Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Jésù Krístì ní Ààrin Gbùngbun Ìgbésí Ayé Wa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Jésù Krístì ní Ààrin Gbùngbun Ìgbésí Ayé Wa

Àwọn ìjìnlẹ̀ ìbéèrè ti ọkàn, àwọn tí wọ́n njẹyọ ninu àwọn wákàtí dúdú jùlọ ati àwọn àdánwò wa gíga jùlọ, ni a nrí ìdáhùn sí nípasẹ̀ ìfẹ́ àìyẹ̀ ti Jésù Krístì.

Bí a ṣe nrin ìrìn-àjò kọjá ní ayé kíkú, nígbà míràn a ndi rírọ̀gbàká nípasẹ̀ àwọn àdánwò: ìrora líle ti àdánù àwọn olùfẹ́, ìjà tó nira ní ìdojúkọ àìsàn, oró ti ìyànjẹ, àwọn ìrírí ìyọnu ti ìyọlẹ́nu tàbí ilòkulò, òjìji àìnìṣẹ́lọ́wọ́, àwọn ìpọ́njú tó wọ́pọ̀, ẹkún jẹ́jẹ́ ti ìdánìkanwà, tàbí àwọn àyọrísí tó banilọ́kànjẹ́ ti àwọn ìjà oníhamọ́ra.1 Ní àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, ọkàn wa npòngbẹ fún ibi ìsádi.2 A nfi ìtara lépa láti mọ̀: Níbo ni a ti le rí ìkunra àlàáfíà?3 Ninu tani a le fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sí láti ràn wá lọ́wọ́ pẹ̀lú ìdára-ẹni-lójú àti okun láti ṣẹ́gun àwọn ìpèníjà wọ̀nyí?4 Tani ó ní sũrù náà, ìfẹ́ ní gbogbo àyíká, àti ọwọ́ agbára àìlópin làti gbé ga kí ó sì mú wa dúró?

Àwọn ìjìnlẹ̀ ìbéèrè ti ọkàn, àwọn tí wọ́n njẹyọ ninu àwọn wákàtí dúdú jùlọ ati àwọn àdánwò wa gíga jùlọ, ni a nrí ìdáhùn sí nípasẹ̀ ìfẹ́ àìyẹ̀ ti Jésù Krístì.5 Ninu Rẹ̀, àti nípasẹ̀ àwọn ìbùkún tí a ṣe ìlérí ti ìhìnrere Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò,6 a nrí àwọn ìdáhùn tí a nwá. Nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀ àìlópin ni a fùn wa ni ẹ̀bùn kan to tayọ ìwọ̀n—ọ̀kan ti ìrètí, ìwòsàn, àti ìdánilójú wíwà Rẹ̀ nígbà gbogbo, tí ó npẹ́ títí ninu ìgbèsí ayé wa.7 Ẹ̀bùn yí wà ní àrọ́wọ́tó sí gbogbo ẹnití ó bá nawọ́ jáde pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ní gbígba àláfíà àti ìràpadà tí Ó fún wa lọfẹ mọ́ra.

Olúwa na ọwọ́ Rẹ̀ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa, àpẹrẹ tí ó jẹ́ pàtàkì gan-an ti ìfẹ́ àti inúrere àtọ̀runwá Rẹ̀. Ìfipè Rẹ̀ sí wa tayọ ìpè kan lásán; ó jẹ́ ọ̀fà àtọ̀runwá, tí a fún lókun nípa agbára pípẹ́ títí ti oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀. Nínú àwọn ìwé-mímọ́, Ó fi pẹ̀lú ifẹ́ dá wa lójú:

“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó nṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.

“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí: ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.

“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”8

Ṣìṣe kedere ìfipè Rẹ̀ “Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi” àti “Ẹ gba àjàgà mi” fi ẹsẹ̀ ìjìnlẹ̀ àdánidá ti ìlérí Rẹ̀ múlẹ̀—ìlérí tó pọ̀ tó sì pé tobẹ́ẹ̀ tí o fi ṣe àpẹrẹ ìfẹ́ Rẹ̀, ní fífúnni ní ìdánilójú ọ̀wọ̀ kan pe: “Ẹ̀yin ó rí ìsinmi.”

Bí a ti nfi pẹ̀lú aápọn lépa ìtọ́ni ti ẹ̀mí,9 a ndáwọ́lé ìrìn-àjò àtúnṣe ìjìnlẹ̀ kan tí ó nfún ẹ̀rí wa lókun. Bí a ti nní òye títóbi ìfẹ́ pípé ti Baba wa Ọ̀run àti Jésù Krístì,10 ọkàn wa nkún fún ìmoore, ìrẹ̀lẹ̀,11 àti ọ̀tun ìfẹ́ inú láti lépa ipa ọ̀nà jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn.12

Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé “Nígbàtí ìfojúsùn ti ìgbésí ayé wa bá wà lórí ètò ìgbàlà Ọlọ́run … àti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ láìkà ohun tó nṣẹlẹ̀ sí—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀—nínú ìgbésí ayé wa. Ayọ̀ nwá láti ọ̀dọ̀ àti nítorí Rẹ̀.”13

Álmà, ní bíbá ọmọ rẹ̀ Hẹ́lámánì sọ̀rọ̀, wí pé: “Àti nísisìyí, Áà ọmọ mi, Hẹ́lámánì, kíyèsĩ, ìwọ wà ní èwe rẹ, àti nítorínã, mo bẹ̀ ọ́ pé kí ìwọ ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí ìwọ ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorítí èmi mọ̀ pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run ni a ó ràn lọ́wọ́ nínú àwọn àdánwò wọn; àti àwọn ìṣoro wọn, àti ìpọ́njú wọn, a ó sì gbé wọn sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn.”14

Hẹ́lámánì, ní bíbá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀, kọ́ni nípa ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ayérayé yí ti fífi Olùgbàlà sí ààrin gbùngbùn ìgbésí ayé wa: “Ẹ rántí, ẹ ránti pé ní orí àpáta Olùràpadà wa, ẹnití í ṣe Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ni ẹ̀yin gbọdọ̀ kọ́ ìpìlẹ̀ yín lé.”15

Ninú Máttéù 14 a kọ́ pé lẹ́hìn gbígbọ́ nípa ikú Jòhánnù Onítẹ̀bọmi, Jésù wá láti dánìkanwà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èrò tẹ̀lé E. Mímọ̀ lára nípa àánú àti ìfẹ́, àti láìfi àyè gba ìbànújẹ́ Rẹ̀ láti dààmú Rẹ̀ kúrò ninu iṣẹ́ ìhìnrere Rẹ̀, Jésù gbà wọ́n mọ́ra, ní ṣíṣe ìwòsàn àwọn aláìsàn ní ààrin wọn. Bí ìrọ̀lẹ́ ti mbọ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn náà dojúkọ ìpèníjà líle kan: ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn èrò pẹ̀lú oúnjẹ díẹ̀ ni àrọ́wọ́tó. Wọ́n gbèrò pé kí Jésù rán àwọn èrò náà lọ láti ra oúnjẹ, ṣùgbọ́n Jésù, pẹ̀lú ìfẹ́ gíga àti àwọn ìrètí gíga, sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn láti bọ́ wọn dípò bẹ́ẹ̀.

Nígbàtí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nṣe akitiyan pẹ̀lú ìpèníjà ẹsẹ̀kẹsẹ̀, Jésù ṣe àfihàn ìgbẹ́kẹ̀lé ninu àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún Baba Rẹ̀, ní àfikún pẹ̀lú ìfẹ́ àìleyẹ̀ fún àwọn ènìyàn náà. O darí àwọn èrò náà láti joko lórí koríko, àti ní mímú awọn ìṣù àkàrà márun ati ẹja méjì péré, Ó yàn láti fi ọpẹ́ fún Baba Rẹ̀, ní jíjẹ́wọ́ ìpèsè ti Ọlọ́run lórí àṣ̣ẹ ati agbára Rẹ̀.

Lẹ̀hìn tí Ó ti dúpẹ́, Jésù bu búrẹ́dì náà, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn sì pín in fún àwọn ènìyàn náà. Pẹ̀lú ìyanu, kìí ṣe pé oúnjẹ náà tó nìkan ṣùgbọ́n ó pọ̀ púpọ̀, pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ méjìlá àwọn àjẹkù. Ninú ẹgbẹ́ tó jẹun ni ẹgbẹ̀rún márun (5,000) àwọn ọkùnrin wà, pẹ̀lu àwọn obìnrin áti àwọn ọmọdé.16

Iṣẹ́ ìyanu yìí kọ́ni ní ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ kan: nígbàtí a bá ni ìdojúkọ pẹ̀lú àwọn ìpèníjà, ó máa nrọrùn láti di dídi lọ́wọ́ ninu àwọn ìṣòro wa. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jésù Krístì ṣe àpẹrẹ agbára fífi ojú sùn sórí Baba Rẹ̀, rírú ẹbọ-ọrẹ ìmoore, ati jíjẹ́wọ́ pé awọn ojutu sí awọn adánwò wa kìí fi ìgbà gbogbo wà pẹ̀lú àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n pẹ̀lu Ọlọ́run.17

Nígbàtí a bá bá àwọn ìṣòro pàdé, ní àdánidá a ó rò láti gbáralé lé àwọn ìdènà tí a kojú. Àwọn ìpèníjà wa jẹ́ ojúlówó wọ́n sì nílò àfiyèsí wa, síbẹ̀ ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ti ṣíṣẹ́gun wọn wà ninu àfojúsùn wa. Nípa fífi Krístì sí ibi pàtàkì àwọn èrò àti àwọn ìṣe wa, a nfi ara wa sí ìbámu pẹ̀lú ìwòye àti okun Rẹ̀.18 Àtúnṣe yi kò dín ìtiraka wa kù; dípò bẹ́ẹ̀, ó nràn wá lọ́wọ́ láti là wọ́n kọjá lábẹ́ ìtọ́ni àtọ̀runwá.19 Bíi àyọrísí, a nṣe àwárí àwọn ìyanjú àti àtìlẹ́hìn tó ndìde láti inú ọgbọ́n to ga jù. Ṣíṣe àmúlò ìwòye àfi-Jèsù yí nrówa lágbára pẹ̀lú okun àti ojú inú láti yí àwọn àdánwò wa padà sí àwọn ìṣẹ́gun,20 tó nránwa létí pé pẹ̀lú Olùgbàlà, ohun tó dàbí ìṣòro pàtàkì le di ipa ọ̀nà sí ìtẹ̀síwájú ti ẹ̀mí títóbijù.

Ìtàn ti Álmà Kékeré ninu Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe àgbékalẹ̀ àlàyé wíwọnilára kan nipa ìràpadà àti ìjìnlẹ̀ ipá ti fífi ayé ẹni si àyíká Krístì. Ní àkọ́kọ́, Álmà dùró bíi alátakò Ìjọ Olúwa, tí ó ndarí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣìnà kúrò ní ipa ọ̀nà òdodo. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdásí àtọ̀runwá kan, ti a ṣe àmì rẹ̀ nipa ìbẹ̀wò ti ángẹ́lì, ta á jí láti inu àwọn ìṣe búburú rẹ̀

Ní wákàtí rẹ̀ tó dúdú jùlọ, o jẹ́ dídá lóró nípa ẹ̀bi tí ó sì múratán láti wá ọ̀nà àbáyọ kúrò ninu ìbànújẹ́ ti ẹ̀mí rẹ̀, Álmà rántí àwọn ìkọ́ni baba rẹ̀ nipa Jésù Krístì ati agbára Ètùtù Rẹ̀. Pẹ̀lú ọkàn tó npòngbẹ fún ìràpadà, ó fi ìtara ronúpìwàdà ó sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìgbóná ọkàn fún àánu Olúwa. Àkókò pàtàkì yí ti jíjọ̀wọ́ ara ẹni pátápátá, ní mímú Krístì wá sí iwájú àwọn èrò rẹ̀ bí Álmà ti fi ìtara wá àánú Rẹ̀, ṣe okùnfà ìyípadà kan tó lápẹrẹ. Àwọn ẹ̀wọ̀n wíwúwo ti ẹ̀bi àti àìnírètí parẹ́, a sì rọ́pò wọn pẹ̀lú ìmọ̀lára títayọ ti ayọ̀ ati àlàáfíà.21

Jésù Krístì ni ìrètí wa ati ìdáhùn sí àwọn ìrora títóbi jùlọ ti ìgbésí ayé. Nípasẹ̀ ìrúbọ Rẹ̀, Ó san àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa Ó sì gbé gbogbo ìjìyà wa sí orí Ara Rẹ̀—ìrora, ìyànjẹ, ìbànújẹ́, àti ẹ̀rù—àti pé Ó ndáríjì Ó sì nwò wá sàn nígbàtí a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé ninu Rẹ̀ tí a sì lépa láti yí ìgbésí ayé wa padà sí dídára síi. Òun ni olùwòsàn wa,22 ní títùwá ninu ati títún ọkàn wa ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ ati agbára Rẹ̀, gẹ́gẹ́bí Ó ti wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ sàn ní àkókò wíwà lórí ilẹ̀ ayé Rẹ̀.23 Òun ni omi ìyè, ní ṣíṣe ìmúṣẹ awọn ìnílò ọkàn wa tó jinlẹ̀ jùlọ pẹ̀lú ìfẹ́ ati àánú Rẹ̀ léraléra. Èyí dàbi ìlérí tí Ó ṣe fún obìnrin ara Samáríà ni ibi kànga, ni fífúnni ní “kànga omi kan ti ó nsun jáde sí ìyè àìlópin.”24

Mo jẹ́ri pẹ̀lú ọ̀wọ̀ pé Jésù Krístì wà láàyè, pé Ó nṣe àkóso lórí èyí, Ìjọ mímọ́ Rẹ̀, Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.25 Mo jẹ́ri pé Òun ni Olùgbàlà aráyé, Ọmọ-Aládé Àlãfíà,29 Ọba awọn ọba, Olúwa awọn olúwa,30 Olùràpadà aráyé. Mo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé a wà ní inú ati ọkàn Rẹ̀ nígbà gbogbo. Bíi májẹ̀mú kan sí èyí, Ó ti mú Ìjọ Rẹ̀ padàbọ̀sípò ní awọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí, Ó sì ti pe Ààrẹ Russell M. Nelson bíi wòlíì Rẹ̀ ati Ààrẹ Ìjọ ni akókò yí.31 Mo mọ̀ pé Ó fi ẹ̀mi Rẹ̀ lélẹ̀ pé kí àwa ó le ní ìyè ayérayé.

Bí a ti ntiraka láti fi Òun sí ààrin gbùngbùn ìgbésí ayé wa, àwọn ìfihàn nṣí sí wa, ìjìnlẹ̀ àlàáfíà Rẹ̀ nyí wa ká, Ètùtù àìlópin Rẹ̀ sì nmú ìdáríjì àti ìwòsàn wa wá.32 Ninú Rẹ̀ ni a ti ṣe àwárí okun láti borí, ìgboyà láti tẹramọ́, àti àlàáfíà to kọjá gbogbo òye. Njẹ́ kí a le tiraka ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti fà súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀ síi, orísun gbogbo ohun tó dára,30 àmì ìrètí ninu ìrìn-àjò wa padà sí ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.