Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 10


Orí 10

Ọba Lámánì kú—Àwọn ènìyàn rẹ ya jàndùkú àti ìpánle ènìyàn, nwọ́n sì gbàgbọ́ nínú ayédèrú àṣà—Sẹ́nífù àti àwọn ènìyàn rẹ̀ borí nwọn. Ní ìwọ̀n ọdún 187 sí 160 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí àwa tún bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìjọba nã, àwa sì bẹ̀rẹ̀sí ní ilẹ̀ nã ní ìní àlãfíà. Mo sì mú kí àwa ṣe àwọn ohun ìjà ogun ní onírurú, pé nípa bẹ̃ èmi yíò ní àwọn ohun ìjà fún àwọn ènìyàn mi di ìgbà tí àwọn ará Lámánì yíò tún tọ̀ wá wá láti bá àwọn ènìyàn mi jagun.

2 Mo sì fi àwọn olùṣọ́ yí gbogbo ilẹ̀ nã ká, kí àwọn ará Lámánì máa bà tún lè kọ lù wá láìfura, kí nwọ́n sì pa wá run; bẹ̃ sì ni èmi dãbò bò àwọn ènìyàn mi, àti àwọn agbo-ẹran mi, tí mo sì pa nwọ́n mọ́ kúrò nínú ìṣubú sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá wa.

3 Ó sì ṣe tí àwa jogún ilẹ̀ àwọn bàbá wa fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, bẹ̃ni, fún ìwọ̀n ogun ọdún àti méjì.

4 Mo sì mú kí àwọn ọkùnrin máa roko, kí nwọ́n sì gbin onírurú wóró, pẹ̀lú onírurú èso lóríṣiríṣi.

5 Mo sì mú kí àwọn obìnrin máa hun aṣọ kí nwọ́n sì ṣe lãlã, kí nwọ́n sì ṣiṣẹ́, kí nwọ́n sì hun aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó dára, bẹ̃ni ati oríṣiríṣi aṣọ, kí àwa lè fi aṣọ bò ìhõhò wa; báyĩ, àwa sí ṣe rere lórí ilẹ̀ nã—báyĩ àwa sì ní àlãfíà títí ní ilẹ̀ nã fún ìwọ̀n ogún ọdún àti méjì.

6 Ó sì ṣe tí ọba Lámánì kú, ọmọ rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí jọba dípò rẹ. Òun sì bẹ̀rẹ̀sí ní rú àwọn ènìyàn rẹ̀ sókè ní ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ènìyàn mi; nítorínã nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí gbáradì fún ogun, àti láti gòkè wá láti bá àwọn ènìyàn mi jagun.

7 Ṣùgbọ́n èmi ti rán àwọn alámí mi jáde kákiri gbogbo ilẹ̀ Ṣẹ́múlónì, kí èmi kí ó lè ṣe àwárí ìgbáradì nwọn, kí èmi kí ó lè ṣọ́ra de nwọn, kí nwọn kí ó má bã kọlũ àwọn ènìyàn mi, kí nwọ́n sì pa nwọ́n run.

8 Ó sì ṣe tí nwọ́n lọ sí apá àríwá ilẹ̀ Ṣílómù, pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun nwọn, àwọn ọkùnrin tí nwọ́n gbáradì pẹ̀lú ọrun àti pẹ̀lú ọfà, àti idà, ati pẹ̀lú símẹ́tà, àti òkúta, àti kànnà-kànnà; nwọ́n sì fá orí nwọn tí nwọn wà láìbò; nwọ́n sì sán àmùrè awọ yíká ìbàdí nwọn.

9 Ó sì ṣe, tí mo mú kí àwọn obìnrin àti ọmọdé nínú àwọn ènìyàn mi fi ara pamọ́ nínú aginjù; èmi sì mú kí gbogbo àwọn arúgbó tí nwọ́n lè lo ohun ìjà, àti gbogbo àwọn ọ̀dọ́ okùnrin mi tí nwọ́n lè lo ohun ìjà, péjọ láti lọ dojúkọ àwọn ará Lámánì ní ogun; èmi sì tò nwọ́n lọ́wọ̃wọ́, gbogbo nwọn gẹ́gẹ́bí ọjọ́ orí nwọn.

10 Ó sì ṣe, tí àwa lọ dojú ìjà kọ àwọn ará Lámánì; tí èmi, àní èmi, ní ọjọ́ ogbó mi, lọ fún ìdojú ìjà kọ àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe, tí àwa lọ jagun nínú agbára Olúwa.

11 Nísisìyí, àwọn ará Lámánì kò mọ́ ohunkóhun nípa Olúwa, tàbí nípa agbára Olúwa, nítorínã nwọ́n gbẹ́kẹ̀lé agbára nwọn. Síbẹ̀síbẹ̀, nwọ́n jẹ́ alágbára ènìyàn, nípa ti agbára ọmọ-ènìyàn.

12 Nwọ́n sì jẹ́ janduku àti ìpánle ènìyàn, tí òngbẹ ẹ̀jẹ̀ ngbẹ, tí nwọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú àṣà àwọn bàbá nwọn, èyí tí ó jẹ́ báyĩ—Níní ìgbàgbọ́ pé a lé nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù nítorí àìṣedẽdé àwọn bàbá nwọn, àti pé àwọn arákùnrin nwọn ṣẹ̀ nwọn nínú aginjù, nwọ́n sì tún ṣẹ̀ nwọn nígbàtí nwọ́n nla òkun kọjá;

13 Àti pẹ̀lú, pé a ṣẹ̀ nwọn nígbàtí nwọ́n wà ní ilẹ̀ ogún nwọn àkọ́kọ́, lẹ́hìn tí nwọ́n ti la òkun kọjá, gbogbo èyí nítorípé Nífáì jẹ́ olódodo nípa pípa òfin Olúwa mọ́—nítorínã ó rí ojúrere Olúwa, nítórítí Olúwa gbọ àdúrà rẹ̀, ó sì dáhùn nwọn, ó sì ṣe aṣãjú nwọn ní ìrìnàjò nwọn nínú aginjù.

14 Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì nṣe ìbínú rẹ̀ nítorípé ìṣe Olúwa kò yé nwọn; nwọ́n tún ṣe ìbínú rẹ̀ lórí omi nítorítí nwọ́n sé àyà nwọn le sí Olúwa.

15 Àti pẹ̀lú, nwọ́n ṣe ìbínú rẹ̀ nígbàtí nwọ́n ti dé ilẹ̀ ìlérí nã, nítorípé nwọ́n ní ó ti gba ìdarí àwọn ènìyàn nã kúrò lọ́wọ́ nwọn; nwọ́n sì lépa láti pípa á.

16 Àti pẹ̀lú, nwọ́n ṣe ìbínú rẹ̀ nítorípé ó kọjá lọ sínú aginjù gẹ́gẹ́bí Olúwa ti pã láṣẹ fún un, ó sì gbé àwọn àkọsílẹ̀ tí a fin sórí àwọn àwo idẹ, nítorítí nwọ́n ní ó jà nwọ́n lólè.

17 Àti báyĩ ni nwọ́n ti kọ́ àwọn ọmọ nwọn pé kí nwọ́n korira nwọn, àti pé kí nwọ́n pa nwọ́n, kí nwọ́n sì jà nwọ́n lólè àti kí nwọ́n kó nwọn, kí nwọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí nwọ́n lè ṣe láti pa nwọ́n run; nítorínã, nwọ́n ní ikorira ayérayé fún àwọn ọmọ Nífáì.

18 Nítorí ìdí èyí ni ọba Lámánì, nípa ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, àti ìpurọ́ rẹ̀, àti ìlérí mèremère, ṣe tàn mí, tí èmi sì mú àwọn ènìyàn mi wọ̀nyí jáde wá sínú ilẹ̀ yí, kí nwọn le pa nwọ́n run; bẹ̃ni, àwa sì ti jìyà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún wọ̀nyí ní ilẹ̀ nã.

19 Àti nísisìyí èmi, Sẹ́nífù, lẹ́hìn tí mo ti sọ gbogbo ohun wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn mi nípa àwọn ará Lámánì, mo ta nwọ́n jí láti lọ sí ójú ogun pẹ̀lú agbára nwọn ní fífi ìgbẹ́kẹ̀lé nwọn sí Olúwa; nítorínã, àwa bá nwọn jà, ní ojú kojú.

20 Ó sì ṣe, tí àwa tún lé nwọn jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa; a sì pa nwọ́n ní ìpakúpa, àní lọ́pọ̀lọpọ̀, tí a kò kà nwọ́n.

21 Ó sì ṣe, tí a tún padà sí ilẹ̀ tiwa, àwọn ènìyàn mi sì tún bẹ̀rẹ̀sí tọ́jú àwọn agbo-ẹran nwọn, àti láti ro ilẹ̀ nwọn.

22 Àti nísisìyí, èmi, nítorípé mo ti darúgbó, gbé ìjọba lé ọ̀kan nínú àwọn ọmọ mi lọ́wọ́, nítorínã, n kò sọ ohun kankan mọ́. Àti kí Olúwa kí ó bùkún àwọn ènìyàn mi. Àmín.