Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Di Gbígbémì nínú Ayọ̀ Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Di Gbígbémì nínú Ayọ̀ Krístì

Mo jẹ́rìí pé Bàbá wa Ọ̀run ngbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ tó kún fún omijé yíò sì fi ìgbà gbogbo dáhùn nínú ọgbọ́n pípé.

A ní ìfẹ́ rẹ̀, Alàgbà Kearon. Ṣé mo le yá àmì-ohùn yi fún ìṣẹ́jú mẹ́wa?

Àwọn Iṣẹ́ ìyanu Tí a Ṣàníyàn-fún

Nínú Májẹ̀mú Titun a kọ́ ẹ̀kọ́ ti Bartimeu afọ́jú, ẹnití ó kígbe sí Jésù tí ó nfẹ́ iṣẹ́ ìyanu kan. “Jésù wí fún un pé, Máa lọ ní ọ̀nà rẹ; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá. Àti lójúkannáà ó gba ìríran rẹ̀.”

Ní àkókò mìíràn, ọkùnrin kan ní Bẹthsáídà ṣàníyàn fún ìwòsàn. Ní ìdàkejí, iṣẹ́ ìyanu yi kò wá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, Jésù bùkún un lẹ́ẹ̀mejì kí a tó “mú un padà bọ̀sípò.”

Nínú àpẹẹrẹ kẹta, àpọ́stélì Paul náà “bẹ Olúwa lẹ́ẹ̀mẹ́ta” nínú ìpọ́njú rẹ̀, áti síbẹ̀síbẹ̀, sí ìmọ̀ wa, ẹ̀bẹ̀ ìtara rẹ̀ ni a kò fi fún un.

Àwọn ènìyàn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn ìrírí àràọ̀tọ̀ mẹ́ta

Nípa bẹ́ẹ̀, ìbéèrè yìí: Kínìdí tí àwọn kan fi máa nyára gba iṣẹ́ ìyanu tí wọ́n nretí, nígbàtí áwọn míran nfi sùúrù faradà, ní dídúró de Olúwa? A lè má mọ kini ìdí rẹ̀, síbẹ̀ pẹ̀lú ìmoore, a mọ Òun ẹnití ó “nífẹ̀ẹ́ [wa]” àti “[tí nṣe] ohun gbogbo fún ire àti ìdùnnú [wa].”

Àwọn Èrèdí Àtọ̀runwá

Ọlọ́run, ẹnití ó rí òpin láti ìbẹ̀rẹ̀, the beginning, fi dáni lójú pé, “Ìdààmú rẹ àti àwọn ìpọ́njú rẹ yóò jẹ́ fún ìṣẹ́jú díẹ̀,” a ó sì yà wọ́n sí mímọ́ “nítorí èrè rẹ.”

Ní ríràn wá lọ́wọ́ láti rí ìtumọ̀ síi nínú àwọn àdánwò wa, Alàgbà Orson F. Whitney kọ́ni pé: “Kò sí ìrora tí a njìyà, kò sí àdánwò tí a nírìírí tí ó ṣòfò. Ó ṣe ìrànṣẹ́ fun ẹkọ wa. … Gbogbo … tí a [fi sùúrù] faradà … , nṣe àgbéga àwọn ìwà wa, nsọ ọkàn wa di mímọ́, fa àwọn ẹ̀mi wa gùn, ó sì nmú wa ní ìtara àti nífẹ àìlẹ́gbẹ́ diẹ sii. … Nípasẹ̀ ìbànújẹ́ àti ìjìyà, làálàá àti ìpọ́njú, ni a fi njèrè ẹ̀kọ́ tí a wá síhìn-ín láti ní, èyí tí yóò sì mú kí a túbọ̀ dàbí [àwọn òbí wa ọ̀run].”

Níní òye pé “agbára Kristi [yíò] bà lé [òun]” nínú àwọn ìpọ́njú rẹ̀, Àpọ́stélì Paul náà fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Nítorí nígbàtí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbànâ ni mo di alágbára.”

Àwọn ìdánwò ìgbésí ayé jẹ́ri wa. Olùgbàlà paapaa “kọ́ ẹ̀kọ́ … igbọràn nípa” a sì sọ ọ́ di “pípé nípasẹ̀ àwọn ìjìyà.”

Ní ọjọ́ kan, Òun yóò sì fi ìyọ́nú kéde pé, “Kíyèsi, èmi ti tún ọ ṣe, èmi ti yàn ọ́ nínú ìléru ìpọ́njú.”

Wíwá láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn èrò àtọ̀runwá Ọlọ́run nmí ìrètí sínú àwọn ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì, ó sì nmú kí ìpinnu rú ní àwọn àkókò ìdààmú àti ìrora ọkàn.

Àwọn Ìwòye Àtọ̀runwá

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ààrẹ Russell M. Nelson ṣe àjọpín ìjìnlẹ̀ òye tó ṣe iyebíye yi: “Bí a ṣe nwo ohun gbogbo pẹ̀lú ojú ìwòye ayérayé, yóò mú ẹrù wa fúyẹ́ lọ́nà tó ṣe pàtàkì.”

Àwòrán
Holly àti Trey Porter.

Láìpẹ́ yìí, ìyàwó mi, Jill, àti èmi rí òtítọ́ yìí nínú ìgbésí ayé tòótọ́ ti Holly àti Rick Porter, tí ọmọkùnrin wọn ẹni ọdún méjìlá (12), Trey, kú nínú ìjambá iná kan. Pẹ̀lú àwọn ọwọ́ àti ẹsẹ̀ tó jóná gidigidi láti inú ìjàkadì akọni láti gba àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀ là, Holly jẹ́rìí nínú ìpàdé sacramenti ní wọ́ọ̀dù nípa àlàáfíà àti ayọ̀ ńlá tí Olúwa ti tú sórí ìdílé rẹ̀ nínú ìdààmú wọn, ní lílo àwọn ọ̀rọ̀ bí iṣẹ́ ìyanu, àrà ọ̀tọ̀, àti ìyàlẹ́nu!.

Àwòrán
Npàtẹ́wọ́ ọwọ́ ìwòsàn.

Ìbànújẹ́ tí kò ṣeé faradà ti ìyá iyebíye yìí ni a rọ́pò nipa àlàáfíà títayọ pẹ̀lú èrò yìí pé: “Ọwọ́ mi kìí ṣe ọwọ́ tí ngbani là. Ọwọ́ wọ̀nnì jẹ́ ti Olùgbàlà! Dípò kí nwo àpá mi bí ìránnilétí ohun tí nkò lè ṣe, mo nrántí àwọn àpá tí Olùgbàlà mi ní.”

Ẹ̀rí Holly mú ìlérí ti wòlíì wa ṣẹ pé: Bí ẹ ti nronú sẹ̀lẹ́stíà, ẹ`yin yóò wo àwọn àdánwò àti àtakò nínú ìmọ́lẹ̀ titun kan.

Alàgbà D. Todd Christofferson sọ pé: “Mo gbàgbọ́ pé ìpèníjà ti bíborí àti dídàgbà nínú ìpọ́njú wú wa lórí nígbà tí Ọlọ́run gbé ètò ìràpadà Rẹ̀ kalẹ̀ nínú ayé ṣáájú ikú. A níláti súnmọ ìpènijà náà nísisìyí ní mímọ pé Baba wa Ọ̀run yóò gbé wa dúró. Ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì pé kí a yí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Láìsí Ọlọ́run, àwọn ìrírí òkùnkùn ti ìjiyà àti ìpọ́njú máa njẹ́ ìrẹ̀wẹ̀sì, àìnírètí, àti ìkorò pàápàá.”

Àwọn Ìpilẹ̀sẹ̀-Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá

Láti yàgò fún òkùnkùn ti àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn ati dípò rẹ̀ kí a rí àlàáfíà, ìrètí, àti ayọ̀ nlá paapaa nígbà àwọn ìpèníjà ìgbé ayé tí ó nira, mo ṣàjọpín àwọn ipilẹ̀sẹ̀-ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá mẹ́ta bíi awọn ìfipè.

Èkínní—ìgbàgbọ́ tí ó lágbára jù nwá nípa fífi Jesu Kristi sí ipò àkọ́kọ́. “Wò mí ní gbogbo ìrònú, Ó kéde; “máṣe ṣiyèméjì, máṣe bẹ̀rù.” Ààrẹ Nelson kọ́ni:

“Ìyè ayérayé [wa] sinmi lé ìgbàgbọ́ [wa] nínú [Kristi] àti nínú Ètùtù Rẹ̀.”

Bí mo ti njìjàkadì pẹ̀lú ìrora gbígbóná janjan tí ìpalára mi ṣẹ̀ṣẹ̀ fà, mo ti ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ pàápàá fún Jésù Kristi àti ẹ̀bùn àìlóye ti Ètùtù Rẹ̀. Ronú nípa rẹ̀! Olùgbàlà jìyà ‘ìrora àti ìpọ́njú àti àwọn ìdẹwò onírúurú’ kí Ó lè tù wá nínú, mú wa láradá, [àti] kí ó sì gbà wá ní ìgbà àìní.”

Ó nbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ìpalára mi ti mú kí nmáa ronú léraléra lórí ‘tótóbi Ẹni Mímọ́ Ísráẹ́lì. Ní àkókò ìmúláradá mi, Olúwa ti fi agbára àtọ̀runwá Rẹ̀ hàn ní àwọn ọ̀nà àlàáfíà àti àìṣìṣe.”

“Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká,” Olùgbàlà wa gbàní yànjú; “mo ti borí ayé.”

Èkejì—ìrètí dídánjù nwá nípa wíwo àyànmọ́ ayérayé wa. Ní sísọ̀rọ̀ nípa agbára tó wà nínú ṣíṣe ìpamọ́ “ìran kan nípa àwọn ìbùkún àgbàyanu tí Baba wa ṣèlérí … lójú wa lójoojúmọ́,” Arábìnrin Linda Reeves jẹ́ri pé: “Èmi kò mọ ìdí tí a fi ní ọ̀pọ̀lọpọ́ àdánwò tí a ní, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìmọ̀lára tèmi fúnra mi pé èrè náà pọ̀ tóbẹ̀ẹ̀, … ní ayọ̀ tóbẹ̀ẹ̀ àti tí ó kọjá òye wa pé ní ọjọ́ èrè náà, a le ní ìmọ̀lára láti sọ fún aláanú, olùfẹ́ni Baba wa pé, ‘Ṣé gbogbo ohun tí a bèèrè lèyí?’ … Kíni yóò já mọ́ … ohun tí a jìyà níhin ti, ní ìparí, àwọn ìdánwo wọnnì… mú wa yẹ fún ìyè ayérayé … ni ìjọba Ọlọ́run?”

Ààrẹ Nelson ṣàjọpín ìjìnlẹ̀ òye yìí: “Ẹ wo ìdáhùn Olúwa sí Joseph Smith nígbà tí ó bẹ̀bẹ̀ fún ìtura nínú Liberty Jail. Olúwa kọ́ Wòlíì náà pé àwọn ìfiyà-jẹni rẹ̀ yìó fún un ní ìrírí yío sì jẹ́ fún rere rẹ̀. ‘Bí o bá fi ara dà á dáradára,’ Olúwa ṣe ìlérí, ‘Ọlọ́run yíò gbé ọ ga lókè.’ Olúwa nkọ́ Jósẹ́fù láti ronú sẹ̀lẹ́stíà àti láti fi ojú inú wo èrè ayérayé kan dípò fífi ojú sùn sórí àwọn ìṣòro onírora ti ọjọ́ náà.”

Ìyípadà ìwòye Jósẹ́fù mú ìsọdimímọ́ jíjinlẹ̀ wá, bí ó ti hàn nínú lẹ́tà yi pé: “Lẹ́hìn tí a ti se mi mọ́ awọn ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n fun oṣu marun-un, ó dàbí ẹnipé ọkàn mi yóò máa fi ìgbà gbogbo tutù lẹ́hìn èyí ju bí ó ti wà rí ní ìṣàájú lọ. … Mo rò pé èmi kò bá ti ní ìmọ̀lára bí mo ti ní báyìí bí èmi kò bá ti jìyà àwọn àṣìṣe tí mo ti jìyà.”

Ẹ̀kẹta—agbára nlá nwa nípa ìdojúkọ lórí ayọ̀. Lákokò àwọn wákàtí tó ṣe pàtàkì jùlọ tí ayérayé, Olùgbàlà wa kò dínkù ṣùgbọ́n ó jẹ́ alábapín nínú ago kíkorò náà. Báwo ni Ó ṣe ṣe é? A kẹ́kọ pé, “nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ̀ [Kristi] farada àgbélébu, ìfẹ́ Rẹ̀ “di gbígbémì nínú ìfẹ́ ti Baba.”

Àwòrán
Krísti ní Gẹ́tsémánì

Gbólóhùn yìí “gbé mì” wú mi lórí jinlẹ̀. Ìfẹ́ mi nínú rẹ̀ pọ̀ síi nígbàtí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé lédè Spáníṣì, “gbé mì” ni a túmọ̀ sí “gbé-mì pátápátá”; ní Jamaní, bíi “jẹ run”; àti ní Ṣainísì, bíi “bori.” Nípa bẹ́ẹ̀, nígbàtí àwọn ìpèníjà ìgbé ayé bá jẹ́ ìrora púpọ̀ tí ó sì kún fún ìbànújẹ́, mo rántí ìlérí Olúwa—pé a “kò gbọ́dọ̀ jìyà àwọn ìpọ́njú onírúurú, bíkòṣe kí ó [di] gbígbémì [gbémì pátápátá, jẹ-run, àti borí] nínú ayọ̀ Kristi.”

Mo rí ayọ̀ yìí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín, èyí tí “[tako] … òye ayé kíkú,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tíì mú àwọn ife kíkorò yín kúrò. Ẹ ṣeun fún títọ́jú àwọn májẹ̀mú yín àti dídúró bí ẹlẹ́ri fún Ọlọ́run Ẹ ṣeun fún nínawọ́ jáde láti bùkún fún gbogbo wa, nígbàtí “nínú ọkàn tí ó dákẹ́ jẹ́jẹ́ [yín] ni ìbànújẹ́ tí ojú kò leè rí farapamọ́ sí.” Nítorí nígbàtí ẹ bá mú ìtura Olùgbàlà wá fún àwọn ẹlòmíràn, ẹ nríi fún ara yín, ni Ààrẹ Camille Johnson kọ́ni.

Àwọn Ìlérí Àtọ̀runwá

Now, return with me to the sacrament meeting where we witnessed the miracle of Holly Porter’s family being succored by the Lord. Lórí ìdúró bí mo ṣe nronú ohun tí mo lè sọ láti tu ìdílé àràọ̀tọ̀ yi àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú, èrò yìí wá pé: “Lo àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà.” Nítorínáà, èmi yíò parí lóni bí mo ti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi náà, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, “èyítí ó wo ọkàn tí ó gbọgbẹ́ sàn.”

“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó nṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.”

“Èmi pẹ̀lú yóò mú àwọn àjàgà yín rọrùn èyítí a gbé lé èjìká yín, àní pé tí ẹ̀yin kì yío ní ìmọ̀lára wọn ní ẹ̀hìn yín, àní nígbàtí ẹ wà nínú ìgbèkùn; … kí ẹ̀yin le mọ̀ dájúdájú pé Èmi, Olúwa Ọlọ́run, mbẹ àwọn ènìyàn mi wò nínú àwọn ìpọ́njú wọn.”

“Èmi kì yíò fi yín sílẹ̀ ní aláìní ìtùnú: Èmi yíó tọ̀ yín wá.”

Ẹ̀ríì Mi

Pẹ̀lú ọ̀wọ̀ ìdùnnú, mo jẹ́rìí sí wíwà láàyè Olùgbàlà wa àti pé àwọn ìlérí Rẹ̀ dájú. Ní pàtàkì fún ẹ̀yin tí ìdààmú bá tàbí ẹ̀yin “tí a npọ́n lójú lọ́nàkọnàr,” Mo jẹ́rìí pé Bàbá wa Ọ̀run ngbọ́ ẹ̀bẹ̀ ẹ̀dùn-ọkàn rẹ àti pé yóò máa dáhùn nígbà gbogbo ní ọgbọ́n pípé. “Kí Ọlọ́run fifún yín,” gẹ́gẹ́bí Ó ti ṣe fún ìdílé wa ní àwọn àkókò àìní ńlá, “kí ẹrù yín lè fúyẹ́,” “àní “tí a gbé e mì nínú ayọ̀ Kristi. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.