Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 4


Ori 4

Nífáì pa Lábánì gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa ó sì gba àwọn àwo idẹ nã nípa lílo àrékérekè—Sórámù yàn láti darapọ̀ mọ́ ìdílé Léhì nínú ijù. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí mo wí fún àwọn arákùnrin mi, wí pé: Ẹ jẹ́ kí á tún gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, ẹ sì jẹ́ kí á ṣe òtítọ́ ní pípa àwọn òfin Olúwa mọ́; nítorí ẹ kíyèsĩ i ó lágbára ju gbogbo ayé, njẹ́ ẽṣe tí kò leè lágbára ju Lábánì àti ãdọ́ta rẹ̀, bẹ̃ni, tàbí ju ẹgbẽgbẹ̀rún rẹ̀ pãpã?

2 Nítorínã ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ; ẹ jẹ́ kí á ní ágbára tí ó dàbí ti Mósè; nítorí ó sọ̀rọ̀ nítõtọ́ sí omi Òkun Pupa wọ́n sì pínyà síhin àti sọ́hun, àwọn bàbá wa sì lã já, jáde ìgbèkun, lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò sì tẹ̀lé wọn wọ́n sì rì sínú omi Òkun Pupa.

3 Wàyí ẹ kíyèsĩ i ẹ̀yin mọ̀ wí pé èyí jẹ́ òtítọ́; ẹ̀yin sì mọ̀ pẹ̀lú wí pé angẹ́lì kan ti sọ̀rọ̀ sí yín; ẽ ha ti se tí ẹ̀yin yíò tún siyèméjì? Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ; Olúwa lè gbà wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn bàbá wa, kí ó sì pa Lábánì run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Égíptì.

4 Nísisìyí nígbàtí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n ṣì n bínú síbẹ̀, wọ́n sì múra si láti kùn; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọ́n tẹ̀lé mi gòkè títí a fi dé ẹ̀hìn odi Jerúsálẹ́mù.

5 Ó sì jẹ́ ní òru; mo sì mú kí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sẹ́hìn odi. Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti fi ara wọn pamọ́, èmi, Nífáì, pa-kọ́lọ́ sínú ìlú nlá nã mo sì lọ níhà ilé Lábánì.

6 Ẹ̀mi sì n tọ́ mi, n kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ àwọn ohun èyí tí èmi ìbá ṣe.

7 Bíótilẹ̀ríbẹ̃ mo tẹ̀ síwájú, bí mo sì ti súnmọ́ ilé Lábánì mo rí ọkùnrin kan, ó sì ti ṣubú sí ilẹ̀ níwájú mi, nítorí tí ó ti mu àmupara pẹ̀lú ọtí-wáínì.

8 Nígbà tí mo sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mo ri wí pé Lábánì ni.

9 Mo sì ṣàkíyèsí idà rẹ̀, mo sì fà á jáde kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; ẽkù rẹ̀ jẹ́ ti wúrà tí ó dá ṣáká, iṣẹ́ rẹ̀ sì dára lọ́pọ̀lọpọ̀, mo sì ri wí pé ojú idà rẹ̀ jẹ́ ti irin oníyebíye jùlọ.

10 Ó sì ṣe Ẹ̀mí rọ̀ mí láti pa Lábánì; ṣùgbọ́n mo sọ nínú ọkàn mi: N kò ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ nígbà-kũgbà rí. Mo sì súnrakì mo fẹ́ wí pé kí n máṣe pa á.

11 Ẹ̀mí sì tún sọ fún mi: Kíyèsĩ i Olúwa ti jọ̀wọ́ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Bẹ̃ni, mo sì tún mọ̀ wí pé ó ti wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí tèmi; bẹ̃ni, òun kò sì fetí sí àwọn òfin Olúwa; ó sì ti gba ohun ìní wa lọ pẹ̀lú.

12 Ó sì ṣe tí Ẹ̀mí tún sọ fún mi: Pa á, nítorí Olúwa ti jọ̀wọ́ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́;

13 Kíyèsĩ i Olúwa yíò pa ènìyàn búburú láti lè mú àwọn èrò rere rẹ̀ jáde wá. Ó sàn kí ènìyàn kan ṣègbé ju kí orílẹ̀-èdè kan rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ kí wọ́n sì ṣègbé.

14 Àti nísisìyí, nígbàtí èmi, Nífáì, ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, mo rántí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí o wí fún mi nínú ijù, wí pé: Níwọ̀n bí àwọn irú-ọmọ rẹ bá pa àwọn òfin mi mọ́, wọn yíò ṣe rere ní ilẹ̀ ìlérí nã.

15 Bẹ̃ni, mo sì rò ó pẹ̀lú wí pé wọn kò le è pa àwọn òfin Olúwa mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, bí kò ṣe pé wọ́n bá ní òfin nã.

16 Mo sì mọ̀ pẹ̀lú wí pé a fín òfin nã sórí àwọn àwo idẹ nã.

17 Ẹ̀wẹ̀, mo mọ̀ wí pé Olúwa ti jọ̀wọ́ Lábánì lé mi lọ́wọ́ fún ìdí èyí—kí èmi lè gba àwọn ìwé ìrántí nã gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin rẹ̀.

18 Nítorínã mo gba ohùn Ẹ̀mí gbọ́, mo sì mú Lábánì níbi irun orí, mo sì gé orí rẹ̀ kúrò pẹ̀lú idà òun tìkara rẹ̀.

19 Lẹ́hìn tí mo sì ti gé orí rẹ̀ kúrò pẹ̀lú idà tirẹ̀, mo mú awọn ẹ̀wù Lábánì mo sì wọ̀ wọ́n sí ara tèmi; bẹ̃ni, àní kan èyí tí ó kéré jùlọ; mo sì gbé ìhámọ́ra rẹ̀ wọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ mi.

20 Lẹ́hìn tí mo sì ti ṣe èyí, mo jáde lọ sí ibi àpótí ìṣura Lábánì. Bí mo sì ti n jáde lọ síhà ibi àpótí ìṣura Lábánì, kíyèsĩ i, mo rí ìránṣẹ́ Lábánì ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ ibi àpótí ìṣura nã lọ́wọ́. Mo sì pàṣẹ fún un ní ohùn Lábánì, pé kí ó lọ pẹ̀lú mi sínú ibi àpótí ìṣura.

21 Ó sì ṣèbí ọ̀gá òun, Lábánì, ni mí, nítorí ó rí awọn ẹ̀wù àti idà tí mo sán mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi pẹ̀lú.

22 Ó sì bá mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn àgbàgbà àwọn Jũ, ó mọ̀ wí pé ọ̀gá òun, Lábánì, ti jáde ní òru pẹ̀lú wọn.

23 Mo sì bá a sọ̀rọ̀ bí ẹni pé Lábánì ni.

24 Mo sì tún wí fún un wí pé èmi yíò gbé àwọn ìfín, èyí tí ó wà lórí àwọn àwo idẹ, lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, tí wọ́n wà lẹ́hìn odi.

25 Mo sì tun pàṣẹ fún un wí pé kí ó tẹ̀lé mi.

26 Òun nã, nítorí tí ó rò wí pé mo n sọ̀rọ̀ nípa àwọn arákùnrin ìjọ onígbàgbọ́, àti wí pé nítõtọ́ ni mo jẹ́ Lábánì nì, ẹni tí mo ti pa, nítorí-èyi ó tẹ̀lé mi.

27 Ó sì bá mi sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà nípa àwọn àgbàgbà àwọn Jũ, bí mo ṣe n jáde lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, tí wọ́n wà lẹ́hìn odi.

28 Ó sì ṣe nígbà tí Lámánì rí mi ó bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀, bẹ̃ nã gẹ́gẹ́ sì ni Lẹ́múẹ́lì àti Sãmú. Wọ́n sì sá kúrò níwájú mi; nítorí wọ́n ṣèbí Lábánì ni, àti wí pé ó ti pa mí ó sì ti wá láti mú ẹ̀mí wọn kúrò pẹ̀lú.

29 Ó sì ṣe tí mo ké sí wọn, wọ́n sì gbọ́ mi; nítorí-èyi wọ́n dẹ́kun sísá kúrò lọ́dọ̀ mi.

30 Ó sì ṣe nígbà tí ìránṣẹ́ Lábánì rí àwọn arákùnrin mi ó bẹ̀rẹ̀ sí n gbọ̀n, ó sì ti fẹ́ sá kúrò níwájú mi kí ó sì padà sí ìlú nlá Jerúsálẹ́mù.

31 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, nítorítí mo jẹ́ ènìyàn tí ó tóbi ní ìnà sókè ènìyàn, àti pẹ̀lú nítorítí mo ti gba agbára púpọ̀ lọ́wọ́ Olúwa, nítorínã mo gbá ìránṣẹ́ Lábánì mú, mo sì dì í mú, kí ó má bá sá.

32 Ó sì ṣe tí mo bá a sọ̀rọ̀, wí pé tí ó bá lè fetí sí ọ̀rọ̀ mi, bí Olúwa ti wà, tí èmi sì wà, àní bẹ̃ni bí òun bá fetí sí ọ̀rọ̀ wa, àwa yíò yọ̃da ẹ̀mí rẹ̀.

33 Mo sì wí fún un, àní pẹ̀lú ìbúra, wí pé kí ó máṣe bẹ̀rù; wí pé yíò di òmìnira bí àwa ṣe wà bí òun bá sọ̀kalẹ̀ sínú ijù pẹ̀lú wa.

34 Mo sì tún sọ fún un, wí pé: Dájúdájú Olúwa ti pá láṣẹ fún wa láti ṣe ohun yĩ; njẹ́ àwa kì yíò sì ha ṣe ãpọn ní pípa àwọn òfin Olúwa mọ́? Nítorínã, bí ìwọ bá lè sọ̀kalẹ̀ sínú ijù sọ́dọ̀ bàbá mi ìwọ yíò ní àyè pẹ̀lú wa.

35 Ó sì ṣe ti Sórámù sì ní ìgboyà nítorí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo sọ. Nísisìyí Sórámù ni orúkọ ìránṣẹ́ nã; ó sì ṣe ìlérí wí pé òun yíò sọ̀kalẹ̀ sínú ijù sí ọ̀dọ̀ bàbá wa. Bẹ̃ni, ó sì ṣe ìbúra fún wa wí pé òun yíò dúró-lẹ́hìn pẹ̀lú wa láti ìgbà nã lọ.

36 Nísisìyí àwa fẹ́ kí ó dúró-lẹ́hìn pẹ̀lú wa fún ìdí èyí, kí àwọn Jũ má bá mọ̀ nípa sísá kúrò wa sínú ijù, kí wọ́n má bá lépa wa kí wọ́n sì run wá.

37 Ó sì ṣe nígbà tí Sórámù ti ṣe ìbúra fún wa, ìbẹ̀rùbojo wa dẹ́kun nípa rẹ̀.

38 Ó sì ṣe tí a mú àwọn àwo idẹ nã àti ìránṣẹ́ Lábánì, a sì lọ kúrò sínu ijù, a sì rin ìrìn-àjò sí àgọ́ bàbá wa.