Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 19


Orí 19

Gídéónì nwá ọ̀nà láti pa ọba Nóà—Àwọn ara Lámánì dótì ilẹ̀ nã—Ọba Nóà kú ikú iná—Límháì ṣe ìjọba sísan owó ìsìn. Ní ìwọ̀n ọdún 145 sí 121 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí àwọn ọmọ ogun ọba padà, lẹ́hìn tí nwọ́n wá àwọn ènìyàn Olúwa lórí asán.

2 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, àwọn ọmọ ogun ọba kéré, nítorítí nwọ́n ti dínkù, ìyapa sì bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín àwọn ènìyàn tí ó kù.

3 Àwọn ìpín tí ó kéré jù sì bẹ̀rẹ̀sí mí ìmí ìkìlọ̀ sí ọba, asọ̀ púpọ̀púpọ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín nwọn.

4 Àti nísisìyí, ọkùnrin kan wà lãrín nwọn tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Gídéónì, ó sì jẹ́ alágbára ènìyàn, àti ọ̀tá sí ọba, nítorínã, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì búra nínú ìbínú rẹ pé òun yíò pa ọba.

5 Ó sì ṣe tí ó bá ọba jà; nígbàtí ọba sì ríi pé ó fẹ́rẹ̀ borí òun, ó sálọ, ó sì sáré lọ sí orí ilé ìṣọ́ gíga èyítí ó wà ní itòsí tẹ́mpìlì.

6 Gídéónì sì sá tẹ̀le e, nígbàtí ó sì fẹ́rẹ̀ dé ibi ilé ìṣọ́ gíga nã láti pa ọba, ọba sì wò yíká kiri sí apá ilẹ̀ Ṣẹ́múlónì, sì kíyèsĩ àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì wà ní etí ilẹ̀ nã.

7 Àti nísisìyí, ọba kígbe sókè nínú àròkàn ọkàn rẹ̀, wípé: Gídéónì, dá mi sí, nítorítí àwọn ará Lámánì ti kọ lù wá nwọn ó sì pa wá run; bẹ̃ni, nwọn ó pa àwọn ènìyàn mi run.

8 Àti nísisìyí, ọba kò ro ti àwọn ènìyàn rẹ tó bí òun ṣe ro ti ẹ̀mí ara tirẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Gídéónì dá ẹ̀mí rẹ sí.

9 Ọba sí pàṣẹ fún àwọn ènìyàn nã pé kí nwọ́n sá fún àwọn ará Lámánì, òun fúnra rẹ̀ sì sá lọ níwájú nwọn, nwọ́n sì sá lọ sínú aginjù, pẹ̀lú àwọn obìnrin nwọn àti àwọn ọmọ nwọn.

10 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámání sá tẹ̀lé nwọn, tí nwọ́n sì bá nwọn, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n.

11 Nísisìyí, ó sì ṣe tí ọba pàṣẹ fún nwọn pé kí gbogbo àwọn ọkùnrin fi ìyàwó àti àwọn ọmọ nwọn sílẹ̀, kí nwọ́n sì sá fún àwọn ará Lámánì.

12 Nísisìyí, àwọn tí nwọn kò fẹ́ láti fi nwọ́n sílẹ̀ pọ̀ púpọ̀, tí ó tẹ́ nwọn lọ́rùn láti dúró kí nwọ́n sì parun pẹ̀lú nwọn. Àwọn yókù sì fi àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ nwọ́n sílẹ̀, nwọ́n sì sálọ.

13 Ó sì ṣe tí àwọn tí ó dúró pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ nwọn, mú kí àwọn ọmọbìnrin nwọn tí ó lẹ́wà jáde, kí nwọ́n sì ṣípẹ̀ fún àwọn ará Lámánì pé kí nwọ́n máṣe pa nwọ́n.

14 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì ṣãnú fún nwọn, nítorítí ẹwà àwọn obìnrin nwọn tù nwọ́n lójú.

15 Nítorínã, àwọn ará Lámánì dá ẹ̀mí nwọn sí, nwọ́n sì mú nwọn ní ìgbèkùn, nwọ́n sì gbé nwọn padà lọ sí ilẹ̀ Nífáì, nwọ́n sì gbà fún nwọn kí nwọ́n ní ilẹ̀ nã fún ìdí èyítí nwọn ó jọ̀wọ́ ọba Nóà lé àwọn ará Lámánì lọ́wọ́, tí nwọn yíò sì jọ̀wọ́ ohun ìní nwọn, àní ìdásíméjì ohun gbogbo tí nwọ́n ní, ìdásíméjì wúrà nwọn, àti fàdákà nwọn, àti ohun gbogbo olówó iyebíye tí nwọ́n ní, báyĩ sì ni nwọn yíò san owó-òde fún ọba àwọn ará Lámánì ní ọdọdún.

16 Àti nísisìyí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba wà lãrín àwọn tí a mú ní ìgbèkùn, tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Límháì.

17 Àti nísisìyí, Límháì ní ìfẹ́ kí bàbá òun máṣe ṣègbé; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Límháì kò ṣe àìmọ̀ nípa gbogbo àìṣedẽdé bàbá rẹ̀, nítorítí òun fúnra rẹ jẹ́ ènìyán tí ó tọ́.

18 Ó sì ṣe tí Gídéónì rán àwọn ènìyàn lọ sínú aginjù ní ìkọ̀kọ̀, láti lè wá ọba àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ lọ. Ó sì ṣe, tí nwọ́n bá àwọn ènìyàn nã ní inú aginjù, gbogbo nwọn àfi ọba àti àwọn àlùfã rẹ.

19 Nísisìyí, nwọ́n ti búra nínú ọkàn nwọn pé nwọn yíò padà sí ilẹ̀ Nífáì, àti pé bí a bá pa àwọn ìyàwó nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, àti àwọn tí ó dúró ti nwọ́n, pé àwọn yíò gbẹ̀san, kí nwọ́n sì parun pẹ̀lú nwọn.

20 Ọba sì pàṣẹ pé kí nwọ́n máṣe padà; nwọ́n sì bínú sí ọba, nwọ́n sì mú kí ó jìyà, àní títí dé ojú ikú nípasẹ̀ iná.

21 Nwọ́n sì gbìyànjú láti mú àwọn àlùfã pẹ̀lú kí nwọ́n sì pa nwọ́n, nwọ́n sì sá lọ mọ́ nwọn lọ́wọ́.

22 Ó sì ṣe, tí nwọ́n gbìyànjú láti padà lọ sí ilẹ̀ Nífáì, nwọ́n sì pàdé àwọn ará Gídéónì. Àwọn ará Gídéónì sì wí fún nwọn nípa gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìyàwó nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, àti pé àwọn ará Lámánì ti gbà fún nwọn kí nwọ́n ṣe ìní ilẹ̀ nã nípa sísan owó-òde fún àwọn ará Lámánì èyí tí iṣe ìdajì ohun ìní nwọn.

23 Àwọn ènìyàn nã sì sọ fún àwọn ará Gídéónì pé nwọ́n ti pa ọba, tí àwọn àlùfã rẹ̀ sì ti sálọ jìnà sínú aginjù.

24 Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí nwọ́n ti parí ètò nã, tí nwọ́n padà lọ sí ilẹ̀ Nífáì, tayọ̀-tayọ̀, nítorípé a kò pa àwọn ìyàwó àti ọmọ nwọn; nwọ́n sì sọ ohun tí nwọ́n ti ṣe fún ọba fún Gídéónì.

25 Ó sì ṣe tí ọba àwọn ará Lámánì dá májẹ̀mú pẹ̀lú nwọn wípé àwọn ènìyàn òun kò gbọ́dọ̀ pa nwọ́n.

26 Límháì pẹ̀lú, ẹnití íṣe ọmọ ọba, ẹnití a gbé ìjọba lé lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, bá ọba àwọn ará Lámánì dá májẹ̀mú wípé àwọn ènìyàn òun gbọ́dọ̀ san owó-òde fún un; àní ìdásíméjì gbogbo ohun ìní nwọn.

27 Ó sì ṣe tí Límháì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìjọba nã lélẹ̀, àti láti fi àlãfíà lélẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

28 Ọba àwọn ará Lámánì sì fi ìṣọ́ yí ilẹ̀ nã kãkiri, kí òun kí ó lè sé àwọn ará Límháì mọ́ inú ilẹ̀ nã, kí nwọn kí ó má lè kọjá sínú aginjù; òun sì nbọ́ àwọn ìṣọ́ rẹ pẹ̀lú owó-òde tí ó gbà láti ọwọ́ àwọn ará Nífáì.

29 Àti nísisìyí ọba Límháì sì ní àlãfíà pẹ́ títí nínú ìjọba rẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì, tí àwọn ará Lámánì kò yọ nwọn lẹ́nu, tí nwọn kò sì lépa láti pa nwọ́n run.