Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 24


Orí 24

Ámúlónì ṣe inúnibíni sí Álmà àti àwọn ènìyàn rẹ̀—A ó pa nwọ́n tí nwọ́n bá gbàdúrà—Olúwa sọ ìnira nwọn di fífúyẹ́—Ó gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú, nwọ́n sì padà sí Sarahẹ́múlà. Ní ìwọ̀n ọdún 145 sí 120 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí Ámúlónì rí ojú rere gbà níwájú ọba àwọn ará Lámánì; nítorínã, ọba àwọn ará Lámánì gbà fún un pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ pé kí a yàn nwọ́n gẹ́gẹ́bí olùkọ́ni lórí àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni, àní lórí àwọn ènìyàn nã tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Ṣẹ́múlónì, àti ní ilẹ̀ Ṣílómù, àti ní ilẹ̀ Ámúlónì.

2 Nítorítí àwọn ará Lámánì ti gbà gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí; nítorínã, ọba àwọn Lámánì ti yan àwọn ọba lórí àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí.

3 Àti nísisìyí, orúkọ ọba àwọn ará Lámánì ni Lámánì, ẹnití a sọ lórúkọ bàbá rẹ̀; nítorínã ni a ṣe pè é ni ọba Lámánì. Ó sì jẹ ọba lórí ọ̀pọ̀ ènìyàn.

4 Ó sì yan àwọn olúkọni nínú àwọn arákùnrin Ámúlónì, nínú gbogbo ilẹ̀ ti àwọn ènìyàn rẹ̀ ti gbà; báyĩ sì ni èdè Nífáì ṣe di kíkọ́ lãrín àwọn ará Lámánì.

5 Nwọ́n sì jẹ́ ènìyàn tí nwọ́n ní ìfẹ́ ara nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọn kò mọ́ Ọlọ́run; bẹ̃ni àwọn arákùnrin Ámúlónì kò kọ́ nwọn ní ohunkóhun nípa Olúwa Ọlọ́run nwọn, tàbí òfin Mósè; tàbí kí nwọ́n kọ́ nwọn ni ọ̀rọ̀ Ábínádì;

6 Ṣùgbọ́n nwọn kọ́ nwọn kí nwọ́n ṣe ìkọsílẹ̀ ìwé ìrántí nwọn, kí nwọ́n sì kọ nwọn láti ọkàn dé òmíràn.

7 Báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀ sĩ pọ̀ sĩ ní ọrọ̀, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe òwò pẹ̀lú ara nwọn, nwọ́n sì pọ̀ síi ní agbára, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sĩ di alárẽkérekè ati ọlọ́gbọ́n ènìyàn, nwọ́n sì gbọ́n ọgbọ́n ayé, bẹ̃ni, nwọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n àrékérekè púpọ̀púpọ̀, tí nwọ́n sì ní inú dídùn sí onírurú ìwà búburú àti ìkógun, àfi tí ó bá jẹ́ lãrín àwọn arákùnrin nwọn.

8 Àti nísisìyí ó sì ṣe, tí Ámúlónì bẹ̀rẹ̀ sĩ pàṣẹ lé Álmà pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ lórí, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sĩ ṣe inúnibíni rẹ̀, tí ó sì mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ nwọn.

9 Nítorítí Ámúlónì mọ́ Álmà, pé òun jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àlùfã ọba, àti pé òun ni ẹnití ó gba ọ̀rọ̀ Ábínádì gbọ́, tí a sì lé e kúrò níwájú ọba, nítorínã, ó bínú síi; nítorítí ó wà lábẹ́ àkóso ọba Lámánì, síbẹ̀, ó ní àṣẹ lórí nwọn, ó sì mú nwọn ṣiṣẹ́, òun sì yan akóni-ṣiṣẹ́ lé nwọn lórí.

10 Ó sì ṣe tí ìpọ́njú nwọn pọ̀ tóbẹ̃ gẹ́ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀ sĩ kígbe pe Ọlọ́run gidigidi.

11 Ámúlónì sì pa á láṣẹ fún nwọn pé kí nwọ́n dẹ́kun igbe wọn; òun sì yan ìṣọ́ lé nwọn, pé ẹnìkẹ́ni tí a bá rí tí ó nképe Ọlọ́run yíò di pípa.

12 Álmà àtí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì gbé ohùn nwọn sókè sí Olúwa Ọlọ́run nwọn, ṣùgbọ́n nwọ́n gbé gbogbo ọkàn nwọn sókè síi; òun sì mọ gbogbo èrò ọkàn nwọn.

13 Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa tọ́ nwọ́n wá nínú ìpọ́njú nwọn, tí ó wípé: Ẹ gbé orí i yín sókè, kí ẹ sì tújúká, nítorítí èmi mọ́ májẹ̀mú tí ẹ̀yin ti dá pẹ̀lú mi; èmi yíò sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi, èmi yíò sì gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú.

14 Èmi yíò sì dẹ ìnilára tí a gbé lée yín ní éjìká, pé ẹ̀yin kò lè mọ̀ ọ́ lórí ẹ̀hìn nyín, bí ẹ̀yin tilẹ̀ wà nínú oko-ẹrú; èyí yíi ni èmi yíò ṣe kí ẹ̀yin kí ó lè dúró gẹ́gẹ́bí ẹlẹ̃rí fún mi ní ọjọ́ tí nbọ̀, àti kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ dájúdájú pé èmi, Olúwa Ọlọ́run nbẹ àwọn ènìyàn mi wò nínú ìpọ́njú nwọn.

15 Àti nísisìyí ó ṣì ṣe tí ìnira tí a gbé ru Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ di fífúyẹ́; bẹ̃ni, Olúwa fún nwọn ní okun kí nwọ́n lè gbé ẹrù nã pẹ̀lú ìrọ̀rùn, nwọ́n sì jọ̀wọ́ ara sílẹ̀ fún ìfẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀yàyà àti sũrù.

16 Ó sì ṣe tí ìgbàgbọ́ àti sũrù nwọn tóbi púpọ̀, tí ohùn Olúwa tún tọ̀ nwọ́n wá, tí ó wípé: Ẹ tújúká, nítorítí ní ọjọ́ ọ̀la, èmi yíò gbà yín kúrò nínú oko-ẹrú.

17 Ó sì wí fún Álmà pé: Ìwọ yíò ṣíwájú àwọn ènìyàn yí, èmi yíò sì bã yín lọ èmi yíò sì gba àwọn ènìyàn yí kúrò nínú oko-ẹrú.

18 Nísisìyí ó sì ṣe tí Álmà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àṣalẹ́ kó àwọn ọwọ́ ohun ọ̀sìn nwọn jọ, pẹ̀lú àwọn irú hóró èso nwọn; bẹ̃ni, àní ní gbogbo alẹ́ ni nwọn fi nkó àwọn ọ̀wọ́ ohun ọ̀sìn nwọn jọ.

19 Àti ní òwúrọ̀, Olúwa mú kí õrun ìwọra kun àwọn ara Lámánì, bẹ̃ni, gbogbo àwọn akóni-ṣiṣẹ́ nwọn sì sùn lọ fọnfọn.

20 Álmà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ sì kọjá lọ sínú aginjù; nígbàtí nwọ́n sì ti rin ìrìnàjò ní gbogbo ọjọ́ nã, nwọ́n pàgọ́ sínú àfonífojì kan, nwọ́n sì pe orúkọ àfonífojì nã ní Álmà, nítorítí ó ṣíwájú nwọn nínú aginjù.

21 Bẹ̃ni, nínú àfonífojì Álmà ní nwọ́n sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítórítí ó ti ṣãnú fún nwọn, ó sì ti mú ìnira nwọn rọrùn, tí ó sì ti gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú; nítorítí nwọ́n wà nínú oko-ẹrú, kò sì sí ẹnití ó lè gbà nwọ́n àfi Olúwa Ọlọ́run nwọn.

22 Nwọ́n sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, bẹ̃ni, gbogbo ọkùnrin nwọn, àti gbogbo obìnrin nwọn, àti gbogbo àwọn ọmọ nwọn tí ó lè sọ̀rọ̀ ni ó gbé ohùn nwọn sókè fún ìyìn Ọlọ́run nwọn.

23 Àti nísisìyí Olúwa wí fún Álmà pé: Ṣe kánkán, kí o sì jáde pẹ̀lú àwọn ènìyàn yí kúrò nínú ilẹ̀ yí, nítorítí àwọn ará Lámánì ti jí nwọ́n sì nlée yín; nítorínã jáde kúrò ní ilẹ̀ yí, èmi yíò sì dá àwọn ará Lámánì dúró nínú àfonífojì yí, kí nwọn kí ó má lè sá tẹ̀lé àwọn ènìyàn yí.

24 Ó sì ṣe tí nwọ́n jáde kúrò ní àfonífojì nã, tí nwọ́n sì tẹ̀síwájú nínú ìrìn-àjò nwọn sínú aginjù.

25 Lẹhìn tí nwọ́n sì ti wà nínú aginjù fún ọjọ́ méjìlá, nwọ́n dé inú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; ọba Mòsíà sì tún gbà nwọ́n tayọ̀tayọ̀.