Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 2


Orí 2

Ọba Bẹ́njámínì bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀—Ó tún sọ nípa ti ìṣòtítọ́, àìṣègbè, àti ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú ohun tí ẹ̀mí—Ó gbà nwọ́n nímọ̀ràn wípé kí nwọ́n sin Ọba wọn ti Òkè-ọ̀run—Àwọn tí nwọ́n tàpá sí Ọlọ́run yíò ṣe àròkàn bĩ ti iná àjõkú ni ìwọ̀n ọdun 124 ki a to bi Oluwa wa.

1 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Mòsíà ti ṣe gẹ́gẹ́bí bàbá rẹ̀ ti paláṣẹ fún un, tí ó sì ti ṣe ìkéde jákè-jádò ilẹ̀ nã, tí àwọn ènìyàn nã sì kó ara nwọn jọ jákè-jádò ilẹ̀ nã, kí nwọn kí ó lè gòkè lọ sí tẹ́mpìlì láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí ọba Bẹ́njámínì yíò bá nwọn sọ.

2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì wà níbẹ̀ tóbẹ̃ tí nwọn kò kà nwọ́n; nítorítí nwọ́n ti bí sĩ púpọ̀púpọ̀, nwọ́n sì ti di alágbára ní ilẹ̀ nã.

3 Nwọ́n sì tún mú nínú àwọn àkọ́bí àwọn agbo ẹran nwọn, kí nwọn kí ó lè rú ẹbọ àti ọrẹ-ẹbọ sísun gẹ́gẹ́bí òfin Mósè;

4 Àti pẹ̀lú kí nwọ́n kí ó lè fi ọpẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run nwọn, ẹnití ó ti mú nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, àti ẹnití ó ti gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, tí ó sì ti yan àwọn ẹnití ó tọ́, láti jẹ́ olùkọ́ nwọn, àti ẹnití ó tọ́ láti jẹ́ ọba nwọn, ẹnití ó ti fi àlãfíà lélẹ̀ ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti ẹnití ó ti kọ́ nwọn láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí nwọ́n kí ó lè yọ̀, kí nwọ́n sì kún fún ìfẹ́ sí Ọlọ́run àti sí gbogbo ènìyàn.

5 Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n gòkè wá sí inú tẹ́mpìlì, nwọ́n pa àgọ́ nwọn yíká kiri, ọkùnrin kọ̃kan gẹ́gẹ́bí ìdílé rẹ̀, èyítí ó jẹ́ ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọkùnrin nwọn, àti àwọn ọmọbìnrin nwọn, bẹ̀rẹ̀ láti èyítí ó dàgbà jùlọ, títí dé èyítí ó kéré jùlọ, ẹbí kọ̃kan sì wà lọ́tọ̀.

6 Nwọ́n sì pàgọ́ nwọn yí tẹ́mpìlì ká, olúkúlùkù sì ṣe ilẹ̀kùn rẹ̀ kí ó kọjú sí tẹ́mpìlì, pé nípa bẹ̃, nwọn ó wà nínú àgọ́ nwọn, nwọn ó sì máa gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ tí Bẹ́njámínì ọba yíò bá nwọn sọ;

7 Nítorítí àwọn ènìyàn nã pọ̀ púpọ̀ tóbẹ̃ tí ọba Bẹ́njámínì kò lè kọ́ nwọn ní ohun gbogbo nínú tẹ́mpìlì, nítorí-èyi, ó pàṣẹ fún kíkọ́ ilé ìṣọnà, pé nípa bẹ̃ èyítí àwọn ènìyàn rẹ̀ yíò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí yíò bá nwọn sọ.

8 Ó sì ṣe tí ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ láti inú ilé ìṣọnà nã; gbogbo nwọn kò sì lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorípé àwọn ènìyàn nã pọ̀ púpọ̀; nítorí-èyi ó pàṣẹ pé kí a kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí òun sọ ránṣẹ́ sí ãrin àwọn tí nwọn kò sí ní agbègbè ìgbọ́ ohùn rẹ̀, kí àwọn nã lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

9 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ, tí ó sì pàṣẹ pé kí nwọ́n kọ, wípé: Ẹ̀yin arákùnrin mi, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti péjọpọ̀, ẹ̀yin tí ẹ lè gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ mi tí èmi yíò bá yín sọ ní òní; nítorítí èmi kò pàṣẹ pé kí ẹ gòkè wá láti ṣe àìkàsí ohun tí èmi yíò bã yín sọ, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó gbọ́ tèmi, kí ẹ ṣí etí yín, kí ẹ̀yin lè gbọ́, àti ọkàn yin kí ẹ̀yin lè ní òye, àti inú yín, kí ohùn ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lè di kedere ní iwájú yin.

10 Èmi kò pàṣẹ fún nyín pé kí ẹ jáde wá kí ẹ lè bẹ̀rù mi tàbí kí ẹ̀yin kí ó rò wípé èmi fúnra mi ju ẹlẹ́ran ara lọ.

11 Ṣùgbọ́n èmi dàbí yin, ẹ̀nití onírũrú àìlera nínú ara àti ẹ̀mí lè bẹ̀wò; síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn yĩ ti yàn mí, bàbá mi sì ti yà mí sọ́tọ̀, a sì gbà fún un nípa ọwọ́ Olúwa, wípé kí èmi kí ó jẹ́ olórí àti ọba lórí ènìyàn yĩ; a sì ti fi mí sí ìtọ́jú àti ìpamọ́ nípa agbára àìlẹ́gbẹ́ rẹ̀, láti sìn yín pẹ̀lú gbogbo agbára, iyè àti ipá ti Olúwa ti fún mi.

12 Mo wí fún yin wípé bí a ti gbà fún mi pé kí èmi kí ó lo ọjọ́ mi ní ṣíṣe iṣẹ́-ìsìn fún nyín, àní, títí di àkokò yĩ, tí èmi kò sì bèrè wúrà tàbí fàdákà tàbí irúkirú ọrọ̀ lọ́wọ́ yin;

13 Bẹ̃ni èmi kò gbà kí a sé yín mọ́ inú túbú, tàbí pé kí ẹ̀yin kí ó ṣe ara nyín bí ẹrú, tàbí kí ẹ̀yin kí ó pànìyàn, tàbí ṣe ìgárá, tàbí jalè, tàbí ṣe panṣágà; bẹ̃ni, èmi kò gbà kí ẹ hu ìwà ìkà, mo sì ti kọ yin pé kí ẹ pa awọn òfin Olúwa mọ́, nínú ohun gbogbo èyítí ó ti pàṣẹ fún un nyin—

14 Bẹ̃ sì ni èmi, tikarami, ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi, pé kí èmi lè ṣe iṣẹ́-ìsìn fún yín, àti pé kí a ma di ẹrú owó-orí lé yin, àti pé kí ohunkóhun kí ó máṣe dé bá yín èyítí ó bá ni nínú jẹ́—àti nínú gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí tí èmi ti sọ, ẹ̀yin fúnra yín jẹ́ ẹlẹ́rĩ lóni.

15 Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò ṣe gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí fún ìgbéraga, bẹ̃ni èmi kò sọ àwọn nkan wọ̀nyí sí ipa pé kí ẹ̀yin kí ó lè fi nyín sùn; ṣùgbọ́n èmi sọ nwọ́n fún nyín kí ẹ̀yin lè mọ̀ wípé mo lè dáhùn sí ẹ̀rí ọkàn ti o mọ́ yéké níwájú Ọlọ́run lóni.

16 Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yin pé nítorípé èmi sọ fún nyín wípé mo ti lo ọjọ́ mi ní iṣẹ́-ìsìn yín, èmi kò ní lọ́kàn láti gbéraga, nítorípé nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run ni èmi sã ti wà.

17 Ẹ sì kíyèsĩ, mo sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún nyín pé kí ẹ̀yin lè kọ́ ọgbọ́n; kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ wípé bí ẹ̀yin bá wà nínú iṣẹ́-ìsìn arákùnrin yín, inú iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run nyín ni ẹ̀yin ṣã wà.

18 Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti pè mí l’ọ́ba yín; njẹ́ bí èmi, tí ẹ̀ npè ní ọba yin, bá nṣiṣẹ́ lati sìn nyín, kò ha yẹ kí ẹ ṣiṣẹ́ láti sin ara yín?

19 Ẹ kíyèsĩ pẹ̀lú, tí èmi, tí ẹ̀ npè ní ọba yín, tí ó ti lo ọjọ́ rẹ̀ ní inú iṣẹ́-ìsìn yín, tí mo sì tún wà nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run, bá ní ẹ̀tọ́ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ láti ọwọ́ yín, A! báwo ni ẹ̀yin ìbá ṣe dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọba òkè-ọ̀run yín tó !

20 Mo wí fún yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé tí ẹ̀yin bá fi gbogbo ọpẹ́ àti ìyìn tí gbogbo ẹ̀mí nyìn ni, fún Ọlọ́run nã ẹnití ó dáa yín, tí ó sì ti pa yín mọ́, tí ó sì dá nyín sí, tí ó sì ti mú kí inú nyín dùn, tí ó sì ti gbà kí ẹ̀yin jọ gbé pọ̀ pẹ̀lú ara yín ní àlãfí—

21 Mo wí fún nyín pé bí ẹ̀yin bá sin ẹni tí ó dá nyín láti ìbẹ̀rẹ̀, tí ó sì npa yín mọ́ láti ọjọ́ dé ọjọ́, nípa fífún yín ní ẽmí, pé kí ẹ̀yin lè wà lãyè, kí ẹ sì rìn, kí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú yín, tí ó sì nràn yín lọ́wọ́ láti ìgbà kan dé òmíràn—mo wípé, bí ẹ̀yin bá lè sìn ín pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí yín, síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin yíò jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ aláìlérè.

22 Ẹ kíyèsĩ, gbogbo ohun tí ó bẽrè lọ́wọ́ yín ni pé kí ẹ pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́; òun sì ti ṣèlérí fún yín pé tí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, ẹ̀yin yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã; Òun kò sì nyípadà kúrò ní èyí tí ó ti sọ; nítorí-èyi, bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, òun yíò bùkún fún yín, yíò sì mú kí ẹ ṣe rere.

23 Àti nísisìyí, ní àkọ́kọ́, Òun ti dáa yín, ó sì ti fún yín ní ẹ̀mí nyín, èyítí ẹ̀yin jẹ ẹ́ ní gbèsè lé lórí.

24 Ní ọ̀nà kejì, ó fẹ́ kí ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́bí Òun ti pàṣẹ fún un yín; èyí tí ó jẹ́ wípé tí ẹ̀yin bá ṣe, Òun máa bùkún fún yín lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀; àti nítorí-èyi, Òun ti san án fún yín. Ẹ̀yin ṣì tún jẹẹ́ ní gbèsè, ẹ̀yin yíò sì jẹẹ́ títí laélaé; nítorí-èyi, kíni ẹ̀yin ní i ẹ nlérí?

25 Àti nísisìyí, èmi bẽrè, njẹ́ ẹ̀yin lè sọ ohun kankan fúnra yín? Èmi dáhùn, Rárá. Ẹ̀yin kò lè sọ pé ẹ̀yin pọ̀ to erùpẹ̀ ilẹ̀; bẹ̃ sì ni a dá nyín láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ti ẹnití ó da nyín nií ṣe.

26 Àti Èmi, èmi pẹ̀lú, tí ẹ pè ní ọba yín, èmi kò sàn ju ẹ̀yin tìkara yín lọ; nítorípé erùpẹ̀ ni èmi nã. Ẹ̀yin sì kíyèsĩ pé èmi ti darúgbó, mo sì ti fẹ́rẹ̀ bọ́ ara yĩ jù sílẹ̀ fún ilẹ.

27 Nítorí-èyi, gẹ́gẹ́bí mo ṣe wí fún un yín wípé èmi ti sìn yín, tí èmi nrìn pẹ̀lú ọkàn tí ó mọ́ níwájú Ọlọ́run, tó bẹ̃ tí èmi ní ìgbà yí láti jẹ́ kí ẹ̀yin péjọ, kí èmi kí ó lè wà láìlẹ́bi, kí ẹ̀jẹ̀ yín máṣe wá sórí mi, nígbàtí èmí yíò bá dúró láti gba ìdájọ́ Ọlọ́run lórí ti àwọn ohun èyítí ó tí pàṣẹ fún mi nípa yín.

28 Mo wí fún nyín pé èmi ti jẹ́ kí ẹ̀yin péjọ pọ̀ kí èmi kí ó lè fọ aṣọ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ yín; ní àkokò yĩ tí èmi ti fẹ́rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ìsà òkú mi, pé kí èmi lè lọ ní àlãfíà, kí ẹ̀mí àìkú mi lè lọ darapọ̀ mọ́ àwọn akọrin lókè ní kíkọ́ orin ìyìn sí Ọlọ́run tí ó tọ́.

29 Àti pẹ̀lú-pẹ̀lù, mo wí fún un yín wípé mo ti mú kí ẹ̀yin kó ara yín jọ pọ̀, kí èmi lè kéde fún nyín pé èmi kò lè jẹ́ olùkọ́ nyín, tàbí ọba nyín mọ́;

30 Nítorípé ní àkokò yíi pãpã, gbogbo ará mi wárìrì púpọ̀púpọ̀ nígbàtí èmi ngbìyànjú láti bá nyín sọ̀rọ̀; ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ndì mí mú, ó sì ti gbà fún mi láti bá yín sọ̀rọ̀, ó sì ti pã láṣẹ fún mi kí èmi kéde fún yín lonĩ, wípé Mòsíà ọmọ mi ni ọba àti alakoso lórí yín.

31 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin mãṣe bí ẹ̀yin ti íṣe látẹ̀hìnwá. Bí ẹ̀yin ṣe pa àwọn òfin mi mọ́, àti àwọn òfin bàbá mi nã, tí ẹ sì ṣe rere, tí a sì ti pa nyín mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nyín, bákannã bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin ọmọ mi mọ́, tàbí òfin Ọlọ́run èyítí a o fi fún yín nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã, àwọn ọ̀tá nyín kò sì ní lágbára lórí nyín.

32 Ṣùgbọ́n, A! ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ṣọ́ra bí bẹ̃kọ́, èdèàìyedè yíò dìde lãrín yín, ẹ̀yin yíò sì ṣe ìfẹ́ ẹ̀mí ibi nã, èyítí bàbá mi Mòsíà sọ nípa rẹ̀.

33 Ẹ kíyèsĩ, a ti fi ègún gún lórí ẹnìkẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ ẹ̀mí nã; nítorítí bí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀, tí ó wà bẹ̃ tí ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyĩyí ni ó mu ègbé sórí ẹ̀mí ara rẹ̀; nítorítí ó ti gba èrè ìyà títí ayé, nítorípé ó rékọjá sí òfin Ọlọ́run ní ìlòdì si ìmọ̀ èyítí ó ní.

34 Mo wí fún yín, pé kò sí ẹnìkẹ́ni lãrín yín, àfi àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín tí a kò tĩ kọ nípa àwọn nkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n tí nwọ́n mọ̀ pé ẹ̀yin jẹ gbésẹ̀ ayérayé sí Bàbá yín ti ọ̀run, láti fún un ní gbogbo ohun tí ẹ ní àti èyítí ẹ jẹ́; a sì ti kọ́ nwọn nípa ìwé ìrántí èyítí ó ní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nínú, èyítí àwọn wòlĩ mímọ́ ti sọ, bẹ̃ni, láti ìgbà tí bàbá wa, Léhì, jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù;

35 Àti pẹ̀lú-pẹ̀lù, gbogbo àwọn ohun tí àwọn bàbá wa ti sọ, títí di ìsisìyí. Ẹ kíyèsĩ, pẹ̀lú, nwọ́n sọ àwọn ohun tí Olúwa pa láṣẹ fún nwọn; nítorí-èyi wọ́n jẹ́ èyítí ó tọ́ àti òtítọ́.

36 Àti nísisìyí, mo wí fún yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti mọ̀, tí a sì ti kọ́ọ yín ní àwọn nkan wọ̀nyí, tí ẹ̀yin bá rékọjá, tí ẹ sì ṣe ìlòdì sí àwọn ohun tí a sọ, tí ẹ̀yin fa ara yín sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ Ẹ̀mí Olúwa, tí kò sì ní ãyè nínú yín láti tọ́ nyín sọ́nà ní ipa ọgbọ́n, pé tí ẹ lè jẹ́ alábùkún-fún, tí e ṣe rere, kí a sì pa nyín mọ́—

37 Mo wí fún yín, wípé ẹ̀ni nã tí ó bá ṣe èyí, ni ó jáde ní ìsọ̀tẹ́ ní gbangban sí Ọlọ́run; nítorínã, ó gbà láti gbọ́ran sí ẹ̀mí ibi nã lẹ́nu, ó sì di ọ̀tá sí òdodo gbogbo; nítorínã, Olúwa kò ní ãyè nínú rẹ̀, nítorítí kò lè gbé nínú tẹ́mpìlì àìmọ́.

38 Nítorínã, tí ẹní nã kò bá ronúpìwàdà, tí ó sì wà bẹ̃, tí ó sì kú gẹ́gẹ́bí ọ̀tá Ọlọ́run, ìbẽrè fún àìṣègbè ti Ọlọ́run yíò ta ẹ̀mí àìkú rẹ̀ jí sí ẹ́bi ara rẹ̀, tí yìó jẹ́ kí ó súnkì kúrò níwájú Olúwa, tí yíò sì kún àyà rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀bi, àti ìrora, àti àròkàn, èyítí ó dàbí iná tí a kò lè pa, èyítí ẹ̀là-iná rẹ̀ nrú sókè, títí láéláé.

39 Àti nísisìyí mo wí fún yín, pé ãnú kò sí fún ẹni nã; nítorínã, àkóyọrí ìpín rẹ ni pé kí ó fi ara da oró tí kò nípẹ̀kun.

40 A, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti gbó, àti ẹ̀yin ọ̀dọ́, àti ẹ̀yin ọmọ wẹ́wẹ́ tí ẹ lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yé, nítorítí èmi ti sọ̀rọ̀ ní kedere sí i yín kí ó lè yé nyín, èmi bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ lè tají sí ìràntí àwọn ipò búburú tí àwọn tí ó ti ṣubú sínú ìwàirékojá wa.

41 Àti pẹ̀lú-pẹ̀lù, mo fẹ́ kí ẹ ro ti ipò alábùkún-fún àti ayọ̀ àwọn tí ó pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Nítorítí kíyèsĩ, nwọ́n jẹ́ alábùkún-fún nínú ohun gbogbo, ní ti ara àti ti ẹ̀mí; tí nwọ́n bá sì forítĩ ní òtítọ́ dé òpin a ó gbà nwọ́n sí ọ̀run, pé nípa èyí nã nwọn ó gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ipò inúdídùn tí kò nípẹ̀kun. A! ẹ rántí, ẹ rántí pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́; nítorítí Olúwa Ọlọ́run ni ó ti sọọ́.