Àwọn Ìwé Mímọ́
Ọ̀rọ̀ Àsọṣãjú


Ọ̀rọ̀ Àsọṣãjú

Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ àpapọ̀ ìwé mímọ́ tí a lè fi wé Bíbélì. Ó jẹ́ ìwé ìrántí ìbáló Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn olùgbé ilẹ̀ Amẹ́ríkà lápapọ̀ ní atijọ́, ó sì ní ẹ̀kún ìhìn-rere àìlópin nínú.

A kọ ìwé nã látí ọwọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlĩ àtijọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn. Àwọn ọ̀rọ̀ wọn, tí a kọ sórí àwọn àwo wúrà, ni wòlĩ-òpìtàn kan tí á n pe orúkọ rẹ̀ ní Mọ́mọ́nì tún wí tí ó sì ké kúrú. Ìwé ìrántí nã fún ni ní ìwé ìtàn ọ̀làjú nlá méjì. Ọ̀kan wá láti Jerúsálẹ́mù ní ẹgbẹ̀ta ọdún kí á tó bí Krístì, lẹ́hìnnã tí wọ́n pín sí orílẹ̀-èdè méjì, tí a mọ̀ sí àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì. Òmíràn ti wá síwájú nígbà tí Olúwa da ahọ́n rú ní Ilé ìṣọ́ gíga Bábélì. Ẹ̀yà yí ni a mọ̀ sí àwọn ará Járẹ́dì. Lẹ́hìn ẹgẹ̃gbẹ̀rún ọdún, gbogbo wọn ni a parun àfi àwọn ará Lámánì, wọ́n sì wà ní ãrin àwọn bàbá-ńlá àwọn ará Indíà ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Ìṣẹ̀lẹ̀ àṣekagbá tí a kọ sínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Jésù Krístì Olúwa ṣe fúnra rẹ̀ lãrín àwọn ará Nífáì ní kété lẹ́hìn àjínde rẹ̀. Ó mú àwọn ẹ̀kọ́ ìhìn-rere jáde, ó fi ìlànà ìgbàlà lélẹ̀ lẹ́sẹsẹ, ó sì sọ fún àwọn ènìyàn ohun tí wọn kò lè ṣàìṣe láti rí àlãfíà gbà ní ayé yí àti ìgbàlà ayérayé ní ayé tí mbọ̀.

Lẹ́hìn tí Mọ́mọ́nì parí àwọn ìkọ̀wé rẹ̀, ó jọ̀wọ́ ìwé ìtàn nã fún ọmọ rẹ̀ Mórónì, ẹni tí ó fi àwọn ọ̀rọ̀ tirẹ̀ díẹ̀ kún un tí ó sì gbé àwọn àwo nã pamọ́ ní òkè Kùmórà. Ní ọjọ̀ kọkànlélógún oṣù kẹsán, ọdún 1823, Mórónì kannã, ẹ̀dá tí a ti ṣe lógo tí ó sì ti jínde nígbànã, farahàn sí Wòlĩ Joseph Smith ó sì kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ nípa ti ìwé ìrántí ti àtijọ́ nã àti ìyírọ̀padà rẹ̀ tí a ti pinnu sí èdè Gẹ̃sì.

Nígbàtí àkókò tó ó jọ̀wọ́ àwọn àwo nã fun Joseph Smith, ẹni tí ó yí ọ̀rọ̀ wọn padà nípasẹ̀ ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run. Ìwé ìrántí nã ni a wá tẹ̀ báyĩ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí titun àti àfikún pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run alãyè, àti kí gbogbo ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí ó bá sì gbọ́ran sí àwọn òfin àti ìlànà ìhìn-rere rẹ̀ lè rí ìgbàlà.

Nípa ìwé ìrántí yí Wòlĩ Joseph Smith wí pé: “Mo sọ fún àwọn arákùnrin pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ó pé jù ìwé èyíkéyí lọ lórí ilẹ̀ ayé, ó sì jẹ́ òkúta-ìṣíkà ìsìn wa, ènìyàn yíò sì súnmọ́ Ọlọ́run nípa bíbá àwọn ìlànà rẹ̀ gbé, ju ti ìwé èyíkéyí míràn.”

Ní àfikún sí Joseph Smith, Olúwa pèsè àwọn mọ́kànlá míràn láti rí àwọn àwo wúrà nã tìkaláawọn àti láti jẹ akanṣe ẹlẹ́rĩ pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ òtítọ́ ati ohun ti Ọ̀run. Àwọn ẹ̀rí wọn tí a kọ ni a fi pẹ̀lú níhìn yĩ gẹ́gẹ́bĩ “Ẹ̀rí Àwọn Ẹlẹ́ri Mẹ́ta” àti “Ẹ̀rí Àwọn Ẹlẹ́ri Mẹ́jọ.”

A pe gbogbo ènìyàn níbigbogbo láti ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, láti rò ní ọkàn wọn ìhìn tí ó wà nínú rẹ̀, nígbànã kí wọ́n sì bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, ní orúkọ Krístì bí ìwé nã bá jẹ́ òtítọ́. Àwọn tí ó bá lépa ipa ọ̀nà yí tí wọ́n sì bèrè ní ìgbàgbọ́ yíò jèrè ẹ̀rí pé ó jẹ́ òtítọ́ àti ti ọ̀run nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́. (Wo Mórónì 10:3–5.)

Àwọn tí ó bá gba ẹ̀rí ti ọ́run yí láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ yíò wá mọ̀ pẹ̀lú nípa agbára kannã pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà ayé, pé Joseph Smith ni olùfihàn àti wòlĩ rẹ̀ ní awọn ọjọ́ ìkẹhìn yĩ, àti pé Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti ọjọ́ Ìkẹhìn ni ìjọba Olúwa tí a tún gbé kalẹ̀ lẹ̃kan sí i lórí ilẹ̀ ayé, ní ìmúrasílẹ̀ fun bíbọ̀ ẹlẹkejì ti Messia.

Ẹ̀rí Àwọn Ẹlẹ́ri Mẹ́ta

A fẹ́ kí ó jẹ́ mímọ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí iṣẹ́ yí yíò wá: Pé àwa, nípa õre-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Bàbá, àti Jésù Krístì Olúwa wa, ti rí àwọn àwo èyí tí ó ní ìwé ìrántí yí nínú, èyí tí ó jẹ́ ìwé ìrántí àwọn ènìyàn Nífáì, àti pẹ̀lú ti àwọn ará Lámánì, àwọn arákùnrin wọn, àti pẹ̀lú ti àwọn ènìyan Járẹ́dì, tí wọ́n wá láti ilé ìṣọ́ gíga èyí tí a ti sọ̀ nípa rẹ. A sì mọ̀ pẹ̀lú pé a ti yí wọn padà sí èdè míràn nípa ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run, nítorí ohùn rẹ̀ ti sọ ọ́ fún wa; nítorí-èyi a mọ̀ dájú pé òtítọ́ ni iṣẹ́ nã. A sì jẹ́rĩ pẹ̀lú pé a ti rí àwọn ìfín èyí tí ó wà lórí àwọn àwo nã; a sì ti fi wọ́n hàn fún wa nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run, kì í sì ṣe tí ènìyàn. A sì sọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́, pé angẹ́lì Ọlọ́run kan sọ́kalẹ̀ láti ọ̀run, ó sì mú wọn wá ó sì gbé wọn kalẹ̀ níwájú wa, tí a sì kíyèsĩ tí a sì rí àwọn àwo nã, àti àwọn ìfín ti orí rẹ̀; a sì mọ̀ pé nípa õre-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Bàbá, àti Jésù Krístì Olúwa wa, ni àwa fi kíyèsĩ tí a sì jẹ́rĩ pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́. Ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa. Bíótilẹ̀riẹ̃, ohùn Olúwa pàṣẹ fún wa pé kí á jẹ́rĩ rẹ̀; nítorí-èyi, láti ní ìgbọ́ran sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run, a jẹ́rĩ àwọn ohun wọ̀nyí. A sì mọ̀ pé bí a bá jẹ́ olódodo nínú Krístì, àwa yíò gba aṣọ wa kúrò ní ẹ̀jẹ̀ gbogbo ènìyàn, a ó sì wa láìlábàwọ́n níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì, a ó sì gbé pẹ̀lú rẹ̀ títí ayérayé ní ọ̀run. Ki ọlá nã sì jẹ́ sí Bàbá, àti sí Ọmọ, àti sí Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí íṣe Ọlọ́run kan. Àmín.

Oliver Cowdery

David Whitmer

Martin Harris

Ẹ̀rí Àwọn Ẹlẹ́ri Mẹ́jọ

A fẹ́ kí ó jẹ́ mímọ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn, si ọ̀dọ̀ àwọn tí iṣẹ́ yí yíò wá: Pé Joseph Smith, Kékeré, olùtúmọ̀-èdè iṣẹ́ yí, ti fi àwọn àwo èyí tí a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ hàn wá, èyí tí ó dàbí wúrà; gbogbo àwọn ojú-ewé tí Smith tí a sọ yí ti tumọ ni a ti dìmú pẹ̀lú ọwọ́ wa; a sì rí àwọn ìfín ti orí rẹ̀ pẹ̀lú, gbogbo èyí tí ó ní ìfarahàn iṣẹ́ àtijọ́, àti ọgbọ́n iṣẹ́ tí ó ṣọ́wọ́n. Èyí ni a sì jẹ́rĩ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́, pé Smith tí a sọ nã ti fi hàn wá, nítorí a ti rí i a sì ti gbé e yẹ̀wò, a sì mọ̀ dájú pé Smith tí á sọ nã ti gba àwọn àwo èyí tí a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. A sì fi orúkọ wa fún gbogbo ayé, láti jẹ́rĩ fún gbogbo ayé ohun èyí tí a ti rí. Àwa kò sì purọ́, Ọlọ́run n jẹ́rĩ rẹ̀.

Christian Whitmer

Hiram Page

Jacob Whitmer

Joseph Smith, Àgbà

Peter Whitmer, Kékeré

Hyrum Smith

John Whitmer

Samuel H. Smith

Ẹ̀rí Wòlĩ Joseph Smith

Àwọn ọ̀rọ̀ Wọ̀lĩ Joseph Smith fúnrarẹ̀ nípa jíjáde wá Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni:

“Ní àṣãlẹ́…ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹsán [ọdún 1823]…Mo dáwọ́lé àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run Olódùmarè. …

“Nígbà tí mo wà ní ipò pípe Ọlọ́run, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan tí ó ńtàn wá nínú yàrá mi, èyí tí ó sì ńpọ̀ si títí tí yàrá nã fi mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan, lẹ́sẹ̀kan nã ẹni nlá kan fi ara hàn ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi, tí ó dúró ní òfúrufú, nítorí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò kan ilẹ̀.

“Ó wọ ẹ̀wù tí ó ṣò, tí funfun rẹ̀ ni ógo jùlọ. Ó funfun ju ohunkóhun ní ayé tí mo ti rí; nkò sì gbàgbọ́ pé a lè mú ohunkóhun ní ayé láti funfun kí ó sì kọ mọ̀nà tó bẹ̃. Aṣọ kò bò àwọn ọwọ́ rẹ̀, àti awọn apá rẹ̀ pẹ̀lú, díẹ̀ sókè àwọn ọrùn-ọwọ́; bẹ̃nã, pẹ̀lú, ni aṣọ kò bo awọn àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀, bí ti ẹsẹ̀ rẹ̀, díẹ̀ sókè ọrùn ẹsẹ̀. Orí rẹ̀ àti ọrùn rẹ̀ wà láìbò pẹ̀lú. Mo lè sọ pé kò wọ aṣọ míràn sọ́rùn àfi ẹ̀wù yí, bí ó ṣe ṣí sílẹ̀, tí mo lè rí àyà rẹ̀.

“Kì í ṣe ẹ̀wù rẹ̀ nìkan ni ó funfun lọ́pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ara rẹ̀ lógo kọjá àpèjúwe, ìrísí rẹ̀ sì yọ bí mànàmáná. Yàrá nã mọ́lẹ̀ rékọjá, ṣùgbọ́n ko mọ́lẹ̀ gan-an tó bí àyíká ara rẹ̀. Nígbàtí mo wò ó lẹ̃kíní, ẹ̀rù bà mí; ṣùgbọn ẹ̀rù nã fi mí sílẹ̀ láìpẹ́.

“Ó pè mí ní orúkọ mi, ó sì wí fún mi pé òun ni ìránṣẹ́ tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí mi, àti pé orúkọ òun ni Mórónì; pé Ọlọ́run ní iṣẹ́ fún mi láti ṣe; àti pé orúkọ mi ni a ó ní fún rere àti búburú lãrín gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, àti èdè, tàbí pé a ó sọ ọ ní rere àti búburú lãrín gbogbo ènìyàn.

“Ó ní iwé kan wà tí a filélẹ̀, tí a kọ sórí àwọn àwo wúrà, tí ó fún ni ní ìwé ìtàn àwọn olùgbé ti tìṣájú ti ìpínlẹ̀-ayé yí, àti orísun ibi tí wọ́n ti sun jáde. Ó sọ pẹ̀lú pé ẹ̀kún Ìhìn-rere àilòpin nì ni a ní nínú rẹ̀, bí Olùgbàlà ti fi sílẹ̀ fún àwọn olùgbé àtijọ́;

“Pẹlú-pẹ̀lù, pé Òkúta méjì wà nínú ọpọ́n fàdákà—àwọn òkúta wọ̀nyí, tí a so mọ́ ìgbàya kan, sì ni ohun tí à npè ní Úrímù àti Túmímù—tí a fi lélẹ̀ pẹ̀lú àwọn àwo nã; ìní àti ìlò àwọn òkúta wọ̀nyí ni ohun tí à npè ní Aríran ní àwọn ìgbà àtijọ́ tàbi ìgbà ìṣãjú; àti pé Ọlọ́run ti pèsè wọn fún ète ìtúmọ̀ iwé nã.

· · · · · · ·

“Ẹ̀wẹ̀, ó sọ fún mi, pé nígbà tí mo bá gba àwọn àwo wọnnì nípa èyí tí ó ti sọ—nítorí àkókò tí a ó gbà wọ́n ni a kò ì tí ì múṣẹ—Èmi kò gbódọ̀ fi wọ́n hàn sí ẹnikẹ́ni; bẹ̃ni ìgbàyà nã pẹ̀lú Úrímù àti Túmímù nã; àfi sí àwọn wọnnì nìkan tí a ó pàṣẹ fún mi láti fi hàn; bí mo bá ṣe é a ó pa mí run. Ní àkókò tí ó n sọ̀rọ̀ pẹ̀lú mi nípa àwọn àwo nã, a ṣí ìran nã sínú iyè mi, tí ó jẹ́ wípé mo lè rí ibi tí a fi àwọn àwo nã lélẹ̀ sí, àti tí ó rí kedere tí ó sì yàtọ̀ tí mo tún mọ́ ibẹ́ nígbà tí mo bẹ̀ ẹ́ wò.

“Lẹ́hìn ọ̀rọ̀ yí, mo rí ìmọ́lẹ̀ inú yàrá nã tí ó bẹ̀rẹ̀ sí nkó jọ lọ́gán ní àyíká ara ẹni tí ó ti n bá mi sọ̀rọ̀, ó sì n ṣe bẹ́ ẹ̀ lọ, títí tí yàrá nã tún padà ṣókùnkùn, àfi ní àyíká rẹ̀ gan, nígbànã ní mo rí i lójúkannã, bí o ṣe rí, ọ̀nà kan tí ó ṣí tãrà sókè sí ọ̀run, ó sì gòkè lọ títí ó fi farasin pátápátá, yàrá nã ni a sì fi sílẹ̀ bí ó ṣe wà kí ó tó di pé ìmọ́lẹ̀ ọ̀run yí ṣe ìfarahàn rẹ̀.

“Mo sùn sílẹ̀ mọ̀ nronú lórí ohun àrà tí ó ṣẹlẹ̀, ní ìyanu nlá sí ohun tí ìránṣẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ yí ti sọ fún mi; nígbàtí, ní ãrín ìṣãrò mi, mo dẽdé ríi tí yàrá mi tún bẹ̀rẹ̀sí mọ́lẹ̀, lójúkannã, ìránṣẹ́ ọ̀run kannã sì tún ti wà ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi.

“Ó bẹ̀rẹ̀, ó tún nsọ àwọn ohun kannã èyí tí ó ti sọ ní àbẹ̀wò àkọ́kọ́ rẹ̀, láìsí ìyàtọ̀ kankan; lẹ́hin eyi, o wí fún mi nípa ìdájọ́ nlá tí ó mbọ̀wá sórí ayé, pẹ̀lú ìsọdahóró nlá nípa ìyàn, idà, àti àjàkálẹ̀-àrùn; àti pé àwọn ìdájọ́ tí mbáni nínú jẹ́ wọ̀nyí yíò wá sí ayé ní ìran yí. Lẹ́hìn tí ó ti sọ àwọn ohun wọ̀nyí, ó tún gòkè lọ bí ó ti ṣe ní àkọ́kọ́.

“Ní àsìkò yí, àwọn ohun tí a tẹ̀ mọ́ ọkàn mi jinlẹ̀ gan-an, tí õrun ti sá kúrò lójú mi, mo sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ní ìyanu sí ohun tí mo tí rí àti tí mo gbọ́. Ṣùgbọ́n kí ni ìyàlẹ́nu mi nígbàtí mo tún kíyèsĩ ìránṣẹ́ kannã ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi, mo sì gbọ́ ọ tí ó tún kà tàbí tún sọ fún mi ẹ̀wẹ̀ àwọn ohun kannã bí ti àtẹ̀hìnwá; ó sì fún mi ní ìkìlọ̀, ó n sọ fún mi pé Sátánì yíò gbìyànjú láti dán mi wò (nítorí ti ipò aláìní tí ìdílé bàbá mi wà), láti gba àwọn àwo nã fún kíkó ọrọ̀ jọ. Èyí ni ó dá mi lẹ́kun sí, ó wí pé èmi kò gbọ́dọ̀ ní ìdí míràn lọ́kàn ní gbígba àwọn àwo bíkòṣe láti yin Ọlọ́run lógo, n kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìdí míràn ní ipa lórí mi ju ti kíkọ́ ìjọba Rẹ̀; bí bẹ̃kọ́ èmi kò lè rí wọn gbà.

“Lẹ́hìn àbẹ̀wò ẹlẹ̃kẹ́ta yí, ó tún gòkè lọ sí ọ̀run bí ti tẹ́lẹ̀, a sì tún fi mí sílẹ̀ láti ro àjèjì ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ìrírí; nígbàtí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbàrà tí ìránṣẹ́ ọ̀run yí n gòkè lọ ní ìgbà ẹ̀kẹ́ta, àkùkọ́ kọ, mo sì rí i pé ọjọ́ ti nsúnmọ́, ó jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ wa ti gba gbogbo òru ọjọ́ nã.

“Láìpẹ́, lẹ́hìn nã mo dìde kúrò ní ibùsùn mi, bí ti àtẹ̀hinwá, mo sì lọ ṣe àwọn iṣẹ́ õjọ́ tí a kò lè ṣe aláìṣe; ṣùgbọ́n, bí mo ti ngbìyànjú láti ṣiṣẹ́ bí ti àwọn ìgbà míràn, mo rí i pé agbára mi ti lọ tán tí ó mú mi láìlẹ́ṣẹ̀ ohun kánkán. Bábà mi, ẹni tí o nsiṣẹ́ pẹ̀lú mi, rí i pe ohun kan nṣe mí, ó si wí fún mi kí n lọ sí ilé. Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èrò lílọ sí ilé; ṣùgbọ́n, bí mo ti ngbìyànjú láti dá ọgbà kọjá kúrò ní pápá èyí tí a wà, agbára mi kùnà pátápátá, mo sì ṣubú lulẹ̀ láìní ìrànlọwọ́, fún ìgbà diẹ̀ nkò sì mọ́ ohunkóhun rárá.

“Ohun èkíní ti mo rántí ni ohùn kan tí ó bá mi sọ̀rọ̀, tí ó n pè mí ni orúkọ. Mo wo òkè, mo sì kíyèsĩ ìránṣẹ́ kannã tí ó dúró lókè sórí mi, tí ìmọ́lẹ̀ yí i ká bí ti tẹ́lẹ̀. Ó sì tún rò fún mi gbogbo ohun tí ó ti ròhìn fún mi ní òru ti ìṣãjú, ó sì pàṣẹ fún mi láti lọ bá bàbá mi kí n sì sọ fún un nípa ìran àti àwọn àṣẹ èyí tí mo ti gbà.

“Mo gbọ́ran; mo padà sọ́dọ̀ bàbá mi ní pápá, mo sì ro gbogbo ọ̀rọ̀ nã fún un. Ó dá mi lóhùn pé ó jẹ́ ti Ọlọ́run, ó sì sọ fún mi láti lọ ṣe bí ìránṣẹ́ nã ti pàṣẹ. Mo kúrò ní pápá nã, mo sì lọ sí ibi tí ìránṣẹ́ nã sọ fún mi pé a fi àwọn àwo nã lélẹ̀ sí; nítorí ti dídáṣáká ìran èyí tí mo ti ní nípa rẹ̀, mo mọ́ ibẹ̀ lójúkannã tí mo dé ibẹ̀.

“Nítòsí ìletò Manchester, ní ìbílẹ̀ Ontario, ní ìpínlẹ̀ New York, ni òkè gíga kan dúró, ó sì ga ju èyíkéyi ní agbègbè nã lọ. Ní apá ìwọ̀-oòrùn òkè yí, tí ko jìnà sí òkè lábẹ́ òkúta kan tí ó tóbi, ni àwọn àwo nã wà, tí a fi lélẹ̀ nínú àpótí òkúta kan. Òkúta yí nípọn ó sì rí roboto ní ãrín apá òkè, ó sì tínrín níhà etẽtí, tí apá ãrín rẹ̀ ṣe é rí láti òkè, ṣùgbọ́n etẽtí rẹ̀ yíká ni erùpẹ̀ bò.

“Lẹ́hìn tí mo ti mú erùpẹ̀ nã kuro, mo rí igi kan tí ó lè gbé nkan sókè, èyí tí mo tì bọ abẹ́ etẽtí òkúta nã, pẹ̀lú agbára díẹ̀ mo sì gbé e sókè. Mo wo inú rẹ̀, níbẹ̀ nítõtọ́ ni mo sì kíyèsĩ àwọn àwo nã, Úrímù àti Túmímù, àti ìgbàyà, bí ìránṣẹ́ nã ti lã lẹ́sẹ̃sẹ. Àpótí èyí tí wọ́n wà nínú rẹ̀ ni a ṣe nípa kíkó àwọn òkúta jọ sínú irú amọ̀ líle kan. Ní ìsàlẹ̀ àpótí nã ni a kó òkúta méjì níbũbú àpótí nã, ní orí àwọn òkúta wọ̀nyí ni àwọn àwo àti àwọn ohun míràn wà.

“Mo gbìyànjú láti gbé wọn jáde, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ nã dá mí lẹ́kun, ó sì tún wí fún mi pé àkókò gbígbé wọn jáde wá kò ì tí ì dé, bẹ̃ni kò ní dé, títí ọdún mẹ́rin láti àkókò nã; ṣùgbọ́n ó sọ fún mi pé kí n wá sí ibẹ̀ ní ọdún kan gẹ̃ láti ìgbà nã, àti pé òun yíò pàdé mi níbẹ̀, àti pé kí èmi máa ṣe bẹ̃ títí àkókò nã yíò dé fún gbígba àwọn àwo nã.

“Bẹ̃gẹ́gẹ́, bí a ṣe pàṣẹ fún mi, mo nlọ ní òpin ọdún kọ̃kan, ní ìgbà kọ̃kan ni mo sì nrí ìránṣẹ́ kannã níbẹ̀, tí mo sì ngba ẹ̀kọ́ àti òye lọ́wọ́ rẹ̀ ní ọ̀kọ̃kan àwọn ọ̀rọ̀ àjọsọ wa, nípa ohun tí Olúwa yíò ṣe, àti báwo àti ní ọ̀nà wo ni a ó fi ṣe àkóso ìjọba Rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn.

· · · · · · ·

“Níkẹhìn, àkókò de fún gbígba àwọn àwo nã, Úrímù àti Túmímù, àti ìgbàyà nã. Ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹ́san, ọdún 1827, bí mo ṣe lọ bí ti àtẹ̀hìnwá ní òpin ọdún míràn sí ibi tí a fi wọ́n lélẹ̀ sí, ìránṣẹ́ ọ̀run kannã gbé wọn fún mi pẹ̀lú àṣẹ yí: Pé kí èmi kí ó tọ́jú wọn; pé bí èmi bá jẹ́ kí wọ́n lọ láìbìkítà, tàbí nípa àìfiyèsí tèmi, a ó ké mí kúrò; ṣùgbọ́n pé bí èmi bá lo gbogbo ìyànjú mi láti pa wọ́n mọ́, títí òun, ìránṣẹ́ nã, yíò padà wá fún wọn, a ó dábò bò wọ́n.

“Láìpẹ́ ni mo rí ìdí tí mo ti fi gba írú àṣẹ líle láti pa wọ́n mọ́, àti ìdí tí ìránṣẹ́ nã fi sọ pé nígbà tí èmi bá ti ṣe ohun tí a fẹ́ lọ́wọ́ mi, òun yíò padà wá fún wọn. Nítorí kò pẹ́ tí àwọn ènìyàn mọ̀ pé mo ní wọn, tí wọ́n nlo ìgbìyànjú tí ó lágbára jùlọ láti gbà wọ̀n lọ́wọ́ mi. Gbogbo àrékérekè tí a lè dọ́gbọ́n ni wọ́n lò fún èté nã. Inúnibíni nã wá korò, ó sì roro ju tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì nṣọ́ra títí láti gbà wọ́n lọ́wọ́ mi bí ó bá ṣeéṣe. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ Ọlọ́run, wọ́n wà láìléwu ní ọwọ́ mi, titi nwọn o fi ran mi lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí àwọn ohun ti a fẹ́ láti ọ́wọ́ mi. Nígbàtí ìránṣẹ́ nã padà wá fún wọn, gẹ́gẹ́bí a ti ṣe ètò rẹ̀, mo gbé wọn fún un; wọ́n sì wà ní ìpamọ́ rẹ̀ títí ọjọ́ yí, tí n ṣe ọjọ́ kejì oṣù karún, ọdún 1838.”

Fún ìwé ìrántí ní kíkún, wo Joseph Smith—Ìwé Ìtàn, nínú Perlì Olówó Iyebíye, àti Ìwé Ìtàn ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Igba Ìkẹhìn, apá kíni, orí kíní dé ẹ̀kẹfà.

Bayi ni a mú ìwé ìrántí àtijọ́ jáde wá láti ilẹ̀ bí ohùn tí ó nsọ̀rọ̀ láti inú eruku wá, tí a sì yí ọ̀rọ̀ rẹ padà sí èdè ìgbà ìsisìyí nípa ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run èyítí a ṣe ijẹri sí nípa ìtẹnumọ́ ti Ọlọ́run, tí a kọ̀kọ́ tẹ sí gbogbo ayé ní èdè Gẹ̃sì ní ọdún 1830 gẹ́gẹ́ bí The Book of Mormon.