Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 19


Ori 19

Nífáì ṣe àwọn àwo ti irin àìpò tútù ó sì kọ ìwé ìtàn àwọn ènìyàn rẹ̀ sínú ìwé ìrántí—Ọlọ́run Ísráẹ́lì yíò wá ní ẹgbẹ̀ta ọdún láti ìgbà tí Léhì kúrò ní Jerúsálẹ́mù—Nífáì sọ nípa ìjìyà àti ìyà ìkànmọ́ àgbélẽbú Rẹ̀—Àwọn Jũ ni a ó kẹ́gàn tí a ó sì túká títí àwọn ọjọ́ ti ìkẹhìn, nígbàtí wọn yíò padà sọ́dọ̀ Olúwa. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí Olúwa pàṣẹ fún mi, nítorí-èyi mo ṣe àwọn àwo ti irin àìpò tútù kí èmi bá lè fín ìwé ìrántí àwọn ènìyàn mi sórí wọn. Sí orí àwọn àwo èyí tí mo sì ṣe ni mo fín ìwé ìrántí bàbá mi, àti pẹ̀lú àwọn írìn àjò wa ní aginjù, àti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ bàbá mi; àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ tèmi ni mo ti fín sórí wọn.

2 Èmi kòsí mọ̀ ní àkókò tí mo ṣe wọ́n pé Olúwa yíò pàṣẹ fún mi láti ṣe àwọn àwo wọ̀nyí; nítorí-èyi, ìwé ìrántí bàbá mi, àti ìtàn ìdílé àwọn bàbá rẹ̀, àti ipa tí ó jùlọ ti àwọn ìṣe wa gbogbo ní aginjù ni a fín sórí àwọn àwo ìṣãjú wọnnì nípa èyí tí mo ti sọ̀rọ̀; nítorí-èyi, àwọn ohun èyí tí o sẹlẹ̀ kí èmi tó ṣe àwọn àwo wọ̀nyí ni, ní òtítọ́, a ṣe ìrántí ní pàtàkì jùlọ sórí àwọn àwo ìṣãjú.

3 Lẹ́hìn tí mo sì ti ṣe àwọn àwo wọ̀nyí nípasẹ̀ ọ̀nà àṣẹ, èmi, Nífáì, gba àṣẹ pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀, àwọn apákan wọn tí ó rí kerekere tí ó sì níyelórí jùlọ, ni a ó kọ sórí àwọn àwo wọ̀nyí; àti pé àwọn ohun èyítí a ó kọ ni a ó tọ́jú fún ẹkọ́ àwọn ènìyàn mi, tí yíò jogún ilẹ̀ nã, àti pẹ̀lú fún àwọn èté ọlọgbọ́n míràn, àwọn èté èyí tí ó jẹ́ mímọ̀ sí Olúwa.

4 Nítorí-èyi, èmi, Nífáì, ṣe ìwé ìrántí kan sórí awọn àwo míràn nì, èyí tí ó fún ni ní ìṣirò, tàbí èyí tí ó fún ni ní ìṣirò tí ó tóbijù ti àwọn ogun àti àwọn ìjà àti àwọn ìparun àwọn ènìyàn mi. Èyí ni mo sì ti ṣe, tí mo sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn mi ohun tí wọn yíò ṣe lẹ́hìn tí èmi bá ti lọ; àti pé àwọn àwo wọ̀nyí ni kí á fi lé lẹ̀ láti ìran kan dé òmíràn, tàbí láti ọwọ wòlĩ kan dé òmíràn, títí di ìgbà tí a ó gba àwọn-ofin Olúwa.

5 Ìṣirò ṣíṣe mi ti àwọn àwo wọ̀nyí ni a ó sì fi fún ni lẹ́hìn èyí; nígbànã sì ni, kíyèsĩ i, èmi tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́bí ti èyí tí mo ti sọ; èyí sì ni mo ṣe kí á lè tọ́jú àwọn ohun mímọ́ jùlọ fún ìmọ̀ àwọn ènìyàn mi.

6 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi kò kọ ohunkóhun sórí àwọn àwo àfi eyi tí mo rò pé o jẹ́ mímọ́. Àti nísisìyí, bí mo bá sì ṣe àṣìṣe, àní bẹ̃gẹ́gẹ́ wọ́n ṣe àṣìṣe ní àtijọ́; kì í ṣe pé èmi yíò ṣe gáfárà fún ara mi nítorí ti àwọn ènìyàn míràn, ṣùgbọ́n nítorí ti àìlera èyí tí ó wà nínú mi, nípa ti ara, èmi yíò ṣe gáfárà fún ara mi.

7 Nítorí àwọn ohun èyí tí àwọn ènìyàn kan kà sí pé ó jẹ́ iye nlá, àti sí ara àti ọkàn, àwọn míràn mu ní asán tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ mọ́lẹ̀. Bẹ̃ni, àní Ọlọ́run Isráẹ́lì gan-an ni àwọn ènìyàn nfi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ mọ́lẹ̀; mo ní, fi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n èmi yíò sọ̀rọ̀ ní gbólóhùn míràn—wọ́n mu u ní asán, wọ́n kò sì fetísílẹ̀ sí ohùn ìmọ̀ràn rẹ̀.

8 Sì kíyèsĩ ó mbọ̀wá, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ ángẹ́lì nã, ní ẹgbẹ̀ta ọdún láti ìgbà tí bàbá mi kuro ní Jerúsálẹ́mù.

9 Aráyé, nítorí ti àìṣedẽdé wọn, yíò sì ṣe ìdájọ́ fún un bí ohun asán; nítorí-èyi wọ́n nà á, ó sì yọ̃da rẹ̀; wọ́n sì lù ú, ó sì yọ̃da rẹ̀. Bẹ̃ni, wọ́n tutọ́ sórí rẹ̀, ó sì yọ̃da rẹ̀, nítorí ti õre rẹ̀ tí ó nífẹ́ àti ìpamọ́ra rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn.

10 Ọlọ́run àwọn bàbá wa, tí a tọ́ jáde ní Égíptì, jáde ní oko ẹrú, àti pẹ̀lú tí a pamọ́ ní aginjù nípa ọwọ́ rẹ̀, bẹ̃ni, Ọlọ́run Ábráhámù, àti ti Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù, yọ̃da ara rẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ angẹ́lì nã, bí ènìyàn, sí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, láti gbé e sókè, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Sénọ́kì, àti láti kàn án mọ́ àgbélèbú, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Néọ́mì, àti láti sìnkú rẹ̀ ní isà-òkú, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Sénọ́sì, èyí tí ó sọ nípa ọjọ́ òkùnkùn mẹ́ta, èyí tí yíò jẹ́ àmì ikú rẹ̀ tí a fi fún àwọn tí yíò gbé inú erékùṣù òkun, ní pãpã jùlọ tí a fi fún àwọn tí ó jẹ́ ará ilé Isráẹ́lì.

11 Nítorí báyĩ ni wòlĩ nã sọ: Olúwa Ọlọ́run dájúdájú yíò bẹ gbogbo ará ilé Isráẹ́lì wo ní ọjọ́ nì, àwọn kan pẹ̀lú ohùn rẹ̀, nítorí ti òdodo wọn, sí ayọ̀ nlá àti ìgbàlà wọn, àti àwọn míràn pẹ̀lú àrá àti mànàmáná agbára rẹ̀, nípasẹ̀ ẹ̀fũfù líle, nípasẹ̀ iná, àti nípasẹ̀ ẽfín, àti ìkũkù òkùnkùn, àti nípasẹ̀ ìṣísílẹ̀ ayé, àti nípasẹ̀ àwọn òkè gíga èyí tí a ó gbé sókè.

12 Gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí kò sì lè ṣe àìwá wá dájúdájú, ni wòlĩ Sénọ́sì wí. Àwọn àpáta ayé kò sì lè ṣe àìfàya; nítorí ti ìkérora ayé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọba erékùṣù òkun sì ni Ẹ̀mí Ọlọ́run yíò ṣiṣẹ́ lé lórí, láti kígbe sókè: Ọlọ́run ẹ̀dá ohun gbogbo jìyà.

13 Bí ó sì ṣe ti àwọn tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, ni wòlĩ nã wí, a ó nà wọ́n lẹ́gba ní ọwọ́ gbogbo ènìyàn, nítorí tí wọ́n kan Ọlọ́run Isráẹ́lì mọ́ àgbélẽbú, wọ́n sì yí ọkàn wọn sí ápákan, wọ́n nkọ àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu sílẹ̀, àti agbára àti ògo Ọlọ́run Isráẹ́lì.

14 Nítorí tí wọ́n sì yí ọkàn wọn si ápákan, ni wòlĩ nã wí, tí wọ́n sì ti kẹ́gàn Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, àwọn yíò rìn kiri lóde ara, wọn ó sì ṣègbé, wọn ó sì di òṣé àti ìfiṣẹ̀sín, a ó sì kórìra wọn lãrín gbogbo orílẹ-èdè.

15 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nígbàtí ọjọ́ ni bá dé, ni wòlĩ nã wí, tí wọn kò yí ọkàn wọn si ápákan kúrò níwájú Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, nígbànã ni òun yíò rántí awọn májẹ̀mú èyí tí ó ti ṣe sí àwọn bàbá wọn.

16 Bẹ̃ni, nígbànã ni òun yíò rántí àwọn erékùṣù òkun; bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì, ni èmi yíò kójọ sínú, ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ Sénọ́sì, láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé.

17 Bẹ̃ni, gbogbo ayé ni yíò sì rí ìgbàlà Olúwa, ni wòlĩ nã wí; olúkúlùkù orílẹ̀-èdè, ìbàtan, èdè àti ènìyàn ni a ó bùkún fun.

18 Èmi, Nífáì, sì ti kọ àwọn ohun wọ̀nyí sí àwọn ènìyàn mi, pé bóyá mo lè yí wọn lọ́kàn padà kí wọ́n lè rántí Olúwa Olùràpadà wọn.

19 Nítorí-èyi, mo sọ̀rọ̀ sí gbogbo ará ilé Isráẹ́lì, bí o bá jẹ́ pé àwọn yíò gba àwọn ohun wọ̀nyí.

20 Nítorí kíyèsĩ i, mo ní àwọn iṣẹ́ ninu ẹ̀mí, èyí tí ó mú mi láarẹ̀ àní tí gbogbo oríkẽ mi jẹ́ aláìlágbára, fún àwọn tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù; nítorí ìbá ṣe pé Olúwa ko ni áanú, láti fi hàn sí mi nípa wọn, gẹ́gẹ́bí ó ti ṣe sí àwọn wòlĩ ti àtijọ́, èmi ì bá ti ṣègbé pẹ̀lú.

21 Dájúdájú òun sì fi hàn sí àwọn wòlĩ àtijọ́ ohun gbogbo nípa wọn; àti pẹ̀lú ó fi hàn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nípa wa; nítorí-èyi, o di dandan pe ki a mọ̀ nípa wọn nítorí a kọ wọ́n sórí àwọn àwo idẹ.

22 Nísisìyí, ó ṣe tí èmi, Nífáì, kọ́ àwọn arákùnrin mi ní ẹ̀kọ́ àwọn ohun wọ̀nyí; ó sì ṣe tí mo ka ohun púpọ̀ sí wọn, èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ, ki wọ́n lè mọ̀ nípa àwọn ohun tí Olúwa ńṣe ní àwọn ilẹ̀ míràn, lãrín àwọn ènìyàn ti àtijọ́.

23 Mo sì ka ohun púpọ̀ sí wọn èyí tí a kọ sínú àwọn ìwé Mósè; ṣùgbọ́n ki emí lè yí wọn lọ́kàn padà ní kíkún jùlọ láti gbàgbọ́ nínú Olúwa Olùràpadà wọn mo ka sí wọn ohun tí wòlĩ Isaiah kọ; nítorí mo fi gbogbo ìwé-mímọ́ wé wa, kí ó lè wà fún ànfàní àti ẹ̀kọ́ wa.

24 Nítorí-èyi mo wí fún wọn, wípé: Ẹ tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ nã, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ìyókù ará ilé Isráẹ́lì, ẹ̀ka tí ó ti ṣẹ́ kúrò; ẹ tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ, èyí tí a kọ sí gbogbo ará ilé Isráẹ́lì, kí ẹ sì fi wọ́n wé ara yín, kí ẹ̀yin lè ní ìrètí gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin yín lọ́dọ̀ àwọn tí ẹ̀yin ti ṣẹ́ kúrò; nítorí ní ọ̀nà yí ni wòlĩ nã ti kọ̀wé.