Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Èso Tí Ó Ṣẹ́ kù
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Èso Tí Ó Ṣẹ́ kù

Níní Ẹmí Mímọ́ láti fi èdìdi di àwọn ìlànà wa ṣe pàtàkì tí a bá fẹ́ ní àwọn ìbùkún tí a ti ṣe ìlérí fún gbogbo ayérayé.

Bí ọmọdékùnrin kan, mo nífẹ, àwọn piishi titun tó pọ́n. Títí di òní, èrò gígé èso piishi tó pọ́n, tó lómi jẹ, pẹ̀lú adùn tángì rẹ̀ nmú kí ẹnu mi ṣomi. Nígbàtí a bá mú àwọn èso piishi tó ti gbó dáradára, wọ́n gba ọjọ́ méjì sí mẹ́rin ṣáájú kí wọn tó bàjẹ́. Mo ní àwọn ìrántí aládùn ti dídara pọ̀ mọ́ ìyá mi àtàwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò mi nínú ilé ìdáná wa bí a ṣe máa nṣe ìpamọ́ àwọn èso pishi tí a ti kórè fún ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tó mbọ̀ nípa dídi wọ́n sínú àwọn ìgò. Ti a ba tọju awọn eso piishi daradara, eso aladun yii yoo pẹ́ fún ọpọlọpọ ọdun, kii ṣe ọjọ meji si mẹrin nikan. Fun awọn píìshì, tí a bá pèsè rẹ̀ dáradára ti a sì mú un gbóná, èso náà yóò wà ní ìpamọ́ títí tí èdìdi yóò jẹ́ fífọ́.

Krístì darí wa láti “lọ mú èso jáde wá, … kí èso yín lè ṣẹ́ kù.”1 Ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn èso píìshì. Ó nsọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún Ọlọrún sí àwọn ọmọ Rẹ̀. Tí a bá dá àti tí a sì pa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, àwọn ìbùkún tí ó ní í ṣe pẹ̀lú májẹ̀mú wa lè gbòòrò kọjá ìgbé ayé yìí kí a sì fi èdìdì dìwọ́n sórí wa, tàbí wà ní ìpamọ́, títí láé, ni] dídi èso tó ṣẹ́kù fún gbogbo ayérayé.

Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ipa àtọ̀runwá Rẹ̀ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti Ìlérí, yóò fi èdìdì di ìlànà kọ̀ọ̀kan lórí àwọn tí wọ́n jẹ́ olóotọ́ sí àwọn májẹ̀mú wọn kí wọ́n lè fìdí múlẹ̀ lẹ́yìn ikú.2 Níní Ẹmí Mímọ́ láti fi èdìdi di àwọn ìlànà wa ṣe pàtàkì tí a bá fẹ́ ní àwọn ìbùkún tí a ti ṣe ìlérí fún gbogbo ayérayé, ní dídi èso tó ṣẹ́kù.

Èyí ṣe pàtàkì paapaa tí a bá fẹ́ láti jẹ́ gbígbéga.3 Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni: a gbọ́dọ̀ “bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òpin nínú ọkàn. … Dájúdájú, fún olúkúlukú wa, ‘òpin’ náà tí a ó fẹ́ jùlọ láti ṣeyọrí ni láti gbé titi lae pẹlu awọn ẹbí wa ni ipo ìgbéga kan nibiti a ó wa niwaju Ọlọrun, Baba wa Ọrun, ati Ọmọ Rẹ̀ Jesu Kristi.”4 Ààrẹ Nelson ti tún sọ pé: “Ìgbéyàwó ti Sẹ̀lẹ́stíà jẹ́ apákan pàtàkì ìgbáradì fún ìyè ayérayé. Ó nílò pé kí ẹnìkan ṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹnití ó tọ́, ní ibi tí ó tọ́, nípasẹ̀ àṣẹ tí ó tọ́, ati láti ṣègbọràn sí májẹ̀mú mímọ́ náà pẹ̀lú ìṣòtítọ́. Lẹ́hìnáà, ẹnìkán le ní ìdánilójú ìgbéga ní ìjọba sẹ̀lẹ́stíà ti Ọlọ́run.”5

Kíni àwọn ìbùkún ìgbéga? Wọ́n pẹ̀lú gbígbé níwájú Ọlọrún fún ayérayé papọ̀ bí ọkọ àti aya, ní jíjogún “àwọn ìtẹ́, àwọn ìjọba, àwọn ilẹ̀ ọba, àti àwọn agbára, … àti wíwà títílọ ti awọn irú ọmọ láé àti títí láé,”6 ní gbígba ohun gbogbo tí Ọlọ́run Baba ní.7

Olúwa fihàn nípasẹ̀ Joseph Smith:

“Nínú ògo ti sẹ̀lẹ́stíà àwọn ọ̀run, tàbí àwọn ìpele mẹ́ta ni ó wà;

“Àti pé láti gba eyìtí ó ga jùlọ, ènìyàn gbọ́dọ̀ wọnú ètò oyè àlùfáà yìí tí ó túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun àti ti ayérayé ti ìgbéyàwó];

“Àti pé tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò lè gbà á.

“Ó lè wọnú òmíràn, ṣùgbọ́n èyíinì ni òpin ìjọba rẹ̀; kò lè ní àlékún si.”8

A kọ́ ẹ̀kọ́ níhin pé ènìyàn lè wà ní ìjọba sẹ̀lẹ́stíà, tàbí gbé ní iwájú Ọlọ́run, kí ó sì jẹ́ àpọ́n. Ṣugbọn lati jẹ́ gbígbega ni ipele giga julọ ti ijọba sẹ̀lẹ́stíà, ẹnìkan gbọ́dọ̀ wọ inú ìgbéyàwó nípasẹ̀ àṣẹ ti ó yẹ àti lẹ́hìnnáà kí ó ṣe òtítọ́ sí àwọn májẹ̀mú ti ó dá nínú ìgbéyàwó náà. Bí a ṣe jẹ́ olóotọ́ sí àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí, Ẹ̀mí Mímọ́ ti Ìlérí lè fi èdìdí di májẹ̀mú ìgbéyàwó wa.9 Irú àwọn ìbùkún tí a fi èdìdì dì bẹ́ẹ̀ di “èso tí ó ṣẹ́ kù.”

Kíni a nílò láti fi pẹ̀lú ìṣòtítọ́ pa májẹ̀mú tuntun àti ti ayérayé ìgbéyàwó mọ́?

Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé oríṣi àwọn ìsopọ̀ méjì ló wà nígbàtí a bá wọnú májẹ̀mú ìgbéyàwó ayérayé: ìsopọ̀ ẹ̀gbẹ́ láàrin ọkọ àti aya, àti ìsopọ̀ ìnàró pẹ̀lú Ọlọ́run.10 Láti ní àwọn ìbùkún ìgbéga ní fífi èdìdí dì sórí wa kí ó sì wà lẹ́hìn ìgbésí ayé yi, a gbọ́dọ̀ jẹ́ olótitọ́ sí àwọn ìsopọ̀ ti ẹ̀gbẹ́ àti inaro ti májẹ̀mú náà.

Láti pa ìsopọ̀ ẹ̀gbẹ́ mọ́ pẹ̀lú ẹnìkeji rẹ, Ọlọ́run ti gba wa nímọ̀ràn láti “fẹ́ aya [tàbí ọkọ] [rẹ] pẹ̀lú gbogbo ọkàn [rẹ], kí o sì … fara mọ́ obìnrin [tàbí ọkùnrin] náà kìí sì ṣe ẹnìkẹ́ni míràn.”11 Fún àwọn tí wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó, láti fara mọ́ obìnrin tàbí ọkùnrin náà àti pé kìí ṣe ẹnìkẹ́ni míràn túmọ̀ sí pé ẹ o máa gba ìmọ̀ràn papọ̀ nínu ìfẹ́, ẹ ó nífẹ ẹ ó sì máa bójúto ara yín, ẹ o fi àkókò pàtàkì sílẹ̀ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya yín ju àwọn ànfàní ti ìta lọ, ẹ ó sì máa pe Ọlọrún láti ràn yín lọ́wọ́ láti borí awọn àìlágbára yín.12 Ó tún túmọ̀ sí pé kò sí ìfarakanra ti ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìbálòpọ̀ lákọlábo èyíkéyìí ní ìta ìgbéyàwó yín, pẹ̀lú ìṣekúṣe tàbí ìbádọ́rẹ̀ẹ́, kò sì sí àwòrán ìwòkuwò, èyí tí nmú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ dàgbà.13

Láti lè pa ìsopọ̀ ti ẹ̀gbẹ́ mọ́ nínú májẹ̀mú, ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹnìkejì gbọdọ̀ ní fẹ́ inú láti wà nínú ìgbéyàwó náà. Ààrẹ Dallin H. ​​Oaks kọ́ni láìpẹ́ yí pé: “A tún mọ̀ pé Òun [Ọlọ́run] kì yóò fipá mú ẹnikẹ́ni sínú àjọṣe tó ní èdìdí ní ìlòdì sí ìfẹ́ ọ̀kùnrin tàbí obìnrin náà. Àwọn ìbùkún ìbáṣepọ̀ tó ní èdìdí ni a mú dájú fún gbogbo àwọn ẹnití wọ́n bá pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́ ṣùgbọ́n kìí ṣe nípa fífi ipá ṣe ìbáṣepọ̀ tó ní èdìdí lórí ẹlòmíràn tí kò yẹ tàbí tí kò fẹ́.”14

Kíni ìsopọ̀ inaro tí Ààrẹ Nelson tọka si? Ìsopọ̀ ìnàró jẹ́ ọ̀kan tí a ṣe pẹ̀lú Ọlọrún.

Láti pa ìsopọ̀ inaro mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, a jẹ́ olóotọ́ sí àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì tí a ti ṣe tí ó ní í ṣe sí àwọn òfin ìgbọràn, ìrúbọ, ìhìnrere, ìwà mímọ́, àti ìyàsọ́tọ̀. A tún bá Ọlọ́run dá májẹ̀mú láti gba alábàákẹ́gbẹ́ wa ayérayé àti láti jẹ́ ẹnìkejì àti òbí olódodo. Bí a ṣe npa ìsopọ̀ inaro mọ́, a kúnjú ìwọ̀n fún àwọn ìbùkún jíjẹ́ ara ẹbí Ọlọ́run nípasẹ̀ májẹ̀mú Ábráhámù, pẹ̀lú àwọn ìbùkún ìrandíran, ìhìnrere, àti oyè àlùfáà.15 Àwọn ìbùkún wọ̀nyi tún jẹ́ èso tí ó ṣẹ́kù.

Nígbà tí a nírètí pé gbogbo àwọn tí wọ́n wọ inú májẹ̀mú titun ati ti àìlópin wà ní jíjẹ́ òtítọ́ tí wọ́n sì ní àwọn ìbùkún ní fífi èdìdí dì sóríí wọn fun gbogbo ayeraye, nígbà míràn àpẹrẹ náà dàbí pé ó kọjá àrọ́wọ́tó wa. Ní gbogbo iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi mo ti pàdé àwọn ọmọ-ìjọ tí wọ́n dá májẹ̀mú tí wọ́n sì pa wọ́n mọ́, ṣùgbọ́n tí ẹnìkejì wọn kò ṣe. Àwọn kan wà bákannáà tí wọn jẹ́ àpọ́n, tí kò láǹfààní láti ṣègbéyàwó nínú ayé ikú. Àwọn kan sì wà tí wọn kò jẹ́ olóotọ́ nínú àwọn májẹ̀mú ìgbéyàwó wọn. Kí ló nṣẹlẹ̀ sí awọn ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ipò wọ̀nyí?

  1. Tí o bá dúró bí olóotọ́ sí àwọn májẹ̀mú tí o dá nígbàtí o gba ẹ̀bùn tẹmpìlì, ìwọ yíò gba àwọn ìbùkún ti ara ẹni tí a ṣèlérí fún ọ nínú ẹ̀bùn náà àní bí ẹnìkejì rẹ bá ti sẹ́ májẹ̀mú rẹ̀ tàbí tí ó fà sẹ́yìn kúrò nínú ìgbéyàwó náà. Bí wọ́n bá ti fi èdìdì dì yín tí ẹ sì kọ ara yín sílẹ̀ lẹ́hìnwa, tí fífi èdìdi dì yín kò sì jẹ́ fífagi lé, àwọn ìbùkún ti ara ẹni ti èdìdì náà ṣì máa wúlò fún ọ bí o bá jẹ́ olóòtọ́.16

    Nígbàmíràn, nítorí ìmọ̀lára ìwà ọ̀dàlẹ̀ àti ìpalára tòótọ́ gidi, olóotọ́ ẹnìkejì kan lè fẹ́ fagi lé fífi èdìdi dì wọn pẹ̀lú aláìṣòótọ́ ẹnìkejì wọn láti jìnnà réré sí wọn bí ó bá ti ṣeéṣe tó, lórí ilẹ̀ ayé àti fún ayérayé. Tí o bá ní àníyàn pé ní ọ̀nà kan ìwọ yóò jẹ́ síso mọ́ ẹnìkejì tẹ́lẹ̀rí tí kò ronúpíwàdà, rántí, ìwọ kì yóò jẹ́ bẹ́ẹ̀! Ọlọ́run kò ní béèrè pé kí ẹnikẹ́ni wà nínú ìbáṣepọ̀ tí a fi èdìdí dí títí ayérayé lòdì sí ìfẹ́ rẹ̀. Baba Wa Ọ̀run yóò rí dájú pé àwa ó gba gbogbo ìbùkún tí àwọn ìfẹ́ inú àti àwọn yíyàn wa gbà láàyè.17

    Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, tí ìfagilé ti èdìdí bá ṣì wuni, a ó bọ̀wọ̀ fún agbára òmìnira. Àwọn ìlànà kan lè di títẹ̀lé. Ṣùgbọ́n èyí kò yẹ kí ó jẹ́ ṣíṣe láìròtẹ́lẹ̀! Àjọ Ààrẹ Èkínní dì àwọn kọ́kọ́rọ́ láti dè ní ayé àti ní ọ̀run mú. Ní kété tí ìfagilé èdìdí kan bá ti di fífi àṣẹ sí nípasẹ̀ Àjọ Ààrẹ Èkínní, àwọn ìbùkún tí ó jọmọ fífi èdìdi dì náà kò ní agbára mọ́; wọ́n ti fagile ní ẹ̀gbẹ́ àti ní ìnàró. Ó ṣe pàtàkì láti lóye pé láti gba àwọn ìbùkún ìgbéga, a gbọ́dọ̀ fi hàn pé a múra tán láti wọlé sínu àti láti pa májẹ̀mú tuntun àti àìlópin yí mọ́ ní òtítọ́, yálà nínú ayé yìí tàbí ní èyí tí nbọ̀.

  2. Fún àwọn tí wọ́n jẹ́ àpọ́n ọmọ Ìjọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí pé “ní ọ̀nà àti àkókò ti Olúwa fúnrarẹ̀, kò sí àwọn ìbùkún kankan tí a ó fàsẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn olóotọ́ Ènìyàn Mímọ́ Rẹ̀. Olúwa yio dá olukúlùkù lẹ́jọ́ yío sì san àn fún wọn ní ìbámu sí ìfẹ́ inú àtọkànwá àti ohun ṣíṣe pẹ̀lú.”18

  3. Ti o kò bá ti jẹ́ olótítọ́ sí àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì, ìrètí ha wà bí? Bẹ́ẹ̀ni Ìhìnrere Jésu Krístì tí a múpadàbọ̀sípò jé ìhìnrere ti ìrètí. Ìrètí náà nwá nípasẹ̀ Jésù Kristi pẹ̀lú ìrònúpìwàdà àtọkànwá àti títẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ Kristi pẹ̀lú ìgbọràn. Mo ti rí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n ṣe àṣìṣe nlá, tí wọ́n ru àwọn májẹ̀mú mímọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa nrí àwọn tí wọ́n ronúpìwàdà tọkàntọkàn, tí wọ́n njẹ́ dídáríjì, tí wọ́n sì padà sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Tí o bá ti sẹ́ àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì rẹ, mo rọ̀ ọ́ láti yípadà sí Jésù Krístì, gba ìmọ̀ràn pẹ̀lú Bíṣọ́pù rẹ, ronúpìwàdà, kí o sì ṣí ẹ̀mí rẹ sí agbára iwòsàn nlá tó wà nítorí Ètùtù Jésù Krístì.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, olùfẹ̀ni Bàbá wa Ọ̀run ti fún wa ní àwọn májẹ̀mú kí a lè ní àyè sí ohun gbogbo tí Ó ní ní ìpamọ́ fún wa. Àwọn ìbùkún mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀nyí dùn ju èyíkéyi èso orí ilẹ̀ ayé lọ. Wọ́n lè jẹ́ pípamọ́ fún wa títí láé bí a ṣe njẹ́ olótitọ sí àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wa.

Mo jẹri pé Ọlọrún ti mú àṣẹ padà bọ̀ sípò láti dè lórí ilẹ̀ ayé àti kí ó le jẹ́ dídè ní ọ̀run. Aṣẹ náà ni a rí nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. Ó wà lọ́wọ́ Àjọ Ààrẹ Èkíní àti Iyejú àwọn Méjìlá, a sì nlò ó lábẹ́ ìdarí Ààrẹ Russell M. Nelson. Àwọn tí wọ́n wọ inú májẹ̀mú tuntun àti àìlópin ti ìgbéyàwó tí wọ́n sì pa májẹ̀mú náà mọ́ ni a lè sọ di pípé kí wọ́n sì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ògo ti Bàbá níkẹhìn, láìka àwọn ipò tó kọjá agbára wọn sí.23

Àwọn ìbùkún tí a ṣe ìlérí wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ ti àwọn májẹ̀mú wa ni a le fi èdìdí dì sórí wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́ ti ìlérí kí ó sì di èso tí ó ṣẹ́kù láé àti títí láéláé. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Jòhánnù 15: 16

  2. Wo Dale G. Renlund, “Níní-ààyè sí Agbára Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn Májẹ̀mú,” Lìàhónà, May 2023, 35–38; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 132:7..

  3. Ìlànà kan ni a nfi èdìdì di nígbàtí a bá mú un fìdí múlẹ̀ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé nítorí pé ó nṣe é láti ọ̀dọ̀ ẹnití ó ní ọlá-àṣẹ tí a sì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

    À nní ìtẹ́sí láti ronú nípa àṣẹ ìfi èdidì dì bí ó ti wúlò sí àwọn ìlànà tẹ́mpìlì kan pàtó, ṣùgbọ́n àṣẹ náà ṣe kókó sí mímú kí ìlànà eyikeyi ní àṣẹ àti sísopọ̀ kọjá ikú. Agbára ìfi èdidì dì nfi ìdì olófin lé orí ìrìbọmi yín, fún àpẹrẹ, kí ó lè dì dídámọ̀ nihin àti ní ọ̀run. Nígbẹ̀hìn, gbogbo àwọn ìlànà oyè-àlùfáà ni à nṣe lábẹ́ àwọn kọ́kọ́rọ́ ti Ààrẹ Ìjọ, àti bí Ààrẹ Joseph Fielding Smith ti ṣàlàyé pé, “Òun [Ààrẹ Ìjọ] ti fúnni ní àṣẹ, ó ti fi àṣẹ fún wa, ó ti fi agbára ìfi èdidì dì sínú oyè-àlùfáà, nítorí òun ni ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ wọnnì mú.’ [ti Harold B. Lee fa jade, ninu Iroyin Apejọ, Oṣu Kẹwa. 1944, 75]” (D. Todd Christofferson, “Agbára èdidì Náà,” Lìàhónà, Nov. 2023, 20).

    “Ìṣe tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti Ìlérí di èdìdì jẹ́ èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀; ó jẹ́ èyí tí Olúwa fọwọ́ sí. … Kò sí ẹnití ó le purọ́ fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti lọ láìdálẹ́bi nipasẹ aimọ. … Àwọn ìlànà wọ̀nyí tún kan gbogbo ìlànà àti ìṣe nínú Ìjọ. Nípa bẹ́ẹ̀, bí àwọn méjèèjì [nínú ìgbéyàwó] bá jẹ́ ‘olódodo àti olóotọ́’ [Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 76:53], tí wọ́n bá yẹ, a fi èdìdì ìfìdí múlẹ̀ sórí ìgbéyàwó tẹ́mpìlì wọn; bí wọn kò bá yẹ, a kò dá wọn láre nípa Ẹ̀mí, a sì dáwọ́ ìfọwọ́sí Ẹ̀mí Mímọ́ dúró. Yíyẹ àtẹ̀lẹ́ yóò fi èdìdi náà lágbára àti pé àìṣòdodo yóò fọ́ èdìdi eyikeyi” (Bruce R. McConkie, “Ẹ̀mí mímọ́ ti ìlérí,” nínú Ìgbáradì fún Ìwé Akẹ́ko Ìgbeyàwó Ayérayé [2003], 136).

    Ẹ̀mí Mímọ́ ti Ìlérí ni Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fi àmì ìtẹ́wọ́gbà lé gbogbo ìlànà: ìrìbọmi, ìmúdájú, ìyàsọ́tọ̀, ìgbéyàwó. Ìlérì náà ni pe aó ri àwọn ìbùkún gbà nípasẹ̀ òtítọ́. Bí ẹnìkan bá rú májẹ̀mú, ìbáà ṣe ti ìbaptisí, ìlànà, ìgbéyàwó tàbí ohunkóhun mìíràn, Ẹ̀mí yóò yọ èdìdì ìtẹ́wọ́gbà kúrò, a kì yóò sì rí ìbùkún gbà. Gbogbo ìlànà ni a fi èdìdí dì, pẹ̀lú ìlérí èrè tí ó dá lórí òtítọ́. Ẹ̀mí Mímọ́ fa àmì ìtẹ́wọ́gbà kúrò níbi tí àwọn májẹ̀mú dídà” (Joseph Fielding Smith, Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìgbàlàkompu. Bruce R. McConkie [1998], 243).

  4. Russell M. Nelson, Ohun tí Ọgọ́run Ọdún Ìgbésí-Ayé Ti Kọ́mi (2023), 15. Gbogbo àwọn májẹ̀mú gbọ́dọ̀ jẹ́ èdìdí nípasẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́ ti ìlérí tí wọn yóò bá ní agbára lẹ́hìn àjínde àwọn òkú” (see Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 132:7

  5. Russell M. Nelson, “Ìgbeyàwó Sẹ̀lẹ́stíà,” Lìàhónà, Nov. 2008, 94.

  6. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 132:19

  7. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:38

  8. Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 131:1–4.

  9. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 132:19–20 Òpin àjò gígajùlọ náà—ìgbéga nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà—ni ìfojúsùn Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.” (Dallin H. Oaks, “Àwọn Ìjọba ti Ògo,” Làìhónà, Nov. 2023, 26).

  10. “Gẹ́gẹ́bí àwọn ìgbéyàwó àti àwọn ìdílé ṣe nṣàjọpín àkànṣe ìdè [èyí tí] ó dá ìfẹ́ àkànṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ìbáṣepọ̀ tuntun ṣe rí nígbàtí a bá so ara wa mọ́ra nípa májẹ̀mú ní tààràtà sí… Ọlọ́run” nígbàtí a bá wọnú májẹ̀mú tuntun àti àìnípẹ̀kun ti ìgbéyàwó (Russell M . Nelson, Ọkàn ti Ọ̀ràn náà,, 41–42).

  11. Ẹkọ ati Àwọn Májẹ̀mú 42:22bakanáà wo Ìwé Ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn, 38.6.16. Nínú ìjíròrò ìgbéyàwó níhìn-ín, mo ntọ́ka sí ìgbéyàwó ní ìbámu pẹ̀lú òfin Ọlọ́run, èyí tí ó ṣètúmọ̀ ìgbéyàwó gẹ́gẹ́bí ìsopọ̀ lábẹ́ òfin àti tí ó yẹ láàárín ọkùnrin àti obìnrin (wo “The Family: A Proclamation to the World,” Gospel Library).

  12. Wo “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí ÀgbáyéIbi-ìkàwé Ìhìnrere.

  13. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 42:22, 24

  14. Dallin H. ​​Oaks, “Awọn ijọba ti Ogo,”Líáhónà, Nov. 2023; àfikún àlàyé.

  15. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 86:8–11; 113:8; Ábráhámù 2:9–11.

  16. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 38.4.1.

    Nígbàtí mo nsìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere alákòókò kíkún kan ní Switzerland, èmi àti alábàákẹ́gbẹ́ mi ṣàjọpín ìhìnrere náà pẹ̀lú tọkọtaya àgbàyanu ará Switzerland kan tí wọ́n jẹ́ ẹni ọgọ́ta ọdún. Bí a ṣe nkọ́ tọkọtaya yìí lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọ Jésù Kristi tí a múpadàbọ̀sípò, obìnrin náà fi ìfẹ́ ńláǹlà hàn nínú ohun tí a nkọ́ni. Ní àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí ó kàn, ó jèrè ẹ̀rí ti òtítọ́ pé Ìjọ ti Jésù Krístì ti di ìmúpadàbọ̀sípò, pẹ̀lú àṣẹ títọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti pé Jésù Krístì ndarí Ìjọ Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì alààyè àti àpóstélì. A nretí láti kọ́ tọkọtaya yìí nípa ọ̀kan lára ​​àwọn ẹ̀kọ́ gíga jù lọ ti Ìmúpadàbọ̀sípò, àǹfààní fún ìgbéyàwó ayérayé. Ó yani lẹ́nu, bí ó ti wù kí ó rí, bí a ṣe nkọ́ tọkọtaya yìí lẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀kọ́ ìgbéyàwó ayérayé, obìnrin ará Switzerland náà sọ pé òun kò nífẹ̀ẹ́ sí wíwà pẹ̀lú ọkọ òun títí ayérayé. Lójú rẹ̀, ọ̀run kò kan wíwà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tí ó ti ṣègbéyàwó fún ọdún mẹ́rìndínlógójì (36). Arábìnrin yìí ṣèrìbọmi, àmọ́ ọkọ rẹ̀ kọ̀. A kò fi èdìdì dì wọ́n ní tẹ́mpìlì.

    Lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀, bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀run kì yóò jẹ́ ọ̀run láìjẹ́ pé wọ́n wà pẹ̀lú ẹnití wọ́n bá ṣègbéyàwó. Láti wà papọ̀ pẹ̀lu ìyàwó tí ó nífẹ, láéláé, nítòótọ́ dàbíi ọrun. Gẹ́gẹ́ bí Alàgbà Jeffrey R. Holland ṣe sọ̀rọ̀ nípa ọ̀wọ́n, aya rẹ̀ olùfẹ́, Pat, ọ̀run kì yóò jẹ́ ọ̀run láìsí rẹ̀ (wo “Scott Taylor: Fun Alàgbà Holland, Ọ̀run láìsí Iyawo Rẹ̀ àti Àwọn Ọmọ Rẹ̀ ‘Kò Jẹ́ Ọ̀run fún Mi,’” Ìròyìn Ìjọ, July 22, 2023, thechurchnews.com).

  17. Wo Dallin H. Oaks, “Dá Ààbò Bo àwọn ỌmọLìàhónà, Nov.–46.

  18. Russell M. Nelson, “Ìgbeyàwó Sẹ̀lẹ́stíàLàìhónàNov. 94.

  19. Wo Jòhánnù 14:15