Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Májẹ̀mú àti àwọn Ojúṣe
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Àwọn Májẹ̀mú àti àwọn Ojúṣe

Ìjọ Jésù Krístì ni a mọ̀ bíi ijọ kan tí ntẹnumọ́ dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run.

“Báwo ni Ijọ rẹ ṣe yàtọ̀ sí àwọn miràn?” Ìdáhùn mi sí ìbéèrè pàtàkì yi ti yàtọ̀ síra bí mo ti ndàgbà àti bí Ìjọ ti ngbèrú síi. Nigbàtí a bí mi ní Utah ní 1932, àwọn ọmọ Ìjọ wa jẹ́ bíi 700,000 péré, tí wọ́n kórajọ púpọ̀jù ní Utah àti àwọn ìpínlẹ̀ itòsí. Ní ìgbà náà, a ní àwọn tẹ́mpìlì méje péré. Lóni iye ọmọ-ìjọ ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn pọ̀ nì iye ju mílìọ́nù mẹ́tàdínlógún lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè bí 170. Ní ọjọ́ kinní Oṣù Kẹrin yí, a ní àwọn tẹ́mpìlì 189 tí a ti yà sí mímọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn 146 síi ní gbígbà-lérò àti kíkọ́ lọ́wọ́. Mo ti ní imọ̀lára nipa ìwúlò àwọn tẹ́mpìlì wọ̀nyí àti ìtàn àti ipa àwọn májẹ̀mú ninu ìjọ́sìn wa. Èyí yío ṣe àfikún sí àwọn ìkọ́ni onímisí ti àwọn ti wọ́n ti sọ̀rọ̀ ṣaájú.

1.

Májẹ̀mú jẹ́ ìfarajì kan láti mú àwọn ojúṣe pàtó kan wá sí ìmúṣe. Àwọn ìfarajì ti ara-ẹni ṣe kókó sí ìdarí ìgbé ayé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa àti sí ìṣiṣẹ́ dèèdè àwùjọ. Erò orí yí ti di pípèníjà lọ́wọ́lọ̀wọ́. Àwọn alẹ́nu-lọ́rọ̀ tí kò pọ̀ níye ntako àgbékalẹ̀ àwọn aláṣẹ, wọ́n sì ntakú pé àwọn ènìyàn níláti jẹ́ òmìnira kurò ninu èyíkéyí àwọn ìdènà tí ó fi òdiwọ̀n sí òmìnira ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan wọn. Síbẹ̀ a mọ̀ láti inu ìrírí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún pé àwọn ènìyàn njọ̀wọ́ àwọn òmìnira ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan kan sílẹ̀ láti gba àwọn ànfààní ti gbígbé nínú àwọn àdúgbò tí ó létò. Irú ìjùsílẹ òmìnira ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan bẹ́ẹ̀ nípàtàkì máa ndá lóri àwọn ìfarajì tàbí àwọn májẹ̀mu, fífẹnusọ tàbí fífinúrò.

Àwòrán
Àwọn òṣìṣẹ́ ológun.
Àwòrán
Àwọn oniṣẹ́ ìlera.
Àwòrán
Awọn panápaná.
Àwòrán
Àwọn Ìránṣẹ́ Ìhìnrere ní kíkún.

Ìwọ̀nyí ni àwọn àpẹrẹ ojuṣe májẹ̀mú ní àwùjọ wa: (1) àwọn adájọ́, (2) àwọn ológun, (3) àwọn òṣìṣẹ́ ìlera, àti (4) àwọn panápaná. Gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ninu àwọn iṣẹ́ tó wọ́pọ̀ wọ̀nyí nṣe ìfarajì—ní ọ̀pọ̀ ìgbà wọ́n nfi àṣẹ síi nípa ìbúra tàbí májẹ̀mú—láti ṣe àwọn iṣẹ́ yíyàn wọn. Èyí kannáà jẹ́ òtítọ́ nipa àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa. Àràọ̀tọ̀ ìwọṣọ wọn tàbí àwọn táàgì orúkọ jẹ́ èrò ọkàn láti ṣe àmì pé ẹnití ó wọ̀ọ́ wà ní abẹ́ májẹ̀mú, àti nítorínáà, ó ní ojúṣe láti kọ́ni àti láti sìn, ó sì níláti jẹ́ títìlẹ́hìn ninu iṣẹ́-ìsìn náà. Èrèdí kan tí ó dàbí rẹ̀ ni láti rán àwọn olùwọ̀ létí nipa àwọn ojúṣe májẹ̀mú wọn. Kò sí idán ninu yíyàtọ̀ ìwọṣọ tàbí àwọn àmì wọn, ó jẹ́ ìránnilétí tí a nílò nìkan nípa àwọn ojúṣe pàtàkì tí àwọn olùwọ̀ ti dáwọ́lé. Èyi jẹ́ òtítọ́ bákannáà nípa àwọn àmì ti àwọn òrùka ìfẹ́nisọ́nà àti ti ìgbéyàwó, àti ipa wọn ní títa àwọn olùwòran ní olobó tàbí rírán olùwọ̀ létí nipa àwọn ojúṣe májẹ̀mú.

Àwòrán
Àwọn òrùka ìgbéyàwó.

ll.

Ohun tí mo ti sọ nípa àwọn májẹ̀mú ní jíjẹ́ ìpìlẹ̀ fún ìdarí àwọn ìgbé ayé ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ àmúlò ní pàtàkì sí àwọn májẹ̀mú ti ẹ̀sìn. Ìpìlẹ̀ àti ìtàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfaramọ́ àti àwọn ìkàyẹ ẹ̀sìn dá lórí àwọn májẹ̀mú. Fún àpẹrẹ, májẹ̀mú ti-Ábráhámù jẹ́ kókó sí púpọ̀ àwọn àṣà nlá ti ẹ̀sìn. Ó nṣe àfihàn èrò nlá ti àwọn ìlérí májẹ̀mú Ọlọ̀run pẹ̀lú àwọn ọmọ Rẹ̀. Májẹ̀mú Láéláé fi léraléra tọ́ka sí májẹ̀mú kan láàrin Ọlọ́run àti Ábráhámù àti irú-ọmọ rẹ̀.

Abala àkọ́kọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, tì a kọ ní àkókò Májẹ̀mú Láéláé, ṣe àpèjúwe kedere ipa àwọn májẹ̀mú ninu ìtàn àti ìjọ́sìn awọn ọmọ Isráẹ́lì. A wí fún Néfì pé àwọn ohun kíkọ ti awọn ọmọ Isráẹ́lì igbà náà jẹ́ “àkọsílẹ̀ àwọn Jũ, èyí tí ó ní awọn májẹ̀mú Olúwa nínú, èyí tí ó ti ṣe sí awọn ará ilé Isráẹ́lì.” Àwọn ìwé ti Néfì ṣe itọ́kasí léraléra sí májẹ̀mú ti-Ábráhámù ati sí Isráẹ́lì bí “àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa.” Ìṣe ti dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run tàbí àwọn olùdarí ẹ̀sìn bákannáà jẹ́ kíkọsílẹ̀ ninu àwọn ohun kíkọ ninu Ìwé ti Mọ́mọ́nì nípa Néfì, Jósẹ́fù ní Egíptì, Ọba Bẹ́njámínì, Álmà, àti Ọ̀gágun Mórónì.

lll.

Nígbàtí àkókò tó fún ìmúpadàbọ̀sípò ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì, Ọlọ́run pe wòlíì kan, Joseph Smith. A kò mọ kíkún àkóónú náà ní ti àwọn ìkọ́ni angẹ́lì Mórónì sí ọ̀dọ́ wòlíì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ndàgbà yí. A mọ̀ pé ó sọ fún Jósẹ́fù pé “Ọlọ́run ní iṣẹ́ kan fún [òun] láti ṣe” àti pé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhìnrere àìlópin” gbọdọ̀ di mimu jáde wá, pẹ̀lú “àwọn ìlérí tí a ṣe fún àwọn baba.” A mọ̀ bákannáà pé àwọn ìwé mímọ́ ti ọ̀dọ́ Jósẹ́fù kà kárakára jùlọ—àní ṣaájú kí ó tó jẹ́ dídarí láti ṣe ètò ìjọ kan—jẹ́ púpọ̀ àwọn ìkọ́ni nípa àwọn májẹ̀mú tí ó ntúmọ̀ ninu Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ìwé náà jẹ́ kókó orísun Ìmúpadàbọ̀sípò fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere, pẹ̀lú ètò Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀, Ìwé ti Mọ́mọ́nì sì kún fún àwọn ìtọ́kasí sí àwọn májẹ̀mú.

Bí ó ti kàwé dáradára ninu Bíbélì, Jósẹ́fù gbọ́dọ̀ ti mọ̀ nípa atọ́ka ti ìwé àwọn Hébérù sí èrò ọkàn Olùgbàlà láti “dá májẹ̀mú titun kan pẹ̀lú ilé Isráẹ́lì àti pẹ̀lú ilé Júdàh.” Àwọn Hébérù bákannáà tọ́ka sí Jésù bí “alágbàwí ti májẹ̀mú titun.” Ní pàtàkì, àkọsílẹ̀ ti-bíbélì nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ti-ikú Olùgbàlà ni àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Májẹ̀mú Titun Náà,” tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ míràn fún “Májẹ̀mú Titun.”

Àwọn májẹ̀mú jẹ́ ti ìpilẹ̀sẹ̀ ninu Ìmúpadàbọ̀sípò ti ìhìnrere náà. Èyí farahàn ninu àwọn igbésẹ̀ ibẹ̀rẹ̀-pẹ̀pẹ̀ tí Olúwa darí Wòlíì láti gbé nínu ṣíṣe ètò Ìjọ Rẹ̀. Ní kété bí Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti di títẹ̀ jáde, Olúwa darí ìgbékalẹ̀ Ìjọ Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò, láìpẹ́ tí a ó pè ní orúkọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. Ìfihàn tí a fúnni ní Oṣù Kẹrin 1830 darí pé àwọn ènìyàn “yio jẹ́ gbígbà nipa irìbọmi si inu ìjọ rẹ̀” lẹ́hìn tí wọ́n bá ti “jẹ́ ẹ̀ri” (tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ri pẹ̀lú ọ̀wọ̀) “pé wọ́n ti ronúpìwàdà gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítòótọ́, wọ́n sì ṣetán láti gba orúkọ Jésù Krístì sí orí wọn, tí wọ́n ní ìpinnu lati sìn ín dé òpin,”

Ìfihàn yí kannáà ṣe ìdarí pé kí Ìjọ ó máa “pàdé papọ̀ nigbàkũgbà láti jẹ nínú àkàrà àti wáìnì [omi] ní ìrántí Jésù Olúwa.” Pàtàkì íláná yí fi ara hàn ninu awọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí ó wà ní pàtó fún alàgbà tàbí àlùfáà tí ó ndari ètò. Ó nsúre sí àmì búrẹdì náà fùn “ọkan gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ …, kí wọn … jẹri sí ọ, Áà Ọlọrun, Bàbá Ayerayé, pé wọn ṣetán lati gba orúkọ Ọmọ rẹ sí órí wọn, kí wọn sì rántí rẹ nígbàgbogbo kí wọn sì pa àwọn ofin rẹ mọ èyí tí ó ti fifun wọn.”

Ipa pàtàkì ti àwọn májẹ̀mú nínú Ìjọ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú padà bọ̀sípò ni a tún ẹsẹ̀ rẹ̀ fi múlẹ̀ nínu ọ̀rọ̀ ìṣaájú tí Olúwa fúnni fún àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ti àwọn ìfihàn Rẹ̀. Níbẹ̀ Olúwa sọ pé Òun ti pe Joseph Smith nitoripe àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé “ti ṣìná kúrò ninu àwọn ìlànà mi, wọ́n sì ti ṣẹ́ májẹ̀mu àìlópin mi.” Ìfihàn yí ṣe àlàyé pé àwọn òfin Rẹ̀ ni a fi fúnni “pé kí májẹ̀mu àìlópin mi le di gbígbékalẹ̀.”

Lónìí a ní òye ipa àwọn májẹ̀mú ninu Ìjọ tí a mú padàbọ̀sípò àti ìjọ́sìn àwọn ọmọ-ijọ rẹ̀. Ààrẹ Gordon B. Hinckley ṣe àkékúrú yi nipa àyọrísí íríbọmi wa àti ṣíṣe àbápín ounjẹ Olúwa ni ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀: “Olukúlùkù ọmọ-ijọ ijọ yi tí o ti wọnu àwọn omi irìbọmi ti di arakan sí májẹ̀mú mímọ́ kan. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbà tí a bá ṣe àbápín àmì májẹ̀mú ti oúnjẹ alẹ̀ Olúwa, a ntún májẹ̀mú náà ṣe.”

A ti ránwa létí nípasẹ̀ púpọ̀ àwọn olùsọ̀rọ̀ níbi ìpàdé àpapọ̀ yí pé Ààrẹ Russell M. Nelson, máa nfi ìgbàkúugbà tọ́ka sí ètò ìgbàlà bíi “ipa ọ̀nà májẹ̀mú” tí “ndarí wa padà sí ọ̀dọ̀ [Ọlọ́run]” ati “tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ nipa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run.” Ó nkọ́ wa nípa pàtàkì àwọn májẹ̀mú ninu àwọn ayẹyẹ tẹ́mpìlì wa ó sì ngbàwá níyànjú láti rí òpin láti ìbẹ̀rẹ̀ àti lati “ronú sẹ̀lẹ́stíà.”

IV.

Nísisìyí mò nsọ̀rọ̀ nípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì. Ní ìmúṣẹ ojuṣe rẹ̀ láti mu ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì bọ̀sípò, Wòlíì Joseph Smith lo púpọ̀ nínú àwọn ọdún ìgbẹ̀hìn rẹ̀ nì dídarí kíkọ́ tẹ́mpìlì kan ní Nauvoo, Illinois. Nipasẹ̀ rẹ̀ Olúwa fi àwọn ìkọ́ni, ẹ̀kọ́, àti àwọn májẹ̀mú mímọ́ hàn fún áwọn àtẹ̀lé rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ lati ṣe àmójútó ninu àwọn tẹ́mpìlì. Níbẹ̀, àwọn ẹni tí wọ́n bá gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì nílati jẹ́ kikọ́ ní ètò ìgbàlà ti Ọlọ́run kí a sì pè wọ́n lati dá àwọn májẹ̀mú mímọ́. Àwọn tí wọ́n bá gbé nítòótọ́ sí àwọn májẹ̀mú náà ni a ṣe ìlérí ìyè ayérayé fún, níbití “ohun gbogbo jẹ́ tiwọn” wọn “yío sì gbé ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti Krístì rẹ̀ láé àti títí láé.”

Àwọn ayẹyẹ gbígba ẹ̀bùn nínu Tẹ́mpìlì Nauvoo ni a ṣe àmójútó rẹ̀ ní kété ṣaájú kí àwọn aṣaájú wa ìbẹ̀rẹ̀ ó tó di lílé lọ láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn onìtàn wọn sí àwọn òkè jíjìnà ni Ìwọ̀ Oòrùn. A ní awọn ẹ̀rí láti ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣaájú, pé agbára tí wọ́n gbà láti inu jíjẹ́ sísopọ̀ mọ́ Krístì ninu gbígba ẹ̀bùn wọn ní Tẹ́mpìlì Nauvoo, fún wọn ní okun láti ṣe ìrin àjò akọni wọn, kí wọn ó sì fi ẹsẹ̀ ara wọn múlẹ̀ ní Ìwọ̀ Oòrùn.

Àwọn ẹni tí a ti fún ni ẹ̀bùn ninu tẹ́mpìlì kan ní ojúṣe láti wọ ẹ̀wù tẹ́mpìlì kan, ara aṣọ wíwọ̀ tí kò farahàn nitorípé ó njẹ́ wíwọ̀ sí abẹ́ aṣọ wíwọ̀ sóde. Ó nrán awọn ọmọ-ìjọ tí wọ́n ti gba ẹ̀bùn létí awọn májẹ̀mú mímọ́ tí wọ́n ti dá àti awọn ìbùkún tí a ti ṣèlérí fún wọn ninu tẹ́mpìlì mímọ́. Láti ní àṣeyọrí àwọn èrèdí mímọ́ wọ̀nyi, a kọ́wa lati wọ àwọn ẹ̀wù tẹ́mpìlì títí lọ, pẹ̀lú àwọn àyàfi tí ó jẹ́ awọn wọnnì tí ó ṣe dandan ní àfojúrí. Nitorípe àwọn májẹ̀mú kìí “gba ààye ọjọ́ kan fún ìsinmi,” láti mú ẹ̀wù tẹ́mpìlì ẹnìkan kúrò le yéni bíi yíyọ ara ẹni ninu àwọn ojúṣe àti àwọn ìbùkún tí wọ́n so mọ́. Ní idàkejì, àwọn ẹnití wọ́n bá wọ àwọn ẹ̀wù wọn lódodo tí wọ́n sì pa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wọn mọ́ títílọ, ṣe ìfimúlẹ̀ ipa wọn bíi ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì Olúwa.

Àwòrán
Máàpù àwọn tẹ́mpìlì.

Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì ní gbogbo àgbáyé. Èrèdí wọn ni láti bùkún àwọn ọmọ májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú ìjọ́sìn tẹ́mpìlì, àti pẹ̀lú àwọn ojúṣe mímọ́ náà àti àwọn agbára, àti awọn ìbùkún àràọ̀tọ̀ ti jíjẹ́ sísopọ̀ sí Krístì, tí wọn gbà nipa májẹ̀mú.

Àwòrán
Tẹ́mpìlì São Paulo Brazil.

Ìjọ Jésù Krístì ni a mọ̀ bíi ijọ kan tí ntẹnumọ́ dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwọn májẹ̀mú wà ninu ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga tí Ìjọ tí a mú padàbọ̀sípò yí nfifúnni. Ìlànà ìrìbọmi àti àwọn májẹ̀mu tí ó rọ̀ mọ́ ọ jẹ́ kókó awọn àmúyẹ fún wíwọlé sí inu ìjọba sẹ̀lẹ́stíà. Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì àti àwọn májẹ̀mu tí ó rọ̀ mọ́ wọn jẹ́ kókó awọn àmúyẹ fún ìgbéga ní ìjọba sẹ̀lẹ́stíà, èyítí í ṣe iyè ayérayé, “ẹ̀bùn títóbi jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run.” Éyi ni àfojúsùn ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn.

Mo jẹ́ri nipa Jésù Krístì, ẹnití í ṣe orí Ìjọ náà, mo sì ké pe awọn ìbùkún Rẹ̀ sórí gbogbo ẹnití ó bá lépa láti pa awọn májẹ̀mú mímọ́ wọn mọ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.