Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 6


Orí 6

Àwọn ará Lámánì olódodo wãsù sí àwọn ará Nífáì oníwà búburú—Àwọn ará méjẽjì ní ìlọsíwájú ní àsìkò tí àlãfíà àti ọ̀pọ̀ wa—Lúsíférì, ẹnití í ṣe olùpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ru ọkàn àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì sókè sí ìpànìyàn ati ìwàbúburú—Àwọn ọlọ́ṣà nã gba ìjọba àwọn ará Nífáì. Ní ìwọ̀n ọdún 29 sí 23 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe nígbàtí ọdún kejìlélọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ ti parí, gbogbo nkan wọ̀nyí sì ti rékọjá tí èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ará Lámánì sì ti di olódodo ènìyàn, tóbẹ̃ tí ìwà ododo nwọn tayọ ti àwọn ará Nífáì, nítorí ìwà ìtẹramọ́ nwọn àti àìyísẹ̀padà kúrò nínú ìgbàgbọ́ nã.

2 Nítorí kíyèsĩ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ará Nífáì nã ní ó ti sé àyà nwọn le tí nwọ́n kò sì ronúpìwàdà, àti nínú ìwà búburú, tóbẹ̃ tí nwọ́n kọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti gbogbo ìwãsù àti ìsọtẹ́lẹ̀ èyítí ó wa pẹ̀lú nwọn.

3 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ènìyàn ìjọ nã ní ayọ̀ nlá nítorí ìyílọ́kànpadà àwọn ará Lámánì, bẹ̃ni, nítorí ìjọ Ọlọ́run, èyítí a ti fi lélẹ̀ lãrín nwọn. Nwọ́n sì ní ìdàpọ̀ ní ọkàn sí ẹlòmíràn, nwọ́n sì nbá ara nwọn yọ̀ ní ọkàn sí ẹlòmíràn, nwọ́n sì ní ayọ̀ nla.

4 Ó sì ṣe tí púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì nã sì sọ̀kalẹ̀ wá sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí nwọn sì sọ nípa bí ìyílọ́kànpadà nwọ́n ti rí fún àwọn ará Nífáì, nwọ́n sì gbà nwọ́n níyànjú láti ní ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà.

5 Bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ó sì wãsù pẹ̀lú agbára nlá àti àṣẹ, tí nwọ́n sì mú púpọ̀ nínú nwọn bọ́sí ipò ìrẹraẹnisílẹ̀, láti lè di onírẹ̀lẹ̀ ọmọ ẹ̀hìn Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́-àgùtàn nã.

6 Ó sì ṣe tí púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì nã lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá; tí Nífáì àti Léhì sì lọ pẹ̀lú sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá; láti wãsù sí àwọn ènìyàn nã. Báyĩ sì ni ọdún kẹtàlélọ́gọ́ta parí.

7 Ẹ sì kíyèsĩ, àlãfíà wà ní gbogbo ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí àwọn ará Nífáì nlọ sí èyíkeyí apá ilẹ̀ nã tí ó bá wù nwọ́n, bóyá lãrín àwọn ará Nífáì tàbí àwọn ará Lámánì.

8 Ó sí ṣe tí àwọn ará Lámánì nã lọ sí ibikíbi tí ó bá wù nwọ́n, bóyá lãrín àwọn ará Lámánì tàbí lãrín àwọn ará Nífáì; báyĩ ni nwọ́n sì ṣe ní ìbáṣepọ̀ dáradára ní ọkàn sí òmíràn, láti rà àti láti tà, àti láti jèrè, gẹ́gẹ́bí ó ti wù nwọ́n.

9 Ó sì ṣe tí nwọ́n sì di ọlọ́rọ̀-ènìyàn púpọ̀púpọ̀, àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Nífáì; nwọ́n sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti fàdákà, àti onírurú òkúta olówó-iyebíye, ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù àti ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá.

10 Nísisìyí ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù ni nwọ́n npè ní Léhì, àti ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá ni nwọ́n npè ní Múlẹ́kì, èyítí nwọ́n pè bẹ̃ lẹ́hìn orúkọ ọmọ Sẹdẹkíàh; nítorítí Olúwa ni ó mú Múlẹ́kì wá sínú ilẹ̀ apá àríwá, àti Léhì sínú ilẹ̀ apá gũsù.

11 Ẹ sì kíyèsĩ, onírurú wúrà ni ó wà nínú àwọn ilẹ̀ yĩ, àti fàdákà, àti irin àìpò olówó iyebíye lóríṣiríṣi; àwọn oníṣẹ́ ọnà sì wa pẹ̀lú, àwọn ẹnití nfi irin àìpò ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́, tí nwọ́n sì nyọ́ọ; báyĩ nwọ́n sì di ọlọ́rọ̀.

12 Nwọ́n sì gbin ọkà lọ́pọ̀lọpọ̀, ní apá àríwá àti ní apá gúsù; nwọ́n sì gbilẹ̀ púpọ̀púpọ̀, ní apá àríwá àti ní gúsù. Nwọ́n sì pọ̀ síi nwọ́n sì di alágbára ní ilẹ̀ nã. Nwọ́n sì nsin ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbo, àti ọ̀wọ́ ẹran, bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àbọ́pa.

13 Ẹ kíyèsĩ àwọn obìnrin nwọn sì nsiṣẹ́, nwọ́n sì nran òwú, nwọ́n sì nṣe onírurú aṣọ, àwọn aṣọ olówó iyebíye àti àwọn onírurú aṣọ láti bò nwọ́n lára. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìnlélọ́gọ́ta kọjá lọ lalãfia.

14 Ní ọdún karundinlãdọrin nwọn sì ní ayọ̀ àti àlãfíà tí ó pọ̀, bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwãsù àti ìsọtẹ́lẹ̀ púpọ̀púpọ̀ nípa ohun tí yíò di mímúṣẹ. Báyĩ sì ni ọdún karundinlãdọrin kọjá lọ.

15 Ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, ẹ kíyèsĩ, ẹni-àìmọ̀ kan sì pa Sẹ́sórámù bí ó ṣe wà lórí ìtẹ́ ìdájọ́. Ó sì ṣe nínú ọdún kan nã, tí nwọn pa ọmọ rẹ̀ ọkùnrin nã ẹnití àwọn ènìyàn ti yàn rọ́pò rẹ. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìndínlãdọ́rin dópin.

16 Nínú ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹtàdínlãdọ́rin ni àwọn ènìyàn nã sì tún bẹ̀rẹ̀sí hu ìwà búburú èyítí ó pọ̀ púpọ̀.

17 Nítorí kíyèsĩ, Olúwa ti bùkúnfún nwọn fún ìgbà pípẹ́ pẹ̀lú àwọn ọrọ̀ ayé tóbẹ̃ tí kò sí ẹnití ó ru nwọn sókè sí ìbínú, tàbí sí ogun, tàbí sí ìtàjẹ̀sílẹ̀; nítorínã nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí gbé ọkàn nwọn lé ọrọ̀ nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí lépa láti lè ga ju ara nwọn lọ; nítorínã nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀, àti láti jalè àti láti ṣe ìkógun, láti lè rí ìfà.

18 Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwọn apànìyàn àti àwọn olè nnì jẹ́ àwọn ẹgbẹ́ tí Kíṣkúmẹ́nì àti Gádíátónì kójọ. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí nwọ́n ti pọ̀, àní lãrín àwọn ará Nífáì, ní ẹgbẹ́ ti Gádíátónì. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nwọ́n pọ̀ lãrín àwọn ará Lámánì nínú àwọn tí ó burú jù lọ. A sì pè nwọn ní àwọn ọlọ́sà àti apànìyàn Gádíátónì.

19 Àwọn sì ni ó pa olórí àlùfã Sẹ́sórámù, àti ọmọ rẹ̀, nígbàtí ó joko lórí ìtẹ́ ìdájọ́; ẹ sì kíyèsĩ, a kò rí nwọn.

20 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé àwọn olóṣà wà lãrín nwọn, nwọn sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi; nwọ́n sì lo gbogbo agbára tí nwọ́n ní láti pa nwọ́n run lórí ilẹ̀ ayé.

21 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Sátánì sì ru ọkàn èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ará Nífáì sókè, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà nã, nwọ́n sì bá nwọn mulẹ̀ nínú ìmùlẹ̀ àti ìbúra nwọn, pé nwọn yíò dábò bò; wọn yíò sì pa ara wọn mọ́ nínú ìṣòro-kíṣòro èyíówù kí nwọ́n ó lè wà, láti má lè jìyà fún ìwà-ìpànìyàn nwọn, àti ìkógun nwọn, àti olè jíjà nwọn.

22 Ó sì ṣe tí nwọ́n ní àwọn àmì nwọn, bẹ̃ni, àwọn àmì ìkọ̀kọ̀ nwọn, àti àwọn ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ nwọn; èyí sì rí bẹ̃ kí nwọn ó lè dá arákùnrin nwọn tí ó bá ti wọ inú ìmùlẹ̀ nã mọ, pé ìwà búburú yìówù kí arákùnrin rẹ̀ ó hu arákùnrin rẹ̀ míràn kò ni pãlára, tàbí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yìókù, tí nwọ́n ti bá nwọn mulẹ̀.

23 Báyĩ sì ni nwọ́n lè pànìyàn, tàbí ṣe ìkógun, tàbí jalè, kí nwọn ó sì ṣe àgbèrè, àti onírurú ìwà búburú, ní ìlòdì sí òfin orílẹ̀-èdè nwọn àti òfin Ọlọ́run nwọn pẹ̀lú.

24 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ẹgbẹ́ nwọn tí ó sì jẹ́ kí ìwà búburú àti ìwà ìríra nwọn ó di mímọ̀ sí aráyé, ni nwọn ó pè lẹ́jọ́, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú òfin orílẹ̀ èdè wọn, ní ìbámu pẹ̀lú òfin búburú nwọn, èyítí Gádíátónì àti Kíṣkúmẹ́nì fi fún nwọn.

25 Nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ìbúra àti ìmùlẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wọ̀nyí ni Álmà paláṣẹ fun ọmọ rẹ pé kò gbọdọ̀ kọjá lọ sínú ayé, ní ìbẹ̀rù pé nwọn yíò jẹ́ ọ̀nà ìparun fún àwọn ènìyàn nã.

26 Nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ìbúra àti ìmùlẹ̀ ìkọ̀kọ̀ nnì kò tẹ Gádíátónì lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn àkosílẹ̀ tí a fi lé Hẹ́lámánì lọ́wọ́; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, a fi nwọ́n sínú ọkan Gádíátónì nípasẹ̀ ẹ̀dá nã tí ó tan àwọn òbí wa àkọ́kọ́ láti jẹ nínú èso nnì tí a kà lẽwọ̀—

27 Bẹ̃ni, ẹ̀dá kan nã tí ó dìtẹ̀ pẹ̀lú Káìnì, pé bí ó bá pa Ábẹ́lì arákùnrin rẹ̀ aráyé kò lè mọ̀ nípa rẹ̀. Ó sì dìtẹ̀ pẹ̀lú Káínì àti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ láti ìgbà nã lọ.

28 Àti pẹ̀lú pé ẹ̀dá ọ̀hún kannã ni ó fi sínú àwọn ènìyàn nã láti kọ́ ilé-ìṣọ́ gíga láti lè lọ sí ọ̀run. Àti pé ẹ̀dá ọ̀hún kannã ni ó darí àwọn ènìyàn nã tí nwọn kúrò láti ilé-ìṣọ́ nã wá sínú ilẹ́ yĩ; tí nwọn tan iṣẹ́ òkùnkùn àti ohun ẽrí kalẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, títí ó fi já àwọn ènìyàn nã lulẹ̀ sí ipò ìparun pátápátá, àti sínú ọ̀run àpãdì ayérayé.

29 Bẹ̃ni, ẹ̀dá ọ̀hún kannã ni ó fi sínú ọkàn Gádíátónì pé kí ó tẹramọ́ iṣẹ́ òkùnkùn ní ṣíṣe, àti ti ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀; ó sì ti nṣe báyĩ láti ìbẹ̀rẹ̀ ọmọ ènìyàn àní títí dé àkokò yĩ.

30 Sì kíyèsĩ, òun ni ẹnití í ṣe olùpilẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀. Sì kíyèsĩ, ó túbọ̀ tẹramọ́ iṣẹ́ òkùnkùn àti ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀, ó sì nfi àwọn ìmọ̀ búburú nwọn, àti àwọn ìbúra nwọn, àti àwọn ìmùlẹ̀ nwọn, àti àwọn ìmọ̀ ìwà búburú nwọn tí ó tóbi, láti ìran dé ìran gẹ́gẹ́bí ó ṣe lè wọnú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn tó.

31 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ó ti wọnú ọkàn àwọn ará Nífáì lọ; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí nwọ́n di ènìyàn tí ó burú púpọ̀púpọ̀; bẹ̃ni, èyítí ó pọ̀ jù nínú nwọn ni ó ti yísẹ̀padà kúrò nínú ọ̀nà òdodo, tí nwọ́n sì ntẹ òfin Ọlọ́run mọ́lẹ̀, tí nwọ́n sì yípadà sí ọ̀nà ara nwọn, tí nwọ́n sì ya ère fún ara nwọn pẹ̀lú àwọn wúrà àti àwọn fàdákà nwọn.

32 Ó sì ṣe tí gbogbo àwọn àìṣedẽdé yĩ dé bá nwọn lãrín ìwọ̀n ọdún díẹ̀, tóbẹ̃ tí púpọ̀ rẹ̀ ni ó dé bá nwọn nínú ọdún kẹtàdínlãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì.

33 Nwọ́n sì ndàgbà nínú àwọn àìṣedẽdé nwọn nínú ọdún kejìdínlãdọ́rin pẹ̀lú, sí ìbànújẹ́ àti ipohunrere-ẹkun àwọn olódodo.

34 Àwa sì ríi báyĩ pé àwọn ará Nífáì bẹ̀rẹ̀sí jó àjorẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, nwọ́n sì ndàgbà nínú ìwà búburú àti ìwà ẽrí, tí àwọn ará Lámánì sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà púpọ̀ nínú ìmọ̀ Ọlọ́run nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa àwọn ìlànà àti òfin mọ́, àti láti máa rìn nínú òtítọ́ àti ìdúróṣinṣin níwájú rẹ̀.

35 Báyĩ sì ni a ríi tí Ẹ̀mí Olúwa bẹ̀rẹ̀sí fà sẹ́hìn lọ́dọ̀ àwọn ará Nífáì, nítorí ìwà búburú àti ọkàn líle nwọn.

36 Báyĩ sì ni àwa ríi tí Olúwa bẹ̀rẹ̀sí da Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lé àwọn ará Lámánì lórí, nítorí ìrọ̀rùn àti ìfẹ́-inú nwọn làti gba ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́.

37 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì dọdẹ àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà Gádíátónì; nwọ́n sì nwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lãrín àwọn tí ó níwà búburú jùlọ nínú nwọn, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi pa àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà yĩ run pátápátá kúrò lãrín àwọn ará Lámánì.

38 Ó sì ṣe ní ìdà kejì, tí àwọn ará Nífáì mú nwọn gbèrú, nwọ́n sì ràn nwọ́n lọ́wọ́, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn tí ó burú jù nínú nwọn, títí nwọ́n fi tàn ká gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Nífáì, tí nwọ́n sì ti kó sínú púpọ̀ nínú àwọn olódodo títí nwọ fi gba ìṣe nwọn gbọ́ tí nwọ́n sì nbá nwọn se àjọpín nínú ìkógun nwọn, àti láti darapọ̀ mọ́ nwọ́n nínú àwọn ìpànìyàn àti ìkójọpọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ nwọn.

39 Báyĩ sì ni nwọ́n gba gbogbo àkóso ìjọba nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì tẹ àwọn tálákà àti àwọn ọlọ́kàn tútù, àti àwọn onírẹ̀lẹ̀ tí nwọn ntẹ̀lé Ọlọ́run mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ nwọn tí nwọ́n sì nlù nwọ́n, tí nwọ́n sì nfìyà jẹ nwọ́n tí nwọ́n sì se àkíyèsí nwọn.

40 Báyĩ àwa sì ríi pé nwọ́n wà ní ipò tí ó burú, tí nwọ́n sì nmúrasílẹ̀ de ìparun ayérayé.

41 Ó sì ṣe tí ọdún kejìdínlãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí báyĩ.