Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 3


Orí 3

Arákùnrin Járẹ́dì rí ìka Olúwa bí ó ṣe nfọwọ́kàn àwọn òkúta wẹ́wẹ́ mẹ́rìndínlógún—Krístì fí ara rẹ̀ ní ẹ̀mí hàn arákùnrin Járẹ́dì—Á kò lè dènà mọ́ àwọn ẹniti ó ni ìmọ̀ pípé láti dá ìbòjú kọjá—Olúwa pèsè àwọn olùtúmọ̀ láti sọ àkọsílẹ̀ àwọn ara Járẹ́dì di mímọ̀.

1 Ó sì ṣe tí arákùnrin Járẹ́dì, (nísisìyí iye àwọn ọkọ̀ tí wọn tí pèsè jẹ́ mẹ́jọ) kọjá lọ sórí òkè, èyítí wọn npè ní òkè Ṣẹ́lẹ́mù, nítorítí ó ga púpọ̀, ó sì yọ́ òkúta wẹ́wẹ́ mẹ́rìndínlógún jáde láti inú òkúta nlá kan; wọ́n sì funfun wọ́n sì mọ́ gãra, àní bĩ dígí dídán gẽre; ó sì ko wọn nínú ọwọ́ rẹ̀ lórí òkè nã, ó sì tún kígbe pè Olúwa, wípé:

2 A! Olúwa, ìwọ ti wí i pé àwọn ìró omi yíò yíwa ká. Nísisìyí kíyèsĩ, A! Olúwa, kí ó má sì ṣe bínú sí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ nitori àìlera rẹ̀ níwájú rẹ̀; nítorítí àwa mọ̀ pé mímọ́ ni ìwọ í ṣe, o sì ngbé nínú àwọn ọ̀run, àti pé àwa jẹ aláìtóye níwájú rẹ; nitori ìṣubú, ìwà wa jẹ́ èyítí ó burú títí; bíótilẹ̀ríbẹ̃, A! Olúwa, ìwọ ti fún wa ní òfin pé àwa gbọ́dọ̀ ké pè ọ́, kí àwa ó lè rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú wa.

3 Kíyèsĩ, A! Olúwa, ìwọ ti kọlũ wà nitori àìṣedẽdé wa, o sì ti lé wa kákiri, àti fun àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdun wọnyĩ ni áwa wà nínú aginjù; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ìwọ ti sãnú fún wa. A! Olúwa, bojú wò mi nínú ãnú, kí ó sì mú ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ yĩ, kí o má sì jẹ́ kí wọn ó dá òkun nlá yĩ kọjá nínú òkùnkùn; ṣùgbọ́n wò àwọn ohun wọ̀nyí tí èmi tí yọ́ láti ìnu òkúta.

4 Ẹmí sì mọ̀, A! Olúwa, pé ìwọ ní gbogbo agbara, ìwọ sì lè ṣe ohunkóhun tí ó bá wù ọ́ fún ànfàní ènìyàn; nitorinã fọwọ́kàn àwọn òkúta wẹ́wẹ́ yĩ, A! Olúwa, pẹ̀lú ìka rẹ, kí ó sì ṣé wọn kí wọn ó lè máa tàn ìmọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn; wọn yíò sì tàn ìmọ́lẹ̀ fún wa nínú àwọn ọkọ̀ tí àwa ti pèsè, kí àwa ó lè ní ìmọ́lẹ̀ nígbàtí àwa yíò kọ́já nínú òkun nã.

5 Kíyèsĩ, A! Olúwa, ìwọ lè ṣe èyí. Àwa mọ̀ pé ìwọ lè fi agbára nlá hàn, èyítí ó dàbíi pé o kere sí òye àwọn ọmọ ènìyàn.

6 O sì ṣe nígbàtí arákùnrin Járẹ́dì ti sọ àwọn ọrọ wọ̀nyí, kíyèsĩ, Olúwa nà ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì fọwọ́kàn àwọn òkúta wẹ́wẹ́ nã pẹ̀lú ìka rẹ̀ lọ́kọ̃kan. Ìbòjú sì ká kúrò lójú arákùnrin Járẹ́dì, ó sì rí ìka Olúwa; ó sì dabi ìka ènìyàn, tí o ni ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀; arákùnrin Járẹ́dì sì wólulẹ̀ níwájú Òluwa, nítorítí ìbẹ̀rù bõ mọ́lẹ̀.

7 Olúwa sì rí i pé arákùnrin Járẹ́dì ti ṣubú lulẹ̀; Olúwa sì wì fún un pé: Dìde, kíni ìdí rẹ̀ ti ìwọ ṣe ṣubú?

8 O sì wí fún Olúwa pé: Mo rí ìka Olúwa, ẹ̀rù sì bà mí pé yíò kọlũ mí; nítorítí emí kò mọ̀ pé Olúwa ní ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀.

9 Olúwa sì wí fún un pe: Nitori ìgbàgbọ́ rẹ ìwọ ti rí i pé èmi yíò gbé ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ wọ̀; kò sì sí ẹnití ó wa sí iwájú mí pẹ̀lú ìrú ìgbàgbọ́ tí ó tayọ báyĩ rí bí ìwọ ti ṣe; nítorí bí kò bá rí bẹ̃ ìwọ kì bá tí rí ìka mi. Njẹ ìwọ ha rí ju èyí bí?

10 O sì dáhùn pé: Rara; Olúwa, fi ara rẹ hàn sí mi.

11 Olúwa sì wí fún un pé: Njẹ ìwọ yíò ha gba àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi yíò sọ gbọ́ bí?

12 O sì dáhùn pé: Bẹ̃ni, Olúwa, emí mọ̀ pé òtítọ́ ní ìwọ nwí, nítorípé Ọlọ́run òtítọ́ ní ìwọ í ṣe, ìwọ kò sì lè purọ́.

13 Nígbàtí ó sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ẹ kíyèsĩ, Olúwa fí ara rẹ̀ hàn sí i, ó sì wípé: Nítorípé ìwọ mọ̀ àwọn ohun wọ̀nyí, a rà ọ́ padà kúrò nínú ìṣubú; nítorinã a mú ọ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi; nitorinã èmi fi ara mi hàn sí ọ.

14 Kíyèsĩ, èmi ni ẹni ti a pèsè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé láti rà àwọn ènìyàn mi padà. Kíyèsĩ, èmi ni Jésù Krístì. Emí ni Bàbá àti Ọmọ. Nínú mi ni gbogbo ènìyàn yiò ní ìyè, èyítí ó wà fún ayérayé, àní àwọn tí yíò gbà orúkọ mi gbọ́; wọn yíò sì dì ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi.

15 Èmi kò sì fi ara mi hàn fún ènìyàn tí emí dá rí, nítorítí ènìyàn ko gbà mi gbọ́ rí gẹ́gẹ́bí ìwọ ti ṣe. Njẹ ìwọ ha rí i pé a dá ọ ní àwòrán ara mi bí? Bẹ̃ni, àní gbogbo ènìyàn ni a dá ní àtètèkọ́ṣe ní àwòrán ara mi.

16 Kíyèsĩ, ara yĩ, èyíti ìwọ nwò yĩ, jẹ́ ara ti ẹ̀mí mi; mo sì dá ènìyàn ní àwòrán ara ti ẹ̀mí mi; àní gẹ́gẹ́bí èmi sì ti farahàn sí ọ ní ti ẹ̀mí ni èmi ó farahàn sí àwọn ènìyàn mi ní ti ara.

17 Àti nísisìyí, nítorípé emí, Mórónì, ti ṣọ wípé emí kò lè ṣe àkọsílẹ̀ nipa àwọn ohun tí wọ́n ti kọ wọ̀nyí, nitorinã ó tó fún mi kí èmi ó wípé Jesu fi ara rẹ̀ han sí ọkunrin yĩ nítí ẹ̀mí, àní gẹgẹbi ó ti farahàn nínú ara kánnã sí àwọn ará Nífáì.

18 O sì jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún un àní gẹ́gẹ́bí ó ti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ara Nífáì; gbogbo èyí ni ó ṣe, kí ọkunrin yĩ lè mọ̀ pé Ọlọ́run ni oun í ṣe, nitori àwọn iṣẹ́ nlá-nlà tí Olúwa ti fi hàn sí i.

19 Àti nítorí ìmọ̀ tí ọkùnrin yĩ ní a kò lè dènà mọ́ ọ láti bojúwò láti inu ìbòjú nã; ó sì ri ìka Jésù, nígbàtí ó sì ríi, ó ṣubú nínú ẹ̀rù; nítorítí ó mọ̀ pé ìka Olúwa ni; kò sì gbàgbọ́ nì kan, nítorítí ó mọ̀, ní áìṣiyèméjì ohunkóhun mọ.

20 Nítorí eyi, nítorípé ó ní imọ pipe nipa Ọlọ́run, a kò lè dènà mọ́ ọ kúrò nínú ìbòjú; nítorínã ó rí Jesu; òn sì jíṣẹ́ iranṣẹ fún un.

21 O sì se ti Olúwa wí fún arákùnrin Járẹ́dì pé: Kíyèsĩ, ìwọ́ kì yíò jẹ́ kí àwọn ohun wọnyĩ tí ìwọ ti ri àti ti ìwọ ti gbọ kọ́já lọ́ sínú ayé, títí di akòkò tí mbọ̀wá tí èmí yíò ṣe orúkọ mi lógo nípà ti ara; nítorí eyi, ìwọ yio pa àwọn ohun wọ̀nyí ti ìwọ ti ri àti tí ìwọ ti gbọ mọ́ nínú ọkàn rẹ, kí ìwọ má sì ṣe fíhàn ẹnikẹ́ni.

22 Sì kíyèsĩ, nígbàtí ìwọ yíò wá sí ọ̀dọ̀ mi, ìwọ yíò kọ wọ́n, ìwọ yíò sì fi èdìdí dì wọ́n, kí ẹnikẹ́ni ó má lè ṣe ìtumọ̀ wọn; nítorítí ìwọ yíò kọ wọ́n ní èdè ti ẹnikẹ́ni kò lè kà.

23 Sì kíyèsĩ, àwọn òkúta méjì yĩ ni emí yíò fi fún ọ, ìwọ yíò sì fi èdìdí dì àwọn nã pẹ̀lú àwọn ohun tí ìwọ yíò kọ.

24 Nítorí kíyèsĩ, èdè tí ìwọ yíò kọ ní emí ti dàrú; nítorí èyí ní emí yíò mú kí àwọn òkúta wẹ́wẹ́ yĩ mú àwọn ohun ti ìwọ yíò kọ tobi ní ojú àwọn ènìyàn nígbàtí àkókò bá tó fun mi.

25 Nígbàtí Olúwa sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọnyĩ, ó fi í hàn sí arákùnrin Járẹ́dì, gbogbo àwọn ẹnití ngbé inu ayé, ní tẹlẹri, àti gbogbo àwọn tí yíò gbé inu rẹ; kò sì dènà mọ́ ọ láti rí wọn, àní títí dé ìkangun ayé.

26 Nítorí ó ti wí fún un ní àwọn àkókò ìṣãjú, pé tí ó bá gbà òun gbọ́ òun lè fí ohun gbogbo hàn án—a ó sì fi wọn hàn án; nítorínã Olúwa kò lè dènà ohunkóhun mọ́ ọ, nítorítí ó mọ̀ pé Olúwa lè fi ohun gbogbo hàn sí oun.

27 Olúwa sì wí fún un pe: Kọ àwọn ohun wọnyĩ kí ó sì dì wọ́n ni èdìdí; èmi yíò sì fi wọ́n hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn nígbàtí àkókò bá tó fún mi.

28 O sì ṣe tí Olúwa pàṣẹ fún un láti dì àwọn okuta wẹ́wẹ́ méjì nã èyítí ó ti gbà ní èdìdí, kí ó má sì fi wọ́n hàn, titi Olúwa yíò fi wọ́n hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn.