Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 3


Ori 3

Àwọn ọmọkùnrin Léhì padà sí Jerúsálẹ́mù láti gba àwọn àwo idẹ—Lábánì kọ̀ láti fi àwọn àwo nã sílẹ̀—Nífáì gba àwọn arákùnrin rẹ̀ níyànjú ó sì mú wọn lọ́kàn le—Lábánì jí ohun ìní wọn ó sì gbìdánwò láti pa wọ́n—Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì lu Nífáì àti Sãmú, angẹ́lì kan sì bá wọn wí. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, padà láti sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú Olúwa, sí àgọ́ bàbá mi.

2 Ó sì ṣe tí ó wí fún mi, wí pé: Kíyèsĩ i mo ti lá àlá kan, nínú èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún mi pé ìwọ àti àwọn arákùnrin rẹ yíò padà sí Jerúsálẹ́mù.

3 Nítorí kíyèsĩ i, Lábánì ní ìwé ìrántí àwọn Jũ àti pẹ̀lú ìtàn ìdílé àwọn baba-nlá mi, a sì fín wọn sórí àwọn àwo idẹ.

4 Nítorí-èyi, Olúwa ti pàṣẹ fún mi pé kí ìwọ àti àwọn arákùnrin rẹ lọ sí ilé Lábánì, kí ẹ sì wá àwọn ìwé ìrántí nã, kí ẹ sì mú wọn wá sísàlẹ̀ níhin sínú ijù.

5 Àti nísisìyí, kíyèsĩ i àwọn arákùnrin rẹ n kùn, wọ́n n wí pé ohun tí ó le ni èyí tí mo bèrè lọ́wọ́ wọn; ṣùgbọ́n kíyèsĩ i èmi kò bèrè rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àṣẹ Olúwa.

6 Nítorínã lọ, ọmọ mi, ìwọ yíò sì rí ojú rere lọ́dọ̀ Olúwa, nítorí tí ìwọ kò kùn.

7 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, sọ fún bàbá mi: Èmi yíò lọ láti ṣe àwọn ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ, nítorí tí èmi mọ̀ wí pé Olúwa kì yíò pa àṣẹ fún àwọn ọmọ ènìyàn, bíkòṣe pé òun yíò pèsè ọ̀nà fún wọn pé kí wọ́n lè parí ohun nã èyí tí òun pa láṣẹ fún wọn.

8 Ó sì ṣe nígbà tí bàbá mi ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ó mọ̀ wí pé mo ti jẹ́ alábùkún-fún lọ́dọ̀ Olúwa.

9 Èmi, Nífáì, àti àwọn arákùnrin mi sì mú ìrìn-àjò wa ní ijù, pẹ̀lú àwọn àgọ́ wa, láti gòkè lọ sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù.

10 Ó sì ṣe nígbà tí a ti gòkè lọ sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, èmi àti àwọn arákùnrin mi fi ọ̀rọ̀ lọ ara wa.

11 A sì ṣẹ́ kèké—tani nínú wa ni kí ó lọ sí ilé Lábánì. Ó sì ṣe tí kèké mú Lámánì; Lámánì sì wọ inú ilé Lábánì lọ ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ bí ó ṣe jóko ní ilé rẹ̀.

12 Ó sì bẽrè lọ́wọ́ Lábánì àwọn ìwé-ìrántí èyí tí a gbẹ́ sórí àwọn àwo idẹ, èyí tí ó ní ìtàn ìdílé bàbá mi nínú.

13 Sì kíyèsĩ i, ó sì ṣe tí Lábánì bínú, ó sì tì í jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀; kì yíò sì jẹ́ kí ó gba àwọn ìwé-ìrántí nã. Nítoríti, ó sọ fún un: Kíyèsĩ i ìwọ jẹ́ ọlọ́ṣà, èmi yíò sì pa ọ́.

14 Ṣùgbọ́n Lámánì sá kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ àwọn ohun tí Lábánì ti ṣe, fún wa. A sì bẹ̀rẹ̀ sí kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, àwọn arákùnrin mi sì fẹ́ padà sí ọ̀dọ̀ bàbá mi nínú ijù.

15 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i mo sọ fún wọn pé: Bí Olúwa ti mbẹ, àti bí àwa ti mbẹ, àwa kì yíò sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá wa nínú ijù títí àwa ó fi ṣe ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún wa parí.

16 Nítorí-èyi, ẹ jẹ́ kí á ṣe òtítọ́ ní pípa àwọn òfin Olúwa mọ́; nítorínã ẹ jẹ́ kí á sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ ìní bàbá wa, nítorí ẹ kíyèsĩ i ó fi wúrà àti fàdákà sílẹ̀, àti oríṣiríṣi ọrọ̀. Gbogbo eleyĩ ni ó sì ṣe nítorí àwọn òfin Olúwa.

17 Nítorí ó mọ̀ pé Jerúsálẹ́mù yíò di píparun, nítorí ti ìwà búburú àwọn ènìyàn nã.

18 Nítorí kíyèsĩ i, wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ sílẹ̀. Nítorí-èyi bí bàbá mi bá gbé ní ilẹ̀ nã lẹ̀hìn tí a ti pàṣẹ fún un láti sá jáde kúrò ní ilẹ̀ nã, kíyèsĩ i, òun yíò ṣègbé pẹ̀lú. Nítorí-èyi, ó di dandan fún un láti sá jáde kúrò ní ilẹ́ nã.

19 Sì kíyèsĩ i, ó jẹ́ ọgbọ́n nínú Ọlọ́run pé kí àwa gba àwọn ìwé-ìrántí wọ̀nyí, kí á lè ṣe ìtọ́jú èdè àwọn bàbá wa fún àwọn ọmọ wa;

20 Àti pẹ̀lú kí àwa lè ṣe ìtọ́jú fún wọn, àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a ti sọ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́, èyí tí a ti fi fún wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí àti agbára Ọlọ́run, láti ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀, àní títí di àkókò lọ́wọ́lọ́wọ́ yĩ.

21 Ó sì ṣe pé irú èdè báyĩ ni mo fi yí àwọn arákùnrin mi lọ́kàn padà, kí wọ́n lè ṣe òtítọ́ ní pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.

22 Ó sì ṣe tí a sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ ìní wa, a sì ṣa wúrà wa jọ; àti fàdákà wa, àti àwọn nkan oníyebíye wa.

23 Lẹ́hìn tí a sì ti ṣa àwọn nkan wọ̀nyí jọ, a lọ sókè lẹ̃kejì sí ilé Lábánì.

24 Ó sì ṣe tí a wọlé tọ Lábánì lọ, a sì bẽrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ó fún wa ní àwọn ìwé-ìrántí nã èyí tí a fín sórí àwọn àwo ìdẹ, fún èyí tí àwa yíò fún un ní wúrà wa, àti fàdákà wa, àti gbogbo àwọn nkan oníyebíye wa.

25 Ó sì ṣe nígbà tí Lábánì rí ohun ìní wa, àti wí pé ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó ṣe ìfẹ́kúfẹ̃ sí i, tóbẹ̃ tí ó tì wá sóde, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti pa wá, kí ó lè gba ohun ìní wa.

26 Ó sì ṣe tí a sá fún àwọn ìránṣẹ́ Lábánì, tí ó fi jẹ́ wí pé a ní láti fi ohun ìní wa sílẹ̀, ó sì bọ́ sí ọwọ́ Lábánì.

27 Ó sì ṣe tí a sá sínú ijù, àwọn ìránṣẹ́ Lábánì kò sì bá wa, a sì fi ara wa pamọ́ nínú ihò àpáta kan.

28 Ó sì ṣe tí Lámánì bínú sí mi, àti pẹ̀lú sí bàbá mi; bákan nã sì ni Lẹ́múẹ́lì, nítorí ó fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Lámánì. Nítorí-èyi Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ líle sí wa, àwa àbúrò wọn ọkùnrin, wọ́n sì lù wá àní pẹ̀lú ọ̀pá.

29 Ó sì ṣe bí wọ́n ṣe n lù wá pẹ̀lú ọ̀pá, kíyèsĩ i, angẹ́lì Olúwa kan wá ó sì dúró níwájú wọn, ó sì wí fún wọn, wí pé: Èéṣe tí ẹ̀yin fi n lu àbúrò yín ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀pá? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé Olúwa ti yàn án láti jẹ́ alákõso lórí yín, ó sì ṣe èyi nítorí àìṣedẽdé yín? Kíyèsĩ i ẹ̀yin yíò tún gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, Olúwa yíò sì fi Lábánì lée yín lọ́wọ́.

30 Lẹ́hìn tí ángẹ́lì nã sì ti sọ̀rọ̀ sí wa, ó lọ kúrò.

31 Lẹ́hìn tí ángẹ́lì nã sì ti lọ kúrò, Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí kùn, wí pé: Báwo ni yíò ti ṣe é ṣe pé Olúwa yíò fi Lábánì lé wa lọ́wọ́? Kíyèsĩ i ó jẹ́ alágbára ọkùnrin, ó sì lè pàṣẹ fún ãdọ́ta, bẹ̃ni, àní ó lè pa ãdọ́ta; njẹ́ ẽṣe tí kò ní le pa wá?