àlãfíà, tí ó ti mú ìhìn-rere ohun rere wá, tí ó ti kéde ìgbàlà; tí ó sì wí fún Síónì pé: Ọlọ́run rẹ njọba!

15 A!, báwo ni ẹsẹ̀ nwọn ti dára tó lórí àwọn òkè nã!

16 Àti pẹ̀lú, báwo ni ẹsẹ̀ àwọn tí nwọ́n ṣì nkéde àlãfíà ti dára tó lórí àwọn òkè nã!

17 Àti pẹ̀lú, báwo ni ẹsẹ̀ àwọn tí nwọn yíò kéde àlãfíà ní ọjọ́ tí mbọ̀ ti dára tó lórí àwọn òkè, bẹ̃ni, láti ìgbà yí lọ àti títí láé!

18 Sì kíyèsĩ, mo wí fún nyín, èyí kĩ ṣe gbogbo rẹ̀. Nítorí A!, báwo ni ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìhìn-rere wá ti dára tó lórí àwọn òkè, ẹnití ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àlãfíà, bẹ̃ni, àní Olúwa, tí ó ti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà; bẹ̃ni, ẹnití ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìgbàlà;

19 Nítorípé tí kò bá ṣe ti ìràpadà èyítí ó ti ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀, èyítí a ti pèsè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, èmi wí fún un yín, tí kò bá ṣe ti èyí, gbogbo ènìyàn kì bá ti parun.

20 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìdè ikú yíò ja, Ọmọ sì jọba, ó sì ní agbára lórí òkú; nítorínã, ó mú àjĩnde òkú ṣẹ.

21 Àjĩnde kan sì mbọ̀ wá, àní àjĩnde èkíní; bẹ̃ni, àní àjĩnde àwọn tí nwọ́n ti wà, tí nwọ́n wà, tí nwọn yíò sì wà, àní títí dé àjĩnde Krístì—nítorípé bẹ̃ni a ó pẽ.

22 Àti nísisìyí, àjĩnde gbogbo àwọn wòlĩ, àti gbogbo àwọn tí ó gba ọ̀rọ̀ nwọn gbọ́, tàbí gbogbo àwọn tí ó pa awọn òfin Ọlọ́run mọ́, yíò jáde wá ní ìgbà àjĩnde èkíní; nítorínã, àwọn ni àjĩnde èkíní.

23 A gbé nwọn dìde kí nwọ́n lè bá Ọlọ́run gbé, ẹnití ó rà nwọ́n padà; nípa báyĩ nwọ́n ní ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Krístì, ẹnití ó ti já ìdè ikú.

24 Àwọn yĩ sì ni àwọn tí ó ní ìpín nínú àjĩnde èkíní; àwọn yĩ sì ni àwọn tí ó ti kú kí Krístì tó dé, nínú ipò àìmọ̀ nwọn, tí a kò kéde ìgbàlà sí nwọn. Báyĩ sì ni Olúwa mú ìmúpadà sípò àwọn wọ̀nyí ṣẹ; nwọ́n sì ní ìpín nínú àjĩnde èkíní, tàbí ìyè àìnípẹ̀kun, nítorípé Olúwa ti rà nwọ́n padà.

25 Àwọn ọmọdé pẹ̀lú sì ní ìyè àìnípẹ̀kun.

26 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ẹ bẹ̀rù ẹ sì wárìrì níwájú Ọlọ́run, nítorítí ó yẹ kí ẹ wárìrì; nítorípé Olúwa kò lè ra ẹnití ó ṣọ̀tẹ̀ sí padà, tí nwọ́n sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; bẹ̃ni, àní gbogbo àwọn tí nwọ́n ti parun nínú ẹ̀ṣẹ̀ ẹ nwọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé, tí nwọ́n ti mọ̃mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, tí nwọ́n ti mọ awọn òfin Ọlọ́run, tí nwọn kò ní pa nwọ́n mọ́; àwọn yí ni nwọn kò ní ìpín nínú àjĩnde èkíní.

27 Nítorínã, kò ha yẹ kí ẹ̀yin kí ó wárìrì bí? Nítorípé ìgbàlà kò sí fún irú àwọn yĩ; nítorípé Olúwa kò ra irú àwọn yĩ padà; bẹ̃ni, Olúwa kò sì lè ra irú àwọn èyí padà; nítorípé Òun kò lè tako ara rẹ̀; nítorípé kò lè tako àìṣègbè nígbàtí ó bá tọ́ ní ṣíṣe.

28 Àti nísisìyí, mo wí fún nyín, pé ìgbà nã yíò dé, tí ìgbàlà olúwa yíò di mímọ̀ fún gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn.

29 Bẹ̃ni, Olúwa, àwọn àlóre rẹ̀ yíò gbé ohun nwọn sókè; nwọn ó jùmọ̀ fi ohùn kọrin; nítorítí nwọn yíò ríi ní ojúkojú, nígbàtí Olúwa yíò mú Síónì padà bọ̀ wá.

30 Bú sí ayọ̀, ẹ jùmọ̀ kọrin, ẹ̀yin ibi ahoro Jerúsálẹ́mù; nítorítí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó ti ra Jerúsálẹ́mù padà.

31 Olúwa ti fi apá rẹ̀ mímọ́ hàn ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; gbogbo ikangun ayé ni yíò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.