Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Yọ̀ nínú Ẹ̀bùn àwọn Kọ́kọ́rọ́ Oyè-àlùfáà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Ẹ Yọ̀ nínú Ẹ̀bùn àwọn Kọ́kọ́rọ́ Oyè-àlùfáà

Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà nṣe àkóso bí a fi lè lo oyè-àlùfáà Ọlọ́run láti mú àwọn èrèdí Olúwa wá àti láti bùkún ẹnítí ó bá tẹ́wọ́gba ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, òní ni ọjọ́ onítàn fún Ààrẹ Dallin H. Oaks àti èmi. Ó jẹ́ Ogójì ọdún sẹ́hìn, ní Ọjọ́ Kéje Oṣù Kẹ́rin, 1984, nígbàtí a ṣe ìmúdúró wá sí Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá. A ti ní ayọ̀ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àti gbogbo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò sẹ́hìn, pẹ̀lú èyì í. Lẹ́ẹ̀kansi a ti di alábùkúnfún pẹ̀lú ìtújáde mímọ́ ti Ẹ̀mí. Mo ní ìrètí pé ẹ ó ṣe àṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé apapọ̀ yí léraléra ní àwọn oṣù tó mbọ̀.

Nígbàtí a bí mi, àwọn tẹ́mpìlì mẹ́fà ni ó nṣiṣẹ́ nínú Ìjọ—ọ̀kọ̀ọ̀kan ní St. George, Logan, Manti, àti Salt Lake City, Utah; bákannáà ní Cardston, Alberta, Canada; àti Laie, Hawaii. Àwọn tẹ́mpìlì méjì ìṣíwájú ti ṣiṣẹ́ ránpẹ́ ní Kirtland, Ohio, àti Nauvoo, Illinois. Bí ara Ìjọ ti nkó lọ ìwọ̀-òòrùn, àwọn Ènìyàn Mímọ́ ni a fi ipá mú láti fi àwọn tẹ́mpìlì méjì náà sílẹ̀ sẹ́hìn.

Tẹ́mpìlì Nauvoo ni a parun láti ọwọ́ àwọn afinájólé. A tunkọ́ àti pé lẹ́hìnáà a sì yàá sí nípasẹ̀ Ààrẹ Gordon B. Hinckley. Tẹ́mpìlì Kirtland ni a sọ di àìmọ́ láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá Ìjọ. Lẹ́hìnnáà Tẹ́mpìlì Kirtland ni a gbà nípasẹ̀ Iletò Krístì, èyí tí ó ni ní ìní fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.

Ní oṣù tó kọjá a kéde pé Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti ra Tẹ́mpìlì Kirtland, lẹgbẹ pẹ̀lú onírurú àwọn ibi onítàn pàtàkì ní Nauvoo. A dúpẹ́ gidigidi fún àwọn èrè ìbárasọ̀rọ̀ ìbárẹ́ àti ìbámu tí a ní pẹ̀lú àwọn olórí láti Ìletò Krístì tí ó darí sí àdéhùn yí.

Àwòrán
Tẹ́mpìlì Kirtland.

Tẹ́mpìlì Kirtland ní ó ní pàtàkì àìwọ́pọ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì nínú. Àwọn onírurú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ni a ti sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún tí ó sì jẹ́ kókó fún Ìjọ Olúwa tí a múpadàbọ̀sípò àti láti mú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọjọ́-ìkẹhìn ṣẹ.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì jùlọ ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọdún Àjínde, Ọjọ́ Kẹta Oṣù Kẹ́rin, 1836. Ní ọjọ́ náà, Joseph Smith àti Oliver Cowdery ní ìrírí oríṣirírṣi nípa àwọn ìbẹ̀wò alámì. Àkọ́kọ́, Olúwa Jésù Krístì farahàn. Wòlíì kọ àkọsílẹ̀ pé ojú Olùgbàlà “dàbí ọ̀wọ́ iná; irun orí rẹ̀ funfun bíi ìrì dídì tí kò ní èérí; ìwò ojú rẹ̀ tàn kọjá ìtànṣán oòrùn; àti pé ohùn rẹ̀ dàbíi ìró omi púpọ̀.”

Ní ìgbà ìbẹ̀wò yí, Olúwa tẹnumọ ìdánimọ̀ Rẹ̀. Ó wípé,“Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ikẹhìn; Èmi ni ẹni náà tí ó wà láàyè, èmi ni alágbàwí yín pẹ̀lú Bàbá.”

Jésù Krístì kéde pé Òun ti tẹ́wọ́gba tẹ́mpìlì náà bí ilé Òun ó sì ṣe ìlérí tí ó wọnilára yí pé: “Èmi ó fi ara mi hàn sí àwọn ènìyàn mi nínú àánú nínú ilé yí.”

Ìlérí pàtàkì yi ti wúlò sí gbogbo tẹ́mpìlì tí a yàsímímọ́ ní òní. Mo pè yín láti jíròrò ohun tí ìlérí Olúwa túmọ̀sí fún yín nìti-araẹni.

Títẹ̀lé ìbẹ̀wò Olùgbàlà, Mósè farahàn. Mósè fi àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkójọ Ísráẹ́lì àti ìpadàbọ̀ àwọn ẹ̀yà mẹwa sórí Joseph Smith.

Nígbàtí ìran yí parí, “Elias farahàn, ó sì fi àkokò iṣẹ́ ìríjú ti ìhìnrere Abraham” fún Joseph.

Lẹ́hìnnáà wòlíì Elijah farahàn. Ìfarahàn rẹ̀ mú ìlérí Malachi ṣẹ pé ṣíwájú Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì, Olúwa yíò rán Elijah láti “yí ọkàn àwọn baba padà sí àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sí baba wọn.” Lẹ́hìnnáà Elijah fi àwọn kọ́kọ́rọ́ agbára èdidì lé Joseph Smith lorí.

Pàtàkì àwọn kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyí ní pípadà sí ayé nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ àtọ̀runwá mẹ́ta lábẹ́ ìdarí Olúwa ni a kò lè sọjù. Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà ni ó ní àṣẹ àti agbára àjọ ààrẹ ìkínní nínú. Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà nṣe àkóso bí a ṣe lè lo oyè-àlùfáà Ọlọ́run láti mú àwọn èrèdí Olúwa wá àti láti bùkún ẹní tí ó bá tẹ́wọ́gba ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì.

Ó ṣe pàtàkì láti kíyèsi pé ṣíwájú ìṣètò Ìjọ, àwọn ìránṣẹ́ àtọ̀runwá ti fi àwọn Oyè-àlùfáà Árọ́nì àti Mẹ́lkisẹ́dẹ́kì lé orí Wòlíì Joseph wọ́n sì ti fún un ní àwọn kọ́kọ́rọ́ fún àwọn oyè-àlùfáà méjèèjì. Àwọn kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyí fún Joseph Smith ní àṣẹ láti ṣètò Ìjọ ní 1830.

Nígbànáà ní Tẹ́mpìlì Kirtland ní 1836, olùfúnni àfikún àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà mẹ́ta—tí a dárúkọ, àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkójọ Ísráẹ́lì, àwọn kọ́kọ́rọ́ ìhìnrere Abraham, àti àwọn kọ́kọ́rọ́ agbára èdidì—ṣe pàtàkì. Àwọn kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyí fi àṣẹ fún Joseph Smith—àti gbogbo àwọn Ààrẹ Ìjọ Olúwa tí ó ntẹ̀le—láti kó Ísráẹ́lì jọ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkelè, láti bùkún gbogbo àwọn ọmọ májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ìbùkún Abraham, láti fi èdidì dì sí àwọn ìlànà àti májẹ̀mú oyè-àlùfáà, àti láti fi èdidì dì sí ẹbí ayérayé. Agbára àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà wọ̀nyí jẹ́ àìlópin àti alámì.

Ẹ ronú bí ayé yín yíò ti yàtọ̀ bí a kò bà ti mú àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà padàbọ̀ wá sí ayé. Láìsí àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà, a kò lè fún yín ní ẹ̀bùn agbára Ọlọ́run. Láìsí àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà, Ìjọ kàn lè dúró bí ìkọ́ni pàtàkì kan àti ìṣètò arannilọ́wọ́ ṣùgbọ́n kìí ṣe púpọ̀ si. Láìsí àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà, kò sí lára wa tí ó ní àyè sí àwọn ìlànà àti májẹ̀mú pàtàkì tí ó dè wá mọ́ àwọn olólùfẹ́ wa títí ayérayé tí ó sì fi àyè gbà wá nígbẹ̀hìn láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run.

Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà mú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn yàtọ̀ kúrò ní eyikeyi ìṣètò míràn ní ayé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣètò míràn ó sì máa mú ayé yín dára si nihin nínú ayé ikú. Ṣùgbọ́n kò sí ìṣètò míràn tí ó àti tí yíò fún ayé yín ní ipá lẹ́hìn ikú.

Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà nfún wa ní àṣẹ láti na àwọn ìbùkún tí a ṣe ìlérí rẹ̀ fún Abraham sí gbogbo ọkùnrin àti obìnrin olùpamọ́ májẹ̀mú. Iṣẹ́ Tẹ́mpìlì nmú kí àwọn ìbùkún títayọ wọ̀nyí wá fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run, láìka ibití tàbí ìgbàtí wọ́n ti gbé, tàbí ngbé nisisìyí sí. Ẹ jẹ́ kí a yọ̀ pé àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà ti wà nílẹ̀-ayé lẹ́ẹ̀kansi!

Mo pè yín láti yẹ àwọn ẹ̀là-ọ̀rọ̀ mẹ́ta wọ̀nyí wò pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.

  1. Ìkọ́jọ Ísráẹ́lì ni ẹ̀rí pé Ọlọ́run fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ níbigbogbo.

  2. Ìhìnrere Abraham ni ẹ̀rí síwájú síi pé Ọlọ́run fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ níbigbogbo. Ó npe gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀—“dúdú àti funfun, ìdè àti òmìnira, akọ àti abo; … gbogbo ènìyàn jẹ́ bákannáà sí Ọlọ́run.”

  3. Agbára èdidì ni ẹ̀rí gígajùlọ nípa bí Ọlọ́run ti fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ tí ó sì fẹ́ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wọn ó yàn láti padà sílé sọ́dọ̀ Rẹ̀.

Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà tí a múpadàbọ̀sípò nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith mu ṣeéṣe fún gbogbo ọkùnrin àti obìnrin olùpamọ́ májẹ̀mú láti gbádùn àwọn ànfàní araẹni àgbàyanu ti ẹ̀mí. Nihin lẹ́ẹ̀kansi, púpọ̀ wà láti kọ́ látinú àkọọ́lẹ̀ ìtàn mímọ́ ti Tẹ́mpìlì Kirtland.

Àdúrà ìyàsímímọ́ ti Joseph Smith nípa Tẹ́mpìlì Kirtland jẹ́ nípa ikẹkọ nípa bí tẹ́mpìlì ti nfi agbára fún yín àti èmi níti-ẹ̀mí láti bá àwọn ìpènijà ìgbésí ayé wa pàdé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí. Mo gbà yín níyànjú láti ṣe àṣàrò àdúrà náà tí a kọsílẹ̀ nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ìpín 109. Àdúrà ìyàsímímọ́ náà, èyí tí a gbà nípa ìfihàn, kọ́ni pé tẹ́mpìli ni “ilé àdúrà, ilé àwẹ̀, ilé ìgbàgbọ́, ilé ikẹkọ, ilé ògo, ilé ètò, ilé Ọlọ́run.”

Ìtosílẹ̀ àwọn ìhùwàsí yí pọ̀ púpọ̀ ju ìjúwe nípa tẹ́mpìlì. Ó jẹ́ ìlérí nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn wọnnì tí wọ́n nsìn tí wọ́n sì njọ́sìn nínú ilé Olúwa. Wọ́n lè retí láti gba àwọn ìdáhùn sí àdúrà, ìfihàn araẹni, ìgbàgbọ́ títóbi, okun, ìtùnú, àlékún ìmọ̀, àti àlékún agbára.

Àkokò nínú tẹ́mpìlì yíò ràn yín lọ́wọ́ láti ronú sẹ̀lẹ́stíà àti láti ní ìran ẹni tí ẹ jẹ́ lódodo, ẹnití ẹ lè dà, àti irú ayé tí ẹ lè gbé títíláé. Ìjọsìn tẹ́mpìlì déédé yíò mú ọ̀nà tí ẹ fi nrí ara yín gbòòrò àti bí ẹ ti wà ní ìbámu sí ètò títóbijùlọ Ọlọ́run. Mo ṣe ìlérí fún yín pé.

Bákannáà a ṣe ìlérí fún wa pé nínú tẹ́mpìlì a lè “gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.” Ẹ ro ohun ìlérí túmọ̀ sí níti jíjẹ́ kí ọ̀run ṣí sílẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tó nfi ìtara wá òtítọ́ ayérayé .

Bákannáà a gba ìkọ́ni pé gbogbo ẹnití ó bá jọ́sìn nínú tẹ́mpìlì nlọ pẹ̀lú agbára Ọlọ́run àti pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì tí ó ní “àṣẹ lórí wọn.” Báwo ni ó ṣe mú ìgbẹ́kẹ̀lé yín pọ̀si sí láti mọ̀ pé, bí obìnrin tàbí ọkùnrin tó ní agbára ẹ̀bùn tí ó rọ̀mọ́ agbára Ọlọ́run, ẹ kò ní láti dá nìkan kojú ìgbé ayé. Kíni ìgboyà tí ó nfún yín láti mọ̀ pé àwọn ángẹ́lì yíò ràn yín lọ́wọ́ lódodo?

Ní òpin, a ṣe ìlérí fún wa pé “kò sí àpapọ̀ àwọn ẹni ibi” tí yíò borí àwọn wọnnì tí wọ́n njọ́sìn nínú ilé Olúwa.

Níní ìmọ̀ àwọn ànfàní ti-ẹ̀mí tí a mú ṣeéṣe nínú tẹ́mpìlì jẹ́ kókó sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lóni.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, nihin ni ìlérí mi. Kò sí ohun tí yíò ràn yín lọ́wọ́ ju láti ṣe ìdìmú yíyára sí ọ̀pá irin ju jíjọ́sìn nínú tẹ́mpìlì déédé bí ipò yín bá ti gbà. Kò sí ohun tí yíò dá ààbò bò yín julọ bí ẹ ti nkojú àwọn òkùnkùn ribiribi ayé. Kò sí ohun tí yíò ṣe ìgbélárugẹ ẹ̀rí yín nípa Olúwa Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ tàbí ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ ètò títóbi jùlọ Ọlọ́run síi. Kò sí ohun tí yíò tu ẹ̀mí yín lára síi ní àwọn ìgbà ìrora. Kò sí ohun tí yíò ṣí àwọn ọ̀run síi. Kò sí!

Tẹ́mpìlì ni ọ̀nà sí àwọn ìbùkún nlá jùlọ tí Ọlọ́run ní fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, nítorí tẹ́mpìlì ni ibì kanṣoṣo lórí ilẹ̀-ayé níbití a ti lè gba gbogbo àwọn ìbùkún tí a ṣe ìlérí fún Abraham. Èyí ni ìdí tí a fi nṣe ohun gbogbo ní ìkáwọ́ wa, lábẹ́ ìdarí Olúwa, láti mú kí àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì wa ní àrọ́wọ́tó sí àwọn ọmọ Ìjọ. Bayi, a ní inúdídùn láti kéde pé à nṣètò láti kọ́ tẹ́mpìlì titun kan sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbí mẹẹdogun wọ̀nyí:

  • Uturoa, French Polynesia

  • Chihuahua, Mexico

  • Florianópolis, Brazil

  • Rosario, Argentina

  • Edinburgh, Scotland

  • Brisbane, Australia agbègbè gúsù

  • Victoria, British Columbia

  • Yuma, Arizona

  • Houston, Texas agbègbè gúsù

  • Des Moines, Iowa

  • Cincinnati, Ohio

  • Honolulu, Hawaii

  • Ìlà-òòrùn Jordan, Utah

  • Lehi, Utah

  • Maracaibo, Venezuela

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, mo jẹri pé èyí ni Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Òun dúró ní orí rẹ̀. Àwa ni ọmọẹ̀hìn Rẹ̀.

Ẹ jẹ́ kí a yọ̀ nínú ìmúpadàbọ̀sípò àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà èyí tí o´ mu ṣeéṣe fún ẹ̀yin àti èmi láti gbádùn gbogbo ìbùkún ti-ẹ̀mí tí à nfẹ́ tí a sì yẹ láti gbà. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.