Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ó Jẹ́ Ọgbọ́n ninu Olúwa Pé Kí Àwa Ó Ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Ó Jẹ́ Ọgbọ́n ninu Olúwa Pé Kí Àwa Ó Ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì

Ó jẹ́ àdúrà mi pé kíka Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní ọdún yi yío jẹ́ ayọ̀ àti ìbùkún fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, a dúpẹ́ gan-an fún àwọn akitiyan yín ní kíka àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú Wá, Tẹ̀lé Mi. Ẹ ṣeun fún gbogbo ohun tí ẹ nṣe. Ìsopọ̀ yín ojojúmọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní àwọn àyọrísí tó jinlẹ̀. “Ẹ̀yin nfi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ nlá kan lélẹ̀. Nínú àwọn ohun kékeré ni èyí ti ó tóbi ti nwá.”

Kíka àwọn ìkọ́ni ti Olùgbàlà ninu àwọn ìwé mímọ́ nràn wá lọ́wọ́ láti yí àwọn ilé wa padà sí àwọn ibi mímọ́ ti ìgbàgbọ́ àti gbùngbùn ti kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere. Ó npè Ẹ̀mí sinú àwọn ilé wa. Ẹ̀mí Mímọ́ nkún inú ọkàn wa pẹ̀lú ayọ̀ ó sì nyí wa lọ́kàn padà sí àwọn ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì títí ìgbé ayé wa.

Ní ọ̀pọ̀ àwọn ọdún tó ti kọjá wọ̀nyí, nigbà kikà àwọn ìwé ti ìwé mímọ́, a ti ṣe àkíyèsí ìwòye ti àwọn ìkọ́ni Ọlọ́run sí àwọn ọmọ Rẹ̀ ninu púpọ̀ gbogbo àwọn ákókò iṣẹ́ ìríjú ìhìnrere.

Ní gbogbo àkókò iṣẹ́ ìríjú, a ti rí àwórán kan tó wọ́pọ̀. Ọlọ́run nmúpadàbọ̀sípò tàbí nfi ìhìnrere Jésù Krístì hàn nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀. Àwọn ènìyàn tẹ̀lé àwọn wòlíì a sì bùkún wọn lọ́pọ̀lọpọ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí àkókò ti nlọ, àwọn ènìyàn kan dáwọ́ dúró ní fífetísí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì wọ́n sì fa ara wọn jinnà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa àti ìhìnrere Rẹ̀. Èyí ni ohun tí a pè ní ìyapa kúrò nínú ìgbàgbọ́. Ìhìnrere náà ni a kọ́kọ́ fi hàn sí Ádámù, ṣùgbọ́n díẹ̀ ninu àwọn ọmọ Ádámù áti Éfà yípadà lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa ninú ìyapa. A rí àwòrán kan ti ìmúpadàbọ̀sípò àti ìyapa kúrò nínú ìgbàgbọ́ tí a túnṣe ní àwọn ákókò iṣẹ́ ìríjú ti Enọ́kù, Nóà, Ábráhámù, Mósè, àti àwọn míràn.

Nísisìyí, lóni, a ngbé ní ìgbà iṣẹ́ ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò. Èyí nìkan ni ákókò iṣẹ́ ìríjú tí kò ní parí ninu ìyapa kan kúrò nínú ìgbàgbọ́. Ó jẹ́ pé àkókò iṣẹ́ ìríjú yí ni yío mú Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olùgbàlà Jésù Krístì àti ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún Rẹ̀ wọlé.

Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kínni ó yàtọ̀ nípa àkókò iṣẹ́ ìríjú yí? Kínni Olúwa ti pèsè fún wa lóni, nípàtàkì fún àkókò wa, tí yío ràn wá lọ́wọ́ láti súnmọ́ Olùgbàlà si kí a má sì fi Í sílẹ̀ láé?

Ìdáhùn kan tí ó wa sí inú mi ni àwọn ìwé mímọ́—nípàtàkì Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Ẹrí Míràn ti Jésù Krístì.

Nígbàtí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé kò ní sí ìyapa kúrò nínú ìgbàgbọ́ káríayé míràn mọ́ láé, a nílò láti ní àfiyèsí kí a sì ṣọ́ra láti yẹra fún ìyapa kúrò nínú ìgbàgbọ́ ti araẹni ní—rírántí, bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni, pé “Olúkúlùlù wa ní ojúṣe fún ìdàgbàsókè ti ẹ̀mi ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.” Ṣíṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì, bí a ti nṣe ní ọdún yí, nfi ìgbà gbogbo mu wa wá sí itòsí Olùgbàlà síi—ó sì nrànwá lọ́wọ́ láti wà nítòsí Rẹ̀.

A pè é ní “àṣàrò,” eyí sì dára nitorípé ó ní akitiyan nínú. Ṣùgbọ́n a kò fi gbogbo ìgbà nílò láti kọ́ àwọn òtítọ́ titun. Nígbà míràn kíka Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ nípa kí a kàn ní ìmọ̀lára ìbáṣepọ̀ sí Ọlọ́run lóni—bíbọ́ ẹ̀mí, gbígba okun ti ẹ̀mí ṣáajú jíjáde lọ láti kojú àwọn aráyé, tàbí rírí ìwòsàn lẹ́hìn ọjọ́ kan tí kò dára tó ní òde ninu ayé.

A nṣe àsàrò àwọn ìwé mímọ́ kí Ẹ̀mí Mímọ́, olùkọ́ni nlá náà, ó le mú ìyípadà ọkàn wa jinlẹ̀ sí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì kí ó sì rànwá lọ́wọ́ láti dàbí Wọn síi.

Pẹ̀lú àwọn èrò wọ̀nyí ní inú, a le gbèrò, “Kínni Ẹ̀mí Mímọ́ ti kọ́ wa ni ọ̀sẹ̀ yí ninu àsàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì wa?” àti pé “Báwo ni èyí ti mú wa súnmọ́ Olùgbàlà sí?”

Ìwọ̀nyí ni àwọn ìbéèrè dáradára fún àṣàrò ìwé mímọ́ wa ni ilé. Bákannáà wọ́n jẹ́ àwọn ìbéèrè tó dárajùlọ láti bẹ̀rẹ̀ kíláàsì Ọjọ́ Ìsinmi ní ilé ìjọsìn. A ngbèrú síi ninu ìkọ́ni wa ni ilé-ijọsìn ni Ọjọ́ Ìsinmi nipa gbígbèrú síi ninu ikẹkọ wa ni ilé ní ààrin ọ̀sẹ̀. Nipa báyi, ninu àwọn kiláàsì wa Ọjọ́ Ìsinmi, “ẹnití nwàásù àti ẹnití ngbàá, ni òye ara wọn, àwọn méjèèjì si di gbígbega wọn sì yọ̀ papọ̀.”

Ìwọ̀nyí ni awọn ẹsẹ díẹ̀ tí Ẹ̀mi ti tẹ̀ mọ́ ọkàn mi làti inú àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti ọ̀sẹ̀ yí:

  • Néfì sọ fún Jákọ́bù láti “pa àwọn àwo wọ̀nyí mọ́ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ … láti ìran dé ìran. Bí ìwãsù bá sì wà èyítí ó jẹ́ mímọ́, tàbí ìfihàn … tàbí sísọtẹ́lẹ̀,” kí Jákọ́bù ó “fín … wọn sí orí àwọn àwo wọ̀nyí … fún ànfãní àwọn ènìyàn [wọn].”

  • Jákọ́bù jẹ́rìí lẹ́hìnwá pé, “A wá inú [awọn ìwé mímọ́], … àti pé nítorítí àwa ní gbogbo àwọn ẹlẹ́rìí wọ̀nyí a gba ìrètí kan, ìgbàgbọ́ wa sì di àìleyẹ̀.”

Nísisìyí, àwọn ẹsẹ wọ̀nyí mú mi ránti ohun ti Néfì sọ ṣaájú nípa àwọn àwo idẹ náà:

“A ti gba àwọn àkọsílẹ̀ nã … a sì ti yẹ̀ wọ́n wò fínni-fínni a sì ri pé wọ́n jẹ́ … iye nlá sí wa, tóbẹ́ẹ̀ tí àwa fi lè pa àwọn òfin Olúwa mọ́ fún àwọn ọmọ wa.

“Nítorí-èyi, ó jẹ́ ọgbọ́n nínú Olúwa pé kí á gbé wọn pẹ̀lú wa, bí a ṣe nrin ìrìn-àjò nínú ijù sí ìhà ilẹ̀ ìlérí.”

Nísisìyí, bí ó bá jẹ́ ọgbọ́n fún Léhì àti ẹbí rẹ̀ láti ní àwọn iwé mímọ́, ó jẹ́ ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún wa lóni. Ìtóye nlá ati agbára ti ẹ̀mí awọn ìwé mímọ́ ntẹ̀síwájú ni àìṣe-bàìbàì ninu ayé wa loni.

Ko tíì sí àwọn ènìyàn kan rí ninu ìtàn tí wọ́n ní ààyè sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti àwọn ìwé mímọ́ míràn tí àwa ngbádùn lóni. Bẹ́ẹ̀ni, Léhì àti ẹbí rẹ̀ jẹ́ alábùkúnfún fún làti gbé awọn àwo idẹ náà pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n wọn kò ní ẹ̀dà kan fún gbogbo àgọ́! Ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni ẹ̀dà ti araẹni wa. Ó jẹ́ ẹ̀dà tí a nkà.

Ninu ìran Léhì ti igi ìyè, Léhì kọ́ wa ní pàtàkì ìrírí ti araẹni pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. Lẹ́hìn tí ó jẹ ninu èso náà, Léhì rí ìyàwó rẹ̀, Sàríà, àti awọn ọmọkùnrin rẹ̀ Néfì ati Sámù ní ọ̀kánkán díẹ̀.

“Wọ́n dúró bí ẹnipé wọn kò mọ́ ibi tí wọn yíò lọ.

“… mo juwọ́ sí wọn,” ni Léhì sọ, “mo sì tún sọ fún wọn pẹ̀lú ohùn ariwo pé kí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí wọ́n ó sì jẹ nínú èso nã, èyí tí ó yẹ ní fífẹ́ tayọ gbogbo èso míràn.

“Ó sì ṣe … wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ mi wọ́n sì jẹ nínú èso náà.”

Mo fẹ́ràn àpẹrẹ Léhì nipa ṣíṣe òbí àtọkànwá. Sàríà, Néfì, àti Sámù ngbé ìgbé ayé dídára, ti òdodo. Ṣùgbọ́n Olúwa ní ohun dídárajù kan, ohun dídùnjù kan fún wọn. Wọn kò mọ ibi tí wọn ó ti rí i, ṣugbọ́n Léhì mọ̀. Nítorínáà, ó pè wọ́n, “pẹ̀lú ohùn ariwo,” láti wá sí ibi igi ìyè náà kí wọn ó sì jẹ ninu èso náà fún ara wọn. Ìdarí rẹ̀ ṣe kedere. Kò le sí èdè àìyédè kankan.

Èmi jẹ́ àmújáde ti irú ṣíṣe òbí àtọkànwá tí ó jọra bẹ́ẹ̀ kan. Nígbàtí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan, bóyá ọmọ ọdún mọ́kànlá tàbí méjìlá, ìyá mi bi mí léèrè pe, “Mark, njẹ́ o mọ̀ fún ara rẹ, nipa Ẹmí Mímọ́, pé ìhìnrere jẹ́ òtítọ́?”

Ìbéèrè rẹ̀ yà mí lẹ́nu. Mo ti máa nfi ìgbà gbogbo gbìyànjú láti jẹ́ “ọmọkùnrin rere,” mo sì rò pé eyí ti tó. Ṣùgbọ́n ìyá mi, bíi Léhì, mọ̀ pé mo nílò ohun kan síi. Mo nílò láti gbé ìgbésẹ̀ kí nsì mọ̀ fún ara mi.

Mo fèsì pé èmi kò tíì ní ìrírí náà síbẹ̀. Kò dàbí ẹnipé ẹnu yà á rárá nipa ìdáhùn mi.

Nígbànáà ó sọ ohun kan tí èmi kò tíì gbàgbé láé. Mo rántí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí di ọjọ́ òní pé: “Baba Ọ̀run fẹ́ kí o mọ̀ fún ara rẹ. Ṣùgbọ́n o gbọ́dọ̀ fi ìtiraka síi. O nílò láti ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì kí o sì gbàdúrà láti mọ̀ nípa Ẹmí Mímọ́. Baba Ọ̀run yíò dáhùn àwọn àdúrà rẹ.”

Ó dára, èmi kò tíì ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì rí tẹ̀lẹ̀. Èmi kò rò pé mo ti dàgbà tó láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyá mi mọ̀ dárajù

Ìbéèré rẹ̀ ṣáná ifẹ́ ninu mi lati mọ̀ fún ara mi.

Nítorínáà, ní alaalẹ́, ninu yàrá tí mo pín pẹ̀lú méjì ninu awọn aràkùnrin mi, mo máa tan iná tó wà ní òkè ibùsùn mi mo si máa ka orí kan ninu Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Lẹ́hìnnáà, ti mo bá ti pa iná, mo máa sún jáde kúrò ní ori ibùsùn mi si orí eékún mi n ó sì gbàdúrà. Mo gbàdurà ní tòótọ́ síi áti pẹ̀lú ifẹ́-inú gígajù ju bi mo ti nṣe ṣaáju. Mo sọ fún Baba Ọ̀run láti jọ̀wọ́ jẹ́ kí nmọ̀ nípa jíjẹ́ òtítọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Láti àkókò ti mo bẹ̀rẹ̀ kíka Ìwé Mọ́rmọ́nì, mo ní ìmọ̀lára pé Baba Ọ̀run mọ̀ nípa àwọn akitiyan mi. Mo sì ní ìmọ̀lára pé mo jámọ́ nkan sí I. Bí mo ti nkà tí mo sì ngbàdúrà, àwọn ìmọ̀lára ìtura, ti álàáfíà bà lé mi. Orí dé orí, ìmọ́lẹ̀ ìgbàgbọ́ ndàgbà ní títàn síi ní inú ọkàn mi. Lẹ́hìn àkókò díẹ̀, mo ríi pé àwọn ìmọ̀lára wọnyí jẹ́ àwọn ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ẹmí Mímọ́. Mo wá mọ̀ fún ara mi pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́, àti pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà aráyé. Mo ti ní ìmoore tó fún ìfipè onímisí ti ìyá mi.

Ìrírí kíka Ìwé ti Mọ́mọ́nì yí bí ọmọdé-kùnrin bẹ̀rẹ̀ àwórán kan ti àṣàrò ìwé-mímọ́ tí ó tẹ̀síwájú lati máa bùkún mi títí di ọjọ́ òní. Mo ṣì nka Ìwé ti Mọ́mọ́nì mo sì nkúnlẹ̀ ninu àdúrà síbẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ sì nfi ẹsẹ̀ áwọn òtítọ́ rẹ̀ múlẹ̀ ní àtúnṣe àti àtúnṣe lẹ́ẹ̀kansíi.

Néfì sọ ọ́ dáradára. Ó jẹ́ ọgbọ́n ninu Olúwa pé kí àwa ó gbé àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú wa jákèjádò ìgbé ayé wa. Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ “òkúta-pàtàkì” tí ó mu àkókò iṣẹ ìríjú yí yàtọ̀ sí gbogbo àwọn àkókò iṣẹ ìríjú ti ìṣaájú. Bí a ti nṣe àṣàro Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti a sì ntẹ̀lé wòlíì alàyè, ko ní sí ìyapa kúrò nínú ìgbàgbọ́ ti araẹni ninu ayé wa.

Ìfipè láti wá sí ibi igi ìyè nipa dídi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú dain-dain kìí ṣe ìfipè kan lásán láti ọ̀dọ̀ Léhì sí ẹbí rẹ̀, àti pé kìí ṣe ìfipè kan lásán láti ọ̀dọ̀ ìyá mi fún èmi láti kà kí nsì gbàdúrà nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó jẹ́ ìfipè kan bákannáà láti ọ̀dọ̀ wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa.

“Mo ṣe ìlérí.” ni ó sọ, “pé bí ẹ ṣe nfi tàdúràtàdúrà ṣe àṣarò Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójojúmọ́, ẹ ó ṣe àwọn ìpinnu dídára sí i—lójojúmọ́. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ṣe njíròrò ohun tí ẹ ṣe àṣàrò rẹ̀, àwọn fèrèsé ọ̀run yíò ṣí sílẹ̀, ẹ ó sì gba àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè ti ara yín àti ìdarí fún ìgbé ayé ti ara yín.”

Ó jẹ́ àdúrà mi pé kíka Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní ọdún yi yío jẹ́ ayọ̀ àti ìbùkún fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa yío sì máa fà wá súnmọ́ Olùgbàlà.

Baba Ọ̀run wà láàyè. Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nínú ó sì nfúnni ní ifẹ́ Rẹ̀. Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì alààyè ti Olúwa lórí ilẹ̀ ayé loni. Mo mọ àwọn ohun wọ̀nyí pé wọ́n jẹ́ òtítọ́ nítorí ẹ̀ri fífẹsẹ̀múlẹ̀ ti Ẹmí Mímọ́, èyítí mo kọ́kọ́ gbà nígbàtí mo nka Ìwé ti Mọ́mọ́nì bi ọmọdé-kùnrin kan. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 64:33.

  2. “Ohun èlò ìkẹ̀kọ̀ọ́ titun nínú ilé, tí ó ní àtìlẹhìn-Ìjọ ní agbára-ìleṣe láti ṣí agbára awọn ẹbí sílẹ̀, bí ẹbí kọ̀ọ̀kan ti ntẹ̀lé e tọkàntọkàn àti pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láti yí ilé wọn padà sí ibi mímọ́ ígbàgbọ́. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ti nfi aápọn ṣiṣẹ́ láti tún ilé yín ṣe sí gbùngbun ikẹkọ ìhìnrere kan, bí ìgbà ti nlọ àwọn ọjọ́ Ìsinmi yín yíò ládùn nítoọ́tọ́. Àwọn ọmọ yín yío ni ìdùnnú láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti làti gbé ìgbé ayé àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà, àti pé ipá ò̩tá ní ìgbésí-ayé yín àti nínú ilé yín yíò dínkù. Àwọn àyípadà ninu ẹbí yin yío dàbí àwòrán eré yío sì ṣeé mú dúró” (Russell M. Nelson, “Dída Àpẹrẹ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2018, 113).

  3. “Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún un yín, èmi yíò pín fún yín lára Ẹmí mi, èyí tí yíò fi òye sí inú yín, èyí tí yíò kún ẹ̀mí yín pẹ̀lú ayọ̀” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 11:13).

  4. “Àwọn àkókò iṣẹ ìríjú jẹ́ àwọn ìgbà ninu èyítí Olúwa ní, ó kéré tán, ìránṣẹ́ kan tí ó ní àṣẹ ní orí ilẹ̀ ayé, ẹnití ó ni oyè-àlùfáà ati awọn kọ́kọ́rọ́, ati tí ó ní àṣẹ àtọ̀runwá kan láti fi ìhìnrere fún àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé” (Awọn Àkòrí ati Awọn Ibéèrè, “Àwọn àkókò iṣẹ ìríjú,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere).

  5. Wo Mósè 5:12–16.

  6. Wòlíì Dáníẹ́lì rí ọjọ́ wa, àwọn àkókò iṣẹ ìríjú wa, nigbàtí ó túmọ̀ àlá Nebukadinésárì. Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni òkúta ninu àlá náà, ti a gé jáde lára òkè láìsí àwọn ọwọ́, tí ó nyí lọ síwájú láti kún gbogbo ilẹ̀ ayé (wo Dáníẹ́lì 2:34–35, 44–45; Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 65:2).

  7. “Ọlọ́run Baba àti Jésù Krístì pe Wòlíì Joseph Smith láti jẹ́ wòlíì ti àkokò iṣẹ ìríjú yí. Gbogbo àwọn agbára àtọ̀runwá ti awọn àkokò iṣẹ ìríjú ti àtẹ̀hìnwá ni yío jẹ́ mimúpadàbọ̀sípò nipasẹ̀ rẹ̀. Ìgbà iṣẹ ìríjú ti kíkún àwọn àkókò yí kì yíò ní òdiwọ̀n ní ti àkókò àti ni ti ibi ìdúró. Kò ní parí sí ìyapa-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́, yío sì kún ayé” (Russell M. Nelson, “Kíkójọ ti Isráẹ́lì Tó Fọ́nká,” Lìàhónà, Oṣù Kọkànlá 2006, 79–80).

  8. Russell M. Nelson, “Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀,” Lìàhónà, Oṣù Kọkànlá 2018, 8.

  9. Wo “Ìyípadà Ọkàn Jẹ́ Àfojúsùn Wa,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Ìwé ti Mọ́mọ́nì 2024, v.

  10. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 50:22; bákannáà wo àwọn ẹsẹ 17–21.

  11. Jákọ́bù 1:3–4.

  12. Jákọ́bù 4:6.

  13. 1 Néfì 5:21–22.

  14. Ó jẹ́ kíkéde láìpẹ́ yi pé mílíọ́nù igba (200) àwọn ẹ̀dà Ìwé Ti Mọ́mọ́nì ni ó ti jẹ́ pípín kiri ní àkókò iṣẹ́ ìríjú yí. Eyíinì jẹ́ ohun tó lápẹrẹ nítòótọ́. Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti jẹ́ títúmọ̀ sí àwọn èdè ọgọ́run kan àti mẹ́tàlá (113), pẹ̀lú ìtumọ̀ èdè titun mẹ́tàdínlógún (17) tó nlọ lọ́wọ́ Ó ti jẹ́ ìbùkún tó láti ní Ìwé Ti Mọ́mọ́nì ní títẹ̀, ní díjítà, ní ohùn, ní fídíò, àti ní àwọn ọ̀nà míràn. Wo (Ryan Jensen, “Ìjọ Pín Ẹ̀dà Tó Fi Pé Igba (200) Mílíọ́nù Ìwé Ti Mọ́mọ́nì,” Ìròhìn Ìjọ, Oṣù Kejìlá 29, 2023, thechurchnews.com.)

  15. 1 Néfì 8:14–16; àfikún àtẹnumọ́.

  16. “Ipá tó lágbára jùlọ ti ẹ̀mí ní ayé ọmọdé ni àpẹrẹ òdodo ti olùfẹ́ni àwọn òbí àti àwọn òbí àgbà tí wọ́n pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ tiwọn mọ́ pẹ̀lú òtítọ́. Àwọn òbí tó mọ̀ọ́mọ̀ máa nkọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi Olúwa kí àwọn náà ‘lè mọ̀ orísun tí wọ́n lè wò fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn’ [2 Néfì 25:26]. Májẹ̀mú pípamọ́ àìròtẹ́lẹ̀ àti àìtẹramọ́ ndarí sí ikú ti ẹ̀mí. Ìbàjẹ́ ti ẹ̀mí máa nfi ìgbà gbogbo ga jùlọ lórí àwọn ọmọ àti awọn ọmọ-ọmọ wa” (Kevin W. Pearson, “Are You Still Willing?,” Liahona, Nov. 2022, 69).

  17. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:22–24.

  18. Wòlíì Joseph Smith wí pé: “Mo wí fún àwọn arákùnrin pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ó péye jùlọ ninu eyikeyi ìwé lórí ilẹ̀ ayé, òun sì ni okúta ìpìlẹ̀ ti ẹ̀sìn wa, àti pé ènìyàn yíò súnmọ́ Ọlọ́run síi nípa gbígbé nipa àwọn ìlànà rẹ̀, ju nipa eyikeyi ìwé miràn lọ” (ninu Ọ̀rọ̀ Ìṣaáju sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì).

  19. Russell M. Nelson, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Kíni Ìgbé Ayé Rẹ̀ Yíò Jẹ́ Láìsí Rẹ̀?,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2017, 62–63.