Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìwà-títọ́: Ìhùwàsí Bíi-ti-Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Ìwà-títọ́: Ìhùwàsí Bíi-ti-Krístì

Gbígbé ìgbésí ayé ìwà-títọ́ nbéèrè pé kí a jẹ́ olotọ sí Ọlọ́run, sí ara wa, àti sí ìdánimọ̀ àtọ̀runwá wa.

Ní àwọn wákàtí ìparí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà, Ó lọ sí Òkè Ólífì sínú ọgbà kan tí à npè ní Getsemane Ó sì pe àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ láti dúró. Nísisìyí ni] Oun nìkan, Ó bẹ̀bẹ̀ sí Baba Rẹ̀, “Bí ìwọ́ bá fẹ́, mú kí ago yí kúrò lórí mi.” Níwọ̀nbí ó ti wà nínú ìrora, Ìjìyà Rẹ̀ tí ó mú Òun tìkara rẹ̀, “àní Ọlọ́run, títóbijùlọ ninu ohun gbogbo, láti gbọn-rìrì nítorí ìrora, àti láti ṣẹ̀jẹ̀ nínú gbogbo ihò ara, … àti ti O fẹ́ pé kí [Òun] máṣe mu nínú ago kíkorò náà, kí ó sì fàsẹ́hìn.” Síbẹ̀ ní àkókò àìnírètí jíjinlẹ̀ yí, Olùgbàlà kò fàsẹ́hìn “ṣùgbọ́n ó jẹ, ó sì parí ìmúrasílẹ̀ [Rẹ̀] fún àwọn ọmọ ènìyàn.”

Bí Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Baba, Jésù Krístì ní agbára lórí ikú, ìrora, àti ìjìyà ṣùgbọ́n kò fàsẹ́hìn. Ó mú májẹ̀mú tí Ó ti dá pẹ̀lú baba Rẹ̀ ṣẹ, àti ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó fi ìhùwàsí bíi Krístì hàn tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì nínú ayé tí a ngbé—ìhùwàsí ìwà-títọ́. Ó dúró ní òtítọ́ sí Ọlọ́run, sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, àti sí ìdánimọ̀ àtọ̀runwá Rẹ̀.

ìwà títọ́

Jésù Krístì ni àpẹrẹ wa. Gbígbé ìgbésí ayé ìwà-títọ́ nbéèrè pé kí a jẹ́ olotọ sí Ọlọ́run, sí ara wa, àti sí ìdánimọ̀ àtọ̀runwá wa. Ìwà-títọ́ nṣàn láti inú òfin nlá àkọ́kọ́ láti nifẹ Ọlọ́run. Nítorí pé ẹ nifẹ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ olotọ sí I nígbàgbogbo. Ẹ lóye pé títọ́ àti àṣìṣe wà, àti pé òtítọ́ pípé wà—òtítọ́ ti Ọlọ́run. Ìwà-títọ́ túmọ̀ sí pé a kò dín àwọn òsùnwọ̀n tàbí ìhùwàsí wa kù láti ṣe ìwúnilórí tàbí jẹ́ gbígbà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ẹ̀yin “ẹ ṣe ohun tí ó tọ́” kí ẹ sì “jẹ́ kí àbájáde náà tẹ̀le.” Àwọn àtúnyẹ̀wò àìpẹ́ yí sí Wàásù Ìhìnrere Mi ìwé atọ́nà ìránṣẹ́ ìhìnrere ní pàtàkì ṣe ìfikún ìwà títọ́ bí ìhùwàsí bíi ti Krístì.

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, a yàn Alàgbà Uchtdorf láti ṣe àtúntò èèkàn wa. Ní àkokò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò wa, ó bi mí ní ìbéèrè kan tí nkò tìí gbàgbé: “Njẹ́ ohun kan wà nínú ìgbésí ayé rẹ tí, bí a bá mú wá sí àfiyèsí àwọn aráàlú, yíò jẹ́ ohun àbùkù sí ìwọ tàbí Ìjọ?” Sí ìyàlẹ́nu, ọkàn mi yára sáré jákèjádò ìgbésí ayé mi, ní gbígbìyànjú láti rántí àwọn àkókò wọ̀nnì nígbàtí mo lè kùnà tí mo sì béèrè lọ́wọ́ ara mi pé, “bí àwọn ẹlòmíràn bá mọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe, kí ni wọ́n máa rò nípa mi tàbí Ìjọ?”

Ní àkokò náà, mo rò pe Alàgbà Uchtdorf nbèèrè nípa yíyẹ nìkan, ṣùgbọ́n mo ti wá sí òye pé ìbéèrè náà gan wà nípa ìwà-títọ́. Ṣé mo jẹ́ òtítọ́ sí ohun tí mo jẹ́wọ́? Njẹ́ aráyé yíò rí ìdúróṣinṣin laarin àwọn ọ̀rọ̀ àti àwọn ìṣe mi? Njẹ́ àwọn míràn yíò rí Ọlọ́run nípasẹ̀ ìwà mi?

Ààrẹ Spencer W. Kimball kọ́ni pé, “Ìwà-títọ́” jẹ́ “ifẹ́ àti agbára wa láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìgbàgbọ́ àti àwọn ìpinnu wa.”

Òtítọ́ sí Ọlọ́run

Ìgbé-ayé ìwà-títọ́ nílò wa láti kọ́kọ́ àti àkọ́kọ́ láti jẹ́ òtítọ́ sí Ọlọ́run.

Láti kékeré wa, a ti kọ ìtàn Dáníẹ́lì nínú ihò kìnnìún. Dáníẹ́lì ṣe òtítọ́ sí Ọlọ́run nígbàgbogbo. Àwọn ojúgbà rẹ̀ tó njowú “wá ọ̀nà láti wá àyè lòdì sí [i]” wọ́n sì gbìmọ̀ sí àṣẹ kan tó sọ pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí àwọn òrìṣà wọn nìkan. Dáníẹ́lì mọ̀ nípa àṣẹ náà ṣùgbọ́n ó lọ sí ilé—àti pẹ̀lú fèrèsé ”rẹ̀ ní ṣíṣí”—ó sì kúnlẹ̀, ó sì gbàdúrà sí Ọlọ́run Ísráẹ́lì lẹ́ẹ̀mẹta lóòjọ́. Nítorí èyí, a ju Dáníẹ́lì sínú ihò’ kìnnìún. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọba rí i pé Ọlọ́run Dáníẹ́lì ti dá a nídè, ó sì gbé àṣẹ titun jáde pé kí gbogbo ènìyàn “wárìrì kí wọ́n sì bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run Dáníẹ́lì: nítorí òun niỌlọ́run alààyè.”

Ọba mọ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìwà-títọ́ Dáníẹ́lì. Àwọn míràn rí Ọlọ́run nípasẹ̀ tiwa—àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Gẹ́gẹ́bí Dáníẹ́lì, ṣíṣe òtítọ́ sí Ọlọ́run yíò túbọ̀ yà wá sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé.

Olùgbàlà ránwa létí, “Nínú ayé ẹ̀yin ó rí ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.” Ààrẹ Nelson gbani nímọ̀ràn bíborí ayé: “[túmọ̀ sí bíborí ayé] túmọ̀ sí bíborí ìdánwò láti ṣe àníyàn síi nipa àwọn ohun ti ayé yí ju àwọn ohun ti Ọlọ́run. Ó túmọ̀ sí gbígbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì ju ẹ̀kọ́ àwọn ènìyàn lọ.” Bákanáà, a gbọ́dọ̀ tako ìdánwò láti rìn “ni ọ̀nà [tiwa], àti ni àwòrán ọlọ́run [tiwa], àwòrán ẹni tí ó dàbí ti ayé.”

Ìfamọ́ra alátakò ti ayé yi jẹ́ apákan pàtàkì ti ètò ìgbàlà Ọlọ́run. Bí a ṣe ndáhùn sí fífàmọ́ra náà jẹ́ kókó irú ẹni tí a jẹ́—ìwọ̀n ìwà-títọ́ wa. Fífàmọ́ra ti ayé lè jẹ́ tààrà bíi láti pa ìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó run, tàbí bíi àrekérekè bíi ìfiránṣẹ́ àwọn àsọyé àìlórúkọ olóminú ní ti ẹ̀kọ́ Ìjọ́ tàbí àṣà. Lílo ìwà-títọ́ nínú àwọn yíyàn wa jẹ́ afihàn ti òde nipa ìfarajì ti inú láti tẹ̀lé Jésù Krístì Olùgbàlà.

Òtítọ́ sí Ẹlòmíràn

Gẹ́gẹ́bí ìwà títọ́ ti nṣàn láti inú òfin nlá àkọ́kọ́ láti nifẹ Ọlọ́run, ṣíṣe òtítọ́ sí ara wa nṣàn láti inú èkejì, láti nifẹ àwọn aládùúgbò wa gẹ́gẹ́bí ara wa. ìgbésí ayé ìwà-títọ́ kìí ṣe ìgbésí ayé jíjẹ́ pípé; ó jẹ́ ìgbésí ayé nínú èyítí a nlàkàkà lójoojúmọ́ láti kọ́kọ́ jẹ́ òtítọ́ sí Ọlọ́run àti nínú àyíká ọ̀rọ̀ náà láti jẹ́ òtítọ́ sí àwọn ẹlòmíràn. Ààrẹ Oaks rán wa létí pé, “Ìtara wa láti pa òfin kejì [náà] mọ́ kò gbọ́dọ̀ mú wa lati gbàgbé ti àkọ́kọ́.”

Aráyé nja ìjàkadì púpọ̀ síi pẹ̀lú ìwà-títọ́ nípa gbígbé àwọn kóòdù ìwà léni lórí tàbí àwọn òfin ìṣe tí ó ṣe àkóso àwọn ìbáṣepọ̀ laarin àwọn ènìyàn àti àwọn ilé-iṣẹ́. Nígbàtí ó dára, àwọn òfin wọ̀nyí ní a kò fi ìdákọ̀ró wọn sínú òtítọ́ pípé wọ́n sì fì sí yíyípadà dà lórí ìtẹ́wọ́gbà sí àṣà. Nì ìfarajọ sí ìbéèrè ti Alàgbà Uchtdorf bèèrè, àwọn àjọ ilé iṣẹ́ kan ṣe idánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ láti ronú báwo ni àwọn ìpinnu wọn tàbí ìlànà ṣíṣe ìpinnu yíò ṣe rí tí wọ́n bá tẹ̀ẹ́ jáde lórí ayélujára tàbí ní ojú-ewé iwájú ti ìwé ìròhìn pàtàkì kan. Bí Ìjọ ti jáde wá kúrò nínú kọ́rọ́ àti òkùnkùn, àwa, bí Dáníẹ́lì, gbọ́dọ̀ dìde tayọ àwọn ìrètí ti ayé kí á sì di ìwò ojú Ọlọ́run òtítọ́ ati alààyè ní gbogbo ìgbà àti ní ibi gbogbo.

Sísọ pé a ní ìwà-títọ́ kò tó bí àwọn ìṣe wa kò bá wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wa. Bákanáà, ìṣoore Krístíánì kì í ṣe ìrọ́pò fún ìwà-títọ́. Bí ènìyàn májẹ̀mú, àti bí olùdarí nínú Ìjọ Rẹ̀, a gbọ́dọ̀ wà tayọ ẹ̀gàn kí a sì wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òsùnwọ̀n tí Olúwa ti gbé kalẹ̀.

Ṣíṣe pẹ̀lú ìwà-títọ́ ngbé ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé dúró ó sì nfi dá àwọn míràn lójú pé a nlépa láti ṣe ìfẹ́ Oluwa nìkan. Nínú àwọn ìgbìmọ̀ wa, a ntako àwọn ipa ìta a sì ntẹ̀lé ìlànà tí Olúwa fi hàn, ní wíwá àwọn òye làti ọ̀dọ̀ obìnrin àti ọkùnrin kọ̀ọ̀kan àti ṣíṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn onimisi tí a gbà.

Ìfojúsùn wa wà lórí Olùgbàlà, a sì nṣọ́ra láti yẹra fún àwọn ìṣe tí a lè rò pé ó nsìn fún àwọn ire ti ara wa, tó nṣe ànfàní fún ẹbí wa, tàbí tó nṣe ojurere ẹnìkan láìbìkítà fún ẹlòmíràn. A nlọ kúro ní ọ̀nà wa láti yẹra fún eyikeyi ìfura pé ọlá àwọn ènìyàn lè nípa lórí àwọn ìṣe wa, láti gba ìdánimọ̀ ti ara ẹni, ṣe àgbékalẹ̀ àwọn fífẹ́ràn díẹ̀ síi, ṣe àtúnsọ ọ̀rọ̀ wa, tàbí ṣe àtẹ̀jáde.

Òtítọ́ sí Ìdánimọ̀ Àtọ̀runwá Wa

Níkẹhìn, ìgbésí ayé ìwà-títọ́ nbéèrè pé ká jẹ́ òtítọ́ sí ìdánimọ̀ àtọ̀runwá wa.

A mọ díẹ̀ nínú àwọn tí kíì ṣe. Èyí tó ṣe pàtàkì gan-an ni Kòríhọ̀ aṣòdì sí Krístì, ẹni tó darí ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn kúrò, tó nfa ìrònú ti ara” wọn mọ́ra.” Síbẹ̀, ní àwọn àkokò ìkẹhìn ìgbésí ayé rẹ̀, ó jẹ́wọ́ pé, “Mo mọ̀ nígbàgbogbo pé Ọlọ́run kan wà.” Ààrẹ Henry B. Eyring kọ́ni pé irọ́ pípa “lòdì sí ìwà àdánidá ti ẹ̀mí wa,” ìdánimọ̀ àtọ̀runwá wa. Kòríhọ̀ tan ara rẹ̀ jẹ, òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀.

Ní ìyàtọ̀, Wòlíì Joseph Smith fi ìgboyà kéde pe, “Mo mọ̀ ọ́, mo sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ ọ́, nkò sì lè sẹ́ ẹ.”

Olúwa fẹ́ràn arákùnrin Joseph Hyrum ni Olúwa fẹ́ràn “nítorí ìwà-títọ́ ọkàn rẹ̀.” Òun àti Joseph jẹ́ olotọ títí dé òpin—òtítọ́ sí ìdánimọ̀ àtọ̀runwá wọn, ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀ tí wọ́n gbà, àti òtítọ́ sí ẹni tí wọ́n mọ̀ pé wọ́n lè dà.

Íparí

Njẹ́ kí á bára wa làjà “sí ìfẹ́ Ọlọ́run” kí á sì mú ìhùwàsí bíi-ti-Krístì ti ìwà-títọ́ dàgbà si. Njẹ́ kí á le tẹ̀lé àpẹrẹ wa, Olùgbàlà ti aráyé, kí a má sì ṣe fàsẹ́hìn ṣùgbọ́n gbé ìgbésí ayé tí ó jẹ́ òtítọ́ sí Ọlọ́run, sí ara wa, àti sí ìdánimọ̀ àtọ̀runwá wa.

Bí Jóbù ti wí pé, “Jẹ́ kí a wọ̀n mí ní ìdiwọ̀n kan, kí Ọlọ́run lè mọ̀ ìwà-títọ́ mi.” Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.