Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ìbìlù Iná Tó-Farasin
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Àwọn Ìbìlù Iná Tó-Farasin

Ọlọ́run ngbọ́ gbogbo àdúrà ti a ngbà, Ó sì nfèsì sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìbámu sí ipa ọ̀nà tí Òun ti là kalẹ̀ fún jíjẹ́ pípé wa.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ tó nírora láti ìgbà ti mo ti wà níbi àga ìwàásù yí ní Oṣù Kẹwa 2022. Ẹ̀kọ́ náà ni pé: Bi o kò bá sọ ọ̀rọ̀ kan tó ṣètẹ́wọ́gbà, a le fi òfin dè ọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpàdé àpapọ̀ tó tẹ̀lé. Ẹ lè ríi pe a tètè yàn mí ninu abala àkọ́kọ́ ti eléyí. Ohun tí ẹ kò le rí ni pé mo ndúró ninu ìlẹ̀kún-pàkúté kan pẹ̀lú àyígbè tó jẹ́ ẹlẹgẹ́ gidi. Bí ọ̀rọ̀ yí kò bá lọ dáradára, èmi kò ní ríi yín fún àwọn ìpàdé àpapọ̀ díẹ̀ míràn.

Nínú ẹ̀mí ti orin isìn rírẹwà náà pẹ̀lú ẹgbẹ́ akọrin rírẹwà yí, mo ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ kan láìpẹ́ yí pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa, mo fẹ́ ṣe àbápín pẹ̀lú yín loni. Èyí yíó mú kí ọ̀rọ̀ yí jẹ́ ti ara ẹni gidi.

Èyí tí ó jẹ́ ti araẹni àti dídunni jùlọ ninu gbogbo àwọn ìrírí àìpẹ́ wọ̀nyí ni kíkọjá lọ ti àyànfẹ́ ìyàwó mi, Pat. Òun ni obìnrin nlá jùlọ ti mo ti mọ̀ rí—ìyàwó àti ìyá pípé, lati máṣe sọ ohunkóhun nípa jíjẹ́ mímọ́ rẹ̀, ẹ̀bùn àsọyé rẹ̀, àti jíjẹ́ ti ẹ̀mí rẹ̀. Ó sọ ọ̀rọ̀ kan nígbàkan rí pẹ̀lú àkòrí “Mímú Òṣùwọ̀n Ìṣẹ̀dá Yín Ṣẹ.” Sí mi, ó dàbí pé ó mú ìwọ̀n ìṣẹ̀dá rẹ̀ ṣẹ ní àṣeyege síi ju bí ẹnikẹ́ni ti le lá àlá pé ó ṣeéṣe lọ. Ó jẹ́ ọmọbìnrin Ọlọ́run pátápátá, àpẹrẹ obìnrin ti Krístì. Èmi jẹ́ olóríire jùlọ ninu àwọn ọkùnrin láti lo ọgọ́ta ọdún (60) ninu ìgbésí ayé mi pẹ̀lú rẹ̀. Bí mo bá jẹ́ kíkàyẹ, fífi èdìdi dì wa túmọ̀ sí pé mo le lo ayérayé pẹ̀lú rẹ̀.

Ìrírí míràn bẹ̀rẹ̀ ni wákàtí méjìdínláádọ́tà lẹ́hìn ìsìnkú ìyàwó mi. Ní àkókò náà, a fi ìyara gbémi lọ sí ilé ìwòsàn nínú ipò àìlera kan tó le gidi. Nígbànáà mo lo ọ̀sẹ̀ mẹ́rin àkọ́kọ́, ninu ọ̀sẹ̀-mẹ́fà dídúró, ní inú ilé àti òde ẹ̀ka to nṣe ìtọ́jú ẹlẹgẹ́, àti ní inú àti òde mímọ-ibití-mo-wà.

Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo ìrírí mi ilé ìwòsàn ní àkókò náà ti sọnù sí ìrántí mi. Ohun tí sọnù ni rírántí mi nípa ìrìn-àjò kan ní òde ilé ìwòsàn náà, síta lọ sí ohun tó dàbí òpin ayérayé. Èmi kò le sọ̀rọ̀ ní kíkún nípa ìrírí náà níhin, ṣúgbọ́n mo le sọ pé apákan ohun tí mo gbà jẹ́ ìgbaniníyànjú láti padà sí iṣẹ ìránṣẹ́ mi pẹ̀lú ìkánjú díẹ̀ síi, ìyàsọ́tọ̀ díẹ̀ síi, ìfojúsùn sára Olùgbàlà díẹ̀ síi, ìgbàgbọ́ díẹ̀ síi ninu ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

Èmi kò le ṣe àìní-ìmọ̀lára pé mo ngba ẹ̀dà ti araẹni tèmi ninu ìfihàn ti a fifún àwọn Méjìlá ní bíi igba ọdún sẹ́hìn:

“Ìwọ yiò jẹ́rìí orúkọ mi … [sì] rán ọ̀rọ̀ mi jáde lọ sí àwọn òpin ayé. …

“… Ní òwòwúrọ̀; àti ní ọjọọjọ́ jẹ́kí ohùn ìkìlọ̀ rẹ ó jáde lọ; àti nígbàtí alẹ́ bá dé máṣe jẹ́kí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé ó tòògbé, nítorí ti ọ̀rọ̀ rẹ. …

“Dìde[,]… gbé àgbélèbú rẹ, kí o [sì] tẹ̀lé mi.”

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arábìnrin ati arákùnrin mi, láti ìgbà ìrírí náà, mo ti gbìyànjú láti gbé àgbélèbú mi pẹ̀lú ìtara síi, pẹ̀lú ìpinnu síi láti wá ibití mo ti le gbé ohun bíi ti àpóstélì kan sókè ti ìfẹ́ni àti ti ìkìlọ̀ ni òwúrọ̀, ní ìgbà ọ̀sán, àti dé òru.

Èyí darí mi sí òtítọ́ kẹta kan tí ó wá ninu àwọn oṣù àdánù, àìlera, àti ìdààmú náà. Èyí jẹ́ ẹ̀rí tí a sọdọ̀tun nípa, àti àìlópin ìmoore fún, agbára àwọn àdúrà àìleyẹsẹ̀ ti Ìjọ yí—àwọn àdúrà yín—ninu èyítí mo ti jẹ ànfààní. Èmi ó ní ìmoore títí ayé fún àdúrà ẹ̀bẹ̀ ti ẹgbẹgbẹ̀rún awọn ènìyàn awọn tí, bíi ti opó ayọnilẹ́nu nnì, wọ́n fi léraléra wá ìdásí ti ọ̀run nítorí mi. Mo gba àwọn ìbùkún oyè-àlùfáà, mo sì ríi pé àwọn ọmọ kíláàsì mi ní ilé ìwé gíga gbaàwẹ̀ fún mi, bí púpọ̀ àwọn wọ́ọ̀dù kọ̀ọ̀kan ti ṣe káàkiri Ìjọ, Orukọ mi sì gbọdọ̀ ti wà lórí ìwé àdúrà ní ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo tẹ́mpìlì ninu Ìjọ.

Ninu ìjìnlẹ̀ ìmoore mi fún gbogbo èyí, mo darapọ̀ mọ́ G. K. Chesterton, ẹnití ó sọ nígbàkan “pé àwọn ìdúpẹ́ ni oríṣi ìrònú tó ga julọ; àti pé … ìmoore jẹ́ ìdùnnú tó di méjì nipasẹ̀ ìyanu,” Pẹ̀lú “ìdùnnú tèmi tó di méjì nipasẹ̀ ìyanu,” mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo yín mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba mi ní Ọ̀run, ẹnití ó gbọ́ awọn àdúrà yín tí ó sì bùkún ayé mi.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo jẹ́ri pé Ọlọ́run ngbọ́ gbogbo àdúrà ti a ngbà, Ó sì nfèsì sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìbámu sí ipa ọ̀nà tí Òun ti là kalẹ̀ fún jíjẹ́ pípé wa. Mo dáamọ̀ pé ní bíi àkókò kannáà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ngbàdúrà fún ìmúpadàsípò ìlera mi, irú iye kannáà—àti èmi náà—ngbàdúrà fún ìmúpadàsípò ìlera ìyàwó mi. Mo jẹ́ri pé àwọn àdúrà méjéèji jẹ́ gbígbọ́ àtidídáhùn nípasẹ̀ Baba Ọ̀run kan aláànú àtọ̀runwa, àní bí àwọn àdúrà fún Pat jẹ́ dídáhùn ní ọ̀nà tí mo ti bèèrè. Ó jẹ́ fún àwọn èrèdí mímọ̀ sí Ọlọ́run nìkan ni àwọn àdúrà ṣe njẹ́ dídáhùn ní yíyàtọ̀ sí bí a ti nírètí—ṣùgbọ́n mo ṣe ìlérí fún yín pé wọ́n njẹ́ gbígbọ́, wọ́n sì njẹ́ dídáhùn ní ìbámu sí ìfẹ́ àti ọ̀pọ̀ ìṣètò àkókò Rẹ̀ tí kìí kùnà.

Bí a “kò bá ṣìbéèrè,” kò sí òpin sí ìgbà wo, níbo, tàbí nípa kínni a nílati gbàdúrà. Ní ìbámu sí àwọn ìfihàn, a níláti “gbàdúrà nigbà gbogbo.” A níláti gbàdúrà, ni Amúlẹkì sọ, fún “àwọn tí wọ́n wà ní àyíká yín,” pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé “àdúrà ìtara àwọn olódodo [ènìyàn] nmú ohun púpọ̀ wa.” Àwọn àdúrà wa yẹ kí ó jẹ́ sísọjáde nígbàtí a bá ní ààyè dídánìkanwà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí èyí kò bá ṣeéṣe, wọ́n niláti jẹ́ gbígbé bíi àwọn ọ̀rọ̀ sísọ jẹ́ẹ́jẹ́ ninu ọkàn wa. A nkọrin pé àwọn àdúrà wa jẹ́ “[àwọn] ìbìlù iná tó farasin,“ láti jẹ́ gbígbà nígbà gbogbo, ní ìbámu sí Olùgbàlà Fúnra Rẹ̀, sí Ọlọ́run Baba Ayérayé ní orúkọ Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi àyànfẹ́, àwọn àdúrà wa ni àwọn wákàtí wa dídùn jùlọ, ifẹ́ inu wa tòótọ́ jùlọ,” irú ìjọ́sìn wa tó rọrùn jùlọ, to jẹ́ àìléèrí jùlọ. A níláti gbàdúrà bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, ninu àwọn ẹbí wa, áti ninu àpéjọpọ̀ ti gbogbo oríṣiríṣi ìwọ̀n. A níláti lo àdúrà bíi ààbò dojúkọ ìdánwò, bì ó bá sì ní àkókò kankan tí a nimọ̀lára láti máṣe gbàdúrà, ó lè dáwa lójú pé ìlọ́ra nwá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹnití npòngbẹ láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Rẹ̀ ní èyíkéyí àti ní gbogbo ìgbà. Ní tòótọ́, àwọn aápọn láti mú kí á má le gbàdúrà nwá tààrà láti ọ̀dọ̀ ọ̀tá. Nigbàtí a kò bá mọ bí a ó ti gbàdúrà tàbí fún ohun wo pàtó, a nílati bẹ̀rẹ̀, kí a sì tẹ̀síwájú, títí tí Ẹ̀mí Mímọ́ yíó fi tọ́ wa sínú àdúrà ti a níláti máa gbà. Ìlànà yí le jẹ́ eyí ti a níláti lò nígbàti a bá ngbàdúrà fún àwọn ọ̀tá wa àti àwọn ti wọ́n nfi àrankàn bá wa lò.

Ní ìgbẹ̀hìn, a le wo àpẹrẹ Olùgbàlà ẹnití ó gbàdúrà nígbàkúùgbà gidi, gidi tó bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìgbà jẹ́ ìwúrí sí mi pé Jésù ní ìmọ̀lára ìnílò láti gbàdúrà rárá. Ṣé Òun kìí ṣe ẹni pípé ni? Nípa kínni Òun nílò lati gbàdúrà? Ó dára, mo ti wá mọ̀ pé Òun náà, pẹ̀lú àwa, fẹ́ láti “wá ojú [Baba], gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, kí ó sì gbẹ́kẹ̀lé oore ọ̀fẹ́ rẹ̀.” Ní àkókò dé àkókò, Ó fàsẹ́hìn kúrò ní àwùjọ láti dá wà kí ó tó dá ọ̀run lu pẹ̀lú àwọn àdúrà Rẹ̀. Ní àwọn ìgbà míràn, Ó gbàdúrà ní ààrin àwọn ojúgbà díẹ̀. Lẹ́hìnnáà Òun ó wá ọ̀run ní ìtìlẹ́hìn àwọn ọ̀pọ̀ èrò tí wọ́n le bo ẹ̀gbẹ́ òkè kan. Ní àwọn ìgbà míràn àdúrà ṣe aṣọ wíwọ̀ Rẹ̀ lógo. Ní àwọn ìgbà míràn ó ṣe ìwò ojú Rẹ̀ lógo. Nígbàmíràn Ó nàró láti gbàdúrà, nígbàmíràn Ó kúnlẹ̀, àti pé ó kéré jù ní ẹ̀ẹ̀kan Ó da ojú Rẹ̀ bolẹ̀ ninu àdúrà.

Lúkù ṣe àpèjúwe ìsọ̀kalẹ̀ Jésù si inú ìjìyà Rẹ̀ bíi nínílò Rẹ̀ láti gbàdúrà “pẹ̀lú ìtara síi.” Báwo ni ẹnìkan tí ó jẹ́ pípé ṣe gbàdúrà pẹ̀lú ìtara síi? A fi inú ròó pé gbogbo àwọn àdúrà Rẹ̀ jẹ́ pẹ̀lú ìtara, síbẹ̀ ní mímú ìrúbọ ìṣètùtù Rẹ̀ wá sí ìmúṣẹ, àti nípasẹ̀ ìrora tó bá àgbáyé, Ó nímọ̀lára láti gbàdúrà pẹ̀lú bíbẹ̀bẹ̀ sìi jùlọ, pẹ̀lú ìwúwo ẹbọ-ọrẹ Rẹ̀ ní ìparí ní mímú ẹ̀jẹ̀ wá láti gbogbo ihò ara.

Ní àtakò sí àsokọ́ ti ìṣẹ́gun Krístì lórí ikú, àti ẹ̀bùn Rẹ̀ àìpẹ́ yí fún mi ní ti àwọn ọ̀sẹ̀ tàbí àwọn oṣù díẹ̀ síi ninu ara kíkú, mo jẹ́ri pẹ̀lú ọ̀wọ̀ nípa jíjẹ́ òtítọ́ ti ìyè ayérayé àti ìnílò fún wa láti jẹ́ alárò-jinlẹ̀ nínú ètò ṣíṣe wa fún un.

Mo jẹ́ri pé nígbàtí Krístì bá dé, Ó níláti dá wa mọ̀—kìí ṣe bí ọmọ-ìjọ tí kò jẹ́ nkan, tí a tò sí orí àkọsílẹ̀ ìrìbọmi tó ti nparẹ́ lọ, ṣùgbọ́n bíi àwọn olùfọkànsìn, onígbàgbọ́ tòótọ́, olùpamọ́ májẹ̀mu ọmọ-ẹ̀hìn dáradára. Èyí jẹ́ ọ̀ràn kíákíá kan fún gbogbo wa, kí a má ba gbọ́ láé pẹ̀lú àbámọ̀ búburú pé: “Èmi kò mọ̀ yín rí,” tàbí, bí Joseph Smith ti ṣe ìtumọ̀ gbólóhùn náà, “[Ẹ̀yin] kò mọ̀ mí rí.”

Pẹ̀lú oríire, a ní ìrànlọ́wọ́ fún iṣẹ́ yí—ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrànlọ́wọ́. A nílò láti gbàgbọ́ nínú awọn ángẹ́lì ati awọn iṣẹ́ ìyanu àti awọn ìlérí oyè-àlùfáà mímọ́. A nílò lati gbàgbọ́ ninu ẹ̀bùn Ẹmí Mímọ́ (náà), ipa awọn ẹbí ati awọn ọ̀rẹ́ rere, ati agbára ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Krístì. A nílò láti gbàgbọ́ nínú ìfihàn ati awọn wòlíì, àwọn aríran, ati awọn olùfihàn ati Ààrẹ Russell M. Nelson. A nílò láti gbàgbọ́ pé pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ àti ìṣòdodo ti ara-ẹni, a le gun òkè nítòótọ́ sí “Orí Òkè Síónì, … ilú Ọlọ́run alààyè, ibi tọ̀run náà, mímọ́ jùlọ ninu ohun gbogbo.”

Ẹ̀yin arákùnrin ati arabinrin, bi a ti nronúpìwàdà awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tí a sì nfi ìgboyà wá sí ibi “ìtẹ́ oore ọ̀fẹ́” náà ní fífi awọn ọrẹ ati awọn ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá wa sílẹ̀ níwájú Rẹ, a ó rí àánú ati inú-rere ati ìdáríjì ni ọwọ́ ìṣoore ti Baba wa Ayérayé ati Ọmọ Rẹ̀ olùgbọ́ràn, ẹni pípé láìlábàwọ́n. Nígbànáà, pẹ̀lú Jobu ati gbogbo awọn olódodo tí a ti túnṣe, a ó rí ayé kan “tó jẹ́ ìyanu púpọ̀jú” láti ní òye. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.