Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 11


Orí 11

Ọba Nóà jọba nínú ìwà búburú—Ó gbáyùn ùn nínú ayé ìfẹ́ kũfẹ́ pẹ̀lú àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀—Ábínádì sọtẹ́lẹ̀ pé a ó kó àwọn ènìyàn nã lẹ́rú—Ọba Nóà lépa ẹ̀mí rẹ. Ní ìwọ̀n Ọdún 160 sí 150 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Sẹ́nífù gbé ìjọba lé Nóà, tí íṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́; nítorínã Nóà bẹ̀rẹ̀ sí jọba dípò rẹ̀; òun kò sì rìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀.

2 Nítorí kíyèsĩ, kò pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, ṣùgbọ́n ó rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̃ ọkàn ara rẹ̀. Ó sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya àti àlè. Ó sì mú kí àwọn ènìyàn rẹ dẹ́ṣẹ̀, kí nwọ́n sì ṣe ohun ẹlẹ́gbin lójú Olúwa. Bẹ̃ni, nwọ́n sì hu ìwà àgbèrè àti onírurú ìwà búburú.

3 Ó sì yàn nwọ́n ní ìdá marun ohun ìní nwọn fún owó-òde, àti ìdá marun wúrà nwọn, àti ti fàdákà nwọn, àti ìdá marun sífì nwọn, àti ti bàbá nwọn, àti ti idẹ nwọn, àti ti irin nwọn; àti ìdá marun ẹran àbópa nwọn; àti pẹ̀lú ìdá marun gbogbo ọkà nwọn.

4 Gbogbo ohun wọ̀nyí ni ó sì fi bọ́ ara rẹ̀, àti àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀; àti àwọn àlùfã rẹ̀, àti àwọn aya nwọn àti àwọn àlè nwọn; báyĩ ó ti yí gbogbo ìṣe ìjọba nã padà.

5 Nítorítí ó rẹ gbogbo àwọn àlùfã ti bàbá rẹ̀ ti yàsọ́tọ̀ sílẹ̀, ó sì ya àwọn míràn sọ́tọ rọ́pò nwọn, irú àwọn èyítí ọkàn nwọn ru sókè fún ìgbéraga.

6 Bẹ̃ni, báyĩ sì ni a tì nwọ́n lẹ́hìn nínú ìwà ọ̀lẹ nwọn àti nínú ìwà ìbọ̀rìṣà nwọn, àti nínú ìwà àgbèrè nwọn, nípasẹ̀ owó-òde ti ọba Nóà ti yàn lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí; báyĩ ni àwọn ènìyàn nã ṣe lãlã púpọ̀púpọ̀ fún àtìlẹhìn àìṣedẽdé.

7 Bẹ̃ni, nwọ́n sì tún di abọ̀rìṣà, nítorípé a tàn nwọ́n jẹ nípa ọ̀rọ̀ asán àti ẹ̀tàn ọba àti àwọn àlùfã; nítorítí nwọn nsọ ohun ẹ̀tàn fún nwọn.

8 Ó sì ṣe tí ọba Nóà kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé tí ó lẹ́wà tí ó sì gbõrò; ó sì ṣe nwọ́n ní ọ̀ṣọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ ọnà igi èyítí ó dára àti pẹ̀lú oríṣiríṣi ohun oníyebíye, ti wúrà, ti fàdákà, ti irin, ti idẹ, ti sífì, àti ti bàbá.

9 Òun sì kọ fún ara rẹ̀, ãfin tí ó gbõrò, àti ìtẹ́-ọba lãrín rẹ, gbogbo èyítí a fi igi dáradára ṣe, tí a sì ṣe ọnà si pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun oníyebíye.

10 Ó sì tún mú kí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ṣe onírurú iṣẹ́ dáradára sí ara ògiri tẹ́mpìlì nã, pẹ̀lú igi oníyebíye, àti ti bàbá, àti ti idẹ.

11 Àti àwọn ijoko tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn olórí àlùfã, tí nwọ́n ga ju àwọn ijoko yókù lọ, ni ó ṣe ní ọ̀ṣọ́ pẹ̀lú wúrà dídán; ó sì mú kí a kó ibi ìgbáralé síwájú nwọn, pé kí nwọ́n lè máa gbé ara àti apá nwọn lée nígbàtí nwọ́n bá nsọ̀rọ̀ irọ́ àti ọ̀rọ̀ asán sí àwọn ènìyàn rẹ̀.

12 Ó sì ṣe, tí ó kọ́ ilé ìṣọna kan sí itòsí tẹ́mpìlì; bẹ̃ ni, tẹ́mpìlì gíga kan, èyí tí ó ga tó bẹ̃ tí òun lè dúró lórí rẹ̀ kí ó sì rí ilẹ̀ Ṣílómù, àti ilẹ̀ Ṣẹ́múlónì, èyítí àwọn ará Lámánì ti gbà ní ìní; òun sì tún lè rí gbogbo àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè nwọn.

13 Ó sì ṣe, tí ó mú kí a kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé nínú ilẹ̀ Ṣílómù; òun sì ṣeé kí nwọn kọ́ ilé ìṣọnà nlá kan sí orí òkè tí ó wà ní ìhà àríwá ilẹ̀ Ṣílómù, èyítí ó ti jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn ọmọ Nífáì ní àkokò tí nwọ́n sá kúrò ní ilẹ̀ nã; báyĩ sì ni ó ṣe lo àwọn ọrọ̀ tí ó kójọ nípa gbígba owó-òde lórí àwọn ènìyàn rẹ̀.

14 Ó sì ṣe tí ó gbé ọkàn rẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀, ó sì lo ìgbà rẹ̀ nínú ayé ifẹkufẹ pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀; bẹ̃ nã sì ni àwọn àlùfã rẹ ṣe lo ìgbà nwọn pẹ̀lú àwọn panṣágà obìnrin.

15 Ó sì ṣe tí ó sì gbin ọgbà àjàrà yíká ilẹ̀ nã; ó sì kọ́ àwọn ibi ìfúntí, ó sì ṣe ọtí wáìnì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀; ó sì di ọ̀mùtí, àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú.

16 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí gbógun ti àwọn ènìyàn rẹ̀, ní díẹ̀díẹ̀, nwọ́n sì npa nwọ́n nínú oko nwọn, àti nígbàtí nwọ́n bá nṣọ́ agbo-ẹran nwọn.

17 Ọba Nóà rán àwọn olùṣọ́ yí ilẹ̀ nã kãkiri láti lé nwọn sẹ́hìn; ṣùgbọ́n nwọn kò pọ̀ tó, àwọn ará Lámánì sì kọlũ nwọ́n, nwọ́n sì pa nwọ́n, nwọ́n sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbo-ẹran nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ nã; báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀ sí pa nwọ́n run, tí nwọ́n sì nfi ikorira nwọn hàn sí nwọn.

18 Ó sì ṣe tí ọba Nóà rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí nwọn, nwọ́n sì lé nwọn padà, tàbí kí a wípé nwọ́n lé nwọn padà fún ìgbà díẹ̀; nítorínã, nwọ́n padà, nwọ́n yọ̀ nínú ìkógun nwọn.

19 Àti nísisìyí, nítorí ìṣẹ́gun nlá yĩ, nwọ́n gbéraga nínú ìgbéraga ọkàn nwọn; nwọ́n lérí nínú agbára ara nwọn, tí nwọn nwí pé àwọn ãdọ́ta nwọ́n lè dojúkọ àwọn ẹgbẽgbẹ̀rún àwọn ará Lámánì; báyĩ ni nwọ́n sì ṣe lérí, tí nwọ́n sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ àwọn arákùnrin nwọn, èyí sì jẹ́ nítorí ìwà búburú ọba àti àwọn àlùfã nwọn.

20 Ó sì ṣe, tí ọkùnrin kan wà lãrín nwọn tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ábínádì; ó sì jáde lọ lãrín nwọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ tẹ́lẹ̀, ó wípé: Kíyèsĩ, báyĩ ni Olúwa wí, báyĩ ni ó sì p aláṣẹ fún mi, wípé, Jáde lọ, kí o sì wí fún àwọn ènìyàn yĩ, báyĩ ni Olúwa wí—Ègbé ni fún àwọn ènìyàn yìi, nítorítí mo ti rí ìríra àti ẹ̀gbin nwọn, àti ìwà búburú nwọn, àti ìwà àgbèrè nwọn; àti pé bí nwọn kò bá ronúpìwàdà, èmi yíò bẹ̀ nwọ́n wò nínú ìbínú mi.

21 Àti pé bí nwọn kò bá ronúpìwàdà kí nwọ́n sì padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, kíyèsĩ, èmi yíò fi nwọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá nwọn; bẹ̃ni, a ó sì mú nwọn bọ́ sí oko-ẹrú; a ó sì jẹ nwọ́n níyà nípa ọwọ́ àwọn ọ̀tá nwọn.

22 Yíò sì ṣe, tí nwọn yíò mọ̀ wípé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run nwọn, àti pé Ọlọ́run owú ni mí, tí ó nbẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi wò.

23 Yíò sì ṣe wípé bí àwọn ènìyàn yí kò bá ronúpìwàdà, kí nwọ́n yípadà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, a ó mu nwọn bọ́ sí oko-ẹrú; kò sì sí ẹni tí yíò gbà nwọ́n là, àfi Olúwa, tí íṣe Ọlọ́run Olódùmarè.

24 Bẹ̃ni, yíò sì ṣe, wípé nígbàtí nwọn bá kígbe pè mí, èmi yíò lọ́ra láti gbọ́ igbe nwọn; bẹ̃ni, èmi yíò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá nwọn kọlũ nwọ́n.

25 Bí nwọn kò bá sì ronúpìwàdà nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú, kí nwọ́n sì kígbe lóhùn rara sí Olúwa Ọlọ́run nwọn, èmi kò ní gbọ́ àdúrà nwọn, bẹ̃ni èmi kò ní gbà nwọ́n lọ́wọ́ ìpọ́njú nwọn; bẹ̃ sì ni Olúwa wí, bẹ̃ sì ni Òun ti pa láṣẹ fún mi.

26 Nísisìyí, ó sì ṣe pé nígbàtí Ábínádì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún nwọn tán, nwọ́n ṣe ìbínú rẹ, nwọ́n sì wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí rẹ; ṣùgbọ́n Olúwa gbã lọ́wọ́ nwọn.

27 Nísisìyí, nígbàtí ọba Nóà ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Ábínádì sọ fún àwọn ènìyàn nã, òun nã ṣe ìbínú; ó sì wípé: Tani Ábínádì, tí èmi àti àwọn ènìyàn mi yíò gba ìdájọ́ rẹ̀, tàbí tani Olúwa, tí yíò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú yí bá àwọn ènìyàn mi?

28 Mo pàṣẹ fún un yín kí ẹ mú Ábínádì wá sí ìhín, kí èmi lè pã, nítorítí ó ti sọ àwọn nkan wọ̀nyí kí ó lè rú àwọn ènìyàn mi sókè kí nwọ́n lè ṣe ìbínú sí ara nwọn, kí nwọ́n sì dá ìjà sílẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn mi; nítorínã èmi yíò pã.

29 Ní báyĩ ojú inú àwọn ènìyàn nã fọ; nítorínã nwọ́n sé àyà nwọn le sí ọ̀rọ̀ Ábínádì, nwọ́n sì nwá láti múu láti ìgbà nã lọ. Ọba Nóà sì sé àyà rẹ̀ le sí ọ̀rọ̀ Olúwa, òun kò sì ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ohun búburú tí ó nṣe.