Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 6


Ori 6

Nífáì kọ nípa àwọn ohun Ọlọ́run—Èrò Nífáì ni láti yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà láti wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ábráhámù kí a sì gbà wọ́n là. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kò kọ ìtàn ìdílé àwọn bàbá mi ni apá ìwé ìrántí mi yĩ; bẹ̃ni èmi kì yíò kọ ọ́ nígbà-kũgbà lẹ́hìn èyí sórí àwọn àwo wọ̀nyí tí èmi n kọ; nítorí ó ti wà nínú ìwé ìrántí èyí tí bàbá mi ti pamọ́; nítorí-èyi, èmi kò kọ ọ́ sínú iṣẹ́ yĩ.

2 Nítorí ó tó mi láti sọ wí pé àwa jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù.

3 Kò sì jẹ́ ohunkóhun sí mi wí pé kí èmi ṣe àníyàn láti kọ ẹ̀kún ìwé ìtàn gbogbo àwọn nkan bàbá mi, nítorí wọn kò ṣe é kọ sórí àwọn àwo wọ̀nyí, nítorí mo fẹ́ ãyè kí èmi lè kọ nípa àwọn ohun Ọlọ́run.

4 Nítorí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrò mi ni kí èmi lè yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà láti wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ábráhámù, àti Ọlọ́run Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù, kí a sì gbà wọ́n là.

5 Nítorí-èyi, àwọn ohun èyí tí ó ṣe ìfẹ́ ti ayé èmi kò kọ, ṣùgbọ́n àwọn ohun èyí tí ó ṣé ìfẹ́ ti Ọlọ́run ati si awọn wọ̃nnì tí kĩ ṣe ti ayé.

6 Nítorí-èyi, èmi yíò pa àṣẹ fún irú-ọmọ mi, pé àwọn kò gbọ́dọ̀ fi ãyè gba àwọn ohun tí kò ní iye sí àwọn ọmọ ènìyàn lórí àwọn àwo wọ̀nyí.