Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 10


Ori 10

Léhì sọtẹ́lẹ̀ pé àwọn Jũ ni a ó mú ní ìgbèkùn nípasẹ̀ àwọn ará Bábílọ́nì—Ó sọ nípa bíbọ̀ Messia kan, Olùgbàlà àti Olùràpadà lãrín àwọn Jũ—Léhì sọ pẹ̀lú nípa bíbọ̀ ẹni tí yíò rì Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run nã bọmi—Léhì sọ nípa ikú àti àjínde òkú ti Messia nã—Ó fi títúká àti kíkójọ Ísráẹ́lì wé igi ólífì—Nífáì sọ nípa Ọmọ Ọlọ́run, nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti nípa ṣíṣe òdodo. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí èmi, Nífáì tẹ̀ síwájú láti kọ ìwé ìtàn àwọn íṣe mi, àti ìjọba àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi sórí àwọn àwo wọ̀nyí; nítorí-èyi, láti tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìwé ìtàn tèmi, mo gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn ohun ti bàbá mi, àti ti àwọn árákùnrin mi pẹ̀lú.

2 Nítorí kíyèsĩ i, ó ṣe lẹ́hìn tí bàbá mi ti parí sísọ àwọn ọ̀rọ̀ àlá rẹ̀, àti gbígbà wọ́n níyànjú sí ãpọn ní ohun gbogbo pẹ̀lú, ó wí fún wọn nípa àwọn Jũ—

3 Wí pé lẹ́hìn tí a bá pa wọ́n run, àní Jerúsálẹ́mù ìlú nlá nì, tí a sì tí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ìgbèkùn lọ sí Bábílọ́nì, gẹ́gẹ́ bí àkókò tí ó yẹ níti Olúwa, wọn yíò tún padà, bẹ̃ni, àní a ó mú wọn padà jáde ní ìgbèkun; lẹ́hìn tí a bá sì mú wọn padà jáde ní ìgbèkun wọn yíò tún gba ilẹ̀ ìní wọn.

4 Bẹ̃ni, àní ní ẹgbẹ̀ta ọdún sí ìgbà tí bàbá mi kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wòlĩ kan ni Olúwa Ọlọ́run yíò gbé dìde lãrín àwọn Jũ—àní Messia kan, tàbí, ní ọ̀nà míràn, Olùgbàlà ayé.

5 Ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú nípa àwọn wòlĩ, bí púpọ̀ ní iye wọn ti jẹ́rĩ sí àwọn ohun wọ̀nyí, nípa Messia yĩ, ẹni tí òun ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, tàbí Olùràpadà ayé yĩ.

6 Nítorí-èyi, gbogbo aráyé wà ní ipò ìsọnù àti ti ìṣubú, wọn ó sì wà bẹ̃ láé àfi tí wọ́n bá gbíyèlé Olùràpadà yĩ.

7 Ó sì wí nípa wòlĩ kan ẹni tí yíò wá ṣíwáju Messia nã, láti tún ọ̀nà Olúwa ṣe—

8 Bẹ̃ni, àní òun yíò jáde lọ yíò sì kígbe ní ijù: Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ sì ṣe ojú-ọ̀nà rẹ̀ tọ́; nítorí ọ̀kan dúró lãrín yín ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀; òun sì lágbára jù mí lọ, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò yẹ láti tú. Púpọ̀ sì ni ohun tí bàbá mi sọ nípa nkan yĩ.

9 Bàbá mi sì sọ wí pé yíò rìnibọmi ní Bẹtabárà, níkọjá Jordánì; ó sì sọ pẹ̀lú pé yíò rìnibọmi pẹ̀lú omi, àní wí pé yíò ṣe ìrìbọmi fun Messia nã pẹ̀lú omi.

10 Àti lẹ́hìn tí ó bá ti ṣe ìrìbọmi fun Messia nã pẹ̀lú omi, yíò jẹ́wọ́ yíò sì jẹ́rĩ wí pé òun ti ri Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run bọmi, ẹni tí yíò mú ẹ̀sẹ̀ ayé lọ.

11 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí bàbá mi ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sọ̀rọ̀ sí àwọn arákùnrin mi nípa ìhìn-rere èyí tí a ó wãsù lãrín àwọn Jũ, àti pẹ̀lú nípa rirẹhin àwọn Jũ nínú ìgbàgbọ́. Lẹ́hìn tí wọ́n bá ti pa Messia nã, ẹni tí yíò wá, lẹ́hìn tí a bá sì ti pa á òun yíò jínde kúrò nínú òkú, yíò sì fi ara rẹ̀ hàn, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, sí àwọn Kèfèrì.

12 Bẹ̃ni, àní bàbá mi sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa àwọn Kèfèrí àti nípa ará ilé Ísráẹ́lì pẹ̀lú, wí pé wọn yíò rí bí igi ólífì, ẹ̀ka èyí tí a ó ṣẹ́ kúrò tí a ó sì túká sórí gbogbo ojú-ilẹ̀ àgbáyé.

13 Nítorí-èyi, ó sọ pé ó ṣe dandan pé kí a tọ́ wa pẹ̀lú ọkàn kan sínú ilẹ̀ ìlérí sí mímú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ, wípé a ó tú wa ká sórí gbogbo ojú-ilẹ̀ àgbáyé.

14 Lẹ́hìn tí a bá sì ti tú ará ilé Ísráẹ́lì ká a ó tún kó wọn jọ; tàbí, ní ṣókí, lẹ́hìn tí àwọn Kèfèrí bá ti gba ẹ̀kún Ìhìn-rere ẹká àdánidá igi ólífi nã, tàbí àwọn ìyókù ará ilé Ísráẹ́lì, ni a ó lọ́ sínú igi nã, tàbí wá sí ìmọ̀ Messia òtítọ́, Olúwa wọn àti Olùràpadà wọn.

15 Irú èdè báyĩ sì ni bàbá mi fi sọtẹ́lẹ̀ tí ó sì sọ̀rọ̀ sí àwọn arákùnrin mi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun sí i pẹ̀lú èyí tí èmi kò kọ sínú ìwé yĩ; nítorí ó ti kọ púpọ̀ tí ó jẹ́ yíyẹ fún mi nínú ìwé mi míràn.

16 Gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí, èyí tí mo ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ni a sì ṣe nígbà tí bàbá mi n gbé nínú àgọ́, ní àfonífojì Lẹ́múẹ́lì.

17 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi, Nífáì, tí mo ti gbọ́ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi, nípa àwọn ohun tí ó rí nínú ìran, àti pẹ̀lú àwọn ohun tí ó sọ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, agbára èyí tí ó gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run—Ọmọ Ọlọ́run nã sì jẹ́ Messia tí yíò wá—èmi, Nífáì, nífẹ pẹ̀lú pé kí èmi lè rí, kí n gbọ́, kí n sì mọ̀ nípa àwọn nkan wọ̀nyí, nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run fún gbogbo àwọn tí ó bá wá a lójúméjẽjì, gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà àtijọ́ àti bí ti ìgbà tí yíò fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn.

18 Nítorí ó jẹ́ ọ̀kan nã ní áná, ní óní, àti títí láé; a sì ti pèsè ọ̀nà fún gbogbo ènìyàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wa, bí ó bá ṣe pé wọ́n ronúpìwàdà tí wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

19 Nítorí ẹni tí ó bá wá lójúméjẽjì yíò rí; ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run ni a ó sì fihàn sí wọn, nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, ní ìgbà yí gẹ́gẹ́ bí ìgbà àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà àtijọ́ bí ìgbà tí nbọ; nítorí-èyi ipa ọ̀nà Olúwa jẹ́ ọ̀nà àìyípadà ayérayé kan.

20 Nítorínã rántí, A! ọmọ ènìyàn, fún gbogbo ìṣe rẹ a o mú ọ wá sínú ìdájọ́.

21 Nítorí-èyi, bí ìwọ bá ti wá láti ṣe búburú ní ìgbà ayé-ìdánwò rẹ, njẹ́ a ó rí ọ ní àìmọ́ níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run; ohun àìmọ́ kan kò sì lè gbé pẹ̀lú Ọlọ́run; nítorí-èyi a ó ta ọ́ nù títí láé.

22 Ẹ̀mí Mímọ́ sì fún mi ní àṣẹ pe ki n sọ àwọn nkan wọ̀nyí, kí n má si ṣe sẹ́ wọn.