Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 15


Ori 15

Irú-ọmọ Léhì yíò gba ìhìn-rere lọ́wọ́ àwọn Kèfèrí ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn—Kíkojọ Isráẹ́lì ni a fi wé igi ólífí èyí tí a ó tún lọ́ àwọn ẹká àdánidá rẹ̀ sínú rẹ̀—Nífáì túmọ̀ ìran igi ìyè ó sọ̀rọ̀ nípa àìṣègbè Ọlọ́run ní yíya ènìyan búburú nípa kuro ní olódodo. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí a ti mú èmi, Nífáì, lọ nínú ẹ̀mí, tí mo sì ti rí gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí, mo padà sí àgọ́ bàbá mi.

2 Ó sì ṣe tí mo kíyèsí àwọn arákùnrin mi, wọ́n sì ṣe àríyànjiyàn pẹ̀lú ara wọn nípa àwọn ohun èyí tí bàbá mi ti sọ fún wọn.

3 Nítorí ó sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nlá fún wọn nítõtọ́, èyí tí o ṣòro láti mọ̀, àfi tí ènìyàn bá bèrè lọ́wọ́ Olúwa; níwọ̀n bí wọ́n sì ti le ní ọkàn wọn, nítorínã àwọn kò yí ojú sí Olúwa bí àwọn ìbá ṣe ṣe.

4 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kẹ́dùn nítorí ti líle ọkàn wọn, àti pẹ̀lú, nítorí ti àwọn ohun èyí tí mo ti rí, mo sì mọ̀ pé láìyẹ̀kúrò wọn kò le ṣe àìṣẹlẹ̀ nítorí ti ìwà búburú àwọn ọmọ ènìyàn.

5 Ó sì ṣe tí a borí mi nítorí ti àwọn ìpọ́njú mi, nítorí mo gbèrò pé àwọn ìpọ́njú mi pọ̀ ju gbogbo ìpọ̀njú lọ, nítorí ti ìparun àwọn ènìyàn mi, nítorí mo ti rí ìṣubú wọn.

6 Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí mo ti gba agbara mo bá àwọn arákùnrin mi sọ̀rọ̀, mo nfẹ́ láti mọ̀ lọ́wọ́ wọn ìdí àwọn àríyànjiyàn wọn.

7 Wọ́n sì ní: Kíyèsĩ i, àwa kò lè mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí bàbá wa ti sọ nípa àwọn ẹ̀ká àdánidá igi ólífì, àti pẹ̀lú nípa àwọn Kèfèrí.

8 Mo sì wí fún wọn: Njẹ́ ẹ̀yin ti bèrè lọ́wọ́ Olúwa?

9 Wọ́n sì wí fún mi: Àwa kò tí ì ṣe bẹ́ ẹ̀; nítorí Olúwa kò fi irú ohun bẹ́ ẹ̀ hàn sí wa.

10 Kíyèsĩ i, mo wí fún wọn: Báwo wá ni tí ẹ̀yin kò pa awọn òfin Olúwa mọ́? Báwo wá ni tí ẹ̀yin yíò ṣègbé, nítorí ti líle ọkàn yín?

11 Ṣé ẹ̀yin kò rántí àwọn ohun èyí tí Olúwa ti sọ?—Bí ẹ̀yin kò bá mú ọkàn yín le, tí ẹ̀yin sì bí mí lẽrè ní ìgbàgbọ́, tí ẹ gbàgbọ́ pé ẹ̀yin yíò rí gbà, pẹ̀lú ãpọn ní pípa awọn òfin mi mọ́, dájúdájú àwọn ohun wọ̀nyí ni a ó fihàn sí i yín.

12 Kíyèsĩ i, mo wí fún un yín, pe ará ilé Isráẹ́lì ni a fi wé igi ólífi, nípasẹ̀ Èmí Olúwa èyí tí ó wà nínú bàbá wa; sì kíyèsĩ i, njẹ́ àwa kò ti yapa kúrò nínú ará ilé Isráẹ́lì, njẹ àwa kì í sì í ṣe ẹ̀ká ará ilé Isráẹ́lì?

13 Àti nísisìyí, ohun tí bàbá wa pète nípa lílọ́ sínú àwọn ẹ̀ká àdánidá nípa ẹ̀kún àwọn Kèfèrí, ni, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, nígbàtí irú-ọmọ wa yíò ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, bẹ̃ni fun ìwọ̀n ọpọlọpọ ọdun, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ irandiran lẹhin tí a ó fi Messia hàn ní ara sí àwọn ọmọ ènìyàn, nígbànã ni ẹ̀kún ìhìn-rere ti Messia yíò wá sí ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí sí ọ̀dọ̀ ìyókù irú-ọmọ wa—

14 Ní ọjọ́ nì sì ni ìyókù irú-ọmọ wa yíò mọ̀ pé àwọn jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì, àti pé àwọn ni ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa; nígbànã sì ni wọn yíò mọ̀ tí wọn ó sì wá sí ìmọ̀ àwọn baba-nlá wọn, àti pẹ̀lú sí ìmọ̀ ìhìn-rere ti Olùràpadà wọn, èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ sí àwọn bàbá wọn nípasẹ̀ rẹ̀; nítorínã, wọn yíò wá sí ìmọ̀ Olùràpadà wọn àti àwọn nkan àfiyèsí ti ẹ̀kọ́ rẹ̀ gan, kí wọn lè mọ̀ bí wọ́n ó ṣe wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí a sì gbà wọ́n là.

15 Nígbànã ní ọjọ́ nì, njẹ́ wọn kì yíò ha yọ̀ tí wọn yíò sì fi ìyìn fún Ọlọ́run Àìlópin wọn, àpáta wọn àti ìgbàlà wọn? Bẹ̃ni, ní ọjọ́ nì, njẹ́ wọn kì yíò ha gba agbára àti bíbọ́ lọ́wọ́ àjàrà òtítọ́? Bẹ̃ni, njẹ́ wọn kì yíò wá sí agbo òtítọ́ Ọlọ́run?

16 Kíyèsĩ i, mo wí fún un yín, Bẹ̃ni; a ó tún rántí wọn lãrín ará ilé Isráẹ́lì; a ó lọ́ wọn, níwọ̀n bí wọ́n ṣe jẹ́ ẹ̀ká àdánidá igi ólífì, sínú igi ólífì tõtọ́.

17 Èyí sì ni ohun tí bàbá wa pète; ó sì pète pé kì yíò ṣẹ títí di lẹ́hìn tí àwọn Kèfèrí yíò tu wọn ká; ó sì pète pé yíò wá nípasẹ̀ àwọn Kèferí, pé kí Olúwa lè fi agbára rẹ̀ hàn sí àwọn Kèfèrí, fún ìdí gan pé a ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ nípa àwọn Jũ, tàbí nípa ará ilé Isráẹ́lì.

18 Nítorí-èyi, bàbá wa kò sọ̀rọ̀ nípa irú ọmọ wa nìkan, ṣùgbọ́n nípa gbogbo ará ilé Isráẹ́lì, ó ntọ́ka sí májẹ̀mú èyí tí a ó mú ṣẹ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn; májẹ̀mú èyí tí Olúwa ṣe pẹ̀lú bàbá wa Ábráhámù, tí ó wípé: Nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó ti fi ìbùkún fún gbogbo ìbátan aráyé.

19 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, sọ̀rọ̀ púpọ̀ fún wọn nípa àwọn nkan wọ̀nyí; bẹ̃ni, mo sọ̀rọ̀ fún wọn nípa ìmúpadà sípò àwọn Jũ ní àwọn ọjọ ìkẹhìn.

20 Mo sì tún àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah kà sí wọn, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìmúpadà sípò àwọn Jũ, tàbí ará ilé Isráẹ́lì; lẹ́hìn tí a sì mú wọn padà sípò a kò ní fọn wọn ká mọ́, bẹ̃ni a kò ní tún tú wọn ká. Ó sì ṣe tí mo sọ àwọn ọ̀rọ̀ púpọ̀ sí àwọn arákùnrin mi, tí wọ́n gbẹ̀rọ̀ tí wọ́n sì rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa.

21 Ó sì ṣe tí wọ́n tún bá mi sọ̀rọ̀, wọ́n nwí pé: Kíni ìtumọ̀ nkan yí èyí tí bàbá wa rí ní àlá? Kíni ìtumọ̀ igi èyí tí ó rí?

22 Mo sì wí fún wọn: ó jẹ́ àwòrán igi ìyè.

23 Wọn sì wí fún mi: Kíni ìtumọ̀ ọ̀pá irin èyí tí bàbá wa rí, tí ó tọ́ sí igi ná à?

24 Mo sì wí fún wọn pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dì í mú kì yíò ṣègbé láé; bẹ̃ni ìdánwò àti àwọn ọfà iná èṣù kò lè borí wọn sí ìfọ́jù, láti tọ́ wọn kúrò sí ìparun.

25 Nítorí-èyi, èmi, Nífáì, gbà wọ́n níyànjú láti ní akíyèsí sí ọ̀rọ̀ Olúwa; bẹ̃ni, mo gbà wọ́n níyànjú pẹ̀lú gbogbo okun-inú ọkàn mi, àti pẹ̀lú gbogbo iyè èyí tí mo ní ní ìní, pé kí wọ́n lè ní akíyèsí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì rántí láti pa awọn òfin rẹ̀ mọ́ nígbà-gbogbo ní ohun gbogbo.

26 Wọ́n sì wí fún mi: Kíni ìtumọ̀ odò omi èyí tí bàbá wa rí?

27 Mo sì wí fún wọn pé omi èyí tí bàbá mi rí nì jẹ́ ìwà ọ̀bùn; ọkàn rẹ̀ ni a sì ti gbémì púpọ̀ sínú àwọn ohun míràn tí kò kíyèsĩ ìwà ọ̀bùn omi ná à.

28 Mo sì wí fún wọn pé ó jẹ́ ọ̀gbun tí ó dẹ́rùbani, èyí tí ó ya àwọn ènìyàn búburú sọ́tọ̀ kúrò lára igi ìyè, àti pẹ̀lú kúrò nínú àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run.

29 Mo sì wí fún wọn pé ó jẹ́ àwòrán ọ̀run àpãdì búburú nì, èyí tí ángẹ́lì ná à wí fún mi pé a pèsè fún àwọn ènìyàn búburú.

30 Mo sì wí fún wọn pé bàbá wa rí pẹ̀lú pé àìṣègbè Ọlọ́run bẹ̃gẹ́gẹ́ pín àwọn ènìyàn búburú kúrò lára olódodo; dídán èyí tí ó dàbí dídán ọ̀wọ̀ iná, èyí tí ó jó lọ sókè sí Ọlọ́run láé àti láéláé, tí kò sì ní òpin.

31 Wọ́n sì wi fun mi: Ṣé ohun yí túmọ̀ sí ìdálóró ara ní àwọn ọjọ́ ìdánwò, tàbí ó túmọ̀ sí ipò ti ìgbẹ̀hìn ọkàn lẹ́hìn ikú ara ti ayé yí, tàbí ṣé ó sọrọ nípa àwọn ohun èyí tí ó jẹ́ ti ayé yí?

32 Ó sì ṣe tí mo wí fún wọn pé ó jẹ́ àwòrán àwọn ohun ti ayé yí àti ti ẹ̀mí pẹ̀lú; nítorí ọjọ́ ná à yíò dé tí a kò lè ṣe àìṣe ìdájọ́ wọn ní ti iṣẹ́ wọn, bẹ̃ni, àní iṣẹ́ èyí tí wọ́n ṣe pẹ̀lú ara ti ayé yì ní àwọn ọjọ́ ìdánwò wọn.

33 Nítorí-èyi, bí wọ́n bá kú nínú ìwà búburú wọn a gbọ́dọ̀ sọ wọ́n kúrò pẹ̀lú, nípa ti àwọn ohun èyí tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí, èyí tí ó nṣe ti òdodo; nítorí-èyi, a gbọ́dọ̀ mú wọn láti dúró níwájú Ọlọ́run, láti ṣe ìdájọ́ wọn ní ti iṣẹ́ wọn; bí iṣẹ́ wọn bá sì ti jẹ́ ìwà ẹ̀gbin o di dandan kí wọn ó ní ẹ́gbin; bí wọ́n bá sì ní ẹ́gbin, o di dandan ki wọn ò má lè gbé inu ìjọba Ọlọ́run; bí ó bá si ri bẹ, o di dandan ki ìjọba Ọlọ́run lẹ́gbin pẹ̀lú.

34 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, mo wí fún yín, ìjọba Ọlọ́run kò ni ẹ́gbin, kò sì lè sí ohun àìmọ́ èyíkèyí tí yíò wọlé sínú ìjọba Ọlọ́run; nítorínã ó di dandan ki a pèsè ibi ẹlẹgbin kan fún ohun nã tí ó lẹ́gbin.

35 Ibì kan sì wà tí a ti pèsè, bẹ̃ni, àní ọ̀run àpãdì búburú nì nípa èyí tí mo ti sọ̀rọ̀, èṣù sì jẹ́ olùpèsè rẹ̀; nítorí-èyi ipò ti ìgbẹ̀hìn ọkàn àwọn ènìyàn ni láti gbé ní ìjọba Ọlọ́run, tàbí kí á sọ wọ́n sóde nítorí ti àìṣègbè nípa èyí tí mo ti sọ̀rọ̀.

36 Nítorí-èyi, àwọn ènìyàn búburú ni a kọ̀ sílẹ̀ kúrò ní ọ̀dọ̀ olódodo, àti pẹ̀lú kúrò ní ara igi ìyè nì, èso èyí tí o jẹ́ iyebíye jùlọ tí ó sì yẹ ní fífẹ́ tayọ gbogbo àwọn èso míràn lọ; bẹ̃ni, ó sì jẹ́ èyí tí ó tóbi jùlọ ní gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run. Báyĩ í ni mo sì wí fún àwọn arákùnrin mi. Àmín.