Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 1


Ìwé Kíní ti Nífáì

Ìjọba Àti Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Rẹ̀

Ìwé ìtàn nípa Léhì àti ìyàwó rẹ̀ Sáráíà, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́rin, tí à n pè ní (bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹnítí ó dàgbà jù) Lámánì, Lẹ́múẹ́lì, Sãmú, àti Nífáì. Olúwa kìlọ̀ fún Léhì láti kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, nítorí tí ó sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn nípa àìṣedẽdé wọn wọ́n sì n wá ọ̀nà láti run ìgbésí ayé rẹ̀. Ó rin ìrìn-àjò ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. Nífáì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ wọ́n sì padà sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù láti gba ìwé ìrántí àwọn Jũ. Ìwé ìtàn ìjìyà wọn. Wọ́n gbé àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ní aya. Wọ́n mú ìdílé wọn wọ́n sì lọ kúrò sínú ijù. Ìjìyà àti ìpọ́njú wọn nínú ijù. Ipa ọ̀nà àwọn ìrìn-àjò wọn. Wọ́n dé ibi omi nlá. Àwọn arákùnrin Nífáì ṣọ̀tẹ̀ sí i. Ó dãmú wọn, ó sì kọ́ ọkọ̀. Wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Ibi-Ọ̀pọ̀. Wọ́n ré omi nlá nã kọjá sínú ilẹ̀ ìlérí, àti bẹ̃bẹ̃ lọ. Èyí jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ti ìwé ìtàn ti Nífáì; tàbí ní ọ̀nà míràn, èmi, Nífáì, ni ó kọ ìwé ìrántí yĩ.

Ori 1

Nífáì bẹ̀rẹ̀ ìwé ìrántí àwọn ènìyàn rẹ̀—Léhì ríran rí ọwọ̀n iná kan ó sì kà láti inú ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ kan—Ó yin Ọlọ́run, ó sọ nípa bíbọ̀ Messia nã, ó sì sọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù—A ṣe inúnibíni sí i nípasẹ̀ àwọn Jũ. Ní ìwọ̀n ọdún 600 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Èmi, Nífáì, nítorí tí a bí mi nípa àwọn òbí dídára, nítorínã a kọ́ mi nínú gbogbo òye bàbá mi; àti nítorí pé mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú ní ìgbà àwọn ọjọ́ mi, bíótilẹ̀ríbẹ̃, nítorí tí mo ti rí ojúrere Olúwa lọ́pọ̀ ní gbogbo àwọn ọjọ́ mi; bẹ̃ni, nítorí pé mo ti ní ìmọ̀ nla nípa õre àti àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, nítorínã mo ṣe ìwé ìrántí àwọn ìṣe mi ní àwọn ọjọ́ mi.

2 Bẹ̃ni, mo ṣe ìwé ìrántí ní èdè bàbá mi, èyí tí ó ní òye àwọn Jũ àti èdè àwọn ará Égíptì.

3 Mo sì mọ̀ wí pé ìwé ìrántí èyí tí mo ṣe jẹ́ òtítọ́; mo sì ṣe é pẹ̀lú ọwọ́ ara mi; mo sì ṣe é gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ mi.

4 Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kíní ti ìjọba Sẹdẹkíàh, ọba Júdà, (bàbá mi, Léhì, tí ó ti gbé ní Jerúsálẹ́mù ní gbogbo àwọn ọjọ́ rẹ̀); àti ní ọdún kan nã yĩ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlĩ wá, wọ́n n sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn wí pé wọn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà, bíbẹ̃kọ́ ìlú nlá nì Jerúsálẹ́mù yíò di píparun.

5 Nítorí-èyi ó sì ṣe pé bàbá mi, Léhì, bí ó ṣe jáde lọ ó gbàdúrà sí Olúwa, bẹ̃ni, àní pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, fún ànfàní àwọn ènìyàn rẹ̀.

6 Ó sì ṣe bí ó ṣe n gbàdúrà sí Olúwa, ọwọ̀n iná kan wá ó sì wà lórí àpáta níwájú rẹ̀; ó sì rí, ó sì gbọ́ púpọ̀; nítorí àwọn ohun tí ó rí àti tí ó gbọ́ ó gbọ̀n ó sì wárìrì lọ́pọ̀lọpọ̀.

7 Ó sì ṣe pé ó padà sí ilé tirẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù; ó sì ju ara rẹ̀ sí orí ibùsùn rẹ̀, nítorí tí a borĩ rẹ̀ pẹ̀lú Ẹ̀mí àti àwọn ohun èyí tí ó ti rí.

8 Nítorí tí a borí rẹ̀ báyĩ pẹ̀lú Ẹ̀mí, a mú un lọ nínú ìran, àní tí ó fi rí àwọn ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, ó sì wòye pé òun rí Ọlọ́run tí ó jóko lórí ìtẹ́-ọba rẹ̀, tí àjọ àìníye àwọn angẹ́lì si yĩ ka ní ìwà kíkọrin àti yíyin Ọlọ́run wọn.

9 Ó sì ṣe pé ó rí Ẹnìkan tí ó n sọ̀kalẹ̀ láti ãrín ọ̀run, ó sì ri pé ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ pọ̀ ju ti õrùn ní agbedeméjì ọjọ́.

10 Ó sì tún rí àwọn méjìlá kan tí wọ́n n tẹ̀lé e, tí dídán wọn sì tayọ ti ìràwọ̀ ní òfúrufú.

11 Wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ wọ́n sì lọ kãkiri ní ojú-ilẹ̀ àgbáyé; ẹni ìṣãjú sì wá ó sì dúró níwájú bàbá mi, ó sì fún un ní ìwé kan, ó sì fi àṣẹ fún un pé kí ó kà á.

12 Ó sì ṣe pé bí ó ṣe n kà á, ó kún fún Ẹ̀mí Olúwa.

13 Ó sì kà á, wí pé: Ègbé, ègbé ni fún Jerúsálẹ́mù, nítorí mo ti rí àwọn ohun ìríra rẹ! Bẹ̃ni, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan sì ni bàbá mi kà nípa Jerúsálẹ́mù—pé a ó pãrun, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; ọ̀pọ̀ ni yíò ṣègbé nípasẹ̀ idà, ọ̀pọ̀ sì ni a ó kó ní ìgbèkùn lọ sí Bábílọ́nì.

14 Ó sì ṣe nígbà tí bàbá mi ti kà á tí ó sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nlá àti àwọn ohun ìyanu, ó kígbe àwọn ohun púpọ̀ sókè sí Olúwa; bíí: Títóbi àti ìyanu ni iṣẹ́ rẹ, A! Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè! Ìtẹ́-ọba rẹ ga ní òkè-ọ̀run, bẹ̃ni agbára rẹ, àti õre, àti ãnú nbẹ lórí gbogbo olùgbé ayé; àti, nítorí tí ìwọ jẹ́ aláanú, ìwọ kì yíò yọ̃da àwọn tí ó bá wá sọ́dọ̀ rẹ pé kí wọ́n ó ṣègbé!

15 Bí irú eleyĩ sì ni èdè bàbá mi ní yínyin Ọlọ́run rẹ̀; nítorí ọkàn rẹ̀ yọ̀, gbogbo ọkàn rẹ̀ sì kún, nítorí àwọn ohun èyí tí ó ti rí, bẹ̃ni, èyí tí Ọlọ́run ti fihàn án.

16 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kò sì ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwé ìtàn àwọn ohun èyí tí bàbá mi ti kọ, nítorí tí ó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun èyí tí ó rí nínú àwọn ìran àti àlá; ó sì ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun pẹ̀lú, èyí tí ó sọtẹ́lẹ̀ tí ó sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀, nípa èyí tí èmi kò ní ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwé ìtàn.

17 Ṣùgbọ́n èmi yíò ṣe ìwé ìtàn àwọn ìṣe mi ní àwọn ọjọ̃ mi. Kíyèsĩ, mo ṣe ìkékúrú ìwé ìrántí bàbá mi, sórí awọn àwo èyí tí mo ti ṣe pẹ̀lú ọwọ́ ara mi; nítorí-èyi, lẹ́hìn tí mo bá ti ké ìwé ìrántí bàbá mi kúrú nígbà nã ni èmi yíò ṣe ìwé ìtàn ti ìgbésí ayé tèmi.

18 Nítorínã, mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀, pé lẹ́hìn tí Olúwa ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìyanu han sí bàbá mi, Léhì, bẹ̃ni, nípa ìparun Jerúsálẹ́mù, kíyèsĩ ó jáde lọ sí ãrín àwọn ènìyàn nì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọtẹ́lẹ̀ ó sì n kéde sí wọn nípa àwọn ohun èyí tí ó ti rí àti tí ó ti gbọ́.

19 Ó sì ṣe tí àwọn Jũ fi ṣe ẹlẹ́yà nítorí àwọn ohun èyí tí ó jẹ́rĩ sí nípa wọn; nítorí tí ó jẹ́rĩ nítõtọ́ sí ìwà búburú wọn àti àwọn ohun ìríra wọn; ó sì jẹ́rĩ pé àwọn ohun èyí tí òun rí tí òun sì gbọ́, àti pẹ̀lú àwọn ohun èyí tí òun kà nínú ìwé nã, fi hàn kedere bíbọ̀ Messia kan, àti pẹ̀lú ìràpadà ayé.

20 Nígbà tí àwọn Jũ sì gbọ́ àwọn nkan wọ̀nyí wọ́n bínú sí i; bẹ̃ni, àní, bĩ sí àwọn wòlĩ ìgbà àtijọ́, tí wọ́n ti sọ sóde, tí wọ́n sì sọ ní òkúta, tí wọ́n sì pa; wọ́n sì tún wá ẹ̀mi rẹ̀, kí wọ́n lè mú un kúrò. Ṣùgbọ́n kíyèsí i, èmi, Nífáì, yíò fihàn sí yín pé ãnú Olúwa tí ó ní ìtùnú nbẹ lórí gbogbo àwọn ẹni tí ó ti yàn, nítorí ti ìgbàgbọ́ wọn, láti ṣe wọ́n ní alágbára àní sí agbára ìdásílẹ̀.