Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 11


Ori 11

Nífáì rí Ẹ̀mí Olúwa, a sì fi igi ìyè hàn á ní ojúran—Ó rí ìyá Ọmọ Ọlọ́run ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìrẹ-ara-sílẹ̀ ti Ọlọ́run—Ó rí ìrìbọmi, iṣẹ́ ìránṣẹ́, áti ìkànmọ́ àgbélèbú ti Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run—Ó rí ìpè àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti àwọn Àpóstélì Méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn pẹ̀lú. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Nítorí ó sì ṣe lẹ́hìn tí mo ti fẹ́ láti mọ́ àwọn ohun tí bàbá mi ti rí, tí mo sì gbàgbọ́ wípé Olúwa lè sọ wọ́n di mímọ̀ fún mi, bí mo ṣe jóko tí mọ̀ nrò nínú ọkàn mi, a mú mi lọ nínú Ẹ̀mí Olúwa, bẹ̃ni, sí òkè gíga gan-an, èyí tí èmi kò tí ì rí rí, orí èyí tí èmi kò sì tí tẹ̀ rí.

2 Ẹ̀mí nã sì sọ fún mi: Kíyèsĩ, kíni ìwọ nfẹ́?

3 Mo sì wípé: Mo fẹ́ láti rí àwọn ohun tí bàbá mi rí.

4 Ẹ̀mí nã sì sọ fún mi: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé bàbá rẹ rí igi èyí tí ó ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

5 Mo sì wípé: Bẹ̃ni, ìwọ mọ̀ wípé mo gba gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi gbọ́.

6 Nígbàtí mo sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ẹ̀mí nã kígbe pẹ̀lú ohùn rara, wípé: Hòsánnà sí Olúwa, Ọlọ́run ẹnití-ó-gá-jùlọ; nítorítí ó jẹ́ Ọlọ́run lórí gbogbo ayé, bẹ̃ni, àní ga ju ohun gbogbo lọ. Alábùkún-fún sì ni ìwọ, Nífáì, nítorítí ìwọ gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run ẹnití-ó-gá-jùlọ; Nítorínã ìwọ yíò rí àwọn ohun tí ìwọ nfẹ́.

7 Sì kíyèsĩ i nkàn yí ni a ó fi fún ọ fún àmì, pé lẹ́hìn tí ìwọ bá ti rí igi èyí tí ó so èso èyí tí bàbá rẹ tọ́wò, ìwọ yíò rí ọkùnrin kan pẹ̀lú tí ó nsọ̀kalẹ̀ jáde láti ọ̀run, òun sì ni ìwọ yíò ṣe lẹ́rĩ; lẹ́hìn tí ìwọ bá sì ti jẹ́rĩ rẹ̀ ìwọ yíò jẹ́rĩ pe ó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run.

8 Ó sì ṣe tí Ẹ̀mí ná à wí fún mi: Wò ó! Mo si wò ó, mo sì kíyèsĩ igi kan; ó sì dàbí igi èyítí bàbá mi ti rí; ẹwà rẹ̀ sì rékọjá jìnà, bẹ̃ni, tayọ gbogbo ẹwà; funfun rẹ̀ sì tayọ funfun ìrì dídì tí afẹ́fẹ́ kójọ.

9 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí mo ti rí igi nã, mo wí fún Ẹ̀mí nã: Mo kíyèsĩ pé ìwọ ti fi igi èyítí ó níye lórí ga ju gbogbo ohun lọ hàn mí.

10 Ó sì wí fún mi: Kíni ìwọ fẹ́?

11 Mo sì wí fún un: Láti mọ́ ìtumọ̀ èyínã—nítorí mo bá a sọ̀rọ̀ bí ènìyàn ṣe nsọ̀rọ̀; nítorí mo kíyèsĩ i wípé ó wà ní ìwo ti ènìyàn; sùgbọ́n bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo mọ̀ wípé Ẹ̀mí Olúwa ni; ó sì bá mi sọ̀rọ̀ bí ènìyàn kan ṣe nbá òmíràn sọ̀rọ̀.

12 Ó sì ṣe tí ó sọ fún mi: Wò ó! Mo sì wò bí ẹni pé kí n wò ó, èmi kò sì rí i; nítorí ó ti lọ kúrò níwájú mi.

13 Ó sì ṣe tí mo wò tí mo sì rí ìlú-nlá Jerúsálẹ́mù nì, àti àwọn ìlú-nlá míràn pẹ̀lú. Mo sì rí ìlú-nlá Násárẹ́tì; ní ìlú-nlá Násárẹ́tì mo sì rí wúndíá kan, ó sì dára, ó sì funfun lọ́pọ̀lọpọ̀.

14 Ó sì ṣe tí mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀; angẹ́lì kan sì sọ̀kalẹ̀ ó sì dúró níwájú mi; ó sì wí fún mi: Nífáì, kíni ìwọ rí?

15 Mo sì wí fún un: Wúndíá kan, tí ó lẹ́wà tí ó sì dára ju gbogbo àwọn wúndíá míràn lọ.

16 Ó sì wí fún mi: Njẹ́ ìwọ mọ́ ìrẹ-ara-sílẹ̀ ti Ọlọ́run?

17 Mo sì wí fún un: Mo mọ̀ wípé ó fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi kò mọ́ ìtúmọ̀ ohun gbogbo.

18 Ó sì wí fún mi: Kíyèsĩ, wúndíá tí ìwọ rí nì jẹ́ ìyá Ọmọ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara.

19 Ó sì ṣe tí mo rí tí a mú u lọ nínú Ẹ̀mí; lẹ́hìn tí a sì ti mú u lọ nínú Ẹ̀mí ní ìwọ̀n ìgbà díẹ̀, angẹ́lì ná à bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Wò ó!

20 Mo sì wò mo sì tún kíyèsĩ wúndíá ná à, ó gbé ọmọ kan ní ọwọ́ rẹ̀.

21 Angẹ́lì nã sì wí fún mi: Wo Ọ̀dọ́-àgùtan Ọlọ́run, bẹ̃ni, àní Ọmọ Bàbá Ayérayé! Njẹ́ ìwọ mọ́ ìtumọ̀ igi èyí tí bàbá rẹ rí?

22 Mo sì dá a lóhùn wípé: Bẹ̃ni, ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, èyítí ó tan ara rẹ̀ ká lóde nínú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn; nítorínã, ó jẹ́ ohun ti o wuni ju gbogbo ohun lọ.

23 Ó sì bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Bẹ̃ni, àti tí o ṣe inú dídùn jùlọ fún ọkàn.

24 Lẹ́hìn tí ó sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wí fún mi: Wò ó! Mo sì wò, mo sì rí Ọmọ Ọlọ́run tí ó n kãkiri lãrín àwọn ọmọ ènìyàn; mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n wolẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un.

25 Ó sì ṣe tí mo rí wípé ọ̀pá irin nã, èyí tí bàbá mi ti rí, jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ó tọ́ni sí orísun omi ìyè, tàbí sí igi ìyè; omi èyí tí ó jẹ́ àpẹrẹ ìfẹ́ Ọlọ́run; mo si tún rí i wípé igi ìyè nã jẹ́ àpẹrẹ ìfẹ́ Ọlọ́run.

26 Angẹ́lì ná à sì tún wí fún mi: Wò kí o sì ri ìrẹ-ara-sílẹ̀ Ọlọ́run!

27 Mo sì wò mo sì rí Olùràpadà ayé, ẹni tí bàbá mi ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀; mo sì tún rí wòlĩ nã ẹni tí yíò tún ọ̀nà ṣe ṣíwájú rẹ̀. Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ná à sì jáde lọ a sì rìi bọmi nípa ọwọ́ rẹ̀; Lẹ́hìn tí a sì rìbọmi rẹ̀, mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, ó sì bà sórí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà.

28 Mo sì rí i wípé ó jáde lọ ó n ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn, ní agbára àti ògo nlá; ọ̀pọ̀ ènìyàn sì jùmọ̀ péjọ láti gbọ́ ọ; mo sì rí i wípé wọ́n lée jáde kúrò lãrín wọn.

29 Mo sì tún rí àwọn méjìlá míràn tí wọ́n ntẹ̀lé e. Ó sì ṣe tí a mú wọn lọ nínú Ẹ̀mí kúrò níwájú mi, èmi kò sì rí wọn.

30 Ó sì ṣe tí ángẹ́li ná à tún bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Wò ó! Mo sì wò, mo sì kíyèsí àwọn ọ̀run tí wọ́n tún ṣí sílẹ̀, mo sì rí àwọn ángẹ́lì tí wọ́n nsọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ọmọ ènìyàn; wọ́n sì ṣe isẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn.

31 Ó sì tún bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Wò ó! Mo sì wò, mo sì kíyèsí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run tí ó nkãkiri lãrín àwọn ọmọ ènìyàn. Mo sì kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n nṣàìsàn, tí a sì pọ́n-lójú pẹ̀lú onírũrú àrùn gbogbo, àti pẹ̀lú àwọn èṣù àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́; angẹ́lì nã sì sọ, ó sì fi gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí hàn mí. Wọ́n sì rí ìwòsàn nípasẹ̀ agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run; àwọn èṣù àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ni a sì lé jáde.

32 Ó sì ṣe tí angẹ́lì ná à tún bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Wò ó! Mo sì wò mo sì kíyèsí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, tí àwọn ènìyàn mú u; bẹ̃ni, Ọmọ Ọlọ́run títí ayé ni a dáléjọ́ nípa ayé; mo sì rí mo sì jẹ́rĩ.

33 Èmi, Nífáì, sì ri i tí a gbé e sókè sórí àgbélèbú tí a sì pa á fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ayé.

34 Lẹ́hìn tí a sì ti pa á, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn ayé, tí wọ́n jùmọ̀ péjọ lati dojú ìjà kọ àwọn àpóstélì Ọ̀dọ́-àgùtàn; nítorí báyĩ ni angẹ́lì Olúwa pe àwọn méjìlá nã.

35 Ọ̀pọ̀ ènìyan ayé sì jùmọ̀ péjọ; mo sì kíyèsí pé wọ́n wà nínú ilé kan tí ó tóbi tí ó sì gbõrò, tí o dàbí ilé èyí tí bàbá mi rí. Angẹ́lì Olúwa ná à sì tún bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Kíyèsí ayé àti ọgbọ́n inú rẹ̀; bẹ̃ni, kíyèsĩ ará ilé Isráẹ́lì ti jùmọ̀ péjọ láti dojú ìjà kọ àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn.

36 Ó sì ṣe tí mo rí tí mo sì jẹ́rĩ, pé ilé tí ó tóbi tí ó sì gbõrò nã jẹ́ ìgbéraga ayé; ó sì wó, wíwó rẹ̀ sì pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Angẹ́lì Olúwa ná à sì tún bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Báyĩ ni ìparun gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè àti ènìyàn yíò rí, tí yíò dojú ìjà kọ àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn.