Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Èrò Ọlọ́run Ni Láti Mú Yín Wálé
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Èrò Ọlọ́run Ni Láti Mú Yín Wálé

Ohun gbogbo nípa ètò Baba fún àwọn ọmọ Rẹ̀ jẹ́ àpẹrẹ láti mú gbogbo ènìyàn wálé.

Èmi yíò fẹ́ láti fi ìmòore hàn fún àwọn àdúrà yín bí mo ti bẹ̀rẹ̀ ìlànà ṣíṣe àtúnṣe sí ìpè náà, nípasẹ̀ Ààrẹ Nelson, láti sìn bí Àpóstélì Olúwa Jésù Krístì. Ó ṣeéṣe kí ẹ lè fojú inú wo bí èyí ti jẹ̀ rírẹnisílẹ̀ tó lára, ó sì ti jẹ́ àkókò rúkèrúdò tó ṣàrà ọ̀tọ̀ àti àyẹ̀wò ara ẹni tó gba ìronú jinlẹ̀. Ó jẹ́, síbẹ̀síbẹ̀ ọlá nla jùlọ láti sin Olùgbàlà, ní eyikeyi agbàra, àti láti ṣe alabapin pẹ̀lú rẹ̀ ní pínpín ìròhìn rere ti ìhìnrere ìrètí Rẹ̀.

Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti wí pé lẹ́hìn gbogbo Àpóstélì titun ni ìyá ìyàwó yìyanilẹnu kan. Èmí ò mọ bóyá a ti sọ́ ìyẹn ní òtítọ́, ṣùgbọ́n ní ọ̀ràn yí, dájúdájú ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Mo fura pé bí ìyá ìyàwó mi kò sì pẹ̀lú wa mọ́ kò ṣe nkankan láti dín ìyàlẹ́nu rẹ̀ kù.

Ní ọ̀pọ̀ oṣù sẹ́hìn, nígbàtí èmi àti ìyàwó mi nṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè míràn fún onírúurú iṣẹ́ ìyànsílẹ̀ Ìjọ, mo jí ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kan, mo sì wòran dáadáa níta fèrèsé ilé ìtura wa. Ní ìsàlẹ̀ ní òpópónà tí ó dí, mo ríi pé wọ́n ti ṣètò ọ̀nà kan pẹ̀lú ọlọpa kan tí ó dúró nítòsí láti yí àwọn ọkọ̀ padà bí wọ́n ṣe dé ibi ìdènà náà. Lakọkọ, àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ díẹ̀ péré ló rìn lójú ọ̀nà tí wọ́n sì yí padà. Ṣùgbọ́n bí àkokò ti nlọ tí ọkọ̀ sì npọ̀ sí i, àwọn ìlà ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í tó.

Láti ojú fèrèsé tó wà lókè, mo ti wo bí ọlọpa náà ṣe dà bí ẹni pé ó ní ìtẹ́lọ́rùn nínú agbára rẹ̀ láti dí ọ̀nà ìrìnàjò tí ó sì nyí àwọn ènìyàn padà. Ní tòótọ́, ó dàbí ẹnipé ó ní orísun nínu ìgbésẹ̀ rẹ̀, bí ẹnipé ó lè bẹ̀rẹ̀ síí ṣe jigì kékeré kan, bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kọ̀ọ̀kan ti súnmọ́ ìdènà náà. Bí ìdààmú bá bá awakọ̀ kan nípa ídínà ojú ọ̀nà, ọlọpa náà kò ṣèràn lọ́wọ́ tàbí kẹ́dùn. Ó kàn mi orí léraléra ó sì tọ́ka sí ọ̀nà ìdàkejì.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ̀yin ọmọ ẹ̀yìn ẹlẹ́gbẹ́ mi ní ojú ọ̀nà ayé kíkú tí nṣamọ̀nà—nípasẹ̀ Jésù Krístì—padà sí ilé ayérayé wa: Ètò rírẹwà Baba wa, àní ètò “àgbàyanu” Rẹ̀, tí a ti múra sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, tí a ṣe láti mú yín wá sílé, kìíṣe láti fiyín sílẹ̀ síta. Kò sẹ́ni tó mọ ìdínà tí ó si mú ẹnìkan síbẹ̀ láti yí yín padà kí ó sì rán yín lọ. Ní tòótọ́, ó jẹ́ ìdàkejì gangan. Ọlọ́run nlépa yín láìṣàárẹ̀. Ó fẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ yàn láti padà sọ́dọ̀ Rẹ̀,” Ó sì nlo gbogbo ìwọ̀n tí ó ṣeéṣe láti mú yín padà wá.

Baba wa olùfẹ́ni ló bójú tó ìṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé yìí gan-an fún èrèdí ṣíṣe kedere láti pèsè ànfàní fún ìwọ àti fún èmi láti ní àwọn ìrírí nínà àti ìyọ́mọ́ ti ikú, ànfààní láti lo agbára láti yàn tí Ọlọ́run fi fún wa láti yan Òun, láti kẹ́kọ̀ọ́, lati dàgbà, láti ṣe àwọn àṣìṣe, láti ronúpìwàdà, láti nifẹ Ọlọ́run àti ẹnìkejì wa, àti láti padà sí ilé lọdọ̀ Rẹ̀ lọ́jọ́ kan.

Ó rán Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ iyebíye sí ayé tí ó ti ṣubú yìí láti gbé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìrírí ènìyàn, láti pèsè àpẹrẹ fún àwọn ọmọ Rẹ̀ yòókù láti tẹ̀lé, àti láti ṣe ètùtù àti láti ràpadà. Ẹ̀bùn ètùtù nlá ti Krístì mú gbogbo ìdínà ikú ti ara àti ti ẹ̀mí kúrò tí yíò yà wá kúrò nínú ilé ayérayé wa.

Ohun gbogbo nípa ètò Baba fún àwọn ọmọ Rẹ̀ jẹ́ àpẹrẹ láti mú gbogbo ènìyàn wálé.

Kíni àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run, àwọn wòlíì Rẹ̀, pé ètò yí nínú ìwé mímọ́ ti Ìmúpadàbọ̀sípò? Wọ́n npèé ní ètò ìràpadà, ètó àánú, ètó ìdùnnú nla, àti ètò ìgbàlà tí ó wà fún gbogbo ènìyàn, “nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo.”

Èrò ètò ìdùnnú nlá ti Baba ni ìdùnnú yín, níhìn-ín, nísisìyí, àti ní ayérayé. Kìí ṣe láti ṣe ìdíwọ́ ìdùnnú wa àti láti fà àníyàn àti ìbẹ̀rù fún wa dípò.

Èrò ètò ìràpadà Baba ní tòótọ́ ni ìràpadà wa, tí a gbà wá nípasẹ̀ àwọn ìjìyà àti ikú Jésù Krístì, ní ìdándè kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Kìí ṣe láti fi yín sílẹ̀ bí ẹ ṣe wa.

Ète ètò àánú Baba ni láti nawọ́ àánú bí a ṣe nyípadà sí I kí a sì bọlá fún májẹ̀mú ìdúróṣinṣin sí I. Kìí ṣe láti sẹ́ àánú àti dípò rẹ̀ fúnni ní ìrora àti ìbànújẹ́.

Èrò ètò ìgbàlà Baba wa ní òtítọ́ ni ìgbàlà wa nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà ti ògo bí a ti ngba ẹ̀rí Jésù” kí a sì fi gbogbo ọkàn wa fún Un. Kìí ṣe láti pa wá mọ́ síta.

Njẹ́ èyí túmọ̀ sí pé ohunkohun lọ pẹ̀lú bí a ṣe ngbé ìgbésí ayé wa? Wípé ọ̀nà tí a yàn láti lo agbára láti yàn wà kò ṣe pàtàkì? Pé a lè gbà tàbí fi àwọn òfin Ọlọ́run sílẹ̀? Rárá, dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́. Dájúdájú ọ̀kan nínú àwọn ìpè àti ẹ̀bẹ̀ dídúró láìyẹsẹ̀ Jésù nígbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀ ni pé kí a yí padà kí a sì ronúpìwàdà kí a sì wá sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ní pàtàkì ní gbogbo àwọn ikẹkọ Rẹ̀ láti gbé ní ipò gíga ti ìwà jẹ́ ipè sí ìlọsíwájú ti araẹni, sí ìgbàgbọ́ ìyípadà nínú Krístì, sí ìyípadà nlá ti ọkàn.

Ọlọ́run nfẹ́ àtúnṣe tó gbòde kan ti ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìgbéraga wa, ìparun ènìyàn àdánidá, fún wa láti “lọ, kí a má sì dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”

Bí a bá gbàgbọ́ gbogbo èrò Baba ni láti gbàwálà, ràwápadà, nawọ́ àánú síwa, nípa bẹ́ẹ̀ mú ayọ̀ fún wa, kí ni èrò Ọmọ nípasẹ̀ ẹni ti a mú ètò nlá yìí wá?

Ọmọ náà sọ fún wa fúnra rẹ̀ pé: “Nítorí èmi sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ ti ara mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”

Ìfẹ́ Jésù ni ìfẹ́ Baba onínúure! Ó fẹ́ mú kó ṣeéṣe fún gbogbo àwọn ọmọ Baba Rẹ̀ tó kẹ́hìn láti gba òpin ibiáfẹ́dé ti ètò náà— ìyè ayérayé pẹ̀lú Wọn. Kò sí ọ̀kan tí a yọ kúrò nínú agbàra àtọ̀runwá yí.

Bí ẹ bá ní ìtara láti ṣe àníyàn pé ẹ̀yin kì yíò diwọ̀n, tàbí pé àrọwọ́tó ìfẹ́ ti Ètùtù àìlópin ti Krístì fi àánú bo gbogbo ènìyàn míràn ṣùgbọ́n kìí ṣe ẹ̀yin, lẹ́hìnnáà ẹ kò ṣe àgbọ́yé. Àìlópin túmọ̀ sí àìlópin. Àìlópin bo ẹ`yin àti àwọn tí nifẹ.

Néfì ṣàlàyé òtítọ́ rírẹwà yìí: “Kò ṣe ohunkóhun bí kò ṣe fún ànfàní aráyé; nítorí ó fẹ́ aráyé, àní tí ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ kí ó lè fa gbogbo ènìyàn sọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorínáà, òun kò pàṣẹ fún ẹnikẹ́ni pé wọn kì yío ní ìpín nínú ìgbàlà rẹ̀.”

Olùgbàlà, Olùṣọ́-àgùtàn rere, lọ nwá àgùtàn Rẹ̀ tí ó sọnù títí Ó fi rí wọn. Òun “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó ṣ̣ègbé.”

“Apá àánú mi nà sí yín, ẹnití ó bá sì wá, òun ni èmí yíò gbà.”

“Njẹ́ ẹ̀yin ní aláìsàn lãrín yín? Ẹ mú wọn wá sìhín. Njẹ́ ẹ̀yin ní àwọn amúkun, tàbí afọ́jú, tàbí arọ, tàbí akéwọ́, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí àwọn gbígbẹ, tàbí adití, tàbí tí a pọ́n lójú ní onírurú ọ̀nà? Ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi èmi yíò sì wò wọ́n sàn, nítorítí èmi ní ìyọ́nú sí yín.”

Kò sọ obìnrin tí ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ nù, Kò fà sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ adẹ́tẹ̀, Kò kọ obìnrin tí a mú nínú àgbèrè sílẹ̀; kò kọ ẹni tí ó ronúpìwàdà—bí ó ti wù kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn le tó. Òun kì yíò sì kọ̀ yín tàbí àwọn tí ẹ fẹ́ràn nígbàtí ẹ bá mú ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrora ọkàn yín wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ìyẹn kìí ṣe ìpinnu Rẹ̀ tàbí èrò Rẹ̀, tàbí ètò Rẹ̀, èrèdí, ìfẹ́, tàbí ìrètí Rẹ̀.

Rárá, kò fi àwọn ìdínà àti àwọn ìdènà síbẹ̀; Ó mú wọn kúrò. Kò fi yín sílẹ̀ síta; Ó kíi yín wolé. Gbogbo iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ jẹ́ ìkéde ààyè ti èrò yìí.

Lẹ́hìnnáà dájúdájú ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ wá fúnrarẹ̀, èyítí ó ṣòro fún wa láti ní òye rẹ̀, kọjá agbára ikú wa láti ní òye. Ṣùgbọ́n, àti pé èyí jẹ́ “ṣùgbọ́n” a lóye rẹ̀, ó yé wa, èrò mímọ́, gbígbanilà ti ẹbọ ètùtù Rẹ̀.

Aṣọ ìkelé tẹ́mpìlì ya sí méjì nígbàtí Jésù kú lórí igi agbelebu, tí ó nṣàpẹrẹ wíwọ́nà padà sí iwájú Baba ti ya ní ọ̀nà gbígbòòrò—sí gbogbo àwọn tí yíò yíjú sí Ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé E, tí wọ́n gbé ẹrù wọn lé E, àti gba àjàgà Rẹ̀ sí orí wọn nípa ìsopò májẹ̀mú.

Ní ọ̀nà míràn, èrò Baba kìí ṣe nípa àwọn ìdínà. Kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ rí; kíì yíò jẹ́ bẹ́ẹ̀ láéláé. Njẹ́ àwọn ohun kan wà láti ṣe, àwọn òfin láti pamọ́, àwọn apákan ti àwọn ẹ̀dá wa láti yípadà? Bẹ́ẹ̀ni. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn wà ní àrọwọtó wa, kò kọjá agbára wa.

Èyí ni ìròhìn tí ó dára! Mo dúpẹ́ fún àwọn òtítọ́ tó rọrùn wọ̀nyí. Àpẹrẹ Baba, ètò Rẹ̀, ìpinnu Rẹ̀, èrèdí Rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀, àti ìrètí Rẹ̀ ní gbogbo láti mú yín láradá, gbogbo láti fún yín ní àláfíà, láti mú gbogbo yín wálé. Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹlẹri ni orúkọ Jésù Krístì, Ọmọ Rẹ̀, àmín.