Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Gbàdúrà, Ó Wà Níbẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Gbàdúrà, Ó Wà Níbẹ̀

Mo pè yín láti gbàdúrà láti mọ̀pé Baba Ọ̀run wà níbẹ̀, ẹ gbàdúrà làti dàgbà láti dabí Òun, kí ẹ sì gbàdúrà láti fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí àwọn ẹlòmíràn.

Ẹ̀yin arákùnrin ati arábìnrin, mo ní ìmọ̀lára ayọ̀ bí mo ti ndáhùn sí ìtẹ̀mọ́ra kan láti bá awọn ọmọdé sọ̀rọ̀!

Ẹ̀yin ọmọbìnrin àti ẹ̀yin ọmọkùnrin, níbikíbi tí ẹ bá wà ní àgbáyé, mo fẹ́ pín ohun kan pẹ̀lú yín.

Bàbá wa Ọ̀run nífẹ́ yín! Ẹ jẹ̀ ọmọ Rẹ̀. Ó mọ̀ ọyín. Ó nfẹ́ láti bùkún yín. Mo gbàdúrà pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi pé ẹ̀yin ó ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀.

Njẹ́ ẹ fẹ́ràn láti gba awọn ẹ̀bùn? Mo fẹ́ bá yín sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀bùn pàtàkì gidi kan tí Baba Ọ̀run ti fi fún yín láti ràn ọyín lọ́wọ́. Ẹ̀bùn àdúrà ni. Àdúrà ti jẹ́ irú ìbùkún kan tó! A le bá Baba Ọ̀run sọ̀rọ̀ nígbàkigbà, níbikíbi.

Àwòrán
Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọdé

Nígbàtí Jésù wà ní ilẹ̀ ayé, Ó kọ́ wa láti gbàdúrà. Ó wí pé, “Ẹ bẽrè, ẹ ó sì rí gbà.”1

Àwọn ẹ̀bùn wo ni ẹ le gbàdúrà fún? Púpọ̀ ló wà, ṣùgbọ́n loni mo fẹ́ ṣe àbápín mẹ́ta:

  1. Gbàdúrà láti mọ̀.

  2. Gbàdúrà láti dàgbà.

  3. Gbàdúrà láti fi hàn.

Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Ìkínní, Gbàdúrà láti Mọ̀

Kíni ẹ nílò láti mọ̀?

Orin kan wà nípa àdúrà tí awọn ọmọ Alakọbẹrẹ máa nkọ káàkiri gbogbo àgbáyé. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbéèrè kan. Njẹ́ ẹ mọ orin tí ó jẹ́? Bí mo bá ní ìgboyà gidi, emi ó kọ ọ́ fún yín!

“Baba Ọ̀run, njẹ́ O wà níbẹ̀ lõtọ́? Ati pé njẹ́ o ngbọ́ o sì ndáhùn àdúrà gbogbo ọmọdé?”2

Báwo ni ẹ ó ṣe mọ̀ bí Baba Ọ̀run bá wà níbẹ̀, àní nígbàtí ẹ kò le rí I?

Ààrẹ Russell M. Nelson ti pè yín láti “tú ọkàn yín jáde sí Bàbá yín Ọ̀run. … Àti nígbànáà ẹ fetísílẹ̀!”3 Ẹ fetísílẹ̀ sí ohun tí ẹ mọ̀lára ninu ọkàn yín, àti sí àwọn èrò tí ó wá sì inú yín.4

Baba Ọ̀run ni ara ẹran àti egungun ológo ó sì jẹ́ Baba ẹ̀mi yín. Nítorípé Baba Ọ̀run ní gbogbo agbára Ó sì mọ ohun gbogbo, Ó le rí gbogbo awọn ọmọ Rẹ̀5 Ó sì le gbọ́ kí Ó sì dáhùn gbogbo àdúrà. Ẹ le wá mọ̀ fún ara yín pé Ó wà níbẹ̀ ati pé Ó fẹ́ràn yín.

Nígbàtí ẹ bá mọ̀ pé Baba Ọ̀run jẹ́ òtítọ́ àti pé Ó fẹ́ràn yín, ẹ le gbé pẹ̀lú ìgboyà àti ìrètí! “Gbàdúrà, Ó wà níbẹ̀; sọ̀rọ̀, Ó nfetísílẹ̀.”6

Njẹ́ ẹ ti ní ìmọ̀lára dídánìkanwà rí? Ní ọjọ́ kan nígbàtí ọmọbìnrin-ọmọ wa Ashley, jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà, òun nìkan ni ó wà láìní ọ̀rẹ́ láti bá ṣeré ní orí pápá ìṣeré ilé iwé. Bí ó ti dúró níbẹ̀, ti ó nní ìmọ̀lára àìjẹ́nkankan àti àìrí, èrò kan pàtó wá sí inú rẹ̀: “Dúro! Èmi kò dá nìkan wà! Mo ní Krístì!” Ashley kúnlẹ̀ ní ààrin pápá ìṣeré níbẹ̀, ó ká àwọn apá rẹ̀ mọ́ra, ó sì gbàdúrà sí Bàbá Ọ̀run. Ní àkókò tí ó la ojú rẹ̀, ọmọbìnrin ọjọ́ orí rẹ̀ ndúró níbẹ̀, o nbèrè bí o bá fẹ́ láti ṣeré. Ashley wá mọ́ pé, “A ṣe pàtàkì sí Olúwa, a kò si dá nìkan wà rí nítòótọ́.”

Nígbàmíràn ẹ le fẹ́ mọ ìdí tí ohun líle kan fi nṣẹlẹ̀ ní ìgbésí ayé yín tàbí, ìdí tí ẹ kò fi gba ìbùkún kan ti ẹ gbàdurà fún. Ní ìgbà púpọ̀ ìbéèrè tó dára jùlọ láti bi Baba Ọ̀run kìí ṣe kínni ìdí ṣùgbọ́n kínni ohun náà?.

Njẹ́ ẹ rántí nígbàtí ebi npa Néfì ati ẹbí rẹ̀ bí wọ́n ti nrin ìrìn-àjò ninu aginjù? Nígbàtí Néfì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ láti wá oúnjẹ, Néfì kán ọrun rẹ̀. Òun kò béèrè pé kínni ìdí.

Àwòrán
Néfì béèrè lọ́wọ́ Léhì ibití yío ti ri oúnjẹ.

Néfì ṣe ọrun titun ó sì bi baba rẹ̀, Léhì, ibi tí òun le lọ láti rí oúnjẹ. Léhì gbàdúrà, Olúwa sì fi ibi tí Néfì le lọ hàn wọ́n.7 Baba Ọ̀run yio tọ́ yín nígbàtí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ Rẹ ohun tí ẹ le ṣe àti ohun tí ẹ le kọ́.

Ìkejì, Ẹ Gbàdúrà láti Dàgbà

Baba Ọ̀run fẹ́ ràn yín lọ́wọ́ láti dàgbà! Ó nifẹ́ wa púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí Ó fi rán Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, láti fi ọ̀nà hàn wá láti gbé.8 Jésù jìyà, Ó kú, a sì jí I dìde kí a lè gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì dàgbà láti dàbí Rẹ̀ síi

Njẹ́ ẹ fẹ́ dàgbà ninu sũrù tàbí ìwà òtítọ́? Njẹ́ ẹ fẹ́ dàgbà nínú iṣẹ́ ọwọ́ kan? Bóyá ẹ ntijú ẹ sì fẹ́ dàgbà ninu ìgboyà. “Gbàdúrà, Ó wà níbẹ̀”!9 Nípasẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ̀, ọkàn yín le yípadá. ẹ sì le gba okun.

Ọ̀rẹ́ mi titun Jonah kọ̀wé pé, “mo máa nfi ìgbà gbogbo ní ìmọ̀lára ara gbígbọ̀n ní ojú ọ̀nà sí ilé ìwé ní òwúrọ̀. Mo máa nṣe àníyàn nípa awọn nkan bíi pípẹ́ dé, gbígbàgbé ohun kan, àti ṣíṣe awọn ìdánrawò. Nígbàtí mo pé ọdún mẹ́wa, mo bẹ̀rẹ̀ sí sọ awọn àdúrà ní ojú ọ̀nà mi sí ilé ìwé ninu ọkọ̀ pẹ̀lú ìyá mi. Mo nbèrè fún ìrànlọ́wọ́ tí mo nílò, mo sì ngbàdúrà fún ẹbí mi náà. Bákannáà mo nronú awọn ohun tí mo ní ìmoore fún. [Gbígbàdúrà sí Bàbá Ọ̀run ti] rànmí lọ́wọ́. Nígbà míràn èmi kìí nímọ̀lára ìtura lọ́gán tí mo bá jáde ninu ọkọ̀, ṣùgbọ́n ìgbà ti mo bá fi máa dé kíláàsì mi, mo nní ìmọ̀lára àlàáfìà.”10

Ìgbàgbọ́ Jónà ndàgbà bí ó ti ngbàdúrà ní ojojúmọ́ ó sì ntẹ̀siwájú.

Ìkẹta, Gbàdúrà láti Fi Hàn

Ẹ lè gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ Baba Ọ̀run han àwọn ẹlòmíràn.11 Nípasẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ̀ Baba Ọ̀run yio ràn yín lọ́wọ́ láti fura sí ẹnìkan tí inú rẹ̀ kò dùn kí ẹ le tù wọ́n ninu. Ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn nipa dídáríji ẹnìkan. Ó le fún yín ní ìgboyà láti sin ẹnikan kí ẹ sì pin pẹ̀lú wọn pé wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Ẹ le ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá mọ̀ kí wọn ó sì fẹ́ràn Jésù áti Baba Ọ̀run bí ẹ̀yin ti ṣe.12

Fún gbogbo ayé mi mo gbàdúrà pé kí baba mi le di ọmọ-ijọ ti Ìjọ Jésù Krístì tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn. Àní bí ọ̀dọ́mọbìnrin kan, mo mọ iye ọ̀pọ̀ àwọn ìbùkún tí òun le gbà. Ẹbí wa le gba awọn ìbùkún ti fífi èdìdi dì fún ayérayé. Ẹbí mi, àwọn ọ̀rẹ́, àti èmi gbàdúrà fún un nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n òun kò darapọ̀ mọ́ Ìjọ. Baba Ọ̀run kìí fi ipá mú ẹnikẹ́ni láti ṣe àṣàyàn kan.13 Ó le rán àwọn ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa ní àwọn ọ̀nà míràn.

Àwòrán
Ààrẹ Porter pẹ̀lú àwọn òbí àti àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò rẹ̀.

Nígbàtí mo dàgbà tó, mo gba ìbùkún baba nlá mi. Ninu ìbùkún náà baba nlá sọ fún mi pé ohun tó dára jùlọ tí mo le ṣe láti ran ẹbí mi lọ́wọ́ láti wà papọ̀ ni ọ̀run ni láti jẹ́ àpẹrẹ ìhìnrere Jésù Krístì. Èyíinì ni ohun tí èmi le ṣe!

Baba mi gbé di ọgọ́rin ọdún àti mẹ́fà (86). Ọjọ́ márun lẹ́hìn tí o kú, mo gba ìmọ̀lára mímọ́ ayọ̀ kan. Baba Ọ̀run jẹ́ kí nmọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ̀ pé baba mi fẹ́ gba àwọn ìbùkún ìhìnrere Jésù Krístì. Èmi ko ní gbàgbé ọjọ́ tí mo kúnlẹ̀ ní àyíka pẹpẹ ninu tẹ́mpìlì pẹ̀lu arábìnrin mi àti àwọn arákùnrin, làti jẹ́ fífi èdìdi dì sí àwọn òbí mi. Mo ti bẹ̀rẹ̀sí gbàdúrà fún ìbùkún yí nígbàtí mo wà ní Alakọbẹrẹ, mo sì gbà á nígbàtí mo jẹ́ ìyá àgbà.

Bóyá ìwọ ngbàdúrà fún àwọn ìbùkún kan fún ẹbí rẹ àti àwọn ẹlòmíràn tí o fẹ́ràn. Máṣe sọ ìrètí nù. Baba Ọrun yío fi ohun tí ìwọ ó ṣe hàn ọ́.

Ṣe àbápín ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ pẹ̀lú Baba Ọ̀run.14 Bí ẹ ti nfi òtítọ́ bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, ẹ ó gba Ẹ̀mí Rẹ̀ láti tọ́ yín.15 Gbígba àdúrà ni ojojúmọ́ yío kún yín pẹ̀lú ìfẹ́ fún Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. Èyí yío ràn yín lọ́wọ́ láti fẹ́ tẹ̀lé Wọn ní gbogbo ayé yín!

Ẹ fi ojú inú wo ohun ti yío ṣẹlẹ̀ bi gbogbo àwọn ọmọdé ní Afríkà, Guúsù Amẹ́ríkà, Ásíà, Europe, Ariwa Amẹrika, ati Australia bá gbàdúrà lójojúmọ́? Gbogbo ayé yio di bibùkún fún pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run púpọ̀ síi!

Àwòrán
Awọn ọmọdé káàkiri àgbáyé ngbàdúrà.

Mo pè yín láti gbàdúrà láti mọ̀ pé Baba Ọ̀run wà níbẹ̀, ẹ gbàdúrà làti dàgbà láti dabí Òun, kí ẹ sì gbàdúrà láti fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí àwọn ẹlòmíràn. Mo mọ̀ pé Ó wà láàyè Ó sì fẹ́ràn yín. “Gbàdúrà, Ó wà níbẹ̀.” Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.