Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 7


Ori 7

Àwọn ọmọkùnrin Léhì padà sí Jerúsálẹ́mù wọ́n sì pe Íṣmáẹ́lì àti agbolé rẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ wọn ní ìrìn àjò wọn—Lámánì àti àwọn míràn ṣọ̀tẹ̀—Nífáì gba àwọn arákùnrin rẹ̀ níyànjú láti ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa—Wọ́n dì í pẹ̀lú okùn wọ́n sì pèrò ìparun rẹ̀—Ó di òmìnira nípa agbára ìgbàgbọ́—Àwọn arákùnrin rẹ̀ tọrọ ìdáríjì—Léhì àti ọ̀wọ́ rẹ̀ rú ẹbọ àti ẹbọ-ọrẹ sísun. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí èmi fẹ́ kí ẹ̀yin lè mọ̀ wí pé lẹ́hìn tí bàbá mi, Léhì, ti fi òpin sí àsọtẹ́lè nípa irú-ọmọ rẹ̀, ó ṣe tí Olúwa tún wí fún un, wí pé kò tọ́ fún un, Léhì, pé kí ó mú ìdílé rẹ̀ nìkan lọ sínú ijù; ṣùgbọ́n pé kí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ gbé àwọn ọmọbìnrin ní aya, kí wọn lè bímọ sí Olúwa ní ilẹ̀ ìlèrí.

2 Ó sì ṣe tí Olúwa pàṣẹ fún un pé kí èmi, Nífáì, àti àwọn arákùnrin mi, tún padà sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, kí a sì mú Íṣmáẹ́lì àti ìdílé rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ wá sí ijù.

3 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi, tún jáde lọ sínú ijù láti gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù.

4 Ó sì ṣe tí a gòkè lọ sí ile Íṣmáẹ́lì, a sì rí ojúrere gbà níwájú Íṣmáẹ́lì tóbẹ̃ tí a sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un.

5 Ó sì ṣe tí Olúwa mú ọkàn Íṣmáẹ́lì rọ̀, àti agbolé rẹ̀ pẹ̀lú, tóbẹ̃ tí wọ́n rin ìrìn-àjò wọn sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú wa sínú ijù sí àgọ́ bàbá wa.

6 Ó sì ṣe bí a ṣe n rìn nínú ijù, kíyèsĩ Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì, àti méjì nínú àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì, àti àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì méjì àti àwọn ìdílé wọn, ṣọ̀tẹ̀ sí wa; bẹ̃ni sí èmi, Nífáì, àti Sãmú, àti bàbá wọn, Íṣmáẹ́lì, àti aya rẹ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ míràn.

7 Ó sì ṣe nínú ọ̀tẹ́ èyí tí, wọ́n fẹ́ láti padà sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù.

8 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, nítorí tí mo kẹ́dùn nítorí líle ọkàn wọn, nítorínã mo wí fún wọn, wí pé, bẹ̃ni, àní sí Lámánì àti sí Lẹ́múẹ́lì: Kíyèsĩ i ẹ̀yin jẹ́ ẹ̀gbọ́n mi, báwo ni tí ẹ̀yin sì ṣe le báyĩ ní ọkàn yín, tí ẹ sì fọ́jú ní inú yín, tí ẹ̀yin fẹ́ kí èmi, àbúrò yín, sọ̀rọ̀ sí yín, bẹ̃ni, kí èmi sì gbé àpẹrẹ kalẹ̀ fún yín?

9 Báwo ni tí ẹ̀yin kò fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Olúwa?

10 Báwo ni tí ẹ̀yin ti gbàgbé pé ẹ̀yin ti rí ángẹ́lì Olúwa kan?

11 Bẹ̃ni, báwo sì ni tí ẹ̀yin ti gbàgbé àwọn ohun nlá tí Olúwa ti ṣe fún wa, ní gbígbà wá kúrò lọ́wọ́ Lábánì, àti pẹ̀lú tí àwa fi rí ìwé ìrántí nã gbà.

12 Bẹ̃ni, báwo sì ni tí ẹ̀yin ti gbàgbé pé Olúwa lè ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, fún àwọn ọmọ ènìyàn, bí ó bá ṣe pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Nítorí-èyi, ẹ jẹ́ kí á jẹ́ olóotọ́ sí i.

13 Bí ó bá sì ṣe pé àwa jẹ́ olóotọ́ sí i, àwa yíò rí ilẹ̀ ìlérí gbà; ẹ̀yin yíò sì mọ̀ ní ìgbà kan tí nbọ̀ pé ọ̀rọ̀ Olúwa yíò dí mímú ṣẹ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù; nítorí gbogbo ohun tí Olúwa ti sọ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù ni gbọdọ̀ di mímú ṣe.

14 Nítorí kíyèsĩ i, Ẹ̀mí Olúwa yíò dáwọ́ dúró láìpẹ́ láti máa bá wọn wọ̀jà; nítorí kíyèsĩ i, wọ́n ti ṣa àwọn wòlĩ tì, Jeremíàh ni wọ́n sì ti jù sí inú túbú. Wọ́n sì ti wá ọ̀nà láti mú ẹ̀mi bàbá mi kúrò, tóbẹ̃ tí wọ́n ti lé e jáde ní ilẹ̀ nã.

15 Nísisìyí kíyèsĩ i, mo sọ fún yín pé bí ẹ̀yin bá padà sí Jerúsálẹ́mù ẹ̀yin nã yíò ṣègbé pẹ̀lú wọn. Àti nísisìyí, bí ẹ̀yin bá ní yíyàn, ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ nã, kí ẹ sì rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, wí pé bí ẹ̀yin bá lọ ẹ̀yin yíò ṣègbé pẹ̀lú; nítorí báyĩ ni Ẹ̀mí Olúwa rọ̀ mí pé kí èmi kí ó sọ.

16 Ó sì ṣe nígbà tí èmi, Nífáì, ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí àwọn arákùnrin mi, wọ́n bínú sí mi. Ó sì ṣe tí wọ́n gbá mi mú, nítorí kíyèsĩ i, wọ́n bínú lọ́pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì dì mí pẹ̀lú okùn, nítorí wọ́n wá láti mú ẹ̀mí mi kúrò, kí wọ́n lè fi mí sílẹ̀ sínú ijù kí àwọn ẹhànnà ẹranko lè pa mí jẹ.

17 Ṣùgbọ́n ó ṣe tí mo gbàdúrà sí Olúwa, wípé: A! Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ mí tí nbẹ nínú rẹ, njẹ́ ìwọ yíò gbà mí lọ́wọ́ àwọn arákùnrin mi; bẹ̃ni, àní kí o fún mi ní agbára kí èmi lè já àwọn èdídì wọ̀nyí èyí tí a fi dì mí.

18 Ó sì ṣe nígbà tí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kíyèsĩ i, àwọn èdídì nã túsílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi, mo sì dúró níwájú àwọn arákùnrin mi, mo sì tún sọ̀rọ̀ sí wọn.

19 Ó sì ṣe tí wọ́n tún bínú sí mi, wọ́n sì wá ọ̀nà láti gbá mi mú; sùgbọ́n kíyèsĩ i, ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì, bẹ̃ni, àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú, àti ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì, ṣìpẹ̀ sí àwọn arákùnrin mi, tóbẹ̃ tí wọ́n mú ọkàn wọn rọ̀; wọ́n sì dẹ́kun lílépa láti mú ẹ̀mí mi kúrò.

20 Ó sì ṣe tí wọ́n kún fún ìbànújẹ́, nítorí ìwà búburú wọn, tóbẹ̃ tí wọ́n tẹríba níwájú mi, wọ́n sì ṣìpẹ̀ sí mi pé kí èmi kí ó dáríjì wọn fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí mi.

21 Ó sì ṣe tí mo dáríjì wọ́n ní ìfinúhàn, gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe, mo sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wọn fún ìdáríjì. Ó sì ṣe tí wọ́n ṣe bẹ̃. Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti gbàdúrà tán sí Olúwa a tún rin ìrìn-àjò wa síhà àgọ́ bàbá wa.

22 Ó sì ṣe tí a sọ̀kalẹ̀ sí àgọ́ bàbá mi. Lẹ́hìn tí èmi àti àwọn arákùnrin mi àti gbogbo ilé Íṣmáẹ́lì sì ti sọ̀kalẹ̀ sí àgọ́ baba mi, wọ́n ṣe ọpẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run wọn; wọ́n sì rú ẹbọ àti ẹbọ-ọrẹ sísun sí i.