Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 6


Orí 6

Ọba Bẹ́njámínì kọ àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ènìyàn o sì yan àwọn àlùfã láti kọ́ nwọn—Mòsíà ṣe ìjọba gẹ́gẹ́bí ọba olódodo. Ní ìwọ̀n ọdún 124 sí 121 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ọba Bẹ́njámínì sì rò wípé ó tọ́, lẹ́hìn tí ó ti bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀ tán, pé kí ó kọ àkọsílẹ̀ orúkọ gbogbo àwọn tí nwọ́n ti wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run láti pa awọn òfin rẹ̀ mọ́.

2 Ó sì ṣe tí kò sí ẹnìkan, àfi àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, tí kò tĩ wọ inú májẹ̀mú nã àti tí kò gba orúkọ Krístì sí ara nwọn.

3 Ó sì tún ṣe nígbàtí ọba Bẹ́njámínì ti parí gbogbo nkan wọ̀nyí, tí ó sì ti ya Mòsíà ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti jẹ́ olórí àti ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀, tí ó sì ti fún un ní gbogbo ọ̀rọ̀ ìyànjú nípa ti ìjọba nã, tí ó sì ti yan àwọn àlùfã lati kọ́ àwọn ènìyàn nã, pé nípa bẹ̃ nwọ́n lè gbọ́ kí nwọ́n sì mọ àwọn òfin Ọlọ́run, àti láti ta nwọ́n jí sí ìrántí ìbúra ti nwọn ti ṣe, ó tú àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã ká, nwọ́n sì padà, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí ìdílé nwọn, lọ sí ilé nwọn.

4 Mòsíà sì bẹ̀rẹ̀sí í jọba dípò bàbá rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀sí í jọba ní ọmọ ọgbọ̀n ọdún, tí ó sì mú gbogbo àkokò nã jẹ́ ìwọ̀n bĩ irínwó ọdún lé mẹ́rindínlọ́gọ̀rin láti àkokò tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù.

5 Ọba Bẹ́njámínì sì gbé ọdún mẹ́ta síi, ó sì kú.

6 Ó sì ṣe tí ọba Mòsíà rìn ní ọ̀nà Olúwa, ó sì ṣe àkíyèsí ìdájọ́ àti ìlànà rẹ̀, ó sì pa awọn òfin rẹ̀ mọ́ nínú ohun gbogbo tí ó pa láṣẹ fún un.

7 Ọba Mòsíà sì pàṣẹ pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ mã dá’ko, òun nã, fúnrarẹ̀, dá’ko, pé nípa bẹ̃ kò ní ni àwọn ènìyàn rẹ̀ lára, kí ó lè ṣe gẹ́gẹ́bí èyítí bàbá rẹ̀ ti ṣe nínú ohun gbogbo. Kò sì sí asọ̀ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún mẹ́ta.